Lílóye Àìsàn Iṣan Òun Ẹran Ara Ríro àti Mímú Un Mọ́ra
GBOGBO ara ha máa ń ro ọ́ bí? Ó ha ń rẹ̀ ọ́ kọjá ààlà bí? Tí o bá jí ní òwúrọ̀, ara rẹ ha máa ń ṣe wokoko, kí ó sì rẹ̀ ọ́ tọwọ́tẹsẹ̀ bí? O ha máa ń gbàgbé nǹkan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bí? Àwọn ohun wọ̀nyí lè jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àmì àìsàn iṣan òun ẹran ara ríro (FMS).
Ted sọ pé: “N kò jẹ́ gbàgbé òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn ní ọdún 1989, tí mo jí, tí n ò lè gbé apá, tí n ò lè gbé ẹsẹ̀ fún ìṣẹ́jú 45.”a Bí àìsàn iṣan òun ẹran ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bá Ted fínra nìyẹn.
Bí àìsàn FMS bá ń ṣe ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí kan. Báwo ni ẹ ṣe lè ràn án lọ́wọ́? Tàbí bí ó bá jẹ́ ìwọ ni ó ń ṣe, kí ni o lè ṣe sí i? Mímọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣòro náà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an láti lóye rẹ̀, kí o sì máa mú un mọ́ra. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ẹni tí ń rí àwọn àmì tí a kà sílẹ̀ yìí la lè sọ pé àìsàn FMS ń ṣe.
Ṣíṣàlàyé Àìsàn Iṣan Òun Ẹran Ara Ríro
Gẹ́gẹ́ bí Ilé Ẹ̀kọ́ Gígajùlọ Nípa Làkúègbé ní Amẹ́ríkà ṣe sọ, “láti ṣàwárí pé ẹnì kan ní àìsàn iṣan òun ẹran ara ríro sinmi lé àkọsílẹ̀ tí ó wà nípa bí ìrora líle aṣeni-lemọ́lemọ́ ṣe ń ṣe é tẹ́lẹ̀ àti bí oníṣègùn bá rí àwọn ibi pàtó kan tí ó jẹ́ ẹlẹgẹ́.” Àwọn àmì mìíràn tún wà, àwọn kan bá ti àwọn àmì àárẹ̀ aṣeni-lemọ́lemọ́ (CFS) mu.
Ní gidi, àwọn àmì àrùn CFS máa ń yọ ọ̀pọ̀ àwọn tí àìsàn FMS ń ṣe lẹ́nu pẹ̀lú. Ìsoríkọ́ àti hílàhílo ṣíṣàjèjì sábà máa ń ṣe àwọn tí àìsàn FMS ń ṣe, ó sì jọ pé kì í ṣe ìyọrísí àwọn ìṣòro wọ̀nyí, àmọ́ àìsàn FMS ló sábà máa ń fa àwọn ìṣòro náà. Àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lóde ara bí ṣíṣàìlo ara tó tàbí lílo ara jù, ìyọgọnbu títutù kan tí ń pọ̀ sí i, àìróorunsùn lóru, tàbí àìfararọ tí ó kọjá ààlà lè mú kí àìsàn FMS gbẹ̀kan.
Lára onírúurú orúkọ tí a mọ̀ ọ́n sí tẹ́lẹ̀ ni làkúègbé inú iṣan, àìsàn FMS náà kì í sọni di alábùkù ara tàbí arọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í wu ìwàláàyè léwu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé a máa ń jogún àìsàn FMS, a ti rí i lára èyí tí ó ju ọ̀kan lọ nínú àwọn ìdílé kan. Ó ń bá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn jà, ó sì ń ṣe àwọn àgbàlagbà ní onírúurú ọjọ́ orí, ó sì máa ń ṣe àwọn obìnrin ju ọkùnrin lọ.
