Rírí Ìtùnú Nínú “Àfonífojì Ibú Òjìji”
Bí Barbara Schweizer ṣe sọ ọ́
Nígbà mìíràn, tí nǹkan ti ń ṣẹnu-unre, ìgbésí ayé mi ti dà bí “pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko.” Ṣùgbọ́n mo tún ti mọ bí ó ṣe rí láti rìn ní “àfonífojì ibú òjìji.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó dá mi lójú pé, nítorí pé Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn wa, a lè kápá ipò èyíkéyìí tí ó bá yọjú.—Sáàmù 23:1-4.
NÍ ỌDÚN 1993, tí èmi àti ọkọ mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé 70 ọdún, a pinnu láti gbé iṣẹ́ tuntun kan ṣe—sísìn ní ibi tí àìní fún àwọn olùkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbé pọ̀ ní Ecuador. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Amẹ́ríkà ni wọ́n bí wa sí, a ń sọ èdè Spanish, ẹrù ìnáwó kankan kò sì sí lọ́rùn wa. Níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé ‘pípẹja ènìyàn’ lérè nínú ní Ecuador, a ṣètò láti dẹ àwọ̀n wa sínú àwọn omi amérèwá wọ̀nyẹn.—Mátíù 4:19.
Lẹ́yìn ọjọ́ aláyọ̀ bí mélòó kan ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Ecuador, a lọ sí ibùdókọ̀ tó wà ní Guayaquil, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà láti lọ sí Machala—ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá tí àìní pàtàkì kan wà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, níbi tí a ti ń dúró de ọkọ̀, àìsàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ọkọ mi, Fred, lójijì, nítorí náà, a pinnu láti dá ìrìn àjò wa dúró. Fred jókòó ti ẹrù wa, èmi sì lọ síbi àpótí tẹlifóònù láti ṣètò kí a lè padà sí ọ́fíìsì ẹ̀ka. Nígbà tí mo padà lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, n kò rí ọkọ mi!
N kò tún rí Fred láàyè mọ́. Ní ibùdókọ̀, nígbà tí n kò sí níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ó ti ní ìṣòro àìlùkìkì ọkàn-àyà tí ó le. Bí mo ṣe ń já lanba nígbà tí mo ń wá a, òṣìṣẹ́ kan ní ibùdókọ̀ náà wá bá mi, ó sì sọ fún mi pé wọ́n ti gbé Fred lọ sí ilé ìwòsàn. Nígbà tí mo dé ilé ìwòsàn, mo gbọ́ pé ó ti kú.
Lójijì, mo rí ara mi lémi nìkan ní orílẹ̀-èdè ṣíṣàjèjì kan, láìsí ibùgbé, tí kò sì sí ọkọ tí mo lè gbára lé. Mo sọ pé, “tí mo lè gbára lé” nítorí pé Fred ló sábà máa ń mú ipò iwájú, tí ó sì máa ń ṣètò àwọn nǹkan fún àwa méjèèjì. N kò fi bẹ́ẹ̀ láyà, inú mi sì máa ń dùn pé ó ń mú ipò iwájú. Àmọ́ nísinsìnyí, mo ní láti ṣe àwọn ìpinnu, kí n ṣètò ìgbésí ayé mi, kí n sì borí ẹ̀dùn ọkàn mi lákòókò kan náà. Ìmọ̀lára tí ń múni banú jẹ́ gbáà ni—bí pé wọ́n jù mí sínú “àfonífojì ibú òjìji.” N óò ha kọ́ láti lè dá nǹkan ṣe fúnra mi bí?
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ àti Mímú Ìgbésí Ayé Wa Rọrùn
Èmi àti Fred ti bá àwọn ẹlòmíràn ṣègbéyàwó rí, a sì ti ṣe ìkọ̀sílẹ̀ nígbà tí a pàdé ara. Ìbáṣọ̀rẹ́ rere kan gbèrú di ipò ìbátan tímọ́tímọ́, a sì pinnu láti ṣègbéyàwó. A wulẹ̀ jẹ́ olùreṣọ́ọ̀ṣì ṣáá ní Seattle, Washington, U.S.A. Ṣùgbọ́n ìsìn kì í ṣe ohun pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé wa títí di ìgbà tí Jamie, ọ̀dọ́ aṣáájú ọ̀nà (ajíhìnrere alákòókò kíkún) kan tí ó ṣèèyàn, wá sí ẹnu ọ̀nà wa. Ó ṣèèyàn gan-an débi pé mo tẹ́wọ́ gba ìfilọni rẹ̀ láti bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Bí Fred pẹ̀lú ti fi ìfẹ́ hàn, àwọn òbí Jamie gba ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ọdún kan lẹ́yìn náà, ní 1968, àwa méjèèjì ṣèrìbọmi. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni fífi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò kíní ti jẹ wá lọ́kàn. (Mátíù 6:33) Dájúdájú, àwọn tọkọtaya tí wọ́n bá wa ṣèkẹ́kọ̀ọ́, Lorne àti Rudi Knust, fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ lọ́nà yìí. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí a ṣèrìbọmi, tí wọ́n kó lọ sí ìlú kan ní Etíkun Ìlà Oòrùn United States, láti sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Èyí gbin ohun kan sọ́kàn wa.
