Ábúráhámù àti Sárà—O Lè Fara Wé Ìgbàgbọ́ Wọn!
BÍBÉLÌ pè é ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.” (Róòmù 4:11) Bákan náà, aya rẹ̀ ọ̀wọ́n ní ìgbàgbọ́. (Hébérù 11:11) Àwọn tá a ń sọ̀rọ̀ wọn ni Ábúráhámù baba ńlá àti Sárà aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yìí sì jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ wọn fi jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ? Kí ni díẹ̀ lára àwọn àdánwò tí wọ́n fara dà? Báwo sì ni ìtàn wọn ti ṣe pàtàkì tó fún wa?
Ábúráhámù fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un láti kúrò ní ilé rẹ̀. Jèhófà sọ pé: “Bá ọ̀nà rẹ lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ àti kúrò ní ilé baba rẹ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:1) Baba ńlá tó jẹ́ olùṣòtítọ́ yìí ṣègbọràn, nítorí Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a pè é, fi ṣègbọràn ní jíjáde lọ sí ibì kan tí a ti yàn án tẹ́lẹ̀ láti gbà gẹ́gẹ́ bí ogún; ó sì jáde lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ibi tí òun ń lọ.” (Hébérù 11:8) Gbé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìṣíkiri rẹ̀ yẹ̀ wò.
Ìlú Úrì ni Ábúráhámù ń gbé, èyí tó wà ní ìhà gúúsù orílẹ̀-èdè Iraq báyìí. Úrì jẹ́ ìlú ọlọ́rọ̀ tó wà ní Mesopotámíà. Àwọn ará ìlú yìí máa ń ṣòwò pẹ̀lú àwọn tó ń gbé láwọn àgbègbè ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Páṣíà, kódà ó ṣeé ṣe kí wọ́n tún máa ṣòwò pẹ̀lú àwọn tó ń gbé àgbègbè Àfonífojì Indus pàápàá. Alàgbà Leonard Woolley, ẹni tó mójú tó àwọn awalẹ̀pìtàn níbi tí wọ́n ti ń fẹ̀sọ̀ walẹ̀ ní ìlú Úrì, sọ pé nígbà ayé Ábúráhámù, ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé ibẹ̀ ni wọ́n fi bíríkì kọ́, tí wọ́n rẹ́ ògiri wọn, tí wọ́n sì kùn lẹ́fun. Bí àpẹẹrẹ, ilé ọ̀kan lára àwọn ọlọ́rọ̀ ìlú náà jẹ́ ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, wọ́n sì da kọnkéré sí àgbàlá ilé náà. Àwọn ìránṣẹ́ àti àlejò ló ń lo àwọn iyàrá ìsàlẹ̀. Wọ́n fi igi ṣe fàráńdà sí ilé náà lókè, fàráńdá yìí làwọn onílé sì máa ń gbà wọnú yàrá wọn. Alàgbà Wooley sọ pé níwọ̀n bí àwọn ilé náà ti ní iyàrá tó tó mẹ́wàá sí ogún, wọ́n “láyè tó pọ̀ gan-an pẹ̀lú àwọn ohun amáyédẹrùn, tá a bá sì fi bí nǹkan ṣe rí ní ìhà Ìlà Oòrùn ayé wò ó, ilé olówó iyebíye ni wọ́n. Àwọn “ọ̀làjú èèyàn ló ń gbé irú àwọn ilé ńlá bẹ́ẹ̀, àwọn ohun amáyédẹrùn inú wọn sì bá ohun tí àwọn tó ń gbé ìlú ńlá wọ̀nyí ń fẹ́ mu.” Bó bá jẹ́ pé irú ilé bẹ́ẹ̀ ni Ábúráhámù àti Sárà fi sílẹ̀, tí wọ́n wá fẹ́ máa lọ gbé inú àgọ́, ohun kékeré kọ́ ni wọ́n fi du ara wọn kí wọ́n bàa lè ṣègbọràn sí Jèhófà.
Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ kọ́kọ́ ṣí lọ sí Háránì, ìlú kan ní ìhà àríwá Mesopotámíà, lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣí lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Èyí jẹ́ ìrìn àjò nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà; ká sòótọ́ ìrìn àjò tó ń tánni lókun ló jẹ́ fún tọkọtaya àgbàlagbà yìí! Nígbà tí wọ́n fi ìlú Háránì sílẹ̀, Ábúráhámù ti pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin, Sárà sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin.—Jẹ́nẹ́sísì 12:4.
