Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń wo Ìjọsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù?
JÉSÙ KRISTI wí pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ inú ìjọba àwọn ọ̀run, bí kò ṣe ẹni náà tí ń ṣe ìfẹ́ inú Bàbá mi tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, awa kò ha . . . ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò wá jẹ́wọ́ fún wọn dájúdájú pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.”—Mátíù 7:21-23.
Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mímọ́ ọlọ́wọ̀, Bíbélì Mímọ́, Ọlọ́run mú ohun tí ìfẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ ṣe kedere. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ha ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run bí? Àbí wọ́n jẹ́ ohun tí Jésù pè wọ́n ‘àwọn oníṣẹ́ ìwà àìlófin’?
Ìtàjẹ̀sílẹ̀
Ní òru ọjọ́ tí ó ṣáájú ikú Ọ̀gá rẹ̀, Peteru fẹ́rẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjà àjàkú akátá pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí a rán láti lọ fàṣẹ ọba mú Jésù. (Jòhánù 18:3, 10) Ṣùgbọ́n Jésù pẹ̀tù sí i lọ́kàn, ó sì kìlọ̀ fún Pétérù pé: “Gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) A tún ìkìlọ̀ tí ó ṣe kedere yìí sọ nínú Ìṣípayá 13:10. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ha ti kọbi ara sí i bí? Àbí wọ́n ṣàjọpín ẹ̀bi fún àwọn ogun tí ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Serbia àti Croatia ni a pa lórúkọ ìsìn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The New Encyclopædia Britannica, ròyìn pé: “Ní Croatia, ìṣàkóso ìjọba ìbílẹ̀ ti aláṣẹ oníkùmọ̀ gbé ìlànà ‘ìsọ-ẹ̀yà-ìran-di-mímọ́’ kalẹ̀, èyí tí ó lọ ré kọjá àwọn ohun tí ìjọba Nazi pàápàá ṣe. . . . A kéde pé ìdá mẹ́ta nínú àwọn ará Serbia ni a óò lé kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, a óò yí ìdá mẹ́ta padà sí ìsìn Roman Kátólíìkì, a óò sì pa ìdá mẹ́ta run yán-ányán-án. . . . Lílọ́wọ́ tí àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà wọ̀nyí lápá kan ṣe ìpalára gidigidi fún ipò ìbátan tí ó wà láàárín orílẹ̀-èdè náà àti ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́yìn tí ogun náà parí.” A fipá mú àìmọye ènìyàn láti di mẹ́ḿbà ìsìn Kátólíìkì tàbí kí wọ́n kú; ẹgbẹẹgbẹ̀rún mìíràn ni a kò tilẹ̀ fún ní yíyàn kan. Àwọn abúlé lódindi—àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé—ni a fipá mú láti lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì wọn, tí a sì pa wọ́n. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kọ́múníìsì alátakò ńkọ́? Àwọn náà ha ní ìtìlẹ́yìn ìsìn bí?
Ìwé náà, History of Yugoslavia, ròyìn pé: “Àwọn kan lára àwọn àlùfáà lọ́wọ́ nínú ogun náà ní ìhà ọ̀dọ̀ agbo ọmọ ogun aṣọ̀tẹ̀síjọba.” Ìwé náà, Yugoslavia and the New Communism, sọ pé: “Àwọn àlùfáà láti inú Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti àwọn ará Serbia àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì pàápàá wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Alátakò náà.” Àwọn èdè àìyedè ìsìn ń bá a nìṣó láti máa bu ẹ̀tù sí iná ogun ní àwọn ilẹ̀ Balkan.
Ní Rwanda ńkọ́? Akọ̀wé àgbà fún Àjọ Kátólíìkì Tí Ń Rí Sí Àjọṣe Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè, Ian Linden, gbà pé òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e yìí nínú ìwé àtìgbàdégbà The Month: “Ìwádìí àjọ Ajàfẹ́tọ̀ọ́ Àwọn Ará Áfíríkà ní London fúnni ní àpẹẹrẹ kan tàbí méjì nínú àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, Áńgílíkà àti Onítẹ̀bọmi àdúgbò tí a ti fẹ̀sùn ṣíṣàì bìkítà nínú ìpànìyàn àwọn ológun tàbí lílọ́wọ́ nínú rẹ̀ kàn. . . . Kò sí àní àní pé ọ̀pọ̀ Kristẹni tí wọ́n yọrí ọlá ní àwọn sàkàání ìtọ́jú àlùfáà, lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn.” Ó báni nínú jẹ́ pé, ìjà láàárín àwọn tí a fẹnu lásán pè ní Kristẹni ṣì ń kó wàhálà bá àárín gbùngbùn Áfíríkà.
