ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/8 ojú ìwé 16-19
  • Ìrìn Àjò Ọlọ́jọ́ Gbọọrọ Mi Láti Inú Ìwàláàyè àti Ikú ní Cambodia

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrìn Àjò Ọlọ́jọ́ Gbọọrọ Mi Láti Inú Ìwàláàyè àti Ikú ní Cambodia
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbésí Ayé Mi Àtilẹ̀wá Bí Onísìn Búdà
  • Ogun àti Àwọn Ìyípadà ní Cambodia
  • Pol Pot àti Pípa Àwọn Tí Ó Kà sí Ọ̀dàlẹ̀
  • Ìgbésí Ayé Tuntun ní United States
  • Ìbẹ̀wò Apániláyà Kan
  • Kíkọ́ Èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Bíbélì
  • Ìpinnu Tí Mo Ṣe Nígbà Tí Mo Wà ní Kékeré
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • “Gbogbo Iwe Mimọ Ti O Ka Wọ Ọkan-aya Mi Ṣinṣin”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Jí!—1998
g98 5/8 ojú ìwé 16-19

Ìrìn Àjò Ọlọ́jọ́ Gbọọrọ Mi Láti Inú Ìwàláàyè àti Ikú ní Cambodia

BÍ WATHANA MEAS ṢE SỌ Ọ́

ỌDÚN 1974 ni, mo sì ń jagun pẹ̀lú ẹgbẹ́ Khmer Rouge ní Cambodia. Mo jẹ́ ọ̀gá nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Cambodia. A mú sójà ẹgbẹ́ Khmer Rouge kan nínú ogun kan. Ohun tí ó wí fún mi nípa ohun tí Pol Pot ń wéwèé fún ọjọ́ iwájú yí ìgbésí ayé mi padà, ó sì mú mi bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò jíjìnnà kan, ní tààràtà àti nípa tẹ̀mí.a

Àmọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò mi. Wọ́n bí mi ní 1945, ní Phnom Penh, níbi tí a mọ̀ sí Kampuchea (Cambodia) lédè Khmer. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìyá mi wá ní ipò pàtàkì kan nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá inú. Ó jẹ́ aṣojú pàtàkì kan fún Ọmọba Norodom Sihanouk tí ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè náà. Níwọ̀n bí wọ́n ti fún un ní ẹ̀tọ́ àtibójútó mi, tí ọwọ́ rẹ̀ sì dí, ó ronú pé ó di ọ̀ràn-anyàn fún òun láti fi mí sí tẹ́ńpìlì Búdà kan, kí wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀.

Ìgbésí Ayé Mi Àtilẹ̀wá Bí Onísìn Búdà

Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ̀dọ̀ olórí àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti ìsìn Búdà. Láti ọdún yẹn títí di ọdún 1969, mo ń pín àkókò mi lò láàárín tẹ́ńpìlì àti ilé. Ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé tí mo ń ṣiṣẹ́ fún ni Chuon Nat, aláṣẹ tí ó ga jù lọ nínú ìsìn Búdà ní Cambodia nígbà náà. Mo ṣiṣẹ́ bí akọ̀wé rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, mo sì ràn án lọ́wọ́ nínú títúmọ̀ ìwé mímọ́ ìsìn Búdà náà, “Apẹ̀rẹ̀ Mẹ́ta” (Tipitaka, tàbí lédè Sanskrit, Tripitaka), tí a mú wọnú èdè Cambodian láti inú ìdè Íńdíà ìgbà láéláé kan.