A ní ìdí mìíràn fún ríronú nípa kíkó lọ síbòmíràn. Fred jẹ́ alábòójútó ní ilé ìtajà ńlá kan. Iṣẹ́ rẹ̀ ń gba àkókò gan-an, ó sì mọ̀ pé kíkólọ sí ibòmíràn yóò jẹ́ kí òun lè mú ìgbésí ayé òun rọrùn, kí òun sì túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí òtítọ́ àti àwọn ọmọ wa méjèèjì. Mo tún bí ọmọbìnrin kan, tí ó ti lọ sílé ọkọ, fún ọkọ òwúrọ̀ mi, òun àti ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́, nítorí náà, ìpinnu wa láti fi Seattle sílẹ̀ ṣòro. Síbẹ̀, wọ́n lóye ohun tó sún wa ṣèpinnu náà, wọ́n sì ṣètìlẹ́yìn fún ìpinnu wa.
Bí ó ṣe rí ní 1973 nìyẹn, tí a fi kó lọ sí ilẹ̀ Sípéènì, orílẹ̀-èdè kan níbi tí ó jẹ́ pé nígbà yẹn, àìní jaburata wà fún àwọn oníwàásù ìhìn rere náà àti àwọn arákùnrin láti mú ipò iwájú. Fred ti ronú pé bí a bá ṣúnwó ná, owó tí a ní nípamọ́ yóò tó láti fi ṣe àwọn ohun tí a nílò ní ilẹ̀ Sípéènì, a óò sì lè ya ọ̀pọ̀ jù lọ lára àkókò wa sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ohun tí a sì ṣe gan-an nìyẹn. Láìpẹ́, Fred ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, nígbà tí ó sì di 1983, àwa méjèèjì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà.
A sìn ní ilẹ̀ Sípéènì fún 20 ọdún, a ń kọ́ èdè ibẹ̀, a sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìrírí dáradára. Lọ́pọ̀ ìgbà, èmi àti Fred máa ń wàásù pa pọ̀, a sì ń bá àwọn tọkọtaya, tí àwọn mélòó kan lára wọn ti di Ẹlẹ́rìí tí ó ti ṣèrìbọmi, ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn tí a ti lo ọdún mélòó kan ní ilẹ̀ Sípéènì, àwọn ọmọ wa méjì tí wọ́n kéré jù, Heidi àti Mike, pẹ̀lú tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀, àkókò yìí ni mo láyọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Ìgbésí ayé wa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. A lè lo àkókò púpọ̀ pa pọ̀ bí ìdílé kan, gẹ́gẹ́ bí òróró opó tí a sì sọ nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì, owó tí a ní nípamọ́, tí a ń ṣún ná, kò ṣàìtó wa rí.—1 Àwọn Ọba 17:14-16.
Kíkó Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Mìíràn Lẹ́ẹ̀kan Sí I
Nígbà tí ó di 1992, a tún bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa kíkó lọ sí ibòmíràn. Àwọn ọmọ wa ti dàgbà, àìní tí ó wà ní ilẹ̀ Sípéènì kò sì pọ̀ bí ti tẹ́lẹ̀ mọ́. A mọ míṣọ́nnárì kan tí ó ti ń sìn ní Ecuador, ó sì ti sọ fún wa nípa àìní púpọ̀ gan-an tí ó wà fún àwọn aṣáájú ọ̀nà àti alàgbà ní orílẹ̀-èdè yẹn. A ha ti dàgbà jù láti ronú nípa lílọ tún bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ní orílẹ̀-èdè tuntun kan bí? A kò rò bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí ara àwa méjèèjì ti dá ṣáká, tí a sì nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìwàásù. Nítorí náà, a kàn sí ẹ̀ka ti Ecuador, a sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò. Ní gidi, ọmọbìnrin mi, Heidi, àti ọkọ rẹ̀, Juan Manuel, tí wọ́n ń sìn ní àríwá ilẹ̀ Sípéènì, pẹ̀lú fẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ wa.