Báwo ni ọ̀ràn náà ì bá ti rí lára Sárà nígbà tí Ábúráhámù sọ pé wọ́n máa fi ìlú Úrì sílẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó máa kọminú pé àwọn á kúrò ní ilé tó ní nǹkan amáyédẹrùn tó sì fọkàn èèyàn balẹ̀, àwọn á ṣí lọ sí ibi táwọn ò lọ rí, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ibi táwọn èèyàn ò ní fẹ́ràn wọn, àwọn á sì máa gbé ìgbésí ayé tálákà. Síbẹ̀, Sárà tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀, ó sì ka Ábúráhámù sí “olúwa” lọ́kàn rẹ̀. (1 Pétérù 3:5, 6) Àwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé èyí fi hàn pé “ó ti mọ́ Sárà lára láti máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀,” èyí sì fi hàn pé “àtọkànwá ni ìgbọràn Sárà, nítorí bó ṣe rí lára rẹ̀ gan-an ló ṣe ń hùwà.” Àmọ́, ju gbogbo rẹ̀ lọ, Sárà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ìtẹríba àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni.
Ní tòótọ́, wọn ò sọ fún wa pé ká fi ilé wa sílẹ̀ ká tó lè ṣègbọràn sí Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan ti fi ìlú wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ wàásù ìhìn rere ní orílẹ̀-èdè mìíràn. Nítorí náà, ibi yòówù ká ti máa sin Ọlọ́run, bá a bá ti ń fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́, yóò máa pèsè ohun tá a nílò fún wa.—Mátíù 6:25-33.
Yálà Ábúráhámù ni o tàbí Sárà ni o, kò sí ọ̀kankan nínú wọn tó kábàámọ̀ ìpinnu tí wọ́n ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí wọ́n bá ti ń bá a nìṣó ní tòótọ́ ní rírántí ibi tí wọ́n ti jáde lọ, àyè ì bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti padà.” Àmọ́, wọn kò padà o. Níwọ̀n bó ti dá wọn lójú pé Jèhófà “ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a,” wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí rẹ̀. Àwa náà gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ bíi tiwọn bá a bá fẹ́ máa sin Jèhófà tọkàntọkàn.—Hébérù 11:6, 15, 16.
Ọrọ̀ Tẹ̀mí àti Ọrọ̀ Tara
Lẹ́yìn tí Ábúráhámù dé Kénáánì, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Nígbà tí Ábúráhámù gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe “orúkọ Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:7, 8) Jèhófà sọ Ábúráhámù di ọlọ́rọ̀, àwọn èèyàn tó wà ní ibùdó rẹ̀ sì pọ̀ gan-an. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nígbà kan, ó kó ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjìdínlógún ọkùnrin tó ti kọ́ níṣẹ́ jọ, ìyẹn àwọn ẹrú tí wọ́n bí sí agboolé rẹ̀, àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí “iye gbogbo àwọn tó wà nínú ibùdó rẹ̀ ju ẹgbẹ̀rún kan lọ dáadáa.” Nítorí ìdí kan ṣá, àwọn èèyàn ń pè é ní “ìjòyè Ọlọ́run.”—Jẹ́nẹ́sísì 13:2; 14:14; 23:6.
Ábúráhámù ló ń mú ipò iwájú nínú ìjọsìn ní agboolé rẹ̀, tó sì ń kọ́ wọn láti “pa ọ̀nà Jèhófà mọ́ láti ṣe òdodo àti ìdájọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:19) Àpẹẹrẹ Ábúráhámù lè jẹ́ ìṣírí fún àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé lónìí nítorí pé ó ṣeé ṣe fún un láti kọ́ àwọn aráalé rẹ̀ láti gbọ́kàn lé Jèhófà kí wọ́n sì máa ṣe òdodo. Abájọ tí Hágárì ará Íjíbítì tó jẹ́ ìránṣẹ́bìnrin Sárà, títí kan ìránṣẹ́kùnrin Ábúráhámù tó dàgbà jù lọ àti Ísákì ọmọ Ábúráhámù fi gbára lé Jèhófà Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 16:5, 13; 24:10-14; 25:21.
Ábúráhámù Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà
Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Ábúráhámù fi hàn pé ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Dípò kí Ábúráhámù jẹ́ kí aáwọ̀ tó wà láàárín àwọn darandaran rẹ̀ àti ti Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ máa bá a lọ bẹ́ẹ̀, ó dámọ̀ràn pé kí àwọn pín ibùdó àwọn sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì sọ fún Lọ́ọ̀tì tó kéré sí i lọ́jọ́ orí láti yan ilẹ̀ tó fẹ́. Ábúráhámù jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà.—Jẹ́nẹ́sísì 13:5-13.
Bó bá ṣẹlẹ̀ pé a ní láti ṣèpinnu, yálà kí a rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ wa tàbí kí a fi àwọn nǹkan kan du ara wa kí àlàáfíà bàa lè wà, ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà kò jẹ́ ki Ábúráhámù ṣaláìní nítorí ẹ̀mí ìgbatẹnirò tó fi hàn sí Lọ́ọ̀tì. Dípò ìyẹn, Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù àti irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí pé òun á fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tí Ábúráhámù fojú rí nígbà tó wò yí ká. (Jẹ́nẹ́sísì 13:14-17) Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, níwọ̀n bí a ó ti pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run.’”—Mátíù 5:9.
Ta Ló Máa Jẹ́ Ajogún Ábúráhámù?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ṣèlérí irú ọmọ kan, Sárà ṣì yàgàn. Èyí sún Ábúráhámù láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Ọlọ́run. Ṣé Élíésérì ìránṣẹ́ rẹ̀ ló máa jogún gbogbo ohun tó ní ni? Rárá o, nítorí Jèhófà ti sọ pé: “Ọkùnrin yìí kò ní rọ́pò rẹ gẹ́gẹ́ bí ajogún, ṣùgbọ́n ẹni tí yóò jáde wá láti àwọn ìhà inú ara ìwọ fúnra rẹ ni yóò rọ́pò rẹ gẹ́gẹ́ bí ajogún.”—Jẹ́nẹ́sísì 15:1-4.
Síbẹ̀, wọn ò bímọ, Sárà tó ti di ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin sì ti gbà pé òun ò lè bímọ mọ́. Látàrí èyí, ó sọ fún Ábúráhámù pé: “Jèhófà ti sé mi mọ́ kúrò nínú bíbímọ. Jọ̀wọ́, ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìránṣẹ́bìnrin mi. Bóyá mo lè ní àwọn ọmọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Nígbà náà ni Ábúráhámù mú Hágárì láti fi ṣe aya rẹ̀ kejì, ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, obìnrin náà sì lóyún. Gbàrà tí Hágárì mọ̀ pé òun ti lóyún, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí tàbùkù sí Sárà olúwa rẹ̀. Sárà ṣàròyé gan-an nípa èyí fún Ábúrámù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ Hágárì lógo tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi sá lọ.—Jẹ́nẹ́sísì 16:1-6.
Ábúráhámù àti Sárà ṣe ohun tí wọ́n rò pé ó bọ́gbọ́n mu gẹ́gẹ́ bí àṣà ìgbà yẹn. Àmọ́ o, kì í ṣe ọ̀nà yẹn ni Jèhófà fẹ́ gbà láti fún Ábúráhámù ní irú ọmọ. Nínú àṣà ìbílẹ̀ wa, àwọn ohun kan lè tọ̀nà nínú onírúurú ipò, àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé Jèhófà fọwọ́ sí i. Ojú tí Jèhófà yóò fi wo ọ̀ràn náà lè yàtọ̀ pátápátá sí tiwa. Látàrí èyí, ó yẹ ká máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ká máa gbàdúrà pé kó jẹ́ ká mọ ọ̀nà tó fẹ́ ká gbà ṣe nǹkan.—Sáàmù 25:4, 5; 143:8, 10.
Kò Sí Ohunkóhun Tó “Ṣe Àrà Ọ̀tọ̀ Jù fún Jèhófà”
Bí àkókò ti ń lọ, Hágárì bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Íṣímáẹ́lì fún Ábúráhámù. Síbẹ̀, òun kọ́ ni Irú Ọmọ tí a ṣèlérí náà. Sárà fúnra rẹ̀ ló máa bí Irú Ọmọ náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti darúgbó.—Jẹ́nẹ́sísì 17:15, 16.
Nígbà tí Ọlọ́run sọ pé Sárà máa bí ọmọkùnrin kan fún ọkọ rẹ̀, “Ábúráhámù dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́rìn-ín, ó sì ń wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: ‘Ọkùnrin ọgọ́rùn-ún ọdún yóò ha bí ọmọ, àti Sárà, bẹ́ẹ̀ ni, obìnrin àádọ́rùn-ún ọdún yóò ha bímọ bí?’” (Jẹ́nẹ́sísì 17:17) Nígbà tí áńgẹ́lì kan tún ọ̀rọ̀ yìí sọ níbi tí Sárà ti gbọ́, ó “rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀.” Ṣùgbọ́n kò sí ohunkóhun tó “ṣe àrà ọ̀tọ̀ jù fún Jèhófà.” Ó yẹ ká gbà gbọ́ pé ó lè ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 18:12-14.