Wọ́n sọ mí di ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ní 1964, mo sì sìn ní ipò yẹn títí di 1969. Láàárín àkókò yìí, mo ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí ń dà mí láàmú, fún àpẹẹrẹ, Èé ṣe tí ìjìyà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láyé, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀? Mo ń rí i tí àwọn ènìyàn ń gbìyànjú ní ọ̀nà púpọ̀ láti tẹ́ àwọn ọlọ́run wọn lọ́rùn, àmọ́ wọn kò mọ bí àwọn ọlọ́run wọn ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro wọn. N kò rí ìdáhùn tí ó tẹ́ mi lọ́rùn nínú àwọn ìwé ìsìn Búdà, bákan náà ni àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé mìíràn kò sì lè rí i. Ó rú mi lójú gan-an tí mo fi pinnu láti kúrò ní tẹ́ńpìlì náà, n kò sì ṣe ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé mọ́.

Níkẹyìn, mo wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Cambodia ní 1971. Wọ́n gbé mi lọ sí Vietnam ní nǹkan bí 1971, wọ́n sì gbé mi ga sí ipò igbákejì lẹ́fútẹ́náǹtì nítorí pé mo kàwé, wọ́n sì yàn mí sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun agbábẹ́lẹ̀ jagun. A ń jagun pẹ̀lú ẹgbẹ́ Khmer Rouge ti Kọ́múníìsì àti agbo ọmọ ogun Vietcong.

Ogun àti Àwọn Ìyípadà ní Cambodia

Mo di onírìírí jagunjagun tí ogun ti sọ ọkàn mi di líle bí òkúta. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni mo ń ri tí a ń pànìyàn. Mo ti ja ogun 157. Nígbà kan, tí a wà nínú igbó jìndunjìndun, àwọn ẹgbẹ́ Khmer Rouge yí wa ká fún ohun tí ó lé ní oṣù kan. Ó lé ní 700 ọmọ ogun tí ó kú. Ẹni 15 ló là á já—mo jẹ́ ọ̀kan lára wọn, mo sì ṣèṣe. Àmọ́ mo là á já.

Ní ìgbà mìíràn, ní 1974, a mú sójà ẹgbẹ́ Khmer Rouge kan. Bí mo ti ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, ó wí fún mi pé, Pol Pot wéwèé láti pa gbogbo àwọn ọ̀gá tẹ́lẹ̀ rí nínú iṣẹ́ ìjọba, títí kan àwọn tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Ó ní kí n jọ̀wọ́ ohun gbogbo, kí n sì sá lọ. Ó sọ pé: “Máa yí orúkọ rẹ padà. Máà jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ẹni tí o jẹ́. Máa ṣe bí ẹni tí kò mọ̀kan, tí kò sì kàwé. Má sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ìgbésí ayé tí o ti gbé tẹ́lẹ̀.” Lẹ́yìn tí mo dá a sílẹ̀ láti padà sí ilé rẹ̀, ìkìlọ̀ yẹn kò kúrò lọ́kàn mi.

Wọ́n ti wí fún àwa sójà pé orílẹ̀-èdè wa ni a ń jà fún, a sì ń pa àwọn ará Cambodia. Àwọn ẹgbẹ́ Khmer Rouge, ẹ̀yà ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì kan tí ń du ipò àléfà, wá láti ara àwọn ènìyàn wa. Ní gidi, àwọn Khmer ni wọ́n pọ̀ jù lọ lára àwọn mílíọ̀nù mẹ́sàn-án olùgbé Cambodia, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni kò sí nínú ẹgbẹ́ Khmer Rouge. Kò bọ́gbọ́n mu rárá lójú mi. A ń pa àwọn àgbẹ̀ aláìmọwọ́mẹsẹ̀, tí wọn kò ní ìbọn, tí ọ̀ràn ogun náà kò kàn.

Pípadà sílé láti ojú ogun sábà máa ń jẹ́ ìrírí bíbanilọ́kànjẹ́. Àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ yóò máa dúró pẹ̀lú ìyánhànhàn láti rí bí ọkọ tàbí bàbá wọn bá bọ̀ láti ojú ogun. Mo ní láti wí fún púpọ̀ lára wọn pé mẹ́ńbà ìdílé wọn ti kú. Nínú gbogbo èyí, ohun tí mo lóye nípa ìsìn Búdà kò fún mi ní ìtùnú rárá.