Níkẹyìn, nígbà tí ó di February 1993, a ti ta mọ́ra, a sì ti dé orílẹ̀-èdè tuntun tí a ń lọ. Inú àwa méjèèjì dùn sí ìfojúsọ́nà ṣíṣiṣẹ́-aṣáájú-ọ̀nà ní Ecuador, níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ń fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ìkínikáàbọ̀ ọlọ́yàyà ní ọ́fíìsì ẹ̀ka, a wéwèé láti bẹ àwọn ìlú ńlá bí mélòó kan, tí wọ́n dámọ̀ràn bí àwọn ibi tí àìní pàtàkì kan gbé wà, wò. Àmọ́ ìgbà yẹn ni ọkọ mi kú.
Nínú “Àfonífojì Ibú Òjìji”
Lákọ̀ọ́kọ́, àyà mi pami, lẹ́yìn náà àìgbàgbọ́ pátápátá. Fred kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàìsàn tẹ́lẹ̀. Kí ni kí n wá ṣe? Ibo ni kí n wá kọrí sí? N kò wulẹ̀ lè ronú já gaara.
Láàárín àkókò bíburújáì yẹn nínú ìgbésí ayé mi, ìtìlẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ olùgbatẹnirò, tí ó dájú pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kò mọ̀ mí rí, jẹ́ ìbùkún fún mi. Àwọn ará tí wọ́n wà ní ọ́fíìsì ẹ̀ka jẹ́ onínúure gan-an, wọ́n sì bójú tó gbogbo nǹkan, títí kan ètò ìsìnkú. Ní pàtàkì, mo rántí ìfẹ́ tí Arákùnrin àti Arábìnrin Bonno fi hàn sí mi. Wọ́n rí i dájú pé n kò dá nìkan wà rí, Edith Bonno tilẹ̀ sùn tì mí fún ọjọ́ bí mélòó kan kí n má bàa nímọ̀lára ìnìkanwà. Ní ti gidi, ìdílé Bẹ́tẹ́lì lódindi fi ìfẹ́ àti ìgbatẹnirò hàn, tí ó fi dà bí pé wọ́n fi kúbùsù ìfẹ́ lílọ́wọ́ọ́rọ́, adáàbòboni bò mí lára.
Láàárín ọjọ́ mélòó kan, àwọn ọmọ mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti dé ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú, ìtìlẹ́yìn wọn kò sì ṣeé fọwọ́ rọ́ tì. Síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn onífẹ̀ẹ́ ń yí mi ká lọ́sàn-án, líla àwọn òru gígùn já túbọ̀ ṣòro. Ìgbà yẹn ni Jèhófà ṣètìlẹ́yìn fún mi. Ìgbàkigbà tí ìnìkanwà tí ó le koko bá bò mí mọ́lẹ̀, mo máa ń yíjú sí i nínú àdúrà, ó sì ń tù mí nínú.
Lẹ́yìn ìsìnkú, ìbéèrè náà dìde pé, Kí ní yẹ kí n fi ìgbésí ayé mi ṣe? Mo fẹ́ láti dúró sí Ecuador nítorí pé ohun tí a pẹnu pọ̀ pinnu nìyẹn, àmọ́ n kò lérò pé mo lè dá ṣe é. Nítorí náà, Heidi àti Juan Manuel, tí wọ́n ti ń wéwèé láti kó lọ sí Ecuador láìpẹ́, ṣàtúnṣe ìwéwèé wọn kí wọ́n lè máa bọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí gbogbo wa sì lè máa ṣiṣẹ́ sìn pa pọ̀.
Láàárín oṣù kan, a rí ilé kan ní Loja, ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá tí ọ́fíìsì ẹ̀ka ti dámọ̀ràn tẹ́lẹ̀. Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò àwọn nǹkan, tí mo fìdí kalẹ̀ ní ibùgbé tuntun kan, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ní orílẹ̀-èdè tuntun kan. Gbogbo ìgbòkègbodò wọ̀nyẹn dín ẹ̀dùn ọkàn mi kù. Síwájú sí i, mo lè sunkún pẹ̀lú ọmọbìnrin mi, tí ó ti jẹ́ kòríkòsùn Fred gan-an, ìyẹn sì ràn mí lọ́wọ́ láti tú ìmọ̀lára mi jáde.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn oṣù mélòó kan, nígbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò mi tuntun, ìmọ̀lára àdánù ńlá tó ṣẹlẹ̀ sí mi wá lé sí i. Mo wá rí i pé n kò lè ronú nípa àwọn àkókò aláyọ̀ tí èmi àti Fred ti ṣàjọpín nítorí pé ó ń ba ọkàn mi jẹ́ gan-an. Mo ń gbàgbé ìgbà tí ó ti kọjá, kò sì sí ọjọ́ kan tí mo lè ronú ohun púpọ̀ nípa ọjọ́ iwájú. Àmọ́ ojoojúmọ́ ni mo ń gbìyànjú láti máa ṣe ohun tí ó gbámúṣé, ní pàtàkì ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù mi. Ohun tí mo fi ń gbéra nìyẹn.
