ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/22 ojú ìwé 21-23
  • Ṣọ́ra Fún Ìmọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣọ́ra Fún Ìmọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àǹfààní Ìwé Kíkà
  • Ojú Ìwòye Tí Ó Wà Déédéé
  • Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
  • Bibeli—Ìrànwọ́ Pípabambarì
  • Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé—Apá Kìíní: Ìwé Kíkà Tàbí Ìran Wíwò?
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Bíbélì Kíkà—Ó Lérè, Ó Sì Gbádùn Mọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 1/22 ojú ìwé 21-23

Ṣọ́ra Fún Ìmọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà

IRÚ ìṣòro ìwé kíkà tuntun kan ti ń gba ayé wa kan. Wọ́n ń pè é ní ìmọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà. A túmọ̀ rẹ̀ sí “ànímọ́ tàbí ipò jíjẹ́ ẹni tí ó lè kàwé, ṣùgbọ́n [jíjẹ́ ẹni tí] kò ní ìfẹ́ ọkàn nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀.” (Ìwé atúmọ̀ èdè Merriam-Webster’s Collegiate Dictionary, Tenth Edition) Bẹ́ẹ̀ ni, ìwé kíkà—tí a máa ń tọrùn bọ̀ nígbà kan rí gẹ́gẹ́ bí ohun fàájì—ni à ń fojú tẹ́ḿbẹ́lú nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí kò gbádùn mọ́ni. Ọmọdébìnrin ọlọ́dún 12 kan ṣàròyé pé: “O ní láti tiraka kí o tó lè kàwé, ìyẹn kì í sì í ṣe ohun tí ó gbádùn mọ́ni.”

Ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ni wọ́n jẹ́ amọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, United States máa ń yangàn níní ìpín 97 nínú ọgọ́rùn-ún iye àwọn tí ó mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà; síbẹ̀, agbára káká ni nǹkan bí ìdajì àwọn àgbàlagbà ará America fi ń ka àwọn ìwé àti ìwé ìròyìn! Ó ṣe kedere pé, agbára àtikàwé kì í fìgbà gbogbo jẹ́ ohun kan náà pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn láti kàwé. Èyí jẹ́ òtítọ́, àní láàárín àwọn tí wọ́n kàwé gan-an. Ẹnì kan tí ó gboyè jáde ní Yunifásítì Harvard sọ pé: “Nígbà tí mo bá darí dé láti ibi iṣẹ́, tí ó sì ti rẹ̀ mí, n óò tan tẹlifíṣọ̀n dípò nínawọ́ gán ìwé. Òun ò le.”

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìwé kíkà? Ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, ìtẹ́wọ́gbà tí ó ní ti tẹrí ba fún àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde tí ń pe gbogbo àfiyèsí. Stratford P. Sherman sọ nínú ìwé ìròyìn Fortune pé: “Nísinsìnyí tí a ti ní ẹ̀ka tẹlifíṣọ̀n olórin kíkọ ṣúlẹ̀—tí a ti ní ẹ̀rọ fídíò àti eré àṣedárayá orí fídíò àti rédíò àtẹ̀bàpò—ìrònú kíkanrí mọ́ ìwé kan kò dà bí ohun tí ó rọrùn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní àwọn ìgbà tí ojú kò tí ì dí tó báyìí.” Àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé ohun tí ń faga gbága pẹ̀lú ìwé kíkà, tí ó sì ń gba àkókò jù lọ ní tẹlifíṣọ̀n. Ní ti gidi, nígbà tí ìpíndọ́gba ará America kan yóò bá fi tó ọmọ ọdún 65, yóò ti lo ọdún mẹ́sàn-án nínú ìgbésí ayé rẹ̀ nídìí tẹlifíṣọ̀n wíwò!

Níwọ̀n bí a ti sábà máa ń fi àwọn àǹfààní ìwé kíkà rúbọ nítorí gọgọwú tí ń tanná yẹ̀rìyẹ̀rì, yóò jẹ́ ohun tí ó dára láti gbé àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

Àǹfààní Ìwé Kíkà

Ìwé kíkà máa ń ru agbára ìrònú sókè. Tẹlifíṣọ̀n máa ń bá ènìyàn ronú ni. Gbogbo nǹkan ni ó máa ń mú kí ó ṣe kedere: ìwò ojú, ìlọsókèlọsódò ohùn, àti ìgbékalẹ̀ ìran náà.