Ohun Tí Ń Fa Àìsàn FMS
A ti dá oríṣiríṣi àbá nípa ohun tí ń fa àìsàn FMS. Ó lè jẹ́ fáírọ́ọ̀sì tàbí àìwàdéédéé èròjà serotonin tí ń gbé ìmọ̀lára kiri inú iṣan, èyí tí ń nípa lórí oorun, àti àìwàdéédéé irú àwọn kẹ́míkà bí endorphin, tí ń bá ìrora inú ara jà lọ́nà àdánidá. Ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ nípa àwọn àbá wọ̀nyí àti àwọn mìíràn.
Nígbà tí a wo iṣan àwọn tí àìsàn FMS ń ṣe nínú awò amúǹkantóbi, ó jọ pé ó lera, àmọ́ àwọn ibi tí agbára ti ń wá nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì iṣan lè máà máa ṣiṣẹ́ bí ó ti yẹ. A kò mọ ohun tí ń fà á àti ohun tí ó lè wò ó sàn. Nínú ọ̀ràn púpọ̀, ẹni náà máa ń sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ agbonijìgì kan tí ó ṣẹlẹ̀ sí i ní ti ara tàbí ìmọ̀lára ṣáájú ìgbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn àmì náà, ní ti àwọn mìíràn ẹ̀wẹ̀, ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣòro.
Ìṣòro Tí Ó Wà Nínú Ṣíṣàwárí Àìsàn FMS
Níwọ̀n bí a ti lè rí èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn àmì rẹ̀ nínú àwọn àìsàn mìíràn, Dókítà Carla Ockley, láti Kánádà sọ pé: “Àìsàn FMS kì í fìgbà gbogbo jẹ́ ohun tí a máa ń fura sí tí aláìsàn kan bá tọ dókítà wá pé oríkèé ara ń ro òun. Bí ìṣòro náà kò bá dáwọ́ dúró lẹ́yìn lílọ rí dókítà bí ìgbà mélòó kan, ni a óò wá ṣàyẹ̀wò síwájú sí i. Bí a bá ṣàwárí pé àìsàn FMS ni, mo sábà máa ń darí aláìsàn náà lọ sọ́dọ̀ onímọ̀ nípa làkúègbé láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
Bí ó ti wù kí ó rí, àìpẹ́ yìí ni ìlànà ṣẹ̀ṣẹ̀ wà fún ṣíṣàwárí àìsàn FMS, nítorí náà, ẹni tí àìsàn náà ń ṣe nìkan ló lè mọ̀ ọ́n lára, àwọn èsì àyẹ̀wò sì ń wà bó ti yẹ. Ìdí nìyẹn tí ó fi ṣàjèjì sí ọ̀pọ̀ dókítà. Obìnrin kan tí ń jẹ́ Rachel kédàárò pé: “Ọdún 25 ni mo fi ń lọ káàkiri ọ̀dọ̀ oríṣiríṣi dókítà, mo sì ná ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là kí wọ́n tó lè ṣàwárí pé àìsàn FMS ló ń ṣe mí.”
Nígbà náà, ibo ni o ti lè rí ìrànlọ́wọ́ bí o bá rò pé àìsàn iṣan òun ẹran ara ríro ló ń ṣe ọ́? Nínú ìwé rẹ̀, When Muscle Pain Won’t Go Away, Gayle Backstrom dámọ̀ràn lílọ sí ẹ̀ka Àjọ Tí Ń Rí sí Àìsàn Oríkèé Ríro tí ó wà ládùúgbò tàbí sọ́dọ̀ onímọ̀ nípa làkúègbé.
Ìtọ́jú
Títí di báyìí, a kò tíì rí ìwòsàn tí ó dájú fún àìsàn FMS, nítorí náà, ìtọ́jú sábà máa ń dá lórí àwọn àmì tó gbé wá. Ọ̀kan lára àwọn apá pàtàkì tó ní ni ìrora, èyí tí ó yàtọ̀ lára ẹnì kan sí ẹlòmíràn, tí líle rẹ̀ sì máa ń yàtọ̀ lójoojúmọ́ kódà lára ẹnì kan náà, bí àwọn àmì mìíràn tí ó ní ṣe máa ń rí.
