ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 4/22 ojú ìwé 17-19
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Jíjẹ́ Kí Ọ̀rẹ́ Mi Gba Àkókò Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Jíjẹ́ Kí Ọ̀rẹ́ Mi Gba Àkókò Mi?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìní fún Àkókò Ara Ẹni àti Ìdáwà
  • “Gbòòrò Síwájú”
  • Lo Àkókò Pẹ̀lú Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Yẹ
  • N Kò Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́ Pẹ́ Títí?
    Jí!—1996
  • Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Mi Tòótọ́?
    Jí!—2012
  • Bí o Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 4/22 ojú ìwé 17-19

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Jíjẹ́ Kí Ọ̀rẹ́ Mi Gba Àkókò Mi?

“Ọ̀rẹ́ mi máa ń ṣe bí pé òun ló ni mí. Kì í jẹ́ kí n rí àkókò gbọ́ tara mi.”—Hollie.

ÒWE ọlọgbọ́n kan sọ pé: “Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” (Òwe 18:24) Bí o bá sì ní ọ̀rẹ́ tí ó ní ìgbàgbọ́, ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani, tàbí ohun àfọkànfẹ́ tó bá tìrẹ dọ́gba, ẹ óò fẹ́ máa wà pọ̀ lọ́nà àdánidá. Èwe kan tí ń jẹ́ Caroline wí pé: “Bíbá tí mo bá àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni dọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ jẹ́ nítorí pé a jọ ń ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Caroline ya oṣù kan sọ́tọ̀, nínú èyí tí ó wéwèé láti lo 60 wákàtí nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣètò àkókò wọn láti tì í lẹ́yìn nínú iṣẹ́ yìí!

Ṣùgbọ́n nígbà tí wíwàpọ̀ ní àwọn àǹfààní tirẹ̀, nígbà mìíràn, ó lè jọ pé ó pọ̀ jù. Hollie, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀, ronú pé ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ òun ti ń gba òun lákòókò jù. Òun nìkan sì kọ́ ló ń ronú báyìí. Hollie wí pé: “Ó jọ pé ìyẹn ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ mìíràn pẹ̀lú. Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ lè kó síra wọn lápò títí dìgbà tí wàhálà bá bẹ́. Wọn á wá yan ara wọn lódì fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀.”

Ohun tó jẹ́ ìṣòro náà ni pé kò rọrùn láti sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ pé o rò pé ó ń gbà ọ́ lákòókò jù, o sì fẹ́ kí ó fún ọ láyè díẹ̀. O lè máa bẹ̀rù pé ìyẹn yóò mú kí o ṣèpalára fún ìmọ̀lára ọ̀rẹ́ rẹ. O tún lè máa bẹ̀rù pé yóò ba àjọṣe yín jẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, fífúnra-ẹni-láyè ní ìwọ̀n tó bọ́gbọ́n mu nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ kan lè ṣèrànwọ́ dípò kí ó ṣèpalára.

Láti ṣàpèjúwe: Nínú ọgbà ìlú kan ní Sydney, Australia, ó di dandan kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n ṣọgbà yí igi ńlá kan ká. Èé ṣe? Nítorí pé àìlóǹkà àwọn olùṣèbẹ̀wò ń fẹsẹ̀ ki ilẹ̀ náà mọ́ra díẹ̀díẹ̀, ó sì ń há àwọn gbòǹgbò mọ́. Bí a kò bá dáàbò bo igi náà, ó lè kú. Ohun kan náà ló lè ṣẹlẹ̀ sí ìbádọ́rẹ̀ẹ́. Wíwàpọ̀jù lè fún àjọṣe kan pa. Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ṣọ̀wọ́n ní ilé ọmọnìkejì rẹ, kí ọ̀ràn rẹ má bàa sú u, òun a sì kórìíra rẹ dájúdájú.”—Òwe 25:17.

Àìní fún Àkókò Ara Ẹni àti Ìdáwà

Kí ló mú kí Sólómọ́nì sọ èyí? Ìdí kan ni pé, gbogbo wa nílò àkókò díẹ̀ fún ara ẹni, kí a sì dá wà. Kódà, Jésù Kristi ní irú àìní bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó máa ń dá lọ “ní òun nìkan láti gbàdúrà.” (Mátíù 14:23; Máàkù 1:35) Bákan náà ni Aísíìkì, olùbẹ̀rù-Ọlọ́run, wá àkókò láti dá wà. (Jẹ́nẹ́sísì 24:63) Ìwọ pẹ̀lú nílò ìwọ̀n àkókò díẹ̀ fún ara rẹ láti bójú tó àwọn nǹkan bí iṣẹ́ àṣetiléwá, iṣẹ́ ilé, àti ìdákẹ́kọ̀ọ́-Bíbélì rẹ. Bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá sì fi àìgbatẹnirò hàn nípa gbígbójúfo àwọn àìní rẹ nínú ọ̀ràn yìí, ìkórìíra lè ru sókè tìrọ̀rùntìrọ̀rùn.

