Ìlérí Ta Lo Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?
“ÀWỌN ìlérí ńlá ló ṣe, bí òun fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ ẹni ńlá nígbà yẹn; ṣùgbọ́n àwọn ìlérí rẹ̀ kò já mọ́ nǹkan kan bí òun náà kò ṣé já mọ́ nǹkan kan mọ́ báyìí.”—Ìwé King Henry the Eighth, tí William Shakespeare ṣe.
Àwọn ìlérí Thomas Wolsey, ìyẹn kádínà ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó lo agbára òṣèlú lọ́nà tó ga ní ilẹ̀ England láàárín ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ni àwọn ìlérí ńlá tí Shakespeare sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yẹn. Àwọn kan lè sọ pé ohun tí Shakespeare sọ yìí bá èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìlérí táwọn ń gbọ́ lónìí mu. Lemọ́lemọ́ làwọn èèyàn máa ń ṣèlérí tó pọ̀ ṣùgbọ́n tó jẹ́ díẹ̀ ni wọ́n máa ń mú ṣẹ. Nígbà náà, kò ṣòro láti lóye ohun tó mú káwọn èèyàn máa ṣiyèméjì láti gba ìlérí èyíkéyìí gbọ́.
Ìjákulẹ̀ Pọ̀ Rẹpẹtẹ
Bí àpẹẹrẹ, nígbà ìjà àjàkú akátá kan tó wáyé láwọn ọdún 1990 ní àgbègbè Balkans, Ìgbìmọ̀ Ààbò fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kéde pé ìlú Srebrenica tó wà ní orílẹ̀-èdè Bosnia jẹ́ “ibi tó láàbò.” Ìyẹn lè dà bí ìfọwọ́sọ̀yà tó ṣe é gbára lé látọ̀dọ̀ díẹ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó jẹ́ Mùsùlùmí ní Srebrenica ló rò bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ní àbárèbábọ̀, ibi tí wọ́n ṣèlérí pé ó láàbò kò láàbò kankan. (Sáàmù 146:3) Ní oṣù July ọdún 1995, àwọn ọmọ ogun alátakò borí àwọn ọmọ ogun Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, bí wọ́n ṣe jẹ gàba lé ìlú náà lórí nìyẹn. Ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àwọn Mùsùlùmí ló fẹsẹ̀ fẹ́, àwọn ará ìlú tó jẹ́ Mùsùlùmí tí wọ́n sì pa danù kò dín ní ẹgbẹ̀fà.
Kíkọ̀ láti mú ìlérí ṣẹ ló gbòde kan nínú ayé lónìí. Ó ń dun àwọn èèyàn pé àwọn kan ti yàn àwọn jẹ gan-an nítorí “àìmọye ìpolówó ọjà tó ń ṣini lọ́nà tí kò sì tún jẹ́ òótọ́” tó pọ̀ bí nǹkan míì lónìí. A ti já wọn kulẹ̀ nítorí “àìmọye ìlérí táwọn olóṣèlú ṣe tí wọ́n kò sì mú ṣẹ.” (The New Encyclopædia Britannica, Ìdìpọ̀ 15, ojú ìwé 37) Àwọn aṣáájú ìsìn táwọn èèyàn fọkàn tán ṣèlérí láti bójú tó àwọn ọmọ ìjọ wọn, ṣùgbọ́n ńṣe ni wọ́n ń fojú àwọn ọmọ ìjọ gbolẹ̀. Kódà nínú irú àwọn iṣẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìwé àti ìmọ̀ ìṣègùn, níbi tó yẹ kí wọ́n ti máa ṣàánú àwọn èèyàn gan-an, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti dalẹ̀ tí wọ́n sì ti kó àwọn mìíràn nífà tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ti ṣekú pa àwọn tí wọ́n ń bójú tó pàápàá. Abájọ tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe máa gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́!—Òwe 14:15.
Àwọn Ìlérí Tá A Mú Ṣẹ
Lóòótọ́ o, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń mú ìlérí wọn ṣẹ, kódà bó tiẹ̀ máa ná wọn ní ohun tó pọ̀. (Sáàmù 15:4) Ọ̀rọ̀ wọn kì í yẹ̀, wọ́n máa ń mú ìlérí wọn ṣẹ ṣáá ni. Ọ̀pọ̀ ló sì jẹ́ pé lóòótọ́ ní wọ́n fẹ́ ṣe ohun tí wọ́n ṣèlérí rẹ̀. Wọ́n ṣe tán, wọ́n sì fẹ́ láti mú ìlérí wọn ṣẹ, ṣùgbọ́n agbára wọn kò gbe mọ́ láti ṣe bí wọ́n ti sọ. Kódà, ipò nǹkan lè dabarú ìwéwèé dáradára tẹ́nì kan ti ṣe.—Oníwàásù 9:11.
Ohun tó wù kó fà á, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gba ìlérí ẹnikẹ́ni gbọ́. Tóò, níbi tọ́rọ̀ dé yìí: Ǹjẹ́ ìlérí èyíkéyìí wà tá a lè gbẹ́kẹ̀ lé? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà. A lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí ló dé tí o kò ṣàyẹ̀wò ohun tí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀lé e yóò sọ lórí kókó yìí? Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ti gbà, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà gbà pé àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò AP/Amel Emric