“Nípa ìgbàgbọ́ ni Sárà fúnra rẹ̀ . . . gba agbára láti lóyún irú-ọmọ, nígbà tí ó ti ré kọjá ààlà ọjọ́ orí pàápàá, níwọ̀n bí ó ti ka ẹni tí ó ṣèlérí sí olùṣòtítọ́.” (Hébérù 11:11) Nígbà tó yá, Sárà bí Ísákì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Ẹ̀rín.”
Ábúráhámù Fi Gbogbo Ọkàn Gbà Pé Ọlọ́run Yóò Mú Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ
Jèhófà sọ pé Ísákì ni ajogún tí ìdílé náà ti ń retí tipẹ́tipẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 21:12) Nípa bẹ́ẹ̀, ìyàlẹ́nu gbáà ló máa jẹ́ fún Ábúráhámù nígbà tí Ọlọ́run sọ pé kó fi ọmọ rẹ̀ rúbọ sí òun. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìdí tó bọ́gbọ́n mu ló wà pé Ábúráhámù fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Ṣé Jèhófà ò lágbára láti jí Ísákì dìde ni bó bá kú? (Hébérù 11:17-19) Ǹjẹ́ Ọlọ́run ò ti fi hàn pé òun jẹ́ alágbára nígbà tó fi iṣẹ́ ìyanu mú kí agbára ìbímọ Ábúráhámù àti Sárà sọ jí kí wọ́n lè bí Ísákì? Nítorí pé ó dá Ábúráhámù lójú pé Ọlọ́run lágbára láti ṣe ohun tí Ó ṣèlérí, ó múra tán láti ṣègbọràn. Lóòótọ́ o, Ọlọ́run kò jẹ́ kó pa ọmọ rẹ̀ rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì 22:1-14) Síbẹ̀, ohun tí Ábúráhámù ṣe nínú ọ̀ràn yìí jẹ́ ká mọ bí kò ṣe rọrùn tó fún Jèhófà Ọlọ́run láti “fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16; Mátíù 20:28.
Ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní nínú Ọlọ́run jẹ́ kó mọ̀ pé ẹni tó jẹ́ ajogún tí Jèhófà ṣèlérí kò lè fẹ́ abọ̀rìṣà láti ilẹ̀ Kénáánì. Báwo ni òbí kan tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe lè fọwọ́ sí i pé kí ọmọ òun lọ fẹ́ ẹni tí kì í sin Jèhófà? Nítorí èyí, Ábúráhámù wá aya tó yẹ fún Ísákì láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní Mesopotámíà, ibi tó ju ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà lọ sí ilé rẹ̀. Ọlọ́run bù kún ìsapá rẹ̀ nípa fífihàn pé Rèbékà ni obìnrin tí òun ti yàn láti di ìyàwó Ísákì àti ìyá ńlá Mèsáyà. Dájúdájú, Jèhófà “bù kún Ábúráhámù nínú ohun gbogbo.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:1-67; Mátíù 1:1, 2.
Ìbùkún fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
Ábúráhámù àti Sárà jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa nínú fífarada àdánwò àti níní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run. Mímú tí Ọlọ́run mú ìlérí yẹn ṣẹ jẹ mọ́ ire aráyé títí láé, nítorí Jèhófà jẹ́ kó dá Ábúráhámù lójú pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ . . . ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.
Ní tòótọ́, Ábúráhámù àti Sárà kì í ṣe ẹni pípé, bí àwa náà kò ti jẹ́ ẹni pípé. Àmọ́, nígbà tí wọ́n mọ ohun tí Ọlọ́run pète láti ṣe, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n ṣègbọràn, láìka ohun tó máa ná wọn sí. Ìdí nìyẹn tí a fi máa ń rántí Ábúráhámù pé ó jẹ́ “ọ̀rẹ́ Jèhófà,” tá a sì ń rántí Sárà pé ó jẹ́ ‘obìnrin mímọ́ tí ó ní ìrètí nínú Ọlọ́run.’ (Jákọ́bù 2:23; 1 Pétérù 3:5) Bí àwa náà bá ń sapá láti fara wé ìgbàgbọ́ Ábúráhámù àti Sárà, a lè ní àjọṣe tó ṣe pàtàkì pẹ̀lú Ọlọ́run. A tún lè jàǹfààní nínú àwọn ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù.—Jẹ́nẹ́sísì 17:7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Nítorí pé Ábúráhámù àti Sárà ní ìgbàgbọ́, Jèhófà fi ọmọ kan bù kún wọn ní ọjọ́ ogbó wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àpẹẹrẹ Ábúráhámù jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí lára Jèhófà nígbà tó jẹ́ kí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo kú