ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 20-21
Gbogbo Ìgbà Ni Jèhófà Máa Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ
Ábúráhámù àti Sérà nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Jèhófà bù kún wọn, ó sì fún wọn ní ọmọkùnrin kan. Nígbà tí wọ́n tún kojú àdánwò, bí wọ́n ṣe jẹ́ onígbọràn fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára nínú àwọn ìlérí Jèhófà.
Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo nígbàgbọ́ tó lágbára nínú àwọn ìlérí Jèhófà tí mo bá kojú àdánwò? Báwo ni mo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára?