WÍwo Ayé
Ó Sàn Ju Èyí Tí Ènìyàn Ṣe Lọ
Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ròyìn pé: “Ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tí ìjì wó mílíọ̀nù 15 igi ní England ní 1987, a rí i pé àwọn àgbègbè igbó tí ènìyàn kò ṣe ohunkóhun lórí rẹ̀ ti hù padà lọ́nà tó dára jù. Ní àwọn ibi tí igi ti ṣubú, ìmọ́lẹ̀ ráyè dé ilẹ̀ sí i. Èyí mú kí àwọn igi kéékèèké lè ga tó mítà mẹ́fà, àwọn kòkòrò, ẹyẹ, àti irúgbìn pẹ̀lú sì ti gbilẹ̀. Ọ̀pọ̀ igi apádò àti igi yew tó ṣubú kò jẹrà gẹ́gẹ́ bí a ti retí, gẹdú wọn, tó ti gbẹ dénú dáadáa nísinsìnyí sì níye lórí ní ìlọ́po mẹ́ta. Alágbàwí ààbò ẹ̀dá náà, Peter Raine, wí pé: “Àwọn àtúnṣe elérò rere [tí ènìyàn ṣe] túbọ̀ ba nǹkan jẹ́ ju bí ìjì náà fúnra rẹ̀ ti ṣe lọ. Ọ̀pọ̀ lára àwọn igi tí a gbìn ní ìgbà ìwọ́wé yẹn ni a fìkánjú gbìn, tí a kò gbìn dáradára, tí wọ́n sì kú.”
Iṣẹ́, Ìdààmú, àti Àrùn Ọkàn-Àyà
Ìwé ìròyìn Frankfurter Rundschau ròyìn pé, dída ọpọlọ láàmú lẹ́nu iṣẹ́ ni kókó pàtàkì tó gba ipò kejì nínú àwọn ohun tí ń fa àwọn àrùn ọkàn àti àwọn àrùn tó kan bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń ṣàn yí ara ká, sìgá mímu ló gba ipò kìíní. Nígbà tí ó ń ṣàkópọ̀ ìwádìí kan tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Àpapọ̀ Lórí Ìlera àti Ààbò Lẹ́nu Iṣẹ́, ní Berlin, Germany, ṣe, ìròyìn náà wí pé: “Àwọn tó wà nínú ewu jù ni àwọn òṣìṣẹ́ tí àǹfààní tí wọ́n ní láti ṣèpinnu mọ níwọ̀n, tí iṣẹ́ wọn kì í sì fi bẹ́ẹ̀ yí padà. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n tún ní pákáǹleke ní àwọn àkókò ọwọ́dilẹ̀ wọn, bí àpẹẹrẹ, nítorí wọ́n ń kọ́lé ara wọn lọ́wọ́ tàbí wọ́n ń tọ́jú ẹbí kan tí ń ṣàìsàn, a jẹ́ pé ewu àrùn ọkàn-àyà náà yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ sí i dé ìlọ́po mẹ́sàn-án.” Ògbógi kan rọni pé kí a túbọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ láǹfààní sí i láti máa ṣèpinnu. “Ìjíròrò kan ṣoṣo péré lóṣù láàárín gbogbo òṣìṣẹ́ ẹ̀ka kan lè mú nǹkan dára sí i.”
‘Ohun Ìrìnnà Tó Gbéṣẹ́ Jù Lágbàáyé’
Ìwé ìròyìn The Island, ti Colombo, Sri Lanka, ròyìn pé, nígbà tí o bá ń rin ìrìn àjò ti kò tó kìlómítà mẹ́jọ láàárín ìlú, kẹ̀kẹ́ lè yá ju mọ́tò lọ. Ẹgbẹ́ alágbàwí àbójútó àyíká lágbàáyé tí ń jẹ́ Àwọn Ọ̀rẹ́ Ilẹ̀ Ayé pe kẹ̀kẹ́ ní “oríṣi ohun ìrìnnà tó gbéṣẹ́ jù lórí Ilẹ̀ Ayé.” Ìròyìn náà sọ pé, wọ́n sọ pé kẹ̀kẹ́ lè rin 2,400 kìlómítà láìbafẹ́fẹ́jẹ́, tí kò sì lò ju agbára tí a ń rí nínú oúnjẹ tí ó dọ́gba pẹ̀lú ìwọ̀n gálọ́ọ̀nù epo ọkọ̀ kan ṣoṣo lọ. Ó tún ṣàfikún pé, kẹ̀kẹ́ tún ń mára le.