Àgbèrè àti Panṣágà
Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wí, kìkì ètò kan ṣoṣo tí ó lọ́lá ni ó wà fún ìbálòpọ̀, ìyẹn sì jẹ́ láàárín ìdè ìgbéyàwó. Bíbélì sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ha ń gbé ẹ̀kọ́ Ọlọ́run yìí lárugẹ bí?
Ní 1989, Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà ní Australia gbé àtẹ̀jáde kan tí a fàṣẹ sí jáde lórí ìbálòpọ̀, èyí tí ó sọ pé ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó kò burú bí àwọn méjèèjì bá ti gbà láti fẹ́ ara wọn. Láìpẹ́ yìí, aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà ní Scotland sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì kò ní láti sọ pé irú àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ burú, pé ó sì jẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀. Ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́dọ̀ gbà pé àbùdá wa ni ó ń fa panṣágà.”
Ní Gúúsù Áfíríkà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwùjọ àlùfáà ti kọrin ire ki ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní 1990, ìwé ìròyìn Gúúsù Áfíríkà náà, You, ṣàyọlò ọ̀rọ̀ òjíṣẹ́ yíyọrí ọlá kan nínú ìjọ Áńgílíkà tí ó sọ pé: “Ìwé Mímọ́ kò gbé wa dè títí láé. . . . Mo gbà gbọ́ pé àwọn ìyípadà yóò wà nínú ìṣarasíhùwà ṣọ́ọ̀ṣì àti ìlànà rẹ̀ sí àwọn ọkùnrin tí ń bẹ́yà kan náà lò pọ̀.”—Fi wé Róòmù 1:26, 27.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé 1994 Britannica Book of the Year ti wí, ìbálòpọ̀ ti di ọ̀ràn tí ó hàn gbangba jù lọ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì America, ní pàtàkì nínú àwọn ọ̀ràn bíi “fífi àwọn tí a kéde pé wọ́n jẹ́ ọkùnrin tí ń bẹ́yà kan náà lò pọ̀ àti àwọn obìnrin tí ń bẹ́yà kan náà lò pọ̀ joyè nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí ìsìn lóye ẹ̀tọ́ àwọn ọkùnrin tí ń bẹ́yà kan náà lò pọ̀, gbígbàdúrà sórí ‘ìgbéyàwó àwọn abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀,’ àti fífàṣẹ sí tàbí ṣíṣàì fọwọ́ sí àwọn ìgbésí ayé tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀.” Ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀ya ṣọ́ọ̀ṣì fàyè gba àwọn àlùfáà tí ń polongo fún òmìnira púpọ̀ sí i nínú ìbálòpọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé 1995 Britannica Book of the Year ṣe sọ, àwọn bíṣọ́ọ̀bù 55 nínú ìjọ Episcopal fọwọ́ sí ìpolongo “ìfàṣẹ sí títẹ́wọ́ gba bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ àti fífi àwọn abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ joyè.”
Àwùjọ àlùfáà kan jiyàn pé kò sí ohun tí ó burú nínú ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, ní sísọ pé Jésù kò sọ̀rọ̀ lòdì sí i rí. Ṣùgbọ́n, ṣe bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí ní ti gidi? Jésù Kristi polongo pé, òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Jòhánù 17:17) Ìyẹ́n túmọ̀ sí pé, ó fara mọ́ ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ ní Léfítíkù 18:22, tí ó kà pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin dà pọ̀ bí obìnrin: ìríra ni.” Ní àfikún sí i, Jésù ka àgbèrè àti panṣágà mọ́ “àwọn ohun burúkú . . . [tí] ń jáde wá lati inú [tí ó] sì ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.” (Máàkù 7:21-23) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà fún àgbèrè gbòòrò ju ọ̀rọ̀ náà fún panṣágà. Ó ṣàpèjúwe gbogbo irú ìbálòpọ̀ tí a ṣe lẹ́yìn òde ìgbéyàwó bíbófinmu, títí kan ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀. (Júúdà 7) Jésù Kristi tún kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti má ṣe fàyè gba olùkọ́ni kankan tí ó sọ pé òun jẹ́ Kristẹni tí ó fojú bíńtín wo bí àgbèrè ṣe wúwo tó.—Ìṣípayá 1:1; 2:14, 20.
