ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 6/8 ojú ìwé 25-26
  • Ìpadàbọ̀ Ibi Ìwòran Globe ti London

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpadàbọ̀ Ibi Ìwòran Globe ti London
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Inú Ibi Ìwòran Globe Tuntun Náà
  • Eré Náà
  • Ìlérí Ta Lo Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Jí!—1998
g98 6/8 ojú ìwé 25-26

Ìpadàbọ̀ Ibi Ìwòran Globe ti London

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRITAIN

WỌ́N ti tún ibi ìwòran Globe, tí William Shakespeare ti máa ń ṣe àwọn eré onítàn rẹ̀, kọ́ sítòsí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀ ní Southwark, ní ìhà gúúsù etí Odò Thames ti London. Ilé onírìísí róbótó yìí, tí ó ní ògiri 20, tí a kọ́ bí ti 1599, jẹ́ ìran àpéwò pàtàkì kan fún àwọn arìnrìn-àjò afẹ́.

Kí òwò ibi ìwòran tó bẹ̀rẹ̀ ní London, dídẹ ajá sí béárì tàbí akọ màlúù ni irú ohun ìnàjú tí ó wọ́pọ̀. Àwọn ènìyàn tí ń pariwo ń sún àwọn ajá láti dá ẹranko kan tí wọ́n so mọ́ òpó kan lóró. Wọ́n máa ń ṣe èyí ní àwọn ibi ìṣeré tí kò nílé lórí tí ó rí bìrìkìtì, tí ó ní àwọn àyè ìjókòó gbígbẹ́nuléra, tí ó wà ní ìpele-ìpele. Wọ́n ń so àwọn ẹranko náà mọ́lẹ̀ sí àárín, tí ó wá di ibi tí pèpéle ibi ìwòran náà wà.

Lẹ́yìn náà, àwọn eré onítàn wá wọ́pọ̀, wọ́n sì kọ́ àwọn ibi ìwòran tuntun káàkiri London. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn sì ń lọ wòran lójoojúmọ́. Àwọn olórí ìlú gbìyànjú láti fòfin de àwọn eré náà látàrí pé wọn kò mọ́, wọ́n sì kún fún ìwàkiwà. Àwọn ọ̀gá iṣẹ́ ṣàròyé pé àwọn eré náà kì í jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ wá síbi iṣẹ́, nítorí pé agogo méjì ọ̀sán ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ eré. Ṣùgbọ́n Ọbabìnrin Elizabeth Kìíní, tí ó ṣonígbọ̀wọ́ ibi ìwòran náà, gbè sí wọn lẹ́yìn. Ẹgbẹ́ Olùgbaninímọ̀ràn rẹ̀ kò jẹ́ kí wọ́n wọ́gi lé àwọn eré náà kí àwọn tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu eré ṣíṣe lè wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti máa dá ọbabìnrin lára yá. Wọ́n sábà máa ń yan àwọn ẹgbẹ́ òṣèré Shakespeare láti ṣeré ní ààfin ọba ju àwọn mìíràn lọ.

Ọdún tí wọ́n ṣí ibi ìwòran Globe ti àtijọ́ ni Shakespeare kọ eré ìtàn Henry V. Nítorí náà, yíyàn tí wọ́n yàn án fún àfihàn ní sáà àkọ́kọ́ ní ibi ìwòran tuntun ti Shakespeare yìí bọ́gbọ́n mu.

Inú Ibi Ìwòran Globe Tuntun Náà

Kí a tó wọlé lọ wo eré oníwákàtí-mẹ́ta náà, a bojú wo òfuurufú, a sì retí pé òjò kò ní rọ̀, nítorí wọn kì í gbà kí a lo agbòjò níbẹ̀, àárín ibẹ̀ kò sì nílé lórí. Pèpéle rẹ̀ yọ síwájú, apá tó ṣe bìrìkìtì lára rẹ̀ sì fẹ̀ ní 30 mítà, ìpele àyè ìjókòó mẹ́ta tí ń gba nǹkan bí 1,000 ènìyàn sì yí i ká. Ṣùgbọ́n a wà lára àwọn tí ń dúró wòran, àwọn 500 ènìyàn tí wọ́n sanwó láti wà lórí ìdúró bí wọ́n ti ń wo eré ní àárín. Ibi ìwòran àtijọ́ ń gba 3,000 ènìyàn tí wọ́n fún mọ́ra. Àmọ́ ìlànà ààbò ti òde òní kò fàyè gba ìyẹn.

