Èyí Tí Mo Yàn Nínú Bàbá Méjì
“Mo kọ̀ ẹ́ lọ́mọ! Jáde nílé yìí kíákíá, má sì wọ ilé yìí mọ́ àyàfi tí o bá kúrò nínú ìsìn yẹn!”
AṢỌ tó wà lọ́rùn mi nìkan ni mo mú jáde. Bọ́ǹbù ń ró ládùúgbò lálẹ́ ọjọ́ yẹn, n kò sì mọ ibi tí n máa forí lé. Ọdún mẹ́fà kọjá kí n tó padà sílé.
Kí ló lè mú kí bàbá kan bínú gan-an débi tí yóò fi lé ọmọ rẹ̀ jáde nílé? Ó dára, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí gbogbo rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀.
Dídàgbà Nínú Ayé Tí Ìkórìíra Ti Pọ̀
Àwọn òbí mi ń gbé Beirut, Lẹ́bánónì, orílẹ̀-èdè kan tí ó ti lókìkí bí ibi tí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ń pé wò. Àmọ́, láti 1975 sí 1990, ìlú ńlá náà jẹ́ ibi tí ogun ti ń ba nǹkan jẹ́. Wọ́n bí mi ní ọdún 1969, èmi ni àkọ́bí lára ọmọ mẹ́ta nínú ìdílé ará Armenia náà. Nípa bẹ́ẹ̀, mo rántí pé àlàáfíà wà ní ìgbà tí mo wà ní ọmọdé.
Àwọn òbí mi ń lọ sí Ìjọ Àpọ́sítélì ti Armenia, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mejì péré ni Màmá máa ń kó wa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́dún—ìgbà ọdún Àjíǹde àti ti Kérésìmesì. Nítorí náà, ìdílé wa kò lẹ́mìí ìsìn ní ti gidi. Síbẹ̀síbẹ̀, ilé ẹ̀kọ́ gíga ti ìjọ Ẹ̀fáńjẹ́líìsì ni wọ́n rán mi lọ, níbi tí mo ti gba ìtọ́ni onísìn. Nígbà yẹn, n kò lọ́kàn ìfẹ́ nínú ìsìn.
Ohun kan tí àwọn ará Armenia ń kọ́ nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé ni láti kórìíra àwọn ará Turkey. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn ará Turkey pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Armenia, wọ́n sì ti gba ibi púpọ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdè Armenia. Ní 1920, ìhà ìlà oòrùn tí ó ṣẹ́ kù di orílẹ̀-èdè olómìnira ti Soviet Union. Bí èwe kan, mo pinnu láti máa jà láti rí i pé òdodo lékè.
Yíyí Ìrònú Padà
Bí ó ti wù kí ó rí, ní 1980, nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́langba, àwọn ohun tí ẹ̀gbọ́n ìyá mi ọkùnrin bá mi sọ bẹ̀rẹ̀ sí mú mi yí ìrònú mi padà. Ó sọ pé Ọlọ́run Olódùmarè yóò ṣàtúnṣe gbogbo àìṣòdodo láìpẹ́. Ó ṣàlàyé pé nípasẹ̀ Ìjọba tí Jésù Kristi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún, a óò jí àwọn tí a pa nínú àwọn rògbòdìyàn ìpànìyàn-nípakúpa pàápàá dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 6:9, 10; Ìṣe 24:15; Ìṣípayá 21:3, 4.
Inú mi dùn. Nítorí pé mo fẹ́ láti gbọ́ sí i, mo bẹ̀rẹ̀ sí bi í ní ìbéèrè. Èyí yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí a ń ṣe ní ilé Ẹlẹ́rìí mìíràn.
Bí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bàbá mi ọ̀run, Jèhófà, tí mo sì wá ń nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an sí i, mo bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù pé n óò dojú kọ ìṣòro líle kan lọ́jọ́ kan—ìṣòro yíyàn láàárín bàbá mi àti Jèhófà Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.
