ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 6/8 ojú ìwé 29-30
  • Àdúrà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àdúrà
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • “Olùgbọ́ Àdúrà”
  • Àwọn Tí Ọlọ́run Ń Gbọ́ Tiwọn
Jí!—1998
g98 6/8 ojú ìwé 29-30

Àdúrà

BÍBÁ Ọlọ́run tòótọ́ tàbí àwọn ọlọ́run èké sọ̀rọ̀ lọ́nà oníjọsìn. Wíwulẹ̀ bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ṣákálá kò fi dandan túmọ̀ sí àdúrà, bí ó ṣe hàn kedere nínú ìdájọ́ tí a ṣe ní Édẹ́nì àti nínú ọ̀ràn ti Kéènì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:8-13; 4:9-14) Àwọn ohun tó ń bá àdúrà rìn ni ìfọkànsìn, ìgbẹ́kẹ̀lé, ọ̀wọ̀, àti èrò gbígbáralé ẹni tí a ń darí àdúrà sí. Àwọn onírúurú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti Gíríìkì nípa àdúrà ń fúnni ní èrò bíbéèrè, títọrọ, pípàrọwà, rírawọ́ ẹ̀bẹ̀, rírọni, bíbẹ̀bẹ̀, wíwá ojúrere, ṣíṣàfẹ́rí, wíwádìí, pa pọ̀ mọ́ ìyìn, ọpẹ́, àti ìbùkún.

Láìsí tàbítàbí, a lè tọrọ nǹkan lọ́wọ́ ènìyàn tàbí kí a bẹ̀ ẹ́ fún ohun kan, a sì ń lo àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan (Jẹ́nẹ́sísì 44:18; 50:17; Ìṣe 25:11), ṣùgbọ́n nígbà tí a bá lo “àdúrà” lọ́nà ti ìjọsìn, kò bá irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ mu. A lè “bẹ” ẹnì kan pé kí ó ṣe nǹkan fúnni, ṣùgbọ́n nígbà tí a ń ṣe bẹ́ẹ̀, a kò ní wo ẹni yìí bí Ọlọ́run wa. Bí àpẹẹrẹ, a kò ní tọrọ nǹkan lọ́wọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, tàbí kí a ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí kò sí níbẹ̀, tí a kò sì lè rí i, bí a ti ń ṣe nígbà tí a ń gbàdúrà sí Ọlọ́run.

“Olùgbọ́ Àdúrà”