Bí ó ti wù kí ó rí, tí ó bá jẹ́ pé ìwé kíkà ni, ìwọ ni yóò yan agbo àwọn òṣèré, ìwọ ni yóò gbé bí ìran náà yóò ṣe rí kalẹ̀, tí o óò sì darí bí wọn yóò ṣe ṣe. Ọmọdékùnrin ọlọ́dún 10 kan sọ pé: “O ní òmìnira fàlàlà. O lè finú ro bí o ṣe fẹ́ kí òṣèré kọ̀ọ̀kan rí gan-an gẹ́lẹ́. O ní ìdarí lórí àwọn nǹkan nígbà tí o bá ń kàwé, ju ìgbà tí o bá ń wo nǹkan lórí tẹlifíṣọ̀n lọ.” Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Bruno Bettelheim ti sọ, “tẹlifíṣọ̀n máa ń gba gbogbo ìrònú ènìyàn, àmọ́ kì í fún un lómìnira. Lọ́gán ni ìwé tí ó bá dára máa ń mú èrò inú ṣiṣẹ́, tí ó sì máa ń fún-un lómìnira.”

Ìwé kíkà máa ń mú kí ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ dàgbà. Reginald Damerall ti Yunifásítì Massachusetts sọ pé: “Kò sí ọmọdé tàbí àgbàlagbà kan tí tẹlifíṣọ̀n wíwò rẹ̀ máa ń sunwọ̀n sí i nítorí pé ó ń wò ó púpọ̀ sí i. Òye iṣẹ́ tí a nílò fún un kéré tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kò tí ì gbọ́ nípa ẹnì kan tí ó ní ìṣòro àìlèwo tẹlifíṣọ̀n rí.”

Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ìwé kíkà máa ń bèèrè fún ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ó sì máa ń mú un dàgbà; ó ní ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ sísọ àti ìwé kíkọ. Olùkọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kan sọ pé: “Iyàn rẹ̀ kò ṣeé jà pé, àṣeyọrí rẹ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ kan sinmi lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí àkópọ̀ wóróhùn ọ̀rọ̀ tí ó mọ̀, ì báà jẹ́ ohun tí o lè lóye nígbà tí o bá ń kàwé, tàbí bí o ṣe ń ronú bí o ṣe ń kọ̀wé, kò sì sí ọ̀nà tí o fi lè mú àkópọ̀ wóróhùn ọ̀rọ̀ dídára tí o mọ̀ sunwọ̀n sí i ju nípa kíkàwé lọ—kò sí ọ̀nà méjì.”

Ìwé kíkà máa ń kọ́ ènìyàn ní sùúrù. Ohun tí ó ju ẹgbẹ̀rún àwòrán lọ lè jáde lórí gọgọwú tẹlifíṣọ̀n ní kìkì wákàtí kan, tí kò sì ní fi àkókò tí ó pọ̀ tó sílẹ̀ fún òǹwòran láti ronú nípa ohun tí ó ń wò. Dókítà Matthew Dumont sọ pé: “Ọ̀nà ìgbàṣe yìí máa ń fa àkókò ìpọkànpọ̀ kíkúrú.” Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, àwọn ìwádìí kan fi hàn pé ìbátan wà láàárín àwòjù tẹlifíṣọ̀n àti ìpinnu ṣíṣe láìní ìkóra-ẹni níjàánu òun araàbalẹ̀—láàárín àwọn ọmọdé àti àgbàlagbà.

Ìwé kíkà ń bèèrè fún sùúrù. Ògbógi kan nípa ìbánisọ̀rọ̀pọ̀, Neil Postman, kọ̀wé pé: “Àwọn gbólóhùn, ìpínrọ̀ àti ojú ewé máa ń ṣàlàyé ara wọn lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀, ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, àti ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n ìrònú tí ó dájú pé kì í ṣe ti ìwàǹwára.” Bí òǹkàwé kan ti ń fẹ̀sọ̀ bá a lọ, ó ní láti ṣètumọ̀ ohun tí ó wà lójú ewé náà, kí ó gbé e yẹ̀ wò, kí ó sì ronú lé e lórí. Ìwé kíkà jẹ́ ọ̀nà ìtúǹkanpalẹ̀ kan tí ó díjú, tí ń bèèrè—sùúrù—tí ó sì ń mú un dàgbà.