Yíyàn Tí Ó Le fún Ọmọ Ọdún 17 Láti Ṣe
Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Màmá gbọ́ pé mo ń dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú bí i gan-an, ó sì pàṣẹ fún mi láti dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi dúró. Nígbà tí ó rí i pé ṣeréṣeré kọ́ ni ìgbàgbọ́ tí mo ní, ó halẹ̀ pé òun yóò sọ fún Bàbá. Nígbà yẹn, n kò bìkítà nítorí mo rò pé n óò lè yanjú ìṣòro náà, kí n sì bá Bàbá fà á. Àmọ́ àṣìṣe gbáà ni mo ṣe.
Nígbà tí Bàbá gbọ́ pé mo ń dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú bí i gan-an. Ó halẹ̀ mọ́ mi pé òun yóò lé mi jáde nílé bí n kò bá dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi dúró. Mo sọ fún un pé, n kò ní dáwọ́ rẹ̀ dúró nítorí pé òtítọ́ ni ohun tí mo ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó lọgun, tí ó ké rara, tí ó sì ṣépè tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí sunkún bí ọmọ ọwọ́. Ó bẹ̀ mí pé kí n má dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́.
Ìmọ̀lára gbò mí jìgìjìgì—n kò mọ èyí tí n óò mú nínú bàbá méjì—òun tàbí Jèhófà. Mo mọ̀ pé àwọn méjèèjì nífẹ̀ẹ́ mi gan-an, mo sì fẹ́ láti tẹ́ àwọn méjèèjì lọ́rùn; àmọ́ ó jọ pé kò ṣeé ṣe. Pákáǹléke náà pọ̀ ju ohun tí mo lè gbé lọ. Mo wí fún Bàbá pé n óò ṣe ohun tí ó ń fẹ́, mo sì ń rò lọ́kàn ara mi pé mo lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ mi padà kí n sì di Ẹlẹ́rìí tí mo bá dàgbà sí i. Ọmọ ọdún 17 péré ni mi nígbà náà.
Lẹ́yìn náà, ohun tí mo ṣe tì mí lójú. Mo ronú pé inú Jèhófà kò dùn àti pé n kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọ̀rọ̀ onísáàmù náà, Dáfídì, tí ó wí pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Ṣùgbọ́n mo ṣì wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, àwọn òbí mi ni wọ́n sì ń sanwó ilé ẹ̀kọ́ mi.
Ìdúró Tí Ó Túbọ̀ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀
Ó lé ní ọdún méjì tí n kò fi lọ sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n ìyá mi ọkùnrin, tí n kò sì rí Àwọn Ẹlẹ́rìí, níwọ̀n bí mo ti mọ̀ pé àwọn òbí mi ń ṣọ́ mi tọwọ́tẹsẹ̀. Lọ́jọ́ kan ní 1989, nígbà tí mo ti pé 20 ọdún, mo pàdé Ẹlẹ́rìí kan tí mo mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tìfẹ́tìfẹ́ ni ó béèrè bí n óò bá fẹ́ láti wá kí òun. Níwọ̀n bí kò ti sọ ohunkóhun nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo lọ rí i nígbà tó yá.
Bí àkókò ti ń lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Mo ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ní ibi iṣẹ́ mi, níbi tí ẹnikẹ́ni kò ti ní dí mi lọ́wọ́. Ní àbájáde rẹ̀, mo wá mọyì àkópọ̀ ìwà onífẹ̀ẹ́ Jèhófà dáradára sí i, mo sì túbọ̀ ní òye sí i nípa ìníyelórí níní ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ lábẹ́ ipò èyíkéyìí, kí a sì pa á mọ́. Ní August ọdún yẹn kan náà, mo tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ohun tí mo ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn.