Àwọn Abúmọ́ni Ń Pọ̀ sí I
Ìwádìí kan tí Yunifásítì La Sapienza ti Róòmù ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ fi hàn pé ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ń kojú oríṣiríṣi ìbúmọ́ni títí kan èébú, líluni, jíjanilólè pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, ìlekokomọ́ni, àti ìhalẹ̀mọ́ni. A kíyè sí àwọn ìwà búburú wọ̀nyí ní pàtàkì, ní Róòmù, níbi tí iye tí ó lé ní ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ti jìyà ìbúmọ́ni láàárín oṣù mẹ́ta péré. Ìwé ìròyìn La Repubblica ti ilẹ̀ Ítálì sọ pé, olùwádìí Anna Costanza Baldry, ṣàlàyé pé: “Nínú àwọn ìjíròrò tó túbọ̀ jinlẹ̀, ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin mẹ́nu ba àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìfìbálòpọ̀-fìtínà-ẹni bíburújáì tí wọn kò fi sùn, nítorí ìbẹ̀rù àti . . . nítorí pé wọ́n ka àwọn oríṣi ìwà pálapàla kan sí èyí tó wọ́pọ̀.”
Àwọn ọmọdé nìkan kọ́ ni a ń bú mọ́. Ìwé ìròyìn The Irish Times ròyìn pé ọ̀pọ̀ àgbàlagbà ni a ń bú mọ́ níbi iṣẹ́ wọn, púpọ̀ ló jẹ́ pé àwọn ọ̀gá ló ń bú mọ́ wọn. Ó wí pé: “Fífi ọ̀rọ̀ nani lọ́rẹ́, ṣíṣàríwísí iṣẹ́ àwọn ènìyàn àti títan àwọn àhesọ kálẹ̀ nípa wọn ni àwọn ọ̀nà tí àwọn abúmọ́ni níbi iṣẹ́ ń yàn láàyò jù. Ìtẹ́nilógo àti gbígbé góńgó tí ọwọ́ kò lè tẹ̀ kalẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ tún wọ́pọ̀.” Ìwé ìròyìn Times náà sọ pé, wọ́n ti rí i pé ìbúmọ́ni ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìyọrísí ìrònú òun ìhùwà tó ní “hílàhílo, ìbínú, ìsoríkọ́, èrò pé a ń dọdẹ ẹni, másùnmáwo, àìnígbọkànlé, àìní iyì ara-ẹni àti ìyọra-ẹni-sọ́tọ̀” nínú. Nínú àwọn ọ̀ràn tó le jù, irú ìbúmọ́ni yìí lè mú “kí ènìyàn wó tàbí kí ó pa ara rẹ̀ pàápàá.”
Ìgbọ́mọjáde Tàbí Ìbímọ Lọ́nà Àdánidá?