Ojú Ìwòye Tí Ó Wà Déédéé

Láìka àwọn àǹfààní ìwé kíkà sí, a gbọ́dọ̀ gbà pé tẹlifíṣọ̀n wíwò ní àwọn àǹfààní tirẹ̀ pẹ̀lú. Ó lè ta ìwé kíkà yọ tí ó bá di ọ̀ràn gbígbé irú àwọn ìsọfúnni pàtó kan jáde.a Ètò orí tẹlifíṣọ̀n tí ó bá fani mọ́ra kan tilẹ̀ lè ru ìfẹ́ ọkàn ẹnì kan sókè láti kàwé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé: “Ìròyìn sọ pé, àwọn ètò tẹlifíṣọ̀n tí ń fi ìwé àwọn ọmọdé àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ hàn máa ń sún àwọn ọmọdé láti máa wá àwọn ìwé tí ó sọ̀rọ̀ lórí àwọn àkòrí wọ̀nyẹn àti àwọn àkòrí tí ó tan mọ́ ọn.”

Ojú ìwòye tí ó wà déédéé ṣe pàtàkì. Àwọn ìwé tí à ń tẹ̀ jáde àti tẹlifíṣọ̀n jẹ́ ọ̀nà méjì tí ó yàtọ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní agbára àti ààlà tirẹ̀. Méjèèjì ni a lè lò—tàbí kí á ṣì lò. Bẹ́ẹ̀ ni, ìwé kíkà àkàjù dórí pé à ń ya ara ẹni láṣo náà lè di ohun tí ó léwu bí àwòjù tẹlifíṣọ̀n.—Owe 18:1; Oniwasu 12:12.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni a kì í ka ìwé kíkà sí bí a ti ń ka eré bọ́wọ́dilẹ̀ oníran wíwò sí. Akọ̀ròyìn ọmọ Japan kan kédàárò pé: “A ti ń lọ kúrò láti orí àṣà jíjẹ́ òǹkàwé sórí jíjẹ́ òǹwòran.” Èyí, ní pàtàkì jù lọ, wọ́ pọ̀ láàárín àwọn èwe. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ lára wọn ń dàgbà di amọ̀ọ́kàmáfẹ̀ẹ́kà, wọ́n sì ń jìyà àbájáde rẹ̀. Nípa báyìí, báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ ọkàn láti kàwé dàgbà?

Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Ṣèrànwọ́

Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Newsweek, tí a fún ní àkọlé náà, “Bí A Ṣe Lè Mú Àwọn Òǹkàwé Rere Jáde,” fún wa ní ìṣírí tí ó ṣe ṣàkó yìí: “Bí ó bá ti di aláwògan sídìí tẹlifíṣọ̀n, àfàìmọ̀ kí ọmọ rẹ̀ náà máà rí bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí àwọn ọmọ rẹ bá rí ọ tí o ṣe ẹ̀yìn gannaku tayọ̀tayọ̀ sídìí ìwé dídára kan, wọn yóò rí i pé, kì í ṣe kìkì pé ò ń wàásù ìwé kíkà nìkan ni, ò ń ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” Lọ́nà tí ó tilẹ̀ sàn jù, àwọn òbí kan máa ń kàwé jákè fún àwọn ọmọ wọn. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń mú ipò ìbátan dídára dàgbà—ohun tí ó bani nínú jẹ́ pé kò sí nínú ọ̀pọ̀ ìdílé lónìí.

Dá àkójọ ìwé kan sílẹ̀. Dókítà Theodore Isaac Rubin dámọ̀ràn pé: “Jẹ́ kí àwọn ìwé wà lárọ̀ọ́wọ́tó—lọ́pọ̀ yanturu. Mo rántí pé mò ń kà wọ́n, nítorí pé wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó, àti nítorí pé gbogbo àwọn yòókù ń kà wọ́n, pẹ̀lú.” Àwọn ọmọ yóò kàwé bí àwọn ìwé bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó fàlàlà. Ìsúnniṣe tí wọ́n ní láti kàwé yóò tilẹ̀ pọ̀ sí i bí àwọn ìwé náà bá jẹ́ ara àkójọ ìwé tiwọn fúnra wọn.

Jẹ́ kí ìwé kíkà gbádùn mọ́ wọn. Àwọn ènìyàn máa ń sọ ọ́ pé, bí ọmọ kan bá fẹ́ràn ìwé kíkà, àbùṣe ìwé kíkọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bùṣe tán. Nítorí náà, mú kí ìwé kíkà jẹ́ ìrírí tí ó gbádùn mọ́ni fún ọmọ rẹ. Lọ́nà wo? Lákọ̀ọ́kọ́, fi ààlà sí àkókò tẹlifíṣọ̀n wíwò; yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ gborí lọ́wọ́ ìwé kíkà. Ẹ̀ẹ̀kejì, jẹ́ kí àyíká tí ó dára fún ìwé kíkà wà; àwọn àkókò tí kò sí ariwo àti àwọn ibi tí kò ní ariwo, irú bí ibi ìkàwé kan tí ó ní iná dídára, máa ń mú kí ìwé kíkà wu ènìyàn. Ẹ̀ẹ̀kẹta, má ṣe fipá mú wọn láti kàwé. Jẹ́ kí àwọn ìwé àti àyè tí wọn yóò fi kàwé wà fàlàlà, àmọ́ jẹ́ kí ọmọ náà mú ìfẹ́ ọkàn dàgbà.