Títí di ìgbà yẹn, àwọn ará ilé mi kò mọ nǹkan kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lọ́jọ́ bí mélòó kan lẹ́yìn náà, èmi àti bàbá mi tún wà á kò, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, mo ti múra sílẹ̀ dáadáa fún ìfojúkojú náà. Ó gbìyànjú láti fi ohùn ìrẹ̀lẹ̀ béèrè pé: “Ọmọ mi, ṣé òótọ́ ni pé o ṣì ń dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” Omijé ti lé sójú rẹ̀ bí ó ti ń retí kí n fèsì. Màmá mi àti àbúrò mi obìnrin ti ń sunkún sínú.
Mo ṣàlàyé pé, kò tíì pẹ́ tí mo tún bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí àti pé mo ti pinnu láti di ọ̀kan lára wọn. Nígbà tí ọ̀rọ̀ ti rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan kò falẹ̀ mọ́. Bàbá fi ìkérara sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Lẹ́yìn náà, ó kì mí mọ́lẹ̀, ó sì ké rara pé, òun kò ní jẹ́ kí n fi ilé náà sílẹ̀ láàyè. Mo já ara mi gbà lọ́wọ́ rẹ̀, bí mo sì ṣe ń sá lọ sísàlẹ̀, mo ń gbọ́ tí àbúrò mi ọkùnrin ń gbìyànjú láti pẹ̀tù sí Bàbá nínú. Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ ni Bàbá mi. Ìwọ ni mo yàn, nítorí náà jọ̀wọ́ tọ́jú mi.”
Ìforóyaró
Ní ọjọ́ bí mélòó kan lẹ́yìn náà, Bàbá gba ilé ẹ̀gbọ́n ìyá mi ọkùnrin lọ, ní ìrètí pé òun yóò rí mi níbẹ̀. Ó lù ú nílùkilù, ó sì fẹ́ pa á, àmọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n wá kí i là wọ́n. Bàbá kúrò níbẹ̀, ó sì lérí pé òun yóò padà wá. Láìpẹ́, ó padà lọ pẹ̀lú àwọn ológun tí wọ́n kó ìbọn lọ́wọ́. Wọ́n kó Àwọn Ẹlẹ́rìí náà àti ẹ̀gbọ́n ìyá mi ọkùnrin, tí ara rẹ̀ kò yá gan-an, lọ sí orílé-iṣẹ́ ológun wọn.
Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dọdẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ní àgbègbè náà. Wọ́n kógun ti ilé ọ̀kan lára wọn. Wọ́n kó àwọn ìwé jọ, títí kan àwọn Bíbélì, wọ́n sì dáná sun wọ́n lójú pópó. Àmọ́ kò tán síbẹ̀. Wọ́n mú Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́fà àti àwọn ènìyàn kan tí wọ́n wulẹ̀ ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n kó gbogbo wọn sínú iyàrá kékeré kan, wọ́n béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì lù wọ́n. Wọ́n fi iná sìgá tẹ àwọn kan. Ìròyìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí yára tàn kálẹ̀ ládùúgbò. Àwọn ológun ń wá mi kiri. Bàbá mi ní kí wọ́n wá mi kàn, kí wọ́n sì lo ọ̀nàkọnà láti fi mú kí n yí ọkàn mi padà.
Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, àwọn ológun já wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ìjọ tí ń lo ibẹ̀ ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́. Wọ́n ní kí gbogbo àwọn ará—ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọ—jáde nínú gbọ̀ngàn náà. Wọ́n gba àwọn Bíbélì wọn, wọ́n sì mú wọn fẹsẹ̀ rìn dé orílé-iṣẹ́ àwọn ológun, níbi tí wọ́n ti bi wọ́n léèrè ọ̀rọ̀.
Sísálọ sí Gíríìsì
Ní gbogbo àsìkò yẹn, ìdílé Àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n jìnnà sí ibi tí rògbòdìyàn ti ń ṣẹlẹ̀ ló ń tọ́jú mi. Ní oṣù kan lẹ́yìn náà, mo kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, mo gba Gíríìsì lọ. Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, mo sì ṣe ìrìbọmi bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi.