Nígbà tí àwọn aṣáájú ìsìn bá ń polongo fún fífi àwọn ọkùnrin tí ń bẹ́yà kan náà lò pọ̀ àti àwọn obìnrin tí ń bẹ́yà kan náà lò pọ̀ joyè, ipa wo ni èyí ń ní lórí àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì wọn, ní pàtàkì àwọn ọ̀dọ́? Kò ha jẹ́ ohun tí ń súnni gbé ìgbésẹ̀ láti fi ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó dánra wò bí? Ní ìyàtọ̀ pátápátá, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwọn Kristẹni láti “sá fún àgbèrè.” (Kọ́ríńtì Kìíní 6:18) Bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni bá ṣubú sínú irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀, a óò fún un ní ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ète mímú un padà bọ̀ sípò sí ojú rere Ọlọ́run. (Jákọ́bù 5:16, 19, 20) Bí a bá kọ ìrànlọ́wọ́ yìí ńkọ́? Bíbélì sọ pé, àyàfi bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá ronú pìwà dà, wọn ‘kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.’—Kọ́ríńtì Kìíní 6:9, 10.
‘Kíka Gbígbéyàwó Léèwọ̀’
Nítorí “ìgbòdekan àgbèrè,” Bíbélì sọ pé, “ó sàn láti gbéyàwó ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara ẹni gbiná.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:2, 9) Láìka ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí sí, ọ̀pọ̀ àlùfáà ni a ti ní kí wọ́n wà ní àpọ́n, ìyẹn ni pé, kí wọ́n má gbéyàwó. Nino Lo Bello ṣàlàyé nínú ìwé rẹ̀ The Vatican Papers pé: “A kò ba ẹ̀jẹ́ wíwà ní àpọ́n jẹ́ bí àlùfáà kan, ọkùnrin tàbí obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé kan bá ní ìbálòpọ̀. . . . A lè rí ìdáríjì fún ìbálòpọ̀ gbà nípa jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tọkàntọkàn, níwọ̀n bí Ṣọ́ọ̀ṣì kì yóò ti fàṣẹ sí kí àlùfáà kan gbéyàwó.” Ẹ̀kọ́ yìí ha tí so èso rere tàbí búburú bí?—Mátíù 7:15-19.
Kò sí iyè méjì pé, ọ̀pọ̀ àlùfáà ń gbé ìgbésí ayé mímọ́, ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé 1992 Britannica Book of the Year, “a ròyìn pé Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ti san 300 mílíọ̀nù dọ́là jáde láti yanjú ọ̀ràn àwùjọ àlùfáà tí ń ṣèṣekúṣe.” Lẹ́yìn náà, ìtẹ̀jáde ti 1994 wí pé: “Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àlùfáà tí àrùn AIDS ti pa táṣìírí pé, àwọn àlùfáà abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ ń bẹ, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ . . . àwọn abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ ni a sì ti fà sínú iṣẹ́ àlùfáà.” Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé ‘kíka ìgbéyàwó léèwọ̀’ jẹ́ “ẹ̀kọ́ ẹ̀mí-èṣù.” (Tímótì Kìíní 4:1-3) Peter de Rosa nínú ìwé rẹ̀, Vicars of Christ, kọ̀wé pé: “Lójú àwọn òpìtàn kan, [wíwà ní àpọ́n àwọn àlùfáà] ti ṣeé ṣe kí ó ṣe ọṣẹ́ fún ìwà rere jù bí ìgbékalẹ̀ míràn ní Ìwọ̀ Oòrùn ti ṣe lọ, títí kan iṣẹ́ aṣẹ́wó. . . . [Ó] ti fìgbà gbogbo jẹ́ àbàwọ́n lórí orúkọ ìsìn Kristẹni. . . . Fífipá múni wà ní àpọ́n ti fìgbà gbogbo yọrí sí àgàbàgebè láwùjọ àwọn àlùfáà. . . . Àlùfáà kan lè ní ìbálòpọ̀ ní ìgbà ẹgbẹ̀rún ṣùgbọ́n òfin ṣọ́ọ̀ṣì ka gbígbéyàwó ní ẹ̀ẹ̀kan péré léèwọ̀ fún un.”