Mo ń ronú padà sẹ́yìn nísinsìnyí lórí bí àwọn nǹkan ṣe yí padà ní Cambodia. Kí ó tó di 1970, àlàáfíà àti àìséwu wà dé àyè kan. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ni kò ní ìbọn; ó jẹ́ ohun tí kò bófin mu, àyàfi tí o bá ní ìwé àṣẹ. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìfipájalè tàbí ìjíǹkangbé. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ogun abẹ́lé bẹ́ sílẹ̀ látàrí ọ̀tẹ̀ Pol Pot àti agbo ọmọ ogun rẹ̀, gbogbo nǹkan yí padà. A ń rí ìbọn níbi gbogbo. Kódà, wọ́n ń dá àwọn èwe ọlọ́dún 12 àti 13 lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n ń kọ́ bí a ṣe ń yìnbọn àti bí a ṣe ń pànìyàn. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Pol Pot rọ àwọn ọmọ kan láti pa àwọn òbí wọn. Àwọn sójà ń wí fún àwọn ọmọdé pé, “Bí o bá nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ, ìwọ yóò kórìíra ọ̀tá rẹ. Bí àwọn òbí rẹ bá ń ṣiṣẹ́ ìjọba, ọ̀tá wa ni wọ́n, o sì gbọ́dọ̀ pa wọ́n—bí bẹ́ẹ̀ kọ́ wọn óò pa ìwọ fúnra rẹ.”

Pol Pot àti Pípa Àwọn Tí Ó Kà sí Ọ̀dàlẹ̀

Ní 1975, Pol Pot ṣẹ́gun náà, Cambodia sì di orílẹ̀-èdè Kọ́múníìsì. Pol Pot bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́, àwọn ọ̀gá nínú iṣẹ́ ìjọba, àti àwọn ẹlòmíràn tí ó bá kàwé, tí ó kà sí ọ̀dàlẹ̀. Bí o bá ki ìgò sójú, wọ́n lè pa ọ́ nítorí wọ́n gbà pé o kàwé! Ìṣàkóso Pol Pot fipá lé àwọn ènìyàn púpọ̀ jù lọ kúrò ní àwọn ìlú ńlá àti ìlú lọ sí àgbègbè àrọko láti lọ ṣiṣẹ́ àgbẹ̀. Gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ múra bákan náà. A ní láti ṣiṣẹ́ fún wákàtí 15 lóòjọ́, láìsí oúnjẹ tí ó tó, kò sí egbòogi, kò sí aṣọ, wákàtí 2 tàbí 3 péré ni a sì fi ń sùn. Mo pinnu láti fi ilẹ̀ ìbí mi sílẹ̀ kí ó tó pẹ́ jù.

Mo rántí ìmọ̀ràn sójà ẹgbẹ́ Khmer Rouge yẹn. Mo sọ gbogbo fọ́tò, ìwé, àti ohunkóhun tí ó lè kó bá mi nù. Mo gbẹ́ ihò kan, mo sì bo díẹ̀ lára àwọn ìwé mi mọ́lẹ̀ sínú rẹ̀. Mo wá lọ sí ìwọ̀ oòrùn síhà Thailand. Ó léwu. Mo ní láti máa sá fún ibi tí àwọn ológun wà lójú ọ̀nà, kí n sì ṣọ́ra gidigidi ní àwọn àkókò kónílégbélé, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn sójà ẹgbẹ́ Khmer Rouge nìkan ni wọ́n lè rìnnà, pẹ̀lú ìyọ̀ǹda ìjọba.

