Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Kíndìnrín Mo fẹ́ sọ bí àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Kíndìnrín Rẹ—Asẹ́ Ìgbẹ́mìíró” (August 8, 1997), ṣe wú mi lórí tó. Dókítà mi ti sọ fún mi pé àrùn kan wà nínú kíndìnrín mi. Àpilẹ̀kọ náà ti wá mú kí n nímọ̀lára pé èmi nìkan kọ́ ni àrùn náà ń ṣe.
V. M., United States
Àrùn kan wà nínú kíndìnrín mi, èyí ló mú kí wọ́n dá mi dúró sí ilé ìwòsàn fún oṣù mẹ́rin. Kíka àpilẹ̀kọ yín ràn mí lọ́wọ́ láti mọ bí mo ti ṣe jẹ́ aláìmọ̀kan nípa ara mi tó. Nísinsìnyí, mo lè ṣàlàyé bí ó ṣe ń ṣe mí fún àwọn ẹlòmíràn.
S. H., Japan
Ìgbà tí wọ́n sọ fún ìyàwó mi pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ nínú kíndìnrín ni àpilẹ̀kọ yìí dé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn náà dẹ́rù bà wá, a wá lóye oríṣiríṣi iṣẹ́ tí kíndìnrín ń ṣe ní kedere nígbà tí oníṣẹ́ abẹ náà ṣàlàyé fún wa. Wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ yíyọ kíndìnrín fún ìyàwó mi, ara rẹ̀ sì ti ń yá nísinsìnyí.
G. S., Íńdíà
Ìtàn Oníṣẹ́ Ọnà Mo dá ọkàn mi lára yá ní kíka ìrírí Celo Pertot náà, “Ohun Kan Tó Sàn Ju Òkìkí Ayé Lọ.” (August 22, 1997) Kí n tó di Kristẹni, mo ń lépa fífi orin kíkọ àti eré orí ìtàgé ṣe iṣẹ́ ṣe. Ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ìrìbọmi mi, àwọn òǹkọ̀wé eré onítàn orí tẹlifíṣọ̀n lílókìkí kan tẹ̀ mí láago. Nígbà tí mo sọ fún wọn pé n kò ṣe eré mọ́, wọ́n ní, “Àbí nǹkan ń ṣe ẹ́ ni?” Bí Celo Pertot, mo nímọ̀lára pé Jèhófà ti bù kún ìpinnu mi lọ́nà kíkọyọyọ.
R. F., United States
Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Ìsìn Ọmọ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ẹ ṣeun gan-an fún títẹ àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.” (August 22, 1997) Mo ní ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ púpọ̀ fún Sergei Ivanenko nítorí pé ó ní ìgboyà àti ọkàn ìfẹ́ nínú títẹ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ jáde nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
S. M., United States
Ìkórìíra Àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ìkórìíra—Èé Ṣe Tí Ó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀? Ìfẹ́—Èé Ṣe Tí Ó Fi Kéré Tó Bẹ́ẹ̀?” (September 8, 1997), ní ọ̀kan lára àwọn èèpo ẹ̀yìn ìwé dídárajùlọ tí ẹ ń tẹ̀ jáde. Àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ rí ìdí tí àwọn ènìyàn kì í fi gbẹ́kẹ̀ lé àwọn àjèjì àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àṣà ìbílẹ̀ tí ó yàtọ̀.
J. M., United States
Àrùn RSD—Àrùn Ríronilára Mo rò pé ojúṣe mi ló jẹ́ láti kọ̀wé sí yín lẹ́yìn tí mo ti ka àpilẹ̀kọ náà, “Àrùn RSD—Àrùn Ríronilára Kan Tí Ń Rúni Lójú.” (September 8, 1997) Ní January, wọ́n sọ fún mi pé mo ní àrùn RSD. Mo gbìyànjú láti wá àwọn ìsọfúnni nípa rẹ̀. Mo sunkún ayọ̀ nígbà tí mo rí àpilẹ̀kọ yìí. Ó gbéṣẹ́, ó sì dáhùn púpọ̀ lára ìbéèrè tí mo ní.
W. B., England
Ó ti pé ọdún mẹ́rin tí àrùn RSD ti ń ṣe mí. Ẹ ṣeun fún ìsapá tí ẹ ṣe láti ṣe ìwádìí kínníkínní nípa kókó ẹ̀kọ́ yìí. Ó fi hàn ní ti gidi pé ẹ ní ìfẹ́ aládùúgbò.
G. S., Germany
Àrùn RSD ń ṣe ọkọ mi, ó sì ṣòro fún wa láti ṣàlàyé àrùn náà fún àwọn ẹlòmíràn. Nísinsìnyí tí ẹ ti jíròrò rẹ̀ kínníkínní nínú àpilẹ̀kọ náà, ó ti wá rọrùn gan-an fún wa. A ti fi àpilẹ̀kọ yìí ránṣẹ́ sí àwọn dókítà àti àwọn ọ́fíìsì ìmúbọ̀sípò. Kíka àlàyé nípa bí Karen Orf ṣe bá àrùn RSD jà dà bí kíkà nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ọkọ mi! Bí Karen, a ń fojú sọ́nà fún ayé tuntun, níbi tí kò ti ní sí ìrora mọ́.
K. P., Australia
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Karen fún àlàyé rẹ̀. Mo ń rántí rẹ̀, mo sì ń fi sínú àdúrà mi, mo sì nírètí pé ara rẹ̀ yóò túbọ̀ máa yá sí i. Àrùn RSD ń ṣe mí lẹ́yìn àti lẹ́sẹ̀ dé àtẹ́lẹsẹ̀. Jíjókòó ní àwọn ìpàdé àti rírìn káàkiri lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ń fa àìfararọ àti ìrora gidigidi fún mi. Àmọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, èyí kò dá mi lọ́wọ́ kọ́.
C. K., England