Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Jíjẹ́jẹ̀ẹ́ Láti Wà Láìgbéyàwó Pọndandan fún Kristẹni Òjíṣẹ́ Bí?
LÁÌDÉÈNÀPẸNU, jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó jẹ́ pípinnu láti má ṣe láya tàbí lọ́kọ rárá. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ti wí, èdè yìí “ni a sábà máa ń lò fún àwọn ẹni tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó nítorí ipa tí wọ́n ń kó gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìsìn, onísìn paraku, tàbí olùfọkànsìn.” Èdè náà “ajẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó” dúró fún “àwọn tí àìláya tàbí àìlọ́kọ wọn jẹ́ nítorí ẹ̀jẹ́ ìjọsìn tàbí ti àṣà yíyọwọ́yọsẹ̀, tàbí ti ìgbàgbọ́ pé ó sàn jù pé kí ẹnì kan ṣàìgbéyàwó nítorí ipò rẹ̀ nínú ìsìn tàbí nítorí bí ó ti fi gbogbo ara jẹ́ onísìn tó.”
Ní àkókò kan tàbí òmíràn, àwọn ìsìn kan tó lókìkí ti gba jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn dandan fún àwọn òjíṣẹ́ wọn. Síbẹ̀, kò sí ẹ̀sìn mìíràn, nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù, tó gba jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó kanríkànyà bí ẹ̀sìn Kátólíìkì. Lónìí, àìfohùnṣọ̀kan rẹpẹtẹ wà lórí jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó ti Kátólíìkì. Ìwé ìròyìn The Wilson Quarterly sọ pé, “ọ̀pọ̀ ìwádìí tí a ṣe láàárín àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí ti fohùn sí pé jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó ọlọ́ranyàn, tó jẹ́ dandan fún àwọn àlùfáà Kátólíìkì láti ọ̀rúndún kejìlá ló ń fa àwọn ìṣòro tí ṣọ́ọ̀ṣì náà ń ní lórí gbígba àwọn àlùfáà síṣẹ́, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ lọ.” Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá náà, Richard A. Schoenherr, ṣe sọ, “àwọn òtítọ́ inú ìtàn àti ìyípadà ètò àwùjọ ń lòdì sí àṣà yíyọ̀ǹda fún àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó nìkan láti di àlùfáà Kátólíìkì.” Kí ni Bíbélì sọ nípa jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó?
Gbígbéyàwó Tàbí Àìgbéyàwó?
Láti ìgbà aláyé ti dáyé ni àìlóǹkà olùfọkànsìn lọ́kùnrin àti lóbìnrin, nínú onírúurú ìsìn, ti ń yàn láti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó. Èé ṣe? Nínú ọ̀pọ̀ ọ̀ràn, ó jẹ́ nítorí pé wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ohun ti ara jẹ́ ti “ibùjókòó ibi.” Lára èyí ni àbá èrò orí náà pé ìjẹ́mímọ́ nípa ti ẹ̀mí ṣeé ṣe kìkì nípasẹ̀ yíyẹra fún gbogbo ìwà ìbálòpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí Bíbélì sọ kọ́ nìyí. Nínú Bíbélì, a fi ìgbéyàwó hàn bí ohun tí kò ní ẹ̀gbin ní ti ìwàhíhù, ó jẹ́ ẹ̀bùn mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ní kedere, àkọsílẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì fi ìgbéyàwó hàn bí ohun tó “dára” lójú Ọlọ́run, tó sì hàn gbangba pé kì í ṣe ìdènà fún ìbátan mímọ́ tẹ̀mí pẹ̀lú Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28, 31; 2:18, 22-24; tún wo Òwe 5:15-19.
Àpọ́sítélì Pétérù àti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn tí wọ́n wà ní ipò àṣẹ nínú ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ jẹ́ àwọn ọkùnrin tó gbéyàwó. (Mátíù 8:14; Ìṣe 18:2; 21:8, 9; 1 Kọ́ríńtì 9:5) Ìtọ́ni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì nípa yíyan àwọn alábòójútó ìjọ, tàbí “àwọn bíṣọ́ọ̀bù,” mú kí èyí ṣe kedere. Ó kọ̀wé pé: “Bíṣọ́ọ̀bù gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; 1 Tímótì 3:2, Revised Standard Version, Ìtẹ̀jáde ti Kátólíìkì) Ṣàkíyèsí pé kò sí ohun kankan tó dábàá pé kò bá nǹkan mu lọ́nàkọnà fún “bíṣọ́ọ̀bù kan” láti gbéyàwó. Pọ́ọ̀lù wulẹ̀ tọ́ka sí i pé “bíṣọ́ọ̀bù” kò gbọ́dọ̀ jẹ́ akóbìnrinjọ ni; pé bí ó bá gbéyàwó, ìyàwó kan péré ló yẹ kó ní. Ní gidi, ìwé agbédègbẹ́yọ̀ Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, tí McClintock àti Strong kọ, parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Kò sí apá kankan nínú Májẹ̀mú Tuntun tí a lè túmọ̀ sí pé ó ka ìgbéyàwó ẹgbẹ́ àlùfáà léèwọ̀ lábẹ́ ìṣètò Ìhìnrere.”