Mo lọ sí àgbègbè kan, mo sì gbé ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ mi kan fún ìgbà díẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹgbẹ́ Khmer Rouge kó gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibẹ̀ lọ sí àgbègbè tuntun kan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn olùkọ́ àti àwọn dókítà. Èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi mẹ́ta sá àsálà. A sá pamọ́ sínú igbó, a sì ń jẹ èsokéso tí a bá rí lórí igi. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo dé abúlé kékeré kan ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Battambang, níbi tí ọ̀rẹ́ mi kan ń gbé. Ó yà mí lẹ́nu láti rí sójà tẹ́lẹ̀ rí tí ó gbà mí nímọ̀ràn lórí bí mo ṣe lè sá àsálà! Nítorí pé mo dá a sílẹ̀, ó fi mí pamọ́ sínú ihò kan fún oṣù mẹ́ta. Ó darí ọmọdé kan láti máa ju oúnjẹ fún mi àmọ́ kò gbọ́dọ̀ wo inú ihò náà.

Bí àkókò ti ń lọ, mo sá àsálà, mo sì rí ìyá mi, àbúrò ìyá mi obìnrin, àti àbúrò mi obìnrin, tí àwọn pẹ̀lú ń sá lọ síhà ààlà ilẹ̀ Thai. Àkókò ìbànújẹ́ ló jẹ́ fún mi. Ara ìyá mi kò yá, àrùn àti àìsí oúnjẹ sì pa á sí àgọ́ ìsádi kan nígbẹ̀yìngbẹ́yìn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ àti ìrètí tàn sínú ìgbésí ayé mi. Mo pàdé Sopheap Um, obìnrin tí ó wá di ìyàwó mi. Èmi pẹ̀lú rẹ̀ àti àbúrò ìyá mi obìnrin àti àbúrò mi obìnrin sá àsálà kọjá ní ààlà ilẹ̀ Thai wọ àgọ́ ìsádi Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ìdílé wa fojú winá gan-an nínú ogun abẹ́lé Cambodia. A pàdánù ẹni 18 nínú ìdílé wa, tí àbúrò mi ọkùnrin àti ìyàwó rẹ̀ wà lára wọn.

Ìgbésí Ayé Tuntun ní United States

Wọ́n ṣèwádìí nípa ìgbésí ayé wa àtẹ̀yìnwá ní àgọ́ ìsádi náà, àjọ UN sì gbìyànjú láti wá onígbọ̀wọ́ kan fún wa kí a bàa lè lọ sí United States. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nǹkan ṣenu-unre! Ní 1980, a gúnlẹ̀ sí St. Paul, Minnesota. Mo mọ̀ pé mo ní láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì bí ó bá ti lè yá tó bí mo bá fẹ́ ní ìtẹ̀síwájú ní orílẹ̀-èdè mi tuntun. Onígbọ̀wọ́ mi rán mi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ fún oṣù bí mélòó kan péré, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí n kẹ́kọ̀ọ́ pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wá iṣẹ́ ìtọ́jú àyíká hòtẹ́ẹ̀lì kan fún mi. Àmọ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba Gẹ̀ẹ́sì tí mo gbọ́, ó di ọ̀ràn àṣìṣe tí ń pani lẹ́rìn-ín. Bí ẹni tí ó ni hòtẹ́ẹ̀lì náà bá ní kí n lọ gbé àtẹ̀gùn wá, n óò lọ gbé ìkólẹ̀sí wá!

Ìbẹ̀wò Apániláyà Kan

Ní 1984, iṣẹ́ alẹ́ ni mo máa ń ṣe, mo sì máa ń fi ọ̀sán sùn. A ń gbé àdúgbò kan tí pákáǹleke ti pọ̀ gan-an láàárín àwọn ará Éṣíà àti àwọn adúláwọ̀. Ìwà ọ̀daràn àti lílo oògùn olóró wọ́pọ̀. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ìyàwó mi jí mi ní agogo mẹ́wàá, ó sì sọ fún mi pé ọkùnrin adúláwọ̀ kan wà lẹ́nu ilẹ̀kùn. Ẹ̀rù ba ìyàwó mi nítorí pé ó rò pé ọkùnrin náà wá fipá jà wá lólè ni. Mo yọjú nínú ihò kan tó wà lára ilẹ̀kùn, ọkùnrin adúláwọ̀ kan tí ó fa àpò lọ́wọ́ ló wà níbẹ̀, òun àti ọkùnrin òyìnbó kan ni. Lójú mi, ó jọ pé kò sí láburú.