Ní àfikún sí ìṣòro náà, ó jọ pé àwọn egbòogi apàrora àti irú àwọn ìtọ́jú kan kì í gbéṣẹ́ mọ́ bí àkókò ti ń lọ. Gayle Backstrom dámọ̀ràn pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, bí o bá wá gbìyànjú lò wọ́n lẹ́yìn náà, ara yóò tún tù ọ́ fún ìgbà díẹ̀.” Àmọ́, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lọ rí dókítà rẹ. Lílo egbòogi pẹ̀lú ní àwọn ìyọrísí búburú tàbí kí ó di bárakú. Ìdí nìyẹn tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gígajùlọ Nípa Làkúègbé ní Amẹ́ríkà fi dámọ̀ràn pé, “a gbọ́dọ̀ yẹra fún lílo àwọn egbòogi apàrora tí ó lágbára.”
Àmì mìíràn tí ó ṣe kókó ni àìtó oorun tí ó ṣe pàtàkì nítorí ìrora àti àwọn ìdíwọ́ mìíràn. Melanie máa ń lo ìrọ̀rí gígùn kan láti dín ìrora kù, ó sì ń lo ìró jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ẹ̀rọ tí ń pèsè ọ̀rinrin ń mú wá kí ariwo láti ìta má bàa ṣèdíwọ́. Àwọn àrànṣe mìíràn lè ní ohun àtẹ̀bọtí àti tìmùtìmù pẹlẹbẹ tàbí tìmùtìmù onírìísí ohun ìkẹ́yinsí kan nínú.b Dókítà Dwayne Ayers láti Àríwá Carolina sọ pé: “Bí mo bá ti lè ran àwọn tí mo ń tọ́jú lọ́wọ́ láti mú ìṣọwọ́sùn wọn sunwọ̀n sí i, àwọn ìtọ́jú mìíràn tètè máa ń ṣiṣẹ́ dáradára lára wọn.”
Gẹ́gẹ́ bí Ilé Iṣẹ́ Tí Ń Rí sí Àìsàn Oríkèé Ríro àti Ẹran Ara Òun Ìgbékalẹ̀ Egungun Ara àti Àwọn Àrùn Awọ Ara ti Orílẹ̀-Èdè, ti sọ, “àwọn tí àìsàn iṣan òun ẹran ara ríro ń ṣe lè jàǹfààní nípa ṣíṣe eré ìmárale, egbòogi, fífi ọwọ́ tàbí ẹ̀rọ ṣètọ́jú ara, àti ṣíṣefàájì lápapọ̀.” Àwọn ìtọ́jú mìíràn lè ní wíwọ́ ara, bíbójútó àìfararọ, àti nína ara nínú. Bí ó ti wù kí ó rí, eré ìmárale lè dà bí ohun tí ẹnì kan tí ara ríro tàbí àárẹ̀ máa ń mú léraléra kò lè ṣe. Ìdí nìyẹn tí àwọn kan fi dámọ̀ràn bíbẹ̀rẹ̀ ṣíṣe eré ìmárale ní wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Sì rí i dájú pé o lọ rí dókítà rẹ kí o tó bẹ̀rẹ̀ ètò eré ìmárale èyíkéyìí.
Lẹ́tà ìròyìn Fibromyalgia Network tó jáde ní July 1997 fa ọ̀rọ̀ Sharon Clark, onímọ̀ nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ eré ìdárayá tí ó tún jẹ́ olùwádìí nípa rẹ̀ ní Portland, Oregon, yọ pé, bí o kò bá lè ṣe eré ìmárale fún 20 ìṣẹ́jú tàbí 30 ìṣẹ́jú, “o lè rin ìrìn ìṣẹ́jú márùn-ún-márùn-ún lẹ́ẹ̀mẹfà lójúmọ́, yóò sì ní àwọn àbájáde tí ó ṣàǹfààní.” Ṣíṣe irú eré ìmárale tí ń mú mímí àti ìgbékiri ẹ̀jẹ̀ sunwọ̀n sí i níwọ̀nba ń jẹ́ kí èròjà endorphin tí ara ń mú jáde pọ̀ sí i, ó ń mú oorun sunwọ̀n sí i, ó sì ń fún ìgbékalẹ̀ ara àti àwọn ẹran ara ní afẹ́fẹ́ oxygen.