Ní Gíríìsì, mo nímọ̀lára ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ ti ẹgbẹ́ àwọn ará tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè púpọ̀ nínú—títí kan àwọn ará Turkey. Mo nírìírí òtítọ́ tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí baba tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí, àwọn ilé àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni, àti nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun.”—Máàkù 10:29, 30.
Láàárín ọdún mẹ́ta tó tẹ̀ lé e, Gíríìsì ni mo wà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo kọ̀wé sí Bàbá ní ìgbà bí mélòó kan, kò fèsì rí. Mo wá gbọ́ lẹ́yìn náà pé ìgbàkigbà tí àwọn ọ̀rẹ́ bá lọ síbẹ̀, tí wọ́n sì béèrè nípa mi lọ́wọ́ rẹ̀, ó máa ń dáhùn pé: “N kò ní ọmọ tó ń jẹ́ orúkọ yẹn.”
Ìpadàṣọ̀kan Lẹ́yìn Ọdún Mẹ́fà
Lẹ́yìn tí ogun ti parí, mo padà lọ sí Beirut ní 1992 láti lọ máa gbé ibẹ̀. Mo rán ọ̀rẹ́ mi kan sí bàbá mi pé mo fẹ́ padà sílé. Ó fèsì pé òun óò fi tìfẹ́tìfẹ́ gbà mí—kìkì bí mo bá ti fi ìsìn mi sílẹ̀. Ìyẹn ló fà á tí mo fi ń gbé ilé gbéetán kan tí mo rẹ́ǹtì fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà, ní November 1995, láìròtẹ́lẹ̀ ni Bàbá wá sí ibi iṣẹ́ mi, tí ó ní òun fẹ́ rí mi. N kò sí níbẹ̀ nígbà yẹn, nítorí náà, ó ránṣẹ́ sílẹ̀ pé òun fẹ́ kí n máa bọ̀ nílé. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣòro fún mi láti gbà á gbọ́. Nítorí náà, mo lọ rí i tìlọ́ratìlọ́ra. Ìpadàṣọ̀kan tí ó mú omijé dání ló jẹ́. Ó sọ pé, òun kò lòdì sí kí n jẹ́ Ẹlẹ́rìí mọ́ àti pé òun fẹ́ kí n máa bọ̀ nílé!
Lónìí, mo ń sìn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni alàgbà àti òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Armenia. Mo sábà máa ń pàdé àwọn ènìyàn bí bàbá mi, tí wọ́n ta ko àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn nítorí pé wọ́n fẹ́ sin Jèhófà. Mo mọ̀ pé Bàbá gbà gbọ́ pé ohun tí ó tọ́ ni òun ń ṣe bí òun ṣe ń ta ko ìjọsìn mi. Bíbélì tilẹ̀ múra àwọn Kristẹni sílẹ̀ nípa sísọ pé kí wọ́n retí àtakò ìdílé.—Mátíù 10:34-37; 2 Tímótì 3:12.
Mo lérò pé, lọ́jọ́ kan, bàbá mi àti àwọn yòókù nínú ìdílé wa yóò ṣàjọpín ìrètí tí a gbé karí Bíbélì tí mo ní nípa ayé kan tí ó sàn jù, tí ń bọ̀. Nígbà yẹn, kò ní sí ogun tàbí rògbòdìyàn ìpànìyàn-nípakúpa mọ́, a kò sì ní lé àwọn ènìyàn kúrò ní ilẹ̀ wọn mọ́ tàbí kí a ṣenúnibíni sí wọn nítorí òdodo. (2 Pétérù 3:13) Bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí pé àwọn ènìyàn ní láti yan ọ̀kan nínú ohun méjì tí ó ṣeyebíye sí wọn gan-an.—A kọ ọ́ ráńṣẹ́.