Nígbà tí Bíbélì pọ́n ìgbéyàwó lé, ó dájú pé kò dẹ́bi fún àìgbéyàwó bí a bá fínnúfíndọ̀ yàn án. Bíbélì dámọ̀ràn rẹ̀ bí ipa tí àwọn kan lè fọkàn fẹ́. (1 Kọ́ríńtì 7:7, 8) Jésù Kristi sọ pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin kan ń fínnúfíndọ̀ yàn láti wà láìgbéyàwó. (Mátíù 19:12) Èé ṣe? Kì í ṣe nítorí pé ohun kan jẹ́ aláìmọ́ pátápátá nípa ìgbéyàwó, tí ó sì lè dí wọn lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Wọ́n yan ọ̀nà yí kìkì kí wọ́n lè pa gbogbo ìsapá wọn pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní àkókò tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ kánjúkánjú.
Ohun Tó Fa Jíjẹ́jẹ̀ẹ́ Láti Wà Láìgbéyàwó Ọlọ́ranyàn
Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan yí padà ní àwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé àkókò Kristi. David Rice, ọmọ ẹgbẹ́ Dominican kan tó fi iṣẹ́ àlùfáà sílẹ̀ kí ó lè gbéyàwó, sọ pé, láàárín ọ̀rúndún mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú Sànmánì Tiwa, “bí àwọn òjíṣẹ́ tó gbéyàwó ṣe wà ni àwọn tí kò gbéyàwó wà.” Lẹ́yìn náà, ohun tí òǹkọ̀wé ìsìn kan pè ní “àdàlú èrò Gíríìkì àti èrò Bíbélì,” tó mú ìdàrúdàpọ̀ wá nínú èrò nípa ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó, bẹ̀rẹ̀ sí nípa lórí àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni.
Síbẹ̀, àwọn kan ṣì fẹ́ láti wà láìgbéyàwó nítorí “kí wọ́n lè ní òmìnira pátápátá láti fi [ara wọn] jin iṣẹ́ ìjọba Ọlọ́run” nìkan. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọgbọ́n èrò orí àwọn kèfèrí tí àwọn mìíràn ti gbà sínú ló ń sún wọn ṣiṣẹ́. Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ìgbàgbọ́ pé ìbálòpọ̀ takọtabo ń sọni di aláìmọ́, àti pé kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ìjẹ́mímọ́, fara hàn [nínú ṣọ́ọ̀ṣì tí a pè ní ti Kristẹni] gẹ́gẹ́ bí ìsúnniṣe tó ta yọ jù fún àṣà jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó.”
Rice sọ pé, ní ọ̀rúndún kẹrin, ṣọ́ọ̀ṣì “fi òfin de àlùfáà tó bá gbéyàwó pé kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ ní alẹ́ tó ṣáájú ṣíṣe ayẹyẹ Gbígba Ara Olúwa.” Nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀rẹ̀ Gbígba Ara Olúwa lójoojúmọ́, ó túmọ̀ sí pé àwọn àlùfáà gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún ìbálòpọ̀. Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n ṣòfin pé àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ gbéyàwó mọ́ rárá. Jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀ranyàn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti di òjíṣẹ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀mí ti sọ ní kedere pé ní àwọn àkókò ìkẹyìn, àwọn kan yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò sì yàn láti fetí sí àwọn ẹ̀mí tí ń tanni jẹ àti àwọn ẹ̀kọ́ tí ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù, . . . Wọn yóò sọ pé èèwọ̀ ni láti gbéyàwó.”—1 Tímótì 4:1, 3, Jerusalem Bible.
Jésù Kristi wí pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) A ń rí i pé ó jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti yà bàrá kúrò nínú àwọn ìlànà Ọlọ́run nínú àwọn iṣẹ́ tàbí ìyọrísí rẹ̀. Òǹkọ̀wé David Rice fọ̀rọ̀ wá ọ̀pọ̀ àlùfáà lẹ́nu wò yíká ayé lórí ọ̀ràn jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó ọlọ́ranyàn. Àwọn kan tó bá sọ̀rọ̀ sọ pé: “Máa bá iṣẹ́ àlùfáà rẹ lọ, ṣe gbogbo àǹfààní tí o bá lè ṣe fún àwọn ènìyàn, nígbà kan náà, fi ọgbọ́n lo àǹfààní ti àwọn obìnrin tí wọ́n gba tìrẹ, tí wọ́n sì ṣe tán láti bá ọ lò pọ̀.”
Nígbà tí ó ń fa ọ̀rọ̀ Mátíù 7:20 yọ, Rice wí pé: “‘Nípa èso wọn ni ẹ ó fi mọ̀ wọ́n,’ ni Jésù wí.” Ó wá sọ̀rọ̀ lórí ipò ìbànújẹ́ tí jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó ọlọ́ranyàn ti yọrí sí pé: “Èso jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó ọlọ́ranyàn ni àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkùnrin tí ń ṣekuṣẹyẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún obìnrin tí ayé wọn ti bàjẹ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ tí àwọn baba wọn tó jẹ́ àlùfáà kọ̀ láti gbà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ti àwọn àlùfáà náà fúnra wọn tí ìmọ̀lára wọn ti gbọgbẹ́ nítorí ipò náà.”
Ìgbéyàwó tó lọ́lá jẹ́ ìbùkún kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó ti já sí pé jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìgbéyàwó ọlọ́ranyàn ń ba ipò tẹ̀mí ẹni jẹ́. Ní apá kejì, nígbà tí fífínnúfíndọ̀ wà láìgbéyàwó kò ṣe pàtàkì fún ìjẹ́mímọ́ tàbí ìgbàlà, ó ti jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tó ṣàǹfààní, tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn nípa ti ẹ̀mí fún àwọn kan.—Mátíù 19:12.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]
Life