ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 4/1 ojú ìwé 29
  • “Gbogbo Iwe Mimọ Ti O Ka Wọ Ọkan-aya Mi Ṣinṣin”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Gbogbo Iwe Mimọ Ti O Ka Wọ Ọkan-aya Mi Ṣinṣin”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìfẹ́ Tí Mo Ní fún Ọlọ́run Látìbẹ̀rẹ̀ Mú Kí N Lè Fara Dà Á
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Awọn Agutan Jesu Fetisilẹ si Ohùn Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 4/1 ojú ìwé 29

Awọn Olùpòkìkí Ijọba Ròhìn

“Gbogbo Iwe Mimọ Ti O Ka Wọ Ọkan-aya Mi Ṣinṣin”

“Ọ̀RỌ̀ Ọlọrun ye, o si ni agbara,” ni apọsteli Pọọlu wi. (Heberu 4:12) Eyi jasi otitọ ninu igbesi aye obinrin kan lati Vietnam ti a tọ́ dagba gẹgẹ bi onisin Buddha. Itan rẹ niyii.

“Awọn obi mi, ti wọn ṣi wa ni Vietnam, jẹ onisin Buddha alafẹnujẹ, nitori naa a tọ́ mi dàgbà gẹgẹ bi onisin Buddha titi di igba igbeyawo mi ni ẹni ọjọ ori 22. Idile ọkọ mi gbiyanju lati fi ipa mu mi lati ṣe baptism ni Ṣọọṣi Katoliki. Wọn sọ pe iya ọkọ mi ti o ti ku ni a nṣedilọwọ fun lati lọ si ọrun nitori pe mo jẹ onisin Buddha! Lakọọkọ mo kọ̀ lati ṣe bẹẹ, ṣugbọn nigba ti o ya mo ṣe baptism ki nle tẹ́ wọn lọrun. Bi o ti wu ki o ri, ninu ọkan mi lọhun-un, mo nimọlara pe mo jẹ́ oponu nitori pe mo koriira agabagebe ti o wa ninu Ṣọọṣi Katoliki. Ko yatọ si isin Buddha. Bakan naa gan-an ni o ṣe nlọwọ ninu ogun ati iṣelu, isin mejeeji si fọwọsi ijọsin awọn babanla ti wọn ti ku.

“Bi o ba jẹ pe mo ti duro ni Vietnam ni, emi ki ba ti ri aaye ti o pọ̀ tó lati fi kẹkọọ otitọ. Mo dagba ni akoko ti irukerudo oṣelu gba gbogbo Guusu Vietnam, mo si gbé ni ilu kan ti o jinna réré sí Saigon. Nitori naa ibukun ni o jẹ́ fun mi lati le sa asala lọ si Australia.

“Mo jẹ ọkan lara awọn ero ọkọ oju-omi ti wọn tubọ rinnakore. Pẹlu ọmọ mi oloṣu meji ni ọwọ mi, mo nilati salọ ninu okunkun lati bọ́ lọwọ ọlọpaa ki nsi wọ ọkọ oju-omi kekere kan ti a fi npẹja. Lẹhin ọjọ meji lori okun, a de Malaysia, nibi ti a duro sí fun oṣu diẹ ninu ibudo awọn olùwá-ibi-ìsádi ki a to wa si Australia.

“Lẹhin ọdun meji ati aabọ ní Australia, awọn Ẹlẹrii Jehofa kàn mi lara ninu iṣẹ ojiṣẹ ile de ile wọn. Nigba ibẹwo akọkọ, mo tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli deedee nitori pe mo rí eyi gẹgẹ bi anfaani daradara kan lati kọ ede Gẹẹsi. Ṣugbọn iwa Ẹlẹrii ti o wá mi ri ati otitọ ti o fi kọ mi wú mi lori lọpọlọpọ. Gbogbo iwe mimọ ti o ka wọ ọkan aya mi ṣinṣin, emi ko si ri agabagebe kankan ninu eto-ajọ Jehofa. Lẹhin ti mo ti kẹkọọ Bibeli fun ọdun kan ati aabọ, mo ya igbesi-aye mi si mímọ́ fun Jehofa mo si ṣe baptism.

“Mo gbọdọ sọ pe otitọ ti yi gbogbo oju iwoye mi nipa igbesi-aye pada. Ọkọ mi jẹ́ alaigbagbọ, ṣugbọn Jehofa ti ran mi lọwọ o si ti tì mí lẹhin duro, papọ pẹlu idile mi kekere. Oun ti jẹ́ Atobilọla Olukọni fun mi o si ti kọ mi lati di aya ati iya ti o sanju. Mo nbaa lọ lati dupẹ lọwọ Jehofa nitori pe o ti ran mi lọwọ lati jade kuro ninu okunkun tẹmi sinu imọlẹ otitọ Bibeli.”

Nitootọ, Ọrọ onimisi Ọlọrun lo agbara fun rere ninu ọrọ yii. Kikẹkọọ Bibeli ati fifi ohun ti a kọ́ silo mu ki igbesi-aye ni itumọ ati ète o si nṣamọna sí iye ayeraye ninu aye titun ti Ọlọrun. Gẹgẹ bi Ọlọrun ti misi Mose lati sọ, “kii ṣe ohun asan fun yin; nitori pe iye yin ni.”—Deuteronomi 32:47.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́