Àwọn dókítà àti àwọn ìyá ní Brazil sábà máa ń yan ìgbọ́mọjáde láàyò ju ìbímọ lọ́nà àdánidá lọ. Ìwé ìròyìn Veja sọ pé, dókítà ń rí i pé “òun lè gbẹ̀bí púpọ̀ sí i, kí òun pawó púpọ̀ sí i ní ọ́fíìsì òun, òun kò sì ní pàdánù òpin ọ̀sẹ̀ òun.” Àwọn ìyá “ń yàn láti máà bímọ lọ́nà àdánidá, kí wọ́n lè yẹra fún ìrora (bí ó ti wù kí ó rí, ìrora tó wà nínú ìkọ́fẹpadà lẹ́yìn ìgbọ́mọjáde pọ̀ ju ti ìbímọ lọ́nà àdánidá lọ), wọ́n sì gbà pé ìlànà náà ṣàǹfààní fún ara lọ́nà ti ẹwà (tí kò rí bẹ́ẹ̀).” Ní àwọn ilé ìwòsàn ìjọba, ìdámẹ́ta gbogbo ìbímọ jẹ́ nípa ìgbọ́mọjáde, ó sì pọ̀ tó ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún ní àwọn ilé ìwòsàn àdáni kan. Dókítà João Luiz Carvalho Pinto e Silva, olórí ẹ̀ka ìṣègùn tó jẹ mọ́ ìbímọ ní Yunifásítì Campinas, sọ pé: “Ìbímọ ti di ọjà tí a ń tà. Àwọn ènìyàn sábà máa ń gbàgbé pé yàtọ̀ sí bí ó ṣe jẹ́ ní ti ìbímọ lọ́nà àdánidá, oríṣi iṣẹ́ abẹ kan ni ìgbọ́mọjáde. A ń pàdánù ẹ̀jẹ̀ jù, àkókò ìpàmọ̀lára ń gùn jù, ṣíṣeéṣe tí ó ṣeé ṣe láti kó àrùn sì ń pọ̀ sí i.” Ìwé ìròyìn Veja sọ pé, gẹ́gẹ́ bí dókítà náà ṣe sọ, “nínú àwọn ọ̀ràn mẹ́ta péré ló ti yẹ ká máa lo ìgbọ́mọjáde: nígbà tí ìwàláàyè ìyá tàbí ti ọmọ bá wà nínú ewu, nígbà tí kò bá sí àmì ìrọbí, tàbí nígbà tí àwọn ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀.”
Ìtara Ìsìn Ń Dín Kù ní Gíríìsì
Ìwé ìròyìn Ta Nea ti Áténì tẹ ìwádìí kan lórí ìsìn ní ilẹ̀ Gíríìsì, tí ó jọ èyí tí ó ṣe ní 1963, jáde láìpẹ́ yìí. Àbájáde náà fi hàn pé ìtara ìsìn dín kù gan-an ní orílẹ̀-èdè náà. Ní ìran kan sẹ́yìn, ìpín 66 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé ó kéré tán, àwọn ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́ẹ̀mejì tàbí ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lóṣù, àwọn tó sọ bẹ́ẹ̀ nínú ìwádìí àìpẹ́ yìí kò tó ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún. Bí ìròyìn Reuters ṣe sọ, ní àgbègbè Áténì ńlá, ó lé ní ìpín méjì nínú mẹ́ta lára 965 àgbàlagbà tí wọ́n bi lọ́rọ̀, tó sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì wúlò “díẹ̀” fún àwùjọ tàbí pé “kò wúlò rárá.” Nígbà tí gbajúmọ̀ olùwádìí ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì náà, Elias Nikolakopoulos, ń kọ ọ̀rọ̀ nínú ìwé ìròyìn Ta Nea, ó sọ nípa “sísọ àwùjọ ilẹ̀ Gíríìkì di aláìka-ìsìn-sí díẹ̀díẹ̀,” ó sì kíyè sí i pé ní báyìí, àwọn ènìyàn ti ń ní “ìfura àti ìkórìíra” sí ṣọ́ọ̀ṣì ní Gíríìsì.
Fi Àwọn Ẹrù Ìwé Tí A Kò Béèrè fún Tòmátì
Kí ni ilé ìfìwéránṣẹ́ kan lè fi 454 tọ́ọ̀nù ìwọ̀n mítà ẹrù ìwé oṣooṣù tí a kò béèrè fún, tí kò sí ẹni tí yóò gbà wọ́n, títí kan àwọn ìwé ajúwe ẹrù àti àwọn ìwé ìpolówó ọjà mìíràn ṣe? Ilé ìfìwéránṣẹ́ Dallas-Fort Worth, Texas, ti bẹ̀rẹ̀ sí kó púpọ̀ lára rẹ̀ ránṣẹ́ láti fi wọ́n ṣe ajílẹ̀. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé, wọ́n wá ń fi àwọn ajílẹ̀ náà gbin tòmátì àti ewébẹ̀ marigold, ó sì ṣeé ṣe kí ó yọrí sí rere. Wọ́n ń fi ọtí bíà kíkan àti àwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò, àwọn ohun tí kò wúlò fún àwọn pọntípọntí mọ́, bọ́ àwọn bakitéríà tí ń sọ àwọn ẹrù ìwé tí a gé sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ náà di ajílẹ̀. Ọtí bíà àti èròjà sódà náà ń ní ṣúgà nínú, ìyẹn sì ni oúnjẹ àwọn bakitéríà náà. Joel Simpson, igbákejì ààrẹ ilé iṣẹ́ ajílẹ̀ tí ń ṣe àfidánrawò náà, sọ pé: “Àwọn ohun kan náà tí ń mú ká sanra ní ń mú àwọn bakitéríà wọ̀nyẹn náà sanra, tó sì ń mú wọn láyọ̀.”
