ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 6/8 ojú ìwé 28
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn Kọ́lẹ́rà Bẹ́ Sílẹ̀ ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà
  • Ríran Àwọn Òkú Lọ́wọ́ Kẹ̀?
  • Àwọn Ohun Iyebíye Tí Ó ní Ìtànṣán Olóró
  • Àṣà Ìwé Kíkà
  • “Ìsìn Tí A Dá Sílẹ̀ Fúnra Ẹni”
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1999
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Ṣọ́ra Fún Ìmọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 6/8 ojú ìwé 28

Wíwo Ayé

Àjàkálẹ̀ Àrùn Kọ́lẹ́rà Bẹ́ Sílẹ̀ ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà

Ìròyìn Associated Press kan tí wọ́n gbé jáde láti Nairobi, Kenya, sọ pé: “Kọ́lẹ́rà ti ó bẹ́ sílẹ̀ ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà ti di àjàkálẹ̀.” Kọ́lẹ́rà, àrùn inú ìfun tí ń fa ìgbẹ́ gbuuru láyàjù, lè pani tí a kò bá lo oògùn sí i. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ti sọ, ó lé ní 61,000 ènìyàn tí wọ́n kó àrùn náà ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà ní 1997, a sì ròyìn pé 2,687 ènìyàn ló kú. Ìbẹ́sílẹ̀ kọ́lẹ́rà wọ́pọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kì í ti ṣe ìmọ́tótó dáradára tó, tí ìtọ́jú kò sì ti tó. Ipò náà máa ń burú sí i tí òjò bá ń gbé ìgbẹ́ ènìyàn lọ sínú omi mímú. Ọ̀mọ̀wé Maria Neira, ọ̀gá ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe àjọ WHO kan tí ń rí sí ọ̀ràn àrùn kọ́lẹ́rà, sọ pé, ó ṣeé ṣe kí àrùn kọ́lẹ́rà máà tán ní àwọn àgbègbè tí ọ̀ràn kan náà àyàfi bí wọ́n bá ní àwọn ibi ìdàdọ̀tísí àti omi mímọ́tónítóní.

Ríran Àwọn Òkú Lọ́wọ́ Kẹ̀?

Ní Hong Kong, yíyangàn kì í sábà dópin nígbà tí ẹnì kan bá kú—ní ti àwọn kan, ó ṣì máa ń ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ikú wọn. Ìyẹn jẹ́ nítorí pé ìjọsìn àwọn baba ńlá kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní China. Èyí ló mú kí oníṣọ́ọ̀bù kan, Kwan Wing-ho, sọ pé: “wọ́n máa ń ronú pé ó ṣe pàtàkì láti fi ọrọ̀ yangàn kódà nígbà tí wọ́n ti di ẹ̀dá ẹ̀mí.” Láti ran àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ tí wọ́n gbẹ̀yìn òkú lọ́wọ́ láti mú kí nǹkan túbọ̀ sunwọ̀n fún olólùfẹ́ wọn tó kú, Ọ̀gbẹ́ni Kwan ń ta oríṣiríṣi àwọn ohun àfiṣàpẹẹrẹ ohun ìní tí a fi bébà ṣe, títí kan tẹlifóònù alágbèéká, kọ̀ǹpútà, ààrò microwave, àti ọkọ̀ Mercedes Benz. Ìròyìn kan tí Associated Press gbé jáde sọ pé: “Wọ́n ń sun àwọn ẹrù náà láàárín ọjọ́ méje lẹ́yìn tí ó kú, ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àyájọ́ ikú rẹ̀, àti bí ẹbí kan bá lálàá pé òkú kan fẹ́ wá nájà.” Ọ̀gbẹ́ni Kwan sọ pé: “Òwò tí ń mówó wá ni, nítorí pé oníbàárà náà kò lè dá ọjà tó rà padà.”

