ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/22 ojú ìwé 21-23
  • Ǹjẹ́ O Ń Tọ́jú—Èékánná Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Ń Tọ́jú—Èékánná Rẹ?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣètò Dídíjú
  • Ìwúlò Wọn
  • Ìtọ́jú Yíyẹ Ń Fún Wọn Lágbára sí I
  • Bíbójútó Bí Wọ́n Ṣe Ń Hù àti Ẹwà Wọn
  • Ohun Tuntun Táá Máa Wáyé ní Ìpàdé Àárín Ọ̀sẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ṣíṣàfọwọ́rá Ṣé Eré Ọwọ́ Ni Àbí Ìwà Ọ̀daràn?
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 5/22 ojú ìwé 21-23

Ǹjẹ́ O Ń Tọ́jú—Èékánná Rẹ?

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Sweden

KÁ NÍ ẹnì kan sọ pé: “Jẹ́ kí n wo èékánná rẹ,” kí ni ìwọ yóò ṣe? Ṣé ìwọ yóò fi èékánná rẹ tí o tọ́jú dáradára hàn tayọ̀tayọ̀, tàbí ìwọ yóò yára fi ọwọ́ rẹ pamọ́ sẹ́yìn rẹ ni? O lè ní ìdí láti fi èékánná rẹ pamọ́. Bóyá wọn kò dára, tàbí o máa ń jẹ èékánná. Mímọ̀ sí i nípa ìgbékalẹ̀ àgbàyanu tí èékánná wa ní yóò jẹ́ kí a túbọ̀ mọyì wọn dáradára, ó sì lè mú kí a máa tọ́jú wọn.

Lájorí ohun tí ó di èékánná ni àwọn òkú sẹ́ẹ̀lì tó ti dì pọ̀ di líle, tó ní èròjà keratin onífọ́nrán tó jẹ́ oríṣi protein kan nínú. Bí èékánná ṣe ń yára hù nínú ìka kọ̀ọ̀kan àti lọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan kò dọ́gba. Èékánná máa ń hù ní ìpíndọ́gba nǹkan bí mìlímítà mẹ́ta láàárín oṣù kan. Èékánná tí a bá dá sí lè gùn dé ìwọ̀n yíyanilẹ́nu kan. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Guinness Book of World Records 1998 ṣe sọ, ọkùnrin ará Íńdíà kan dá èékánná ìka márààrún ọwọ́ òsì rẹ̀ sí, wọ́n sì gùn tó 574 sẹ̀ǹtímítà lápapọ̀. Èékánná àtàǹpàkò rẹ̀ gùn ní sẹ̀ǹtímítà 132.

Ìṣètò Dídíjú

Bí o bá wo èékánná fìrí, o lè rò pé ẹyọ kan ni, abala èékánná. Nítorí náà, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé a lè ka èékánná sí ohun tó ní àwọn ẹ̀yà mélòó kan tí ó ṣeé rí àti àwọn kan tí a kò lè rí. Ẹ jẹ́ kí a wo ìgbékalẹ̀ èékánná láwòfín.

1. Abala èékánná. Èyí ni ẹ̀yà nínípọn tí a sábà máa ń pè ní èékánná. Abala èékánná ní ìpele méjì, ti òkè àti ti ìsàlẹ̀. Bí a ṣe to àwọn sẹ́ẹ̀lì inú àwọn apá méjèèjì yàtọ̀ síra, bí wọ́n sì ṣe ń yára hù kò dọ́gba. Ara èyí tó wà lókè ń dán bọ̀rọ́bọ̀rọ́, nígbà tí ara ti ìsàlẹ̀ ní àwọn ìhunjọ tí kò fara kanra, tó ṣeé pè ní ìlà abẹ́ èékánná lórí ibi tí èékánná sùn lé. Ìlà abẹ́ èékánná ẹni méjì kì í jọra, ó sì ṣeé lò bí ohun ìdánimọ̀ kan.

2. Ìdí èékánná. Èyí ni apá tó funfun, tó dà bí àṣẹ̀ṣẹ̀lé-oṣù nísàlẹ̀ abala èékánná. Gbogbo èékánná kọ́ ló ní ìdí èékánná tó hàn sí gbangba. Èékánná máa ń hù láti inú ìṣùpọ̀ alààyè ẹran ara kékeré tó wà nísàlẹ̀ abala èékánná, tí a ń pè ní ẹran ìdí èékánná. Èyí ni apá tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbékalẹ̀ èékánná. Ìdí èékánná ni orí ẹran ìdí èékánná, nípa bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ apá tó hàn síta lára alààyè èékánná náà. Àwọn òkú sẹ́ẹ̀lì ló para pọ̀ di gbogbo èyí tó kù lára abala èékánná.