Ìtọ́jú fún Àwọn Tó Ní Àwọn Àrùn Awọ Ara
Ìwé ìròyìn The Irish Times ròyìn pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ní àwọn àrùn awọ ara ni kì í wá ìtọ́jú nítorí ìtìjú, wọ́n sì lè lo ọ̀pọ̀ ọdún ‘tí wọ́n fi ń mú ìrora mọ́ra.’” Nígbà tí Dókítà Gillian Murphy ń tẹnu mọ́ ìṣòro tí wọ́n ní, ó wí pé: “Àwọn aláìsàn kan tí ń wá gbàtọ́jú lọ́dọ̀ mi ní àrùn psoriasis, tí awọ ara wọn ń bó ní ti gidi nígbà tí wọ́n bá ń bọ́ aṣọ wọn, wọ́n sì ka ara wọn sí aláìmọ́ àti ẹni ìtìjú tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò jẹ́ gbé òtẹ́ẹ̀lì tàbí kí wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn aṣerunlọ́sọ̀ọ́.” Bill Cunliffe, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa awọ ara ní Yunifásítì Leeds, fi kún un pé: “Irorẹ́ ń nípa lórí àwọn ènìyàn nínú ara àti nínú ọpọlọ. Wọ́n ní èrò náà pé èérí ni, ó sì ń ranni. Bí ẹni méjì tó ní agbára láti ṣiṣẹ́ bákan náà bá wá fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, èyí tí kò ní irorẹ́ nínú wọn ni iṣẹ́ náà yóò bọ́ sí lọ́wọ́.” Cunliffe sọ pé, àwọn aláìsàn kan ti wá sọ́dọ̀ òun tí níní tí wọ́n ní irorẹ́ ti pá wọn láyà débi tí wọ́n ti gbìyànjú láti pa ara wọn. Àwọn dókítà tó wà níbi Àpérò Ilé Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ìmọ̀ Nípa Awọ Ara àti Àwọn Àrùn Ìbálòpọ̀ ní Dublin, Ireland, tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí a tètè máa wá ìtọ́jú. Dókítà kan sọ pé: “Ìṣòro lílekoko ni fún àwọn ènìyàn kan, àmọ́ ó ṣe pàtàkì láti rántí pé àwọn ìtọ́jú gbígbéṣẹ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó.”
Kí Òbí Máa Bá Ọmọ Ọwọ́ Sọ̀rọ̀ —Kì Í Ṣe Ìró Dídùnmọ́ni Lásán Kẹ̀?
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé, ó ṣeé ṣe kí ó máà jẹ́ ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ lásán ni àwọn òbí tí ń bá ọmọ ọwọ́ wọn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń bá wọn ṣeré ń fún wọn. Patricia Kuhl, láti Yunifásítì Washington, àti àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ wádìí nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí a ń sọ sí àwọn ìkókó nínú èdè mẹ́ta—Russian, Swedish, àti Gẹ̀ẹ́sì. Ó jọ pé ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ àwọn òbí, tó ta yọ dáradára, kì í wulẹ̀ gba àfiyèsí àwọn ọmọ wọn lásán, ṣùgbọ́n ó tún ń jẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ọmọ náà láti kọ́ èdè ọ̀hún. Ìwé ìròyìn Science wí pé: “Nígbà tí àwọn ọmọ bá fi pé oṣù 6, wọ́n ń kọ́ láti pín àwọn ìró fáwẹ́ẹ̀lì sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, wọ́n ń fiyè sí àwọn ìyàtọ̀ tó nítumọ̀ nínú èdè àbínibí wọn, bí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ‘í’ àti ‘á,’ láìfiyèsí àwọn ìyàtọ̀ tí kò nítumọ̀.”