Àwọn Ohun Iyebíye Tí Ó ní Ìtànṣán Olóró

Gbígbọ́ tí a gbọ́ pé àwọn òkúta iyebíye tí wọ́n tà fún oníṣòwò kan ní Bangkok ní ìtànṣán olóró ta ni jí láti túbọ̀ wà lójúfò nípa ìṣòwò àgbáyé. Sahabudeen Nizamudeen, oníṣòwò kan tí ó gbọ́n féfé, máa ń mọ̀ bí òwò kan bá máa péni. Nítorí náà, nígbà tí oníṣòwò kan láti Indonesia fi 50 ohun iyebíye cat’s-eye lọ̀ ọ́, tí ó ní kí ó san iye tí ó kéré gan-an sí iye rẹ̀ gangan, ó bẹ́ mọ́ ọn. Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ rí bí ṣokoléètì kan tí a kúndùn gan-an, ìlà bí ìmọ́lẹ̀ tí ó jọ ilà inú ọmọlójú ológbò sì là á láàárín.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó wá ṣẹlẹ̀ pé ìmọ́lẹ̀ tí ń kọ nínú rẹ̀ jẹ́ ti nǹkan mìíràn. Wọ́n ti ṣí wọn payá sí ìtànṣán láti mú àwọ̀ wọn gbé fúkẹ́, kí wọ́n lè níye lórí díẹ̀ sí i. Òkúta mìíràn, tí a rí níbi ìpàtẹ ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye kan ní Hong Kong, ní ìwọ̀n ìtànṣán tí ó fi ìgbà 25 ré kọjá ìwọ̀n tí kò léwu tí a fọwọ́ sí ní ilẹ̀ Éṣíà. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Títí di báyìí, èròjà chrysoberyl ti ohun iyebíye cat’s-eye nìkan ló ní ìṣòro náà.”

Àṣà Ìwé Kíkà

Ìwé ìròyìn Jornal da Tarde sọ pé, ní ìpíndọ́gba, ìwé 2.3 ni àwọn ará Brazil ń kà lọ́dọọdún. Bí àwọn ará Brazil bá ti jáde ilé ẹ̀kọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni kì í tún ṣe ohun tí ó tan mọ́ ìwé mọ́. Akọ̀wé Ilé Iṣẹ́ Ètò Iṣẹ́ Àgbẹ̀, Ottaviano de Fiore, sọ pé: “Ohun tí ó jẹ́ ìṣòro náà gan-an ni pé ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ìwé tí a ń kà ní Brazil ló jẹ́ èyí tí a ṣe ní kàn-ń-pá” fún àwọn ọmọ ní ilé ẹ̀kọ́. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Lára ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún yòókù, èyí tí ó pọ̀ jù lọ ló jẹ́ ìwé ìsìn àti èyí tí ó wà fún kíkà àwọn kan pàtó, àwọn ìwé tí ń sọ nípa ìbálòpọ̀, tàbí àwọn ìwé tí a lè kà láti lè dá ṣe ohun kan.” De Fiore sọ nípa àṣà ìwé kíkà pé: “Àwọn ọmọ máa ń kóra jọ nínú ìdílé, ní ilé ẹ̀kọ́, àti sídìí tẹlifíṣọ̀n. Bí kò bá sí ẹni tí ó kúndùn ìwé kíkà nínú ìdílé, wọn kò ní ní ìsúnniṣe kankan níbẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Ní ti tẹlifíṣọ̀n, fífúnni níṣìírí láti kàwé ló kẹ́yìn lára àwọn ohun tó jẹ àwọn ìkànnì pàtàkì-pàtàkì lógún.”

“Ìsìn Tí A Dá Sílẹ̀ Fúnra Ẹni”

Onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá náà, Fortunato Mallimaci, sọ pé, púpọ̀ lára àwọn ará Látìn Amẹ́ríkà ń ṣe “ìsìn tí a dá sílẹ̀ fúnra ẹni.” Àwọn ènìyàn ti ń jìnnà sí ṣọ́ọ̀ṣì àti ìlànà ìsìn, wọ́n ń gbádùn wíwà lómìnira láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yoga, kí wọ́n ka ìwé nípa ìfòyemọlọ́run ti àwọn ará Ìlà Oòrùn, kí wọ́n lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ tí àwọn oníwàásù ti ń ṣèwòsàn, tàbí kí wọ́n lọ sí àwọn ibi ètò ìsìn tí àwọn ará Áfíríkà ti ilẹ̀ Brazil ń ṣe. Mallimaci sọ pé: “Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn ènìyàn kò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn mọ́. Wọ́n ní ìgbàgbọ́, àmọ́ wọ́n ti dá ìsìn tiwọn sílẹ̀.” Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin sọ pé, nígbà tí onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá náà ń sọ̀rọ̀ níbi Ìjíròrò Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin Nípa Ibi Ìjọsìn Àwọn Ọmọ Ìjọ ní ìhà ìsàlẹ̀ ìlàjì Gúúsù Amẹ́ríkà (Látìn Amẹ́ríkà), ó wí pé, “àtúntò kan ‘tí ń fa ìyapa àti ìforígbárí tí ó burú jáì’ ń lọ lọ́wọ́ nínú ìsìn Kátólíìkì.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́