ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 28-ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1
  • Sérà Bímọ Nígbà Tó Darúgbó!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sérà Bímọ Nígbà Tó Darúgbó!
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Pè É Ní “Ìyá Ọba”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ábúráhámù àti Sárà—O Lè Fara Wé Ìgbàgbọ́ Wọn!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • “O Jẹ́ Obìnrin Kan Tí Ó Lẹ́wà Ní Ìrísí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ta Ni Ábúráhámù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 28-ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1
Sérà wà nínú àgọ́, ó sì ń tẹ́tí gbọ́ ohun táwọn áńgẹ́lì ń sọ fún Ábúráhámù

Ẹ̀KỌ́ 9

Sérà Bímọ Nígbà Tó Darúgbó!

Ọjọ́ pẹ́ tí Ábúráhámù àti Sérà ti jẹ́ tọkọtaya. Ní ìlú Úrì tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀, àwọn nǹkan tó lẹ́wà wà nílé wọn, àmọ́ ní báyìí, inú àgọ́ ni wọ́n ń gbé. Síbẹ̀, Sérà kò ráhùn, ìdí sì ni pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

Ó wu Sérà gan-an pé kóun náà bímọ. Lọ́jọ́ kan, ó sọ fún ọkọ ẹ̀ pé: ‘Màá fún ẹ ní Hágárì ìránṣẹ́ mi kó o fi ṣe ìyàwó, tó bá sì bímọ, màá tọ́jú ọmọ náà bíi pé ọmọ mi ni.’ Nígbà tó yá, Hágárì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Orúkọ ọmọ náà ni Íṣímáẹ́lì.

Sérà lóyún

Lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn àlejò mẹ́ta kan wá sílé wọn. Nígbà yẹn, Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) Sérà sì jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún (89). Ábúráhámù ní kí wọ́n wá sinmi díẹ̀ lábẹ́ igi kí wọ́n sì jẹun. Ǹjẹ́ o mọ àwọn àlejò tó wá sílé wọn? Àwọn áńgẹ́lì ni! Wọ́n sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Ní àsìkò yìí lọ́dún tó ń bọ̀, Sérà ìyàwó ẹ máa bí ọmọkùnrin fún ẹ.’ Sérà ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú àgọ́ tó wà. Ó rọra rẹ́rìn-ín, ó sì sọ nínú ọkàn ẹ̀ pé: ‘Ṣé èmi arúgbó yìí tún lè bímọ ṣá?’

Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì Jèhófà ṣẹ, Sérà bí ọmọkùnrin kan. Ábúráhámù sọ ọmọ náà ní Ísákì. Ìtumọ̀ orúkọ ọmọ náà ni “Ẹ̀rín.”

Ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ísákì jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún (5). Sérà kíyè sí i pé Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́. Torí pé Sérà fẹ́ dáàbò bo Ísákì, ó lọ bá ọkọ ẹ̀, ó sì sọ fún un pé kó lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ. Ábúráhámù ò kọ́kọ́ gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Tẹ́tí sí ohun tí Sérà sọ. Màá tọ́jú Íṣímáẹ́lì. Àmọ́, nípasẹ̀ Ísákì ni màá gbà mú àwọn ìlérí mi ṣẹ.’

Sérà di Ísákì mú bí Hágárì àti Íṣímáẹ́lì ṣe ń lọ

“Ìgbàgbọ́ mú kí Sérà náà gba agbára láti lóyún ọmọ, . . . torí ó ka Ẹni tó ṣe ìlérí náà sí olóòótọ́.”​—Hébérù 11:11

Ìbéèrè: Kí ni Sérà gbọ́ táwọn áńgẹ́lì náà sọ fún Ábúráhámù? Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Ísákì?

Jẹ́nẹ́sísì 16:1-4, 15, 16; 17:25-27; 18:1-15; 21:1-14; Hébérù 11:11

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́