Wọ́n fi kẹ́míkà pa òrùlé òkè àyè ìjókòó láti dènà iná. Pákó tí iná kò lè jó àti ìgbékalẹ̀ páìpù olómi ìpaná pèsè àfikún ààbò. Ọdún 1613 ni ibi ìwòran Globe àtijọ́ náà bà jẹ́ nígbà tí ọwọ́ agogo orí pèpéle kan ṣáná, tó sì ran òrùlé rẹ̀.

Wọ́n gba àwọn tí ń dúró wòran láyè láti máa rìn káàkiri, kí wọ́n tilẹ̀ gbápá lé etí pèpéle. Ní 400 ọdún sẹ́yìn, àwọn èrò oníwàkiwà máa ń jẹun, wọ́n sì máa ń mutí títí eré yóò fi parí, wọ́n sì sábà máa ń bá ara wọn jà. Pẹ̀lú àríwísí lílégbákan, ìgbà tó bá wù wọ́n ni wọn máa ń sọ̀rọ̀, ni wọn ń dún ṣììì tàbí kí wọ́n pàtẹ́wọ́. Òǹkọ̀wé kan nígbà náà ṣàpèjúwe rẹ̀ pé, wọ́n ń “fún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí,” ó sì pè wọ́n ní “aláìníláárí.”

Apádò ni igi tí wọ́n lò jù láti fi kọ́ ibi ìwòran Globe ìgbàlódé náà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà apádò ìkanlé ni wọ́n fi mú àwọn igun rẹ̀ pọ̀. Àwọn igi apádò tí wọ́n rí kó lẹ́yìn ìjì líle tí ó hú ẹgbẹẹgbẹ̀rún igi ní October 1987 ni wọ́n lò. Èyí tí ó ṣòro jù láti rí ni òpó tí ó gùn ní mítà 13, tí wọ́n fi bo apá iwájú ìbòrí pèpéle náà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdààmú, wọ́n rí igi kan tí ó bá a mu, tí gíga rẹ̀ lé ní 20 mítà, ní nǹkan bí 150 kìlómítà ní ìwọ̀ oòrùn London.

Ó jọ pé àwọn òpó onímábìlì ni wọ́n gbé ìbòrí náà lé. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀, pákó ni wọ́n fi ṣe àwọn òpó náà pẹ̀lú, bí ti àwọn tí wọ́n fi ṣe ibi ìwòran Globe àkọ́kọ́ náà, tí ẹnì kan tí ó fẹ́ràn rẹ̀ sọ pé, “wọ́n kùn ún gan-an bí mábìlì débi pé ó lè kó oníṣẹ́ ọnà mábìlì tí ó gbọ́nféfé jù lọ nígàn-án.”

Ní báyìí, àwọn àyè ìjókòó ti kún. Díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n ń dúró wòran fún pọ̀ síwájú pèpéle nígbà tí àwọn mìíràn fara ti àwọn ògiri onígẹdù ara ọ̀gangan ibi ìṣeré. Bí orin ti bẹ̀rẹ̀ sí dún ni ariwo ń dẹwọ́. Nínú àkọ́yọ kan tí ó wà ní òkè pèpéle náà, àwọn akọrin mẹ́fà tí wọ́n wọ aṣọ bí ti sànmánì agbedeméjì ń fi àwọn ohun èlò orin ìgbà ayé Shakespeare kọrin: kàkàkí, cornet, àti percussion.