3. Awọ eteetí èékánná, ti ìsàlẹ̀ àti ti ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́. Ìwọ̀nyí ni àwọn awọ tó yí eteetí abala èékánná ká. Awọ yìí kò parí sídìí abala èékánná, ńṣe ló ṣẹ́ sínú, tó sì bo abala èékánná tí ń yọ bọ̀ náà. Àwọn awọ wọ̀nyí ń dáàbò bo àwọn àyíká èékánná náà, wọ́n sì ń fún ìdí rẹ̀ lágbára.

4. Awọ ìbòdí èékánná. Èyí ni abala awọ tẹ́ẹ́rẹ́ tó dà bí pé ó parí síbi ìdí abala èékánná náà. Nígbà mìíràn, wọ́n ń pè é ní awọ tó yọ síta.

5. Awọ tó yọ síta. Ojúlówó awọ tó yọ síta jẹ́ ìmúgbòòrò kékeré kan lábẹ́ awọ ìbòdí èékánná. Ó jẹ́ ìpele awọ tó ti bó, tí kò ní àwọ̀ kan pàtó, tí ó lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ abala èékánná nísàlẹ̀.

6. Orí èékánná tó yọ síta. Apá tó yọ kọjá ìka lára èékánná.

7. Ẹran ara àlẹ̀pa. Ẹran ara yìí tó wà lábẹ́ orí èékánná tó yọ síta ló dí abẹ́ èékánná pa tó bẹ́ẹ̀ tí omi kò lè wọlé, òun ló ń dáàbò bo ibi tí èékánná sùn lé lọ́wọ́ àkóràn àrùn.

Ìwúlò Wọn

Àwọn èékánná wa wúlò lọ́nà púpọ̀, bí fífi họ nǹkan. Wọ́n wúlò nígbà tí a bá ń bó ọsàn, tí a bá ń tú ìdè ara nǹkan, tàbí tí a bá ń lo àwọn nǹkan kéékèèké. Síwájú sí i, èékánná ló ń fún orí ìka tí kì í pẹ́ mọ nǹkan lára lágbára, tó sì ń dáàbò bò ó.

Kò yẹ kí a gbójú fo ìjẹ́pàtàkì èékánná nínú ẹwà. Àwọn èékánná wa lè fi àṣà ìtúnraṣe—tàbí àìtúnraṣe—hàn. Wọ́n ń kópa pàtàkì nínú ìfaraṣàpèjúwe lásán, bí a bá sì tọ́jú wọn dáradára, wọ́n lè mú kí àwọn ọwọ́ wa lẹ́wà. Bí kò bá sí wọn, a kò ní lè ṣe àwọn ohun kan nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, yóò sì jọ pé àwọn ọwọ́ wa kò pé.

Ìtọ́jú Yíyẹ Ń Fún Wọn Lágbára sí I

Ó yẹ kí a tọ́jú àwọn èékánná wa bó ṣe yẹ nítorí pé wọ́n jẹ́ apá kan nínú àgbàyanu ara wa. Bí o bá ní àbùkù gidi kan nínú èékánná rẹ, ó yẹ kí o lọ rí dókítà. Ká sọ òótọ́, o lè ní àmì àìsàn ara díẹ̀ ní orí ìka rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni, a ti gbọ́ pé a lè mọ àwọn àìsàn kan nípa wíwulẹ̀ wo èékánná rẹ.

Ǹjẹ́ jíjẹ èròjà calcium tàbí fítámì sí i máa ń mú kí èékánná lágbára sí i? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Bo Forslind, olùwádìí kan nípa èékánná ní Ilé Ẹ̀kọ́ Karolinska ní Stockholm, Sweden, sọ fún Jí! pé: “Kò tíì sí ẹ̀rí kankan láti ti èrò yẹn lẹ́yìn. Àyẹ̀wò èròjà calcium tó wà nínú èékánná lọ́nà tó wọ́pọ̀ wulẹ̀ fi àwọn àmì díẹ̀ hàn pé èròjà yìí wà níbẹ̀ ni.”

Ní gidi, omi ló ń ṣèrànlọ́wọ́ láti mú kí àwọn èékánná rẹ lágbára, kí wọ́n sì rọ́. Bí a ti sọ ṣáájú, èékánná ní èròjà keratin. Àwọn fọ́nrán keratin wọ̀nyí ń fẹ́ omi kí wọ́n lè rọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n Forslind fúnni ní àpẹẹrẹ kan pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ègé èékánná tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ gé lè rọ́, ègé èékánná kan náà yóò ti ṣeé rún gan-an nígbà tí ó bá gbẹ mọ́jú.” Ọ̀rinrin yóò mú kí èékánná rẹ rọ́, kí ó sì lágbára. Ṣùgbọ́n ibo ni ọ̀rinrin yìí ti ń wá? Ó jọ pé abala èékánná le, ṣùgbọ́n omi lè wọ inú rẹ̀. Ọ̀rinrin tí ń wá láti ibi tí èékánná sùn lé ń gba inú abala èékánná lọ sí gbangba, níbi tó ti ń gbẹ. Kí ni a lè ṣe ki èékánná máà máa gbẹ, kí èékánná sì máa lágbára? Ọ̀jọ̀gbọ́n Forslind sọ pé: “Fífi epo pa á lójoojúmọ́ ṣàǹfààní.”