Gbogbo àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ jẹ́rìí pé Jèhófà ni Ẹni tí ó yẹ kí a máa gbàdúrà sí (Sáàmù 5:1, 2; Mátíù 6:9), òun ni “Olùgbọ́ àdúrà” (Sáàmù 65:2; 66:19), ó sì lágbára láti ran àwọn tí ń ké pè é lọ́wọ́. (Máàkù 11:24; Éfésù 3:20) Ó fi hàn pé gbígbàdúrà sí àwọn ọlọ́run èké àti àwọn ère òrìṣà wọn jẹ́ ìwà òmùgọ̀, nítorí pé àwọn òrìṣà náà kò lágbára láti gbọ́ tàbí láti ṣe nǹkan kan, àwọn ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣojú fún kò tó fi wé Ọlọ́run tòótọ́. (Àwọn Onídàájọ́ 10:11-16; Sáàmù 115:4, 6; Aísáyà 45:20; 46:1, 2, 6, 7) Ìdíje tó wáyé lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì, lórí ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run láàárín Báálì àti Jèhófà, ṣàfihàn ìwà òmùgọ̀ tó wà nínú gbígbàdúrà sí àwọn ọlọ́run èké.—1 Àwọn Ọba 18:21-39; fi wé Àwọn Onídàájọ́ 6:28-32.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan sọ pé a lè gbàdúrà sí àwọn ẹlòmíràn lọ́nà yíyẹ, bí sí Ọmọ Ọlọ́run, ẹ̀rí tẹnu mọ́ ọn pé kò rí bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, àwọn àkókò kọ̀ọ̀kan wà tí a ń darí ọ̀rọ̀ sí Jésù Kristi tó wà lọ́run. Nígbà tí Sítéfánù ń kú lọ, ó jírẹ̀ẹ́bẹ̀ sí Jésù pé: “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” (Ìṣe 7:59) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àyíká ọ̀rọ̀ náà fi ipò kan hàn, tó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ọ̀rọ̀ tí irú rẹ̀ kì í sábà ṣẹlẹ̀ tó sọ yìí. Ní àkókò yẹn gan-an, Sítéfánù rí ìran “Jésù tí ó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,” òun ní kedere sì ń sọ̀rọ̀ bí pé ó wà níwájú Jésù ní gidi, ó lómìnira láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ sí ẹni tí òun mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 7:55, 56; Kólósè 1:18) Bákan náà, àpọ́sítélì Jòhánù sọ níparí Ìṣípayá pé, “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” (Ìṣípayá 22:20) Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kan sí i, àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé, nínú ìran kan (Ìṣípayá 1:10; 4:1, 2), Jòhánù ti ń gbọ́ tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa bíbọ̀ rẹ̀ ọjọ́ iwájú, Jòhánù sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fèsì, ní sísọ ìdàníyàn rẹ̀ fún bíbọ̀ yẹn jáde. (Ìṣípayá 22:16, 20) Nínú ọ̀ràn méjèèjì, ti Sítéfánù àti ti Jòhánù, ipò náà yàtọ̀ díẹ̀ sí ti ìjíròrò tí Jòhánù bá ẹ̀dá ọ̀run kan ṣe nínú ìran Ìṣípayá yìí. (Ìṣípayá 7:13, 14; fi wé Ìṣe 22:6-22.) Kò sí ẹ̀rí pé àwọn Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn bá Jésù sọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀ ní àwọn ipò mìíràn lẹ́yìn tí ó gòkè re ọ̀run. Nípa bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.

Nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, tí ó fi rúbọ sí Ọlọ́run, “a . . . ní àìṣojo fún ọ̀nà ìwọlé sínú ibi mímọ́,” ìyẹn ni ìgboyà láti dé iwájú Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà, kí a lọ “pẹ̀lú ọkàn-àyà tòótọ́ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ti ìgbàgbọ́.” (Hébérù 10:19-22) Nítorí náà, Jésù Kristi ni “ọ̀nà” kan ṣoṣo fún bíbá Ọlọ́run làjà àti dídé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà.—Jòhánù 14:6; 15:16; 16:23, 24; 1 Kọ́ríńtì 1:2; Éfésù 2:18.

Àwọn Tí Ọlọ́run Ń Gbọ́ Tiwọn

Àwọn ènìyàn “ẹlẹ́ran ara gbogbo” lè wá sọ́dọ̀ “Olùgbọ́ àdúrà,” Jèhófà Ọlọ́run. (Sáàmù 65:2; Ìṣe 15:17) Kódà, láàárín àkókò tí Ísírẹ́lì fi jẹ́ “dúkìá àdáni” Ọlọ́run, àwọn ènìyàn májẹ̀mú rẹ̀, àwọn àjèjì lè dé ọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà nípa mímọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ohun èlò tí Ọlọ́run yàn, àti mímọ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ibi tí ó yàn fún ẹbọ rírú. (Diutarónómì 9:29; 2 Kíróníkà 6:32, 33; fi wé Aísáyà 19:22.) Lẹ́yìn náà, ikú Kristi mú ìyàtọ̀ àárín Júù àti Kèfèrí kúrò láé fáàbàdà. (Éfésù 2:11-16) Nínú ilé Kọ̀nílíù ará Ítálì náà, Pétérù sọ pé, “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Nítorí náà, kókó pàtàkì jù lọ náà ni ọkàn-àyà ẹni náà àti ohun tí ọkàn-àyà rẹ̀ ń sún un ṣe. (Sáàmù 119:145; Ìdárò 3:41) Àwọn tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ń “ṣe àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀,” ní ìdánilójú pé “etí” rẹ̀ ń ṣí sí àwọn.—1 Jòhánù 3:22; Sáàmù 10:17; Òwe 15:8; 1 Pétérù 3:12.