Síbẹ̀, ènìyàn yàtọ̀ síra, bí àìsàn FMS sì ṣe le tó lára wọn lè yàtọ̀ síra. Elaine wí fún wa pé: “Lájorí àṣeyọrí kan tí mo ṣe ni rírìnlọ rìn bọ̀ ní ọ̀nà tí ó yà sí ilé mi lẹ́ẹ̀kan, tí ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, tí àìsàn FMS ń ṣe òun náà sì ń rin kìlómítà kan ààbọ̀.” Èyí kì í ṣe ọ̀ràn “bí o kò ṣeré ìmárale, ara ò ní yé ro ọ́,” àmọ́ ó ṣe kedere pé ó jẹ́ ọ̀ràn “má ṣe juwọ́ sílẹ̀.” Ted, tí ó ní àmì àrùn CFS àti àìsàn FMS, sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, kẹ̀kẹ́ eré ìdárayá mi tí ń wà lójú kan ni mo ń lè lò fún ìṣẹ́jú méjì tàbí mẹ́ta lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Nísinsìnyí, mo máa ń ṣe eré ìmárale fún ohun tí ó lé ní 20 ìṣẹ́jú lẹ́ẹ̀mẹta tàbí ẹ̀ẹ̀mẹrin lọ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n ó lé ní ọdún mẹ́rin kí n tó lè ṣàṣeyọrí.”
Ọ̀ràn ti ìtọ́jú àfirọ́pò, bí acupuncture, yíyí ìgbékalẹ̀ ara padà lọ́nà pàtó, àti irú àwọn ìtọ́jú mìíràn tàbí lílo egbòogi ìbílẹ̀ tàbí àwọn àfikún ìlànà ìṣóúnjẹjẹ mìíràn, ti wáyé. Níwọ̀n bí àwọn púpọ̀ ti sọ pé ipò àwọn ti sunwọ̀n sí i nígbà tí àwọn lo díẹ̀ lára ìlànà tí ó wà lókè yìí, àwọn mìíràn kò sọ bẹ́ẹ̀. Àwọn olùwádìí ń wádìí nípa àwọn mélòó kan lára àwọn ìtọ́jú wọ̀nyí, àmọ́ kò tíì sí àbájáde pàtó nípa wọn.
Nígbà mìíràn, lílo egbòogi máa ń fa inú ríro nítorí ebi, tàbí kí oúnjẹ jíjẹ di ọ̀nà tí ẹnì kan ń gbà bá hílàhílo jà. Bí ó ti wù kí ó rí, sísanra sí i ń dá kún àìfararọ tí a ń kó bá àwọn ẹran ara, èyí tí ń yọrí sí ìrora púpọ̀ sí i. Nítorí náà, nínú àwọn ọ̀ràn kan, dókítà máa ń dámọ̀ràn dídín bí ènìyàn ṣe sanra tó kù díẹ̀.
Ṣíṣàwárí pé àìsàn FMS ń ṣe ẹnì kan lè fa ìpayà àti ìbínú. Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà kan wà tí a lè gbà kojú irú àwọn ìmọ̀lára tí ó sábà ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, kí a má bàa ṣe ẹnikẹ́ni léṣe. Ọ̀nà mìíràn tí wọ́n tún lè gbà hùwà padà ni bíbanújẹ́. Ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti banú jẹ́ bí a bá pàdánù ohun kan tí ó ṣeyebíye sí wa bí ìlera wa.
Nígbà Tí Ó Bá Ń Dí Iṣẹ́ Rẹ Lọ́wọ́
Àwọn tí àìsàn FMS ń ṣe lè máa ní ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́. Li ti wà lẹ́nu iṣẹ́ tó ń ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ ńṣe ni ó túbọ̀ ń nira fún un nítorí àìlera rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó bá àwọn ọ̀gá rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó rí iṣẹ́ aláàbọ̀ àkókò kan ní ilé iṣẹ́ kan náà, èyí sì dín àìfararọ rẹ̀ kù. Bákan náà, ẹnu yà á pé wọ́n fi kún owó tó ń gbà.