Bíbójútó Bí Wọ́n Ṣe Ń Hù àti Ẹwà Wọn

Níwọ̀n bí èékánná ti ń hù láti inú ẹran ìdí èékánná, ó ṣe pàtàkì pé kí a máa tọ́jú ẹ̀yà ara yìí bó ṣe yẹ. Títa ẹran ìdí èékánná jí nípa fífi ìpara tàbí epo ra á déédéé lè ṣe abala èékánná láǹfààní. Láfikún sí í, kíkán epò díẹ̀ sábẹ́ orí èékánná tó yọ síta tún lè ṣàǹfààní, nítorí pé kì í jẹ́ kí èékánná gbẹ.

Bí o ṣe ń fá èékánná rẹ tàbí bí o ṣe ń gé wọn lè mú kí wọ́n lágbára tàbí kí wọ́n di aláìlágbára. Àbá wà pé kí o máa fá èékánná rẹ láti ẹ̀gbẹ́ lọ sí àárín. Fi sọ́kàn pé fífá àwọn igun èékánná dà nù ń sọ èékánná di aláìlágbára. Èyí yóò mú kí èékánná ṣe sósóró, tí ó jẹ́ ìrísí aláìlágbára jù lọ, nítorí pé kò sí ohun tó mú un mọ́lẹ̀ ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́. Láti ní èékánná kúkúrú tó lágbára, àbá wà pé kí o jẹ́ kí èékánná rẹ yọ tó nǹkan bí mìlímítà 1.5 ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, kí o sì fá a roboto bí igun orí ìka ti rí.

Àwọn obìnrin kan lè fẹ́ kí èékánná wọn fi díẹ̀ gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ìṣọ́ra kan wà. Èékánná tó bá gùn jù lè gba àfiyèsí tí kò tọ́, kí ó sì dí ọ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Nítorí náà, ní èrò tó wà déédéé nípa bí èékánná rẹ ṣe gùn tó. Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, èékánná rẹ yóò jẹ́ búrùjí kan, yóò sì fún àwọn ẹlòmíràn ní èrò rere.

Àwọn ògbógi sọ pé, má ṣe fi nǹkan mímú kankan kó ìdọ̀tí abẹ́ èékánná rẹ. Èyí lè ba ẹran ara àlẹ̀pa, tó wà lábẹ́ orí èékánná tó yọ síta jẹ́. Ẹran ara yìí ló dí abẹ́ èékánná pa, tó sì ń dáàbò bò ó. Bí eléyìí bá bàjẹ́, ó lè ya èékánná kúrò lára ibi tó sùn lé, kí ó sì kó àrùn. Bí o bá fẹ́ kó ìdọ̀tí abẹ́ èékánná, lo búrọ́ọ̀ṣì tó ṣe múlọ́múlọ́ gan-an.

Lọ́nà kan, èékánná tó lágbára, tí ara rẹ̀ sì dá ṣáṣá máa ń jẹ́ nítorí àwọn kókó àjogúnbá kan. Ìdí nìyẹn tí àwọn ènìyàn kan fi ń ní abala èékánná tó lágbára tó sì rọ́, nígbà tí àwọn mìíràn ń ní èékánná tó gbẹ tàbí tó lè tètè ṣẹ́. Ipò tó wù kí èékánná rẹ wà, o lè mú kí ó ní ìrísí tó sàn nípa ṣíṣe ìtọ́jú rẹ̀ níwọ̀nba, àti nípa ṣíṣe é déédéé. Ní tòótọ́, mímọ ìṣètò, ìṣiṣẹ́, àti ìtọ́jú yíyẹ nípa ìgbékalẹ̀ èékánná ń fún ọ lóye bí o ṣe lè ṣe é. Fífọgbọ́nlo irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ yóò yọrí sí rere.

Ní gidi, èékánná jẹ́ àgbàyanu ẹ̀yà kan lára ènìyàn. Ìṣètò àti ìṣiṣẹ́ rẹ̀ jẹ́rìí sí olóye tí ó ṣe é. Ọba Dáfídì ti ìgbà láéláé fìrẹ̀lẹ̀ kan sáárá sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀, bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Sáàmù 139:14 pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

1. Abala èékánná;

2. ìdí èékánná;

3. awọ eteetí èékánná, ti ìsàlẹ̀ àti ti ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́;

4. awọ ìbòdí èékánná;

5. awọ tó yọ síta;

6. orí èékánná tó yọ síta;

7. ẹran ara àlẹ̀pa;

8. ẹran ìdí èékánná;

9. ibi tí èékánná sùn lé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́