Àwọn òbí kan máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í kàwé fún àwọn ọmọ wọn nígbà tí wọ́n wà ní pínníṣín. Èyí lè ṣàǹfààní. Àwọn ògbógi kan sọ pé, nígbà tí ọmọ kan yóò bá fi pé ọmọ ọdún mẹ́ta, yóò ti lóye ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn èdè tí yóò lò nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ lásán kan nígbà tí ó bá dàgbà—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò tí ì yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu síbẹ̀. Ìwé The First Three Years of Life sọ pé: “Àwọn ọmọ máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ láti lóye èdè ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àti kíákíá ju bí wọ́n ṣe máa ń mọ̀ ọ́n sọ lọ.” Bibeli sọ nípa Timoteu pé: “Lati ìgbà ọmọdé jòjòló ni iwọ ti mọ ìwé mímọ́.” (2 Timoteu 3:15) Ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, infant, tí a túmọ̀ sí ọmọdé jòjòló wá láti inú ọ̀rọ̀ Latin infans, tí ó túmọ̀ ní ti gidi sí “aláìlèsọ̀rọ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, Timoteu gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ tipẹ́tipẹ́ ṣaájú kí ó tó lè sọ̀rọ̀.

Bibeli—Ìrànwọ́ Pípabambarì

Ìwé The Bible in Its Literary Milieu sọ pé: “Bibeli jẹ́ àkójọ ìwé kíkọ kíkàmàmà kan.” Ní ti gidi, ìwé 66 tí ó wà nínú rẹ̀ ní àwọn ọ̀rọ̀ ewì, orin àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn, èyí tí àtàgbà àtọmọdé lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀. (Romu 15:4) Síwájú sí i, Bibeli “ni Ọlọrun mí sí ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́nisọ́nà, fún mímú awọn nǹkan tọ́, fún ìbániwí ninu òdodo.”—2 Timoteu 3:16.

Bẹ́ẹ̀ ni, ìwé kíkà tí ó ṣè pàtàkì jù lọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Ìdí tí ó dára wà tí a fi bèèrè pé kí ọba Israeli kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ tirẹ̀, kí ó sì “máa kà nínú rẹ̀ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo.” (Deuteronomi 17:18, 19) A sì pàṣẹ fún Joṣua láti máa ka ìwé mímọ́ ‘nípa ṣíṣe àṣàrò nínú rẹ̀’—ìyẹ́n túmọ̀ sí, kíkà á pẹ̀lú ohùn pẹ̀lẹ́, sínú ara rẹ̀—“ní ọ̀sán àti ní òru.”—Joṣua 1:8.

Òtítọ́ ni pé àwọn apá kan nínú Bibeli kò rọrùn láti kà. Wọ́n lè bèèrè fún ìpọkànpọ̀. Rántí pé Peteru kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí awọn ọmọdé jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn kan fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ naa.” (1 Peteru 2:2) Pẹ̀lú sùúrù, ìfẹ́ fún “wàrà” Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lè di ohun tí a ti dá mọ́ni bí ọmọdé jòjòló tí ń yánhànhàn fún wàrà ìyá rẹ̀. A lè mú ìmọrírì fún Bibeli kíkà dàgbà.b Ó tó bẹ́ẹ̀. Onípsalmu náà kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà fún [ẹsẹ̀] mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.” (Orin Dafidi 119:105) Kì í ha í ṣe gbogbo wa ni a nílò irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ ní àkókò ìṣòro wa?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nítorí mímọ èyí, Watch Tower Society ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn kásẹ́ẹ̀tì fídíò tí ó sọ̀rọ̀ lórí onírúurú àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Bibeli kún àwọn ìwé títẹ̀ tí wọ́n ń ṣe jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí.

b Láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọdé láti mú irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà fún ìmọ̀ Bibeli, Watch Tower Society ti ṣe àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó rọrùn láti kà, irú bí Iwe Itan Bibeli Mi àti Fifetisilẹ si Olukọ Nla na jáde. A lè rí àwọn ìwé méjèèjì tí a gbà sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tísí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́