Gbígbé ojú ìwòye Ọlọ́run yẹ̀ wò nípa ìjọsìn Báálì, kò ṣòro láti fòye mọ ojú tí yóò fi wo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù tí wọ́n ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ìwé tí ó kẹ́yìn Bíbélì pa onírúurú gbogbo ìjọsìn èké pọ̀ sábẹ́ orúkọ náà “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.” Bíbélì fi kún un pé: “Nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn wọnnì tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 17:5; 18:24.
Nítorí náà, Ọlọ́run rọ gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ láti jẹ́ olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀. . . . Ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, yóò . . . dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo a óò sì fi iná sun ún pátápátá, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alókunlágbára.”—Ìṣípayá 18:4, 8.
Ìbéèrè náà dìde nísinsìnyí pé: Lẹ́yìn jíjáde kúrò nínú ìsìn èké, níbo ni ẹnì kan yóò lọ? Irú ìjọsìn wo ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìbọ̀rìṣà
Ìjọsìn Báálì ní lílo ère nínú. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbìyànjú láti mú ìjọsìn Jèhófà mọ́ ti Báálì. Wọ́n tilẹ̀ mú àwọn òrìṣà wá sínú tẹ́ḿpìlì Jèhófà. Ojú ìwòye Ọlọ́run nípa jíjọ́sìn ère ni a mú ṣe kedere nígbà tí ó mú ìparun dé bá Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀.
Ère kún ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù dẹ́nu, yálà àwọn ère náà jẹ́ àgbélébùú, ère ìsìn, tàbí ère Màríà. Ní àfikún sí i, a ti kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láti máa tẹrí ba, kúnlẹ̀, tàbí fi ọwọ́ ṣe àmì àgbélébùú níwájú àwọn ère wọ̀nyí. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, a pàṣẹ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ láti “sá fún ìbọ̀rìṣà.” (Kọ́ríńtì Kìíní 10:14) Wọ́n gbìyànjú láti fi àwọn ohun tí a lè fojú rí jọ́sìn Ọlọ́run.—Jòhánù 4:24.
[Credit Line]
Musée du Louvre, Paris
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
“Aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì Yẹ Kí Ó Jẹ́ Aláìlárìíwísí”
GBÓLÓHÙN yìí wá láti inú Títù 1:7, gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ Bíbélì Today’s English Version ṣe sọ. Bíbélì King James Version kà pé: “Ó yẹ kí bíṣọ́ọ̀bù jẹ́ aláìlẹ́gàn.” Ọ̀rọ̀ náà “bíṣọ́ọ̀bù” wá láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí ó túmọ̀ sí “alábòójútó.” Nítorí náà, àwọn ọkùnrin tí a yàn sípò láti mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì. Bí wọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ mú wọn kúrò ní ipò àbójútó tí wọ́n wà, níwọ̀n bí wọn kò ti jẹ́ “àpẹẹrẹ fún agbo” mọ́. (Pétérù Kìíní 5:2, 3) Báwo ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe mú ohun àbéèrèfún yìí ní ọ̀kúnkúndùn tó?
Nínú ìwé rẹ̀, I Care About Your Marriage, Ọ̀mọ̀wé Everett Worthington tọ́ka sí ìwádìí tí a ṣe nípa 100 pásítọ̀ ní ìpínlẹ̀ Virginia, U.S.A. Èyí tí ó lé ní ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún gbà pé àwọn ti lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà tí ń ru ìfẹ́ onígbòónára sókè pẹ̀lú ẹnì kan tí kì í ṣe ẹnì kejì wọn nínú ìgbéyàwó. Púpọ̀ nínú wọn ti ṣe panṣágà.
Ìwé ìròyìn Christianity Today sọ pé: “Jálẹ̀ ẹ̀wádún tí ó kọjá, bí àwọn kan nínú àwọn aṣáájú tí a bọ̀wọ̀ fún jù lọ ṣe ń ṣí ìwà pálapàla tí wọ́n ti hù payá ti ṣe ṣọ́ọ̀ṣì náà ní kàyéfì.” Àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tí A Kò Fi Ní Láti Gba Àwọn Pásítọ̀ Panṣágà Padà Sí Ipò Wọn” gbé ìpènijà dìde sí àṣà tí ó wọ́pọ̀ nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù ti títètè gba àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì padà sí ipò wọn àtẹ̀yìnwá lẹ́yìn tí a ti “dá wọn lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀.”