Nítorí náà, má bẹ̀rù láti jẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ mọ ìgbà tí o bá nílò àkókò díẹ̀ fún ara rẹ. Níwọ̀n bí ìfẹ́ Kristẹni ti jẹ́ èyí tí “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan,” ọ̀rẹ́ tòótọ́ kan yóò gbìyànjú láti lóye rẹ̀ nígbà gbogbo. (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5; Òwe 17:17) Èwe kan kọ̀wé pé: “Láàárín àkókò tí ìdánwò àṣekágbá mi ń sún mọ́, àwọn ọ̀rẹ́ mi tì mí lẹ́yìn, wọ́n sì fòye hàn gan-an. Kì í ni mí lára láti sọ pé kí wọ́n máa lọ nígbà tí mo bá nílò àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́. Ó rọrùn láti bá àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ òtítọ́; wọ́n mọ̀ pé gbogbo wa la ní àwọn ẹrù iṣẹ́.”

Ó dájú pé Òfin Oníwúrà náà béèrè pé kí o fi irú ìgbatẹnirò kan náà hàn fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. (Mátíù 7:12) Ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Tamara kọ̀wé pé: “Níní tí mo ní ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ ti mú kí n túbọ̀ mọ àìní ọ̀rẹ́ mi láti ní àkókò fún ara rẹ̀ lára dájúdájú.” Nígbà tí Tamara bá sì ní àwọn iṣẹ́ tó fẹ́ ṣe nílé, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kì í rọ̀ ọ́ láti kánjú ṣe wọ́n tàbí pé kí ó pa wọ́n tì dìgbà mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Tamara sọ pé, “lọ́pọ̀ ìgbà, wọn yóò ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ mi kí a lè jọ ṣe àwọn nǹkan pọ̀ lẹ́yìn náà.” Ẹ wo irú ìṣúra tí àwọn ọ̀rẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ jẹ́—ẹ sì wo bí ó ṣe jẹ́ ìjùmọ̀lo-àkókò bó ti yẹ tó!

“Gbòòrò Síwájú”

Ìdí mìíràn tún wà tí ó fi lọ́gbọ́n nínú láti fúnra ẹni láyè díẹ̀ nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ kan. Nígbà tí a bá kó gbogbo àkókò àti ìmọ̀lára wa lé orí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ kan ṣoṣo, a lè máa pa àwọn àjọṣe mìíràn—bí àjọṣe àwa pẹ̀lú àwọn òbí wa àti àwọn ọmọ ìyá wa àti àwọn Kristẹni mìíràn—tì. Bẹ́ẹ̀ ni a ń pààlà sí ìdàgbà wa ní ti ìmọ̀lára àti tẹ̀mí gan-an. Bíbélì wí pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” (Òwe 27:17) Ní kedere, ìwọ̀nba ni ‘pípọ́n’ tí o lè rí nípa bíbá ẹnì kan ṣoṣo kẹ́gbẹ́—pàápàá, bí ẹni náà bá jẹ́ ojúgbà rẹ.

Bíbélì tipa bẹ́ẹ̀ ṣàìfún kíkáṣà ẹgbẹ́ ẹyẹ lẹyẹ ń wọ́ lé, pípààlà ẹni tí a ń bá kẹ́gbẹ́, tàbí ṣíṣàìfún àwọn mìíràn láǹfààní ìbákẹ́gbẹ́ níṣìírí. Ó rọ̀ wá láti “gbòòrò síwájú.” (2 Kọ́ríńtì 6:13) Ìwé Moods and Feelings rọni pé: “Kódà, bí o bá ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan, ó ṣe pàtàkì láti wá àyè, kí o sì yọjú sí àwọn ọ̀rẹ́ mìíràn pẹ̀lú.”

Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti lò. Ọ̀dọ́ Kristẹni kan tí ń jẹ́ Michael sọ pé: “Èmi àti Troy jọ máa ń ṣe gbogbo nǹkan pọ̀ nínú ìjọ àti nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. A kò ṣeé yà nípá. Nígbà náà ni ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí mìíràn dé sínú ìjọ náà. Èmi pẹ̀lú rẹ̀ jọ fẹ́ máa ṣiṣẹ́ bí oníwàásù alákòókò-kíkún, nítorí náà, a bẹ̀rẹ̀ sí jọ lo àkókò papọ̀.” Kí ló yọrí sí? Michael wí pé: “Troy bẹ̀rẹ̀ sí yàn mí lódì, lẹ́yìn tí mo sì sapá láti mú ipò nǹkan tọ́ títí, tó sì ń já sí pàbó, n kò sọ̀rọ̀ sí i mọ́. Èyí ń lọ bẹ́ẹ̀ fún ọdún kan.” Ó ṣàpèjúwe ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn bí èyí tí a “fi owú sọ di tẹni.”

Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àjọṣe gbígbámúṣé, àwọn ọ̀rẹ́ kò ní láti hùwà sí ara wọn bí ohun ìní. Nítorí náà, bí ọ̀rẹ́ kan kò bá fara mọ́ ìsapá rẹ láti gbòòrò síwájú, ẹ ní láti jùmọ̀ fikùn lukùn. Bóyá ọ̀rẹ́ rẹ wulẹ̀ nílò ìmúdánilójú pé o ṣì ń ṣìkẹ́ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ òun ni. Jẹ́ kí ó ṣe kedere pé ẹ óò ṣì máa ṣe nǹkan papọ̀.

A gbà pé ó lè gba àkókò díẹ̀ kí ọ̀rẹ́ rẹ tó yí èrò padà. Bí àpẹẹrẹ, Zaneta, ọmọ ọdún 16, nímọ̀lára owú nígbà mélòó kan nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ bẹ̀rẹ̀ sí lo àkókò pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n Zaneta sọ pé òun ṣẹ́gun ìmọ̀lára wọ̀nyí, “ọpẹ́lọpẹ́ àdúrà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́-Bíbélì.” Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè máa bá àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nìṣó. Troy, ọ̀rẹ́ Michael, pẹ̀lú borí owú tó ní níbẹ̀rẹ̀, wọ́n sì tún di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i. Bóyá, ọ̀rẹ́ rẹ lè ṣe bákan náà. Ní gidi, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, gbígbòòrò-síwájú ń ṣe gbogbo ẹni tí ọ̀ràn kan láǹfààní. Debbie, ọmọ ọdún 17, rí i pé nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ òun bá ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, “wọ́n sábà máa ń di àwọn ọ̀rẹ́ tèmi náà.”

Bí ọ̀rẹ́ rẹ bá wá wulẹ̀ kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba àwọn ìyípadà wọ̀nyí nínú ipò ìbátan yín ńkọ́? Ẹ lè ṣàìní ọ̀nà mìíràn ju kí olúkúlùkù máa bá tirẹ̀ lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, kí ẹ tó gbà pé kò sí àtúnṣe mọ́, o kò ṣe béèrè èrò àwọn òbí rẹ lórí ọ̀ràn náà? Ó ṣe tán, àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ jù lọ. Wọ́n sì lè ní àwọn ìdámọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí ìṣọ̀rẹ́ náà forí ṣánpọ́n láìfi àìní rẹ fún àkókò láti fi gbọ́ tara rẹ báni dọ́rẹ̀ẹ́.

Lo Àkókò Pẹ̀lú Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Yẹ

Ìkìlọ̀ kan nìyí: Gbígbòòrò-síwájú kò túmọ̀ sí jíjẹ́ ẹni tí ń bá tajátẹran dọ́rẹ̀ẹ́ ṣáá. Ìwé kan lórí ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ wí pé: “Ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti dà bí àwọn ènìyàn tí o ń bá lo àkókò púpọ̀. Nígbà mìíràn, èyí lè ṣẹlẹ̀ láìsí pé o mọ̀ nípa rẹ̀. O lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú, kí o sì máa hùwà bí àwọn ojúgbà rẹ láìka ìmọ̀lára rẹ sí. Lọ́nà yìí, àwọn ojúgbà rẹ lè máa darí rẹ.” Bíbélì sọ kókó kan náà yìí ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn nígbà tó wí pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.

Nígbà tí o bá wà nílé ẹ̀kọ́ tàbí níbi iṣẹ́, o lè ní láti lo àkókò pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí kò lọ́kàn ìfẹ́ nínú sísin Jèhófà. Ṣùgbọ́n nígbà ti o bá ń yan àwọn alájọṣepọ̀ tímọ́tímọ́, rántí ìmọ̀ràn tí Bíbélì fúnni pé: “Ẹgbẹ́ búburú ní ń ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:33, Today’s English Version.

Tún rántí pé, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, ṣe pàtàkì ju ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí lọ. Debbie, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ṣáájú, ní àwọn ọ̀rẹ́ rere mélòó kan. Síbẹ̀, ìmọ̀ràn rẹ̀ ni pé kí a “rí i dájú pé Jèhófà ló wà nípò kìíní nígbà gbogbo.” Ábúráhámù olóòótọ́ ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà láéláé, Jèhófà sì pè é ní “ọ̀rẹ́ mi” lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Aísáyà 41:8) Sì gbé èyí yẹ̀ wò: Jèhófà kì í bínú sí lílò tí o bá lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀; ní gidi, ó fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀ níṣìírí. Ẹ wo irú Ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí ó jẹ́!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ ń mọ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe nílò àkókò láti fi gbọ́ tara rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́