Mo bi í pé kí ló ń tà. Ó fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! hàn mí. N kò lóye ohunkóhun. Mo gbìyànjú láti kọ̀ wọ́n nítorí pé ní oṣù bí mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n ti tàn mí san dọ́là 165 fún ìdìpọ̀ àwọn ìwé márùn-ún kan lọ́wọ́ ọkùnrin Pùròtẹ́sítáǹtì kan tí ń tajà. Bí ó ti wù kí ó rí, ó fi àwọn àwòrán inú ìwé ìròyìn náà hàn mí. Àwọn àwòrán náà wuni wọ́n sì jojú ní gbèsè gan-an! Ọkùnrin náà sì ní ẹ̀rín músẹ́ tí ó gbayì, tí ń fani mọ́ra lẹ́nu. Nítorí náà, mo ṣe ìtọrẹ dọ́là kan, mo sì gbà wọ́n.

Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, ó padà wá, ó sì béèrè bí mo bá ní Bíbélì èdè Cambodian. Ní gidi, mo ní ọ̀kan tí mo gbà ní ṣọ́ọ̀ṣì Nazarene kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lóye rẹ̀. Àmọ́ ó wú mi lórí pé àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá sẹ́nu ọ̀nà mi. Ó wá bi mí léèrè pé, “Ṣé o fẹ́ kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì?” Dájúdájú, mo fẹ́ bẹ́ẹ̀, àmọ́ mo ṣàlàyé fún un pé n kò ní owó láti san fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Ó sọ fún mi pé òun yóò kọ́ mi lọ́fẹ̀ẹ́, òun yóò lo ìwé kan tí a gbé karí Bíbélì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò mọ ìsìn tí ó ń ṣojú fún, mo rò nínú ara mi pé, ‘Ó ṣe tán n kò ní sanwó, n óò sì kọ́ bí a ti ń kọ̀wé tí a sì ń kàwé lédè Gẹ̀ẹ́sì.’

Kíkọ́ Èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Bíbélì

Kò yá rárá. Yóò fi ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, Jẹ́nẹ́sísì, hàn mí, n óò sì pè é ní èdè Cambodian, “Lo ca bat.” Yóò sọ pé, “Bíbélì,” èmi yóò sì sọ pé, “Compee.” Mo bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ síwájú, ìyẹn sì fún mi níṣìírí. Mo máa ń mú ìwé atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Cambodian mi, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kan, Bíbélì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, àti Bíbélì Cambodian mi lọ síbi iṣẹ́. Tí mo bá wà lákòókò ìsinmi, mo máa ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́, mo sì máa ń kọ́ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan inú èdè Gẹ̀ẹ́sì nípa fífi àwọn ìtẹ̀jáde náà wéra. Ìgbésẹ̀ tí kò yára yìí, pa pọ̀ pẹ̀lú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, gba ohun tí ó lé ní ọdún mẹ́ta. Àmọ́, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo lè ka èdè Gẹ̀ẹ́sì!

