ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 December ojú ìwé 5
  • Ohun Tuntun Táá Máa Wáyé ní Ìpàdé Àárín Ọ̀sẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tuntun Táá Máa Wáyé ní Ìpàdé Àárín Ọ̀sẹ̀
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Òwú Àtùpà Tí Ń jó Lọ́úlọ́ú Pa Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Kristi Wọ Jerusalẹmu Pẹlu Ayọ̀ Ìṣẹ́gun
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ọba Gun Ọmọ Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọ Jerúsálẹ́mù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • A7-G Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Ṣe Kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù (Apá Kìíní)
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 December ojú ìwé 5
Ìhìn Rere Mátíù látinú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun èyí tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ìkànnì

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ohun Tuntun Táá Máa Wáyé ní Ìpàdé Àárín Ọ̀sẹ̀

Bẹ̀rẹ̀ láti January 2018, ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ wa máa ní apá kan tá a pè ní àlàyé ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwòrán àti fídíò tá a mú jáde látinú ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun èyí tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ (nwtsty) lórí ìkànnì, kódà tí ẹ̀dà Bíbélì yìí kò bá tiẹ̀ tíì sí ní èdè rẹ. Ó dájú pé apá tuntun yìí máa jẹ́ kó o túbọ̀ gbádùn bó o ṣe ń múra ìpàdé sílẹ̀. Àmọ́ ní pàtàkì, a nígbàgbọ́ pé ó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́.

ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀

Àlàyé ọ̀rọ̀ máa fún wa ní ìsọfúnni nípa àṣà, ilẹ̀ àti èdè tó máa jẹ́ ká túbọ̀ ní òye tó jinlẹ̀ nípa ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì.

Mátíù 12:20

Òwú àtùpà: Láyé àtijọ́, amọ̀ ni wọ́n máa ń fi ṣe àtùpà, wọ́n á wá bu òróró ólífì sínú rẹ̀. Òwú àtùpà náà máa fa òróró sókè kí iná lè máa jó. Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n tú sí “òwú àtùpà” lè jẹ́ òwú tó máa ń yọ èéfín tí iná orí rẹ̀ bá ti kẹ̀ bó ṣe ń jó lọ́úlọ́ú tàbí tí iná rẹ̀ bá ti kú. Aísáyà 42:3 sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa jẹ́ aláàánú, ó sọ pé kò ní fẹ́ iná ìrètí tí ó ṣẹ́ kù pa lára àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àtàwọn tó sorí kọ́.

Mátíù 26:13

Lóòótọ́: Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà, a·menʹ, wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà ʼa·menʹ, tó túmọ̀ sí “bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí,” tàbí “á rí bẹ́ẹ̀.” Jésù sábà máa ń lo gbólóhùn yìí tó bá fẹ́ sọ̀rọ̀, tó bá fẹ́ ṣe ìlérí tàbí tó bá fẹ́ sọ tẹ́lẹ̀, láti fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni òun ń sọ àti pé ọ̀rọ̀ òun ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Ọ̀nà tí Jésù gbà lo ọ̀rọ̀ náà “lóòótọ́,” tàbí àmín, ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an nínú Ìwé Mímọ́. Tí wọ́n bá lò ó léraléra (a·menʹ a·menʹ), gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìhìn Rere Jòhánù, gbólóhùn Jésù náà túmọ̀ sí “lóòótọ́-lóòótọ́.”​—Jo 1:51.

ÀWÒRÁN ÀTI FÍDÍÒ

Àwòrán àtàwọn fídíò tó ṣàlàyé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nínú Bíbélì.

Bẹtifágè, Òkè Ólífì, àti Jerúsálẹ́mù

Fídíò kékeré yìí fi ọ̀nà kan hàn tó gba abúlé et-Tur (tí àwọn èèyàn gbà pé òun ni Bẹtifágè àtijọ́) wọlé sí Jerúsálẹ́mù láti apá ìlà oòrùn lọ sí apá ibi tó ga jù lórí Òkè Ólífì. Ìlú Bẹ́tánì ní tiẹ̀ wà ní ìlà oòrùn ìlú Bẹtifágè tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìlà oòrùn Òkè Ólífì. Nígbàkúgbà tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá wá sí Jerúsálẹ́mù, Bẹ́tánì ni wọ́n sábà máa ń sùn sí. Lónìí, ìlú tó wà ní ọ̀gangan ibi tí Bẹ́tánì wà nígbà yẹn ni wọ́n ń pè ní el-ʽAzariyeh (El ʽEizariya ) ní èdè lárúbáwá, èyí tí ó túmọ̀ sí “Ilé Lásárù.” Èyí fi hàn lóòótọ́ pé ilé tí Màtá, Màríà àti Lásárù ń gbé ni Jésù máa ń dé sí. (Mt 21:17; Mk 11:11; Lk 21:37; Jo 11:1) Tí Jésù bá ń rin ìrìn àjò láti ilé wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀nà tó wà nínú fídíò yẹn ló máa ń gbà. Ní oṣù Nísàn 9, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, tí Jésù gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gba orí Òkè Olífì lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Bẹtifágè ló ti kúrò, tó sì gba ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.

Ọ̀nà tó ṣeé ṣe kí Jésù máa gbà láti Bẹ́tánì lọ sí Jerúsálẹ́mù
  1. Ọ̀nà láti Bẹ́tánì lọ sí Bẹtifágè

  2. Bẹtifágè

  3. Òkè Ólífì

  4. Àfonífojì Kídírónì

  5. Òkè Tẹ́ńpìlì

Ìṣó nínú Egungun Gìgísẹ̀

Ìṣó nínú egungun gìgísẹ̀ èèyàn

Àwòrán ohun tó jọ egungun gìgísẹ̀ èèyàn rèé, wọ́n sì fi ìṣó irin tí ó gùn tó sẹ̀ńtímítà mọ́kànlá ààbọ̀ [11.5 cm] gún un ní àgúnyọ. Ọdún 1968 ni wọ́n rí egungun yìí, nígbà tí wọ́n ń walẹ̀ ní apá àríwá Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣeé ṣe kó ti wà níbẹ̀ látìgbà ayé àwọn ará Róòmù. Ó jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé wọ́n máa ń lo ìṣó nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kan àwọn èèyàn mọ́gi. Ó ṣeé ṣe kí ìṣó yìí jọ irú èyí tí àwọn ọmọ ogun Róòmù fi kan Jésù Kristi mọ́gi. Inú òkúta kan tí wọ́n gbẹ́ bí àpótí ni wọ́n ti rí egungun yìí. Inú irú àwọn òkúta bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń kó egungun àwọn tó bá ti kú sí, lẹ́yìn tí ẹran ara wọn bá ti jẹrà. Èyí sì fi hàn pé wọ́n lè sìnkú ẹni tí wọ́n bá kàn mọ́gi.​—Mt 27:35.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́