Mo ti sábà fẹ́ràn wíwàásù àti kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ènìyàn sì máa ń fetí sílẹ̀ gan-an ní Ecuador tí ó fi jẹ́ kí iṣẹ́ náà gbádùn mọ́ni. Nígbà kan lára àwọn ìgbà tí mo kọ́kọ́ jáde nínú iṣẹ́ ilé dé ilé níbẹ̀, mo bá ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ abilékọ kan pàdé, ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì!” Òun ni mo kọ́kọ́ bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Ecuador. Irú ìrírí yẹn gba àfiyèsí mi, kò sì jẹ́ kí n máa ronú jù nípa ìbànújẹ́ mi. Jèhófà bù kún iṣẹ́ ìsìn pápá mi gidigidi. Ó jọ pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìgbà tí mo bá jáde lọ wàásù ìhìn rere náà ni mo ń ní ìrírí tí ó dára.
Láìsí àní-àní, bíbá a lọ láti máa sìn bí aṣáájú ọ̀nà jẹ́ ìbùkún kan. Ó fún mi ní iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe kan ṣe, ó sì pèsè ohun títọ̀nà láti máa ṣe lójoojúmọ́. Láìpẹ́ láìjìnnà, mo ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́fà.
Láti ṣàpèjúwe ìtẹ́lọ́rùn tí mo ń rí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi, ẹ jẹ́ kí n mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ obìnrin kan tí kò tí ì dàgbà jù tí ó fi ìmọrírì hàn fún àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì láìpẹ́ yìí. Nígbà tí mo fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan hàn án, ó kọ́kọ́ fẹ́ lóye rẹ̀ dáradára, lẹ́yìn náà, ó fẹ́ láti fi ìmọ̀ràn tí ó wà níbẹ̀ ṣèwàhù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ń gbé ìgbésí ayé oníwà-pálapàla nígbà kan rí, nígbà tí ọkùnrin kan, tí ó fẹ́ kí ó máa bá òun gbé, fi ìbálòpọ̀ lọ̀ ọ́ láìpẹ́ yìí, ó kọ̀ jálẹ̀jálẹ̀. Ó sọ bí inú òun ti dùn tó láti rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ìwé Mímọ́ fún mi, níwọ̀n bí òun ti wá ń gbádùn ìfọ̀kànbalẹ̀ tí òun kò ní rí. Irú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn ń mú ọkàn àyà mi yọ̀, wọ́n sì ń mú kí n nímọ̀lára pé mo wúlò.
Níní Ayọ̀ Nìṣó
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ sísọnidi-ọmọ-ẹ̀yìn ń mú ayọ̀ púpọ̀ wá fún mi, ẹ̀dùn ọkàn mi kò yára lọ. Nínú ọ̀ràn mi, bí ìbànújẹ́ ti ń wá ni ó ń lọ. Ọmọbìnrin mi àti àna mi ti ṣètìlẹ́yìn àgbàyanu fún mi, àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí mo bá rí i tí wọ́n ń gbádùn àwọn àkókò àkànṣe pa pọ̀, àdánù tó ṣẹlẹ̀ sí mi túbọ̀ máa ń mú mi banú jẹ́ gan-an. Aáyun ọkọ mi ń yun mi gan-an, kì í ṣe kìkì nítorí pé kòríkòsùn ni wá àmọ́ nítorí pé òun ló ń ṣe ohun púpọ̀ fún mi. Àwọn àkókò wà tí àìlè bá a sọ̀rọ̀, àìlèbéèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ rẹ̀, tàbí àìlèṣàjọpín ìrírí iṣẹ́ ìsìn pápá pẹ̀lú rẹ̀ ń fa ìbànújẹ́ àti àìjámọ́ǹkan tí kò rọrùn rárá láti kojú rẹ̀.