Ìyàwó mi ṣì ń lọ sí tẹ́ńpìlì Búdà, ó sì ń fi oúnjẹ sílẹ̀ fún àwọn baba ńlá. Dájúdájú, àwọn eṣinṣin nìkan ni wọ́n gbádùn rẹ̀! Mo ní àwọn ìwà abèṣe tí mo ti jingíri nínú wọn, tí ó ti ń bá mi bọ̀ láti ìgbà tí mo wà nínú ẹgbẹ́ ológun àti nínú ìsìn Búdà. Nígbà tí mo jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé, àwọn ènìyàn máa ń mú àwọn ohun ìfirúbọ wá, tí sìgá wà lára rẹ̀. Wọ́n gbà gbọ́ pé bí ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé bá ń mu sìgá, ń ṣe ló jọ pé àwọn baba ńlá àwọn ń mu sìgá. Nítorí náà, mo sọ èròjà nicotine di bárakú. Bákan náà, nínú iṣẹ́ ológun pẹ̀lú, mo máa ń mutí gan-an, mo sì máa ń mu èròjà opium láti fún mi ní ìgboyà fún ogun jíjà. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo ní láti ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà. Ìgbà yẹn ni mo wá mọ̀ pé ìrànlọ́wọ́ ńlá ni àdúrà jẹ́. Láàárín oṣù bí mélòó kan péré, mo borí àwọn àṣà burúkú mi. Ẹ wo bí ìyẹn ṣe mú inú àwọn mẹ́ńbà ìdílé yòó kù dùn tó!

Mo ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí kan ní 1989, ní Minnesota. Ní àkókò yẹn ni mo gbọ́ pé àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí ń sọ èdè Cambodian àti àwùjọ àwọn ará Cambodia títóbi kan wà ní Long Beach, California. Lẹ́yìn tí èmi àti ìyàwó mi jíròrò rẹ̀, a pinnu láti kó lọ sí Long Beach. Ó jẹ́ ìyípadà pàtàkì kan! Àbúrò mi obìnrin ló kọ́kọ́ ṣèrìbọmi, lẹ́yìn náà, àbúrò ìyá mi obìnrin (tí ó jẹ́ ẹni ọdún 85 nísinsìnyí) pa pọ̀ pẹ̀lú ìyàwó mi. Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àbúrò mi obìnrin fẹ́ Ẹlẹ́rìí kan, tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ nísinsìnyí.

A ti la ọ̀pọ̀ ìdánwò kọjá níhìn-ín ní United States. A ti nírìírí ìṣòro ìnáwó bíburújáì àti àwọn ìṣòro àìlera díẹ̀, àmọ́ nípa rírọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì, a ń bá a lọ ní gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà. Ó ti bù kún àwọn ìsapá mi nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Ní 1992, wọ́n yàn mí láti sìn bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ, nígbà tí ó sì di 1995, mo di alàgbà níbí ní Long Beach.

Ní báyìí ná, ìrìn àjò tí ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí mo jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti ìsìn Búdà, tí mo sì wá di ọ̀gá ní àwọn pápá ogun ilẹ̀ Cambodia tí ogun gbò jìgìjìgì ti dópin, àlàáfíà àti ayọ̀ sì wà nínú ilé àti orílẹ̀-èdè wa tuntun. A sì ní ìgbàgbọ́ tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí nínú Jèhófà Ọlọ́run àti Kristi Jésù. Ó dùn mí láti mọ̀ pé àwọn ènìyàn ṣì ń pa ara wọn ní Cambodia. Ìdí gan-an nìyẹn tí èmi àti ìdílé mi fi ní láti dúró, kí a sì kéde ayé tuntun tí a ṣèlérí náà, níbi tí onírúurú ogun kò ti ní sí mọ́, tí gbogbo ènìyàn yóò sì nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn bí ara wọn ní tòótọ́!—Aísáyà 2:2-4; Mátíù 22:37-39; Ìṣípayá 21:1-4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà yẹn, Pol Pot ni ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì tí ń ṣáájú àwọn ọmọ ogun ẹgbẹ́ Khmer Rouge, tí ó borí ogun náà, tí ó sì gba Cambodia.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

VIETNAM

LAOS

THAILAND

CAMBODIA

Battambang

Phnom Penh

Ní àwọn ọdún tí mo jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti Búdà

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Èmi àti ìdílé mi, ní Gbọ̀ngàn Ìjọba

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́