Eré Náà

Bí ohùn orin náà ṣe ń lọ sókè sí i, àwọn òṣèré ń jáde wá, wọ́n sì ń fi ọ̀pá wọn kilẹ̀ orí pèpéle bá ìró orin mu tagbára-tagbára. Àwọn tí ń dúró wòran dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n ń fi ẹsẹ̀ kilẹ̀. Lójijì, wọn kò fi nǹkan ki ilẹ̀ mọ́. Òṣèré kan tí ó ka ọ̀rọ̀ ìṣíré mú kí àwọn òṣèré gbára dì láti bẹ̀rẹ̀ eré. Ojú àwọn ènìyàn ti wà lọ́nà fún eré náà gan-an. Lójijì, àwọn òṣèré méjì tí wọ́n wọ aṣọ pupa gbàgìẹ̀ bọ́ sórí pèpéle—Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti Canterbury àti bíṣọ́ọ̀bù ti Ely. Eré bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu, nígbà tí eré sì ń lọ lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ṣọ́ọ̀ṣì àti ìwà jìbìtì tí wọ́n ń hù ní bòókẹ́lẹ́ pẹ̀lú Ọba Henry Karùn-ún ti England yóò jálẹ̀ sí ṣíṣẹ́gun ilẹ̀ Faransé ní pápá ogun Agincourt tí ìtàjẹ̀sílẹ̀ ti sọ dìbàjẹ́ níkẹyìn.

Láìpẹ́, wọ́n gbé ìtẹ́ ọba sórí pèpéle, a sì rí Ọba Henry tí ń bá mẹ́ta lára àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ sọ̀rọ̀. Bí àwọn olóyè ṣe gun orí pèpéle, a bẹ̀rẹ̀ sí fi ìfẹ́ hàn sí ìjójúlówó àwọn aṣọ bí ti sànmánì agbedeméjì tí wọ́n wọ̀. Síbẹ̀, ohun kan ṣàjèjì sí wa nípa àwọn òṣèré náà. A yẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa wò. Bẹ́ẹ̀ ni, ọkùnrin ni gbogbo àwọn tí ó yẹ kí wọ́n ṣe eré náà! Kò sí apá tí ó kan obìnrin nínú eré ìtàn àkókò Elizabeth. Bí òpìtàn nípa àlámọ̀rí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà náà, G. M. Trevelyan, ti sọ, àwọn ọmọdékùnrin ni a ń “dá lẹ́kọ̀ọ́ kínníkínní, láti ìgbà tí wọ́n ti wà lọ́mọdé, láti máa fi iyì, ẹ̀mí ọ̀yàyà àti ìgbọ́nféfé kó ipa àwọn obìnrin nínú eré.” Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí.

Àwọn ènìyàn kò pàtẹ́wọ́ mọ́, a sì bọ́ síta. A tún wo ibi ìwòran Globe náà lẹ́ẹ̀kan sí i, èérún pòròpórò olómiwúrà tí wọ́n fi bo orí rẹ̀, bí àwọn gẹdú apádò rẹ̀, tí ń mú ibòji wà. Mímú tí ó mú wa padà sí àkókò tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 400 ọdún sẹ́yìn jẹ́ ìrírí aláìlẹ́gbẹ́.

Lẹ́yìn náà, a rìn káàkiri Ibi Ìpàtẹ tó wà ní Ibi Ìwòran Globe ti Shakespeare náà. A ń rí orúkọ náà, Shakespeare, ní gbogbo ibi tí a bá yí sí. Bí a ti ń ronú nípa àwọn àfihàn náà ni a ń béèrè lọ́kàn ara wa pé, Ta tilẹ̀ ni òǹkọ̀wé eré onítàn náà, William Shakespeare? Ohun tí ó ṣàjèjì nípa William Shakespeare yóò jẹ́ kókó àpilẹ̀kọ kan tí yóò jáde nínú Jí! lọ́jọ́ iwájú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwòrán ibi ìwòran Globe àtijọ́

[Credit Line]

Láti inú ìwé náà, The Comprehensive History of England, Ìdìpọ̀ Kejì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ibi ìwòran Globe lónìí

[Àwọn Credit Line]

John Tramper

Richard Kalina

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́