Kí ló ń ràn mí lọ́wọ́ ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀? Mo ń fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì ń ní kí ó ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ kí n máa ronú nípa ohun mìíràn, ohun títọ̀nà. (Fílípì 4:6-8) Ó sì ràn mí lọ́wọ́ ní tòótọ́. Ní báyìí, lẹ́yìn ọdún mélòó kan, mo ń lè sọ nípa àwọn àkókò aláyọ̀ tí èmi àti Fred gbádùn pa pọ̀. Ó ṣe kedere pé ìgbésẹ̀ ìkọ́fẹpadà náà ń ní ipa rẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Bí onísáàmù náà, Dáfídì, mo nímọ̀lára pé mo ti rìn ní “àfonífojì ibú òjìji.” Ṣùgbọ́n Jèhófà wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti tù mí nínú, àwọn ará olùṣòtítọ́ sì fi inú rere tọ́ mi sí ọ̀nà títọ́.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí Mo Ti Kọ́
Bí ó ti jẹ́ pé Fred ló sábà máa ń mú ipò iwájú, n kò fìgbà kan ronú pé n óò lè máa bá a lọ ní dídá-nǹkan-ṣe fúnra mi. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ìdílé mi, àti àwọn ará, mo ti fàyà rán an. Ní àwọn ọ̀nà kan, mo ti lókun ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Mo sábà máa ń yíjú sí Jèhófà ju bí mo ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ, mo sì ń kọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu fúnra mi.
Inú mi dùn gan-an pé èmi àti Fred ti lo gbogbo 20 ọdún wọ̀nyẹn ní ilẹ̀ Sípéènì ní sísìn pa pọ̀ ní ibi tí àìní gbé pọ̀. Nínú ètò àwọn nǹkan yìí, a kò mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, nítorí náà, mo rò pé ó ṣe pàtàkì gan-an láti sa gbogbo ipá wa nínú iṣẹ́ Jèhófà àti fún ìdílé wa nígbà tí a ní àǹfààní rẹ̀. Àwọn ọdún wọ̀nyẹn mú ìgbésí ayé wa àti ìgbéyàwó wa sunwọ̀n lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì dá mi lójú pé wọ́n múra mi sílẹ̀ láti kojú àdánù tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi. Níwọ̀n bí ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà ti di ọ̀nà ìgbésí ayé mi tẹ́lẹ̀ kí Fred tó kú, ó fún mi ní èrò níní ètè nígbà tí mo ń tiraka láti gba kámú.
Nígbà tí Fred kú, lákọ̀ọ́kọ́, ó jọ pé ìgbésí ayé tèmi pẹ̀lú ti dópin. Ṣùgbọ́n, dájúdájú, ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Mo ní iṣẹ́ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mo sì ní àwọn ènìyàn láti ràn lọ́wọ́. Lójú òtítọ́ náà pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n wà láyìíká mi ṣì nílò òtítọ́, mo ṣe ní láti jáwọ́? Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ṣèrànwọ́ fún èmi náà, bí Jésù ṣe sọ pé yóò rí. (Ìṣe 20:35) Ìrírí mi nínú iṣẹ́ ìsìn pápá fún mi ní àwọn ohun tí n óò máa retí, àwọn ohun tí n óò máa wéwèé fún.
Ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, ìmọ̀lára ìnìkanwà tí mo máa ń nírìírí rẹ̀ tún bò mí mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo jáde nílé láti lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ayọ̀ mi tún kún. Ní wákàtí méjì lẹ́yìn náà, bí mo ti padà sílé, mo ní ìtẹ́lọ́rùn àti ìgbéniró. Bí onísáàmù náà ti sọ, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè “fi omijé fúnrúgbìn,” àmọ́ kí Jèhófà bù kún ìsapá wa, kí a sì “fi igbe ìdùnnú ká a.”—Sáàmù 126:5, 6.
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo ní láti ṣàtúnṣe ìgbòkègbodò mi díẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ríru, mo sì jẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ títí lọ ní báyìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ń kò ronú pé n óò lè borí àdánù tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi pátápátá nínú ètò àwọn nǹkan yìí láé, mo ń gbé ìgbésí ayé onítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Inú mi máa ń dùn tí mo bá ń rí àwọn ọmọ mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo ń fojú sọ́nà láti tún ri Fred nínú ayé tuntun. Ó dá mi lójú pé inú rẹ̀ yóò dùn láti mọ̀ nípa iṣẹ́ tí mo ti gbé ṣe ní Ecuador—pé ìwéwèé wa so èso.
Mo gbàdúrà pé kí ọ̀rọ̀ onísáàmù náà lè máa jẹ́ òtítọ́ nípa mi. “Dájúdájú, ohun rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi; èmi yóò sì máa gbé inú ilé Jèhófà fún gígùn ọjọ́.”—Sáàmù 23:6.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní San Lucas, Loja, Ecuador