Àwọn tí ń ṣètọ́jú aláìsàn nípa fífún un ní ìgbòkègbodò ẹnu iṣẹ́ ṣe tàbí nípa lílo ìlànà fífi ọwọ́ tàbí ẹ̀rọ ṣètọ́jú ara lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wá àwọn ọ̀nà tí o lè gbà ṣe iṣẹ́ rẹ lọ́nà tí o kò ní lo ara rẹ jù. Lisa rí i pé lílo àga ìjókòó tí ó ní ìgbápálé ṣèrànwọ́. Wọ́n dámọ̀ràn pé kí Yvonne gba àga ìjókòó mìíràn àti tábìlì mìíràn. Ṣùgbọ́n bí ó bá pọndandan láti fi iṣẹ́ kan sílẹ̀, àwọn ilé iṣẹ́ kan wà tí wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́.
Bí O Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé, àti àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá, lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àìsàn FMS, kí wọ́n sì wá mọ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí àìsàn FMS ń ṣe kì í dà bí ẹni tí nǹkan ń ṣe, àìsàn lílekoko kan tí ń fa ìrora àti àárẹ̀ ń bá wọn fínra. Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gbígbámúṣé tún ṣe pàtàkì. Jennie sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìdílé wa máa ń jíròrò láti rí bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe lè ṣèrànwọ́.” Apá pàtàkì kan nínú ṣíṣàṣeyọrí ní mímú àìsàn FMS mọ́ra ni pé kí aláìsàn náà kọ́ bí yóò ṣe máa ṣún agbára lò nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan. Èyí lè béèrè fún agbára láti kojú ipò nǹkan, pa pọ̀ pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹni tí ń ṣètọ́jú aláìsàn nípa fífún un ní ìgbòkègbodò ẹnu iṣẹ́ ṣe lè ṣèrànwọ́.
O lè ran ọ̀rẹ́ kan tí àìsàn FMS ń ṣe lọ́wọ́ nípa jíjẹ́ “elétíigbáròyé” tí kì í gbé ìdájọ́ karí èrò ara rẹ̀. Gbìyànjú láti jẹ́ kí ìjíròrò wúlò, má sì ṣe máa dárúkọ àìsàn iṣan àti ẹran ara ríro lemọ́lemọ́ nínú gbogbo ìjíròrò náà. Kí ni ó yẹ kí a sọ tàbí tí kò yẹ kí a sọ? Fún àwọn àbá, wo àpótí tí ó wà lójú ewé 23. Bí àìsàn FMS bá ń ṣe ọ́, gbìyànjú láti ní ju “elétíigbáròyé” kan lọ, kí “etí” rẹ̀ má bàa ya. Sì rántí pé, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni yóò máa fẹ́ láti gbọ́ nípa àìsàn FMS tí ń ṣe ọ́.
Mímú Ara Bá Àwọn Ìyípadà Mu
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a máa ń ní ìtẹ̀sí láti bínú sí àwọn ìyípadà, pàápàá àwọn tí ó bá jẹ́ kànńpá. Ṣùgbọ́n olùtọ́jú ẹni tí ń ṣètọ́jú nípa lílo ìlànà fífi ọwọ́ tàbí ẹ̀rọ ṣètọ́jú ara tí ó ti ran nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ènìyàn tí àìsàn FMS ń ṣe lọ́wọ́ wí fún wa pé: “Mo ń gbìyànjú láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ní láti gba kámú nípa ipò wọn. Wọ́n tún ní láti ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n má sì jẹ́ kí àwọn ìfàsẹ́yìn tí kì í wà títí lọ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn tàbí kí ó mú wọn bínú. Nípa bíbójútó ara wọn, ìmọ̀, òye, àti eré ìmárale, wọ́n lè káwọ́ àìsàn FMS tí ń ṣe wọ́n dípò kí wọ́n jẹ́ kí ó máa ṣàkóso wọn.”