Lódì kejì, Ọlọ́run kì í gbọ́ ti àwọn tí ń ṣàìnáání Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti òfin rẹ̀, tí wọ́n ń tàjẹ̀ sílẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun burúkú mìíràn; àdúrà wọn pàápàá jẹ́ “ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí” lọ́dọ̀ rẹ̀. (Òwe 15:29; 28:9; Aísáyà 1:15; Míkà 3:4) Àdúrà irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pàápàá lè “di ẹ̀ṣẹ̀.” (Sáàmù 109:3-7) Sọ́ọ̀lù Ọba pàdánù ojúrere Ọlọ́run nípasẹ̀ ọ̀nà ìṣọ̀tẹ̀, oníkùgbùù rẹ̀, “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù ń wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, Jèhófà kò dá a lóhùn rárá, yálà nípasẹ̀ àwọn àlá tàbí nípasẹ̀ Úrímù tàbí nípasẹ̀ àwọn wòlíì.” (1 Sámúẹ́lì 28:6) Jésù sọ pé àwọn alágàbàgebè tí ń wá ọ̀nà láti pàfiyèsí sí ìtara ìjọsìn wọn nípa gbígbàdúrà ti gba ‘èrè wọn ní kíkún’—láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 6:5) Àwọn Farisí tí ń fara hàn bí onítara ìjọsìn máa ń gba àwọn àdúrà gígùn, wọ́n ń yangàn pé ìwà àwọn ní láárí jù, síbẹ̀ Ọlọ́run dá wọn lẹ́bi nítorí ipa ọ̀nà onígbèéraga wọn. (Máàkù 12:40; Lúùkù 18:10-14) Bí wọ́n tilẹ̀ ń fi ẹnu wọn sún mọ́ Ọlọ́run, ọkàn-àyà wọn jìnnà sí òun àti Ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ̀.—Mátíù 15:3-9; fi wé Aísáyà 58:1-9.

Ẹni náà gbọ́dọ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ó sì gbà gbọ́ pé ó jẹ́ “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a” (Hébérù 11:6), kí ó wá nínú “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ti ìgbàgbọ́.” (Hébérù 10:22, 38, 39) Ó tún ṣe pàtàkì kí ó jẹ́wọ́ ipò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nígbà tí ó bá sì dẹ́ṣẹ̀ ńlá, ẹni náà gbọ́dọ̀ “tu Jèhófà lójú” (1 Sámúẹ́lì 13:12; Dáníẹ́lì 9:13) nípa kíkọ́kọ́ tu ọkàn-àyà ara rẹ̀ lójú nípa ìrònúpìwàdà, ìrẹ̀lẹ̀, àti ẹ̀dùn àtọkànwá. (2 Kíróníkà 34:26-28; Sáàmù 51:16, 17; 119:58) Nígbà náà, Ọlọ́run lè gbọ́ àrọwà rẹ̀, ó lè dárí jì í, ó sì lè máa gbọ́ tirẹ̀ (2 Àwọn Ọba 13:4; 2 Kíróníkà 7:13, 14; 33:10-13; Jákọ́bù 4:8-10); ẹni náà kò sì ní ní ìmọ̀lára pé Ọlọ́run ti ‘fi ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kí àdúrà má lè là á kọjá.’ (Ìdárò 3:40-44) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má ta ẹnì kan nù pátápátá nínú bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, àdúrà rẹ̀ lè “ní ìdènà,” bí ó bá ń kùnà láti máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run. (1 Pétérù 3:7) Àwọn tí ń fẹ́ ìdáríjì gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn ẹlòmíràn.—Mátíù 6:14, 15; Máàkù 11:25; Lúùkù 11:4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́