Dave, tí àìsàn FMS ń ṣe, sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o máa ní ìtẹ̀sí láti ṣe ohun púpọ̀ ní àwọn ọjọ́ tí ara bá tù ọ́, ì bá sàn kí o ṣẹ́ agbára kù fún ti ọjọ́ kejì kí o má bàa wá wó kalẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tó kù nínú ọ̀sẹ̀ náà.” Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè rò pé kò burú tí o bá lọ síbi àpèjẹ kan tàbí ibi ayẹyẹ pàtàkì kan, kí o sì wá jẹ̀rán rẹ̀ lẹ́yìn náà. Kì í fìgbà gbogbo bọ́gbọ́n mu láti máa gbìyànjú láti fi àìsàn FMS tí ń ṣe ọ́ bò fún àwọn ènìyàn, pàápàá fún àwọn tí wọ́n bìkítà. Sì gbìyànjú láti ní ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani pẹ̀lú. André sọ pé: “Mo wá rí i pé mo máa ń sùn lẹ́yìn tí mo bá ti rẹ́rìn-ín kèékèé tàbí tí mo bá wo eré ẹ̀fẹ̀ kan tí ó dùn.”
Tún rántí pé Jèhófà kì í fi bí o ṣe lè ṣe tó wé ti àwọn ẹlòmíràn, àmọ́ ó mọrírì ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí o ń fi hàn. (Máàkù 12:41-44) Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni láti mọ bí ìwọ yóò ṣe máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú bí agbára rẹ ṣe mọ, kí o má sì kẹ́ ara rẹ jù, kí o má sì lo ara rẹ nílòkulò. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run láti fún ọ ní ọgbọ́n àti okun láti sa ipá rẹ. (2 Kọ́ríńtì 4:16) Kí o sì rántí ìlérí tí ó ṣe nípa àkókò kan tí yóò dé láìpẹ́, nígbà tí ilẹ̀ ayé yóò jẹ́ párádísè níbi tí “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Dájúdájú, ara rẹ yóò tún yá lọ́jọ́ kan!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí díẹ̀ lára àwọn orúkọ padà.
b Jí! kò dámọ̀ràn irú ohun àfisùn pàtó kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì dámọ̀ràn irú ìtọ́jú pàtó kan fún àìsàn FMS.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Ìtùnú Tí Bíbélì Fúnni
• Jèhófà ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.—Sáàmù 34:18.
• Jèhófà yóò gbé ọ ró.—Sáàmù 41:3.
• Ju gbogbo ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà; ó ń bìkítà fún ọ.—Sáàmù 55:22; 1 Pétérù 5:7.
• Inú Jèhófà ń dùn sí ìsapá àtọkànwá rẹ láti sìn ín, bí ó ti wù kí iṣẹ́ ìsìn yẹn kéré tó.—Mátíù 13:8; Gálátíà 6:4; Kólósè 3:23, 24.
• Àwa kò juwọ́ sílẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:16-18.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Sọ
• Inú mi dùn láti rí ọ.
• Ó dájú pé o ti sapá gidigidi láti dé ibí.
• Mo wá ràn ọ́ lọ́wọ́ ni. Mo bìkítà nípa rẹ.
• Mo mọrírì ìsapá rẹ.
Ohun Tí Kò Yẹ Kí A Sọ
• Mo lóye ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ọ.
• Ara rẹ le gan-an. Ibo ni àìsàn ti ń bọ̀?
• Ké sí mi bí o bá nílò ohunkóhun.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Àwọn àmì dúdú tóótòòtó yìí ni díẹ̀ lára àwọn ibi tí ó jẹ́ ẹlẹgẹ́ tí a máa ń wá bí a bá ń ṣàyẹ̀wò láti ṣàwárí àìsàn iṣan òun ẹran ara ríro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gbígbámúṣé àti ìjíròrò nínú ìdílé ṣe pàtàkì