Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Bí Kò Bá Nífẹ̀ẹ́ Mi Bí Mo Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ Ńkọ́?
“Ọkàn mi ò balẹ̀, ẹ̀rù sì ń bà mí. Ìfẹ́ rẹ̀ ti kó sí mi lórí. Àmọ́, mi ò mọ̀ bóyá ó nífẹ̀ẹ́ mi. Kí ni kí n ṣe? Ṣé kí n sọ fún un pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni? Ó tì o, ká máà rí i, mi ò lè ṣe é! Kí ni àwọn èèyàn máa sọ nípa mi?”—Huda.a
HUDA, ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ilẹ̀ Lẹ́bánónì kan, nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan tí kò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ìṣòro kan tó wọ́pọ̀ ni èyí jẹ́. Irú ohun kan náà ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́bìnrin mìíràn, tí ń jẹ́ Zeina. Ó rántí pé: “Ojoojúmọ́ ni mo máa ń rí i nítorí pé àdúgbò wa ló ń gbé nígbà náà. Ọmọkùnrin dára síbẹ̀. Bí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe kó sí mi lórí nìyẹn.”
Lótìítọ́, kò sí ohun tí ó burú nínú kí a ní ìfẹ́ ẹnì kan gidigidi—ká ní ẹni yẹn jẹ́ ẹni tí Kristẹni lè bá ṣe ìgbéyàwó lọ́nà tí ó yẹ. (Òwe 5:15; 1 Kọ́ríńtì 7:39) Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó burú nínú kí ọ̀dọ́bìnrin kan fẹ́ láti lọ́kọ, kí ó sì ní ìdílé. Àmọ́, ká ní ìfẹ́ ẹnì kan tí ó yẹ kó sí ọ lórí, tí kò sì mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun—tàbí tí kò nífẹ̀ẹ́ rẹ bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀—ńkọ́?
Ohun Tí Ń Dunni Nínú Ṣíṣàìsàn Ìfẹ́
Bí Huda, o lè ronú pé o wà nínú pákáǹleke ìmọ̀lára. Ìsoríkọ́ tí ń sọni di ìdàkudà lè wá gbẹ̀yìn ìmọ̀lára amóríyá tí ń pani bí ọtí. Zeina sọ pé: “Nígbà mìíràn, ìmọ̀lára mi máa ń dà bí ti ọmọbìnrin tí ó láyọ̀ jù lọ lágbàáyé, ní àwọn ìgbà mìíràn kẹ̀, ńṣe ló máa ń ṣe mí bí pé èmi ni inú mi bàjẹ́ jù lọ.” Bí ẹnì kan kò bá nífẹ̀ẹ́ ẹni tó bí a ṣe nífẹ̀ẹ́ onítọ̀hún lè jẹ́ orísun hílàhílo, àìróorunsùn mọ́jú, àti ìsoríkọ́ pàápàá.
Bíbélì sọ nínú ìwé Òwe 13:12 pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” Bí ohun tí a ń fojú sọ́nà fún kò bá sì ṣẹlẹ̀ rárá, ó lè múni banú jẹ́! O lè rí i tí o ń ronú nípa ẹni yẹn ní gbogbo ìgbà, tí o ń hára gàgà láti ṣáà gbọ́ nǹkankan nípa rẹ̀. O lè gbèrò àwọn ọ̀nà tí wàá fi pe àfiyèsí rẹ̀ sí ara rẹ tàbí àwọn ìdí tí kò ṣe gúnmọ́ láti ṣá lè wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí o bá sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó lè ṣòro fún ọ láti hùwà bí o ti máa ń ṣe.
Ní pàtàkì, nǹkan máa ń dojú rú nígbà tí ẹni tí o nífẹ̀ẹ́ náà bá fún ọ ní àfiyèsí pàtàkì ní àwọn ìgbà kan, tí ó sì wá ń hùwà bí pé kò gba tìrẹ ní àwọn ìgbà mìíràn. Tí o bá wá rí i tí ó ń fún ẹlòmíràn ní àfiyèsí púpọ̀ tàbí tí ó ń ṣe inú rere àti ìwà rere, tí ó sì ń hùwà rere sí àwọn ẹlòmíràn, ó lè tanná ran owú lára rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ìwà ìkà ti ìhónú ń bẹ, àti àkúnya ìbínú pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ní lè dúró níwájú owú?”—Òwe 27:4.
Huda gbà bẹ́ẹ̀ ní sísọ pé: “Mo ní irú owú kíkorò bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ká ní n kò yí ìṣarasíhùwà mi padà ni, orí mi ì bá dà rú.” Ó tún lè yọrí sí kíkórìíra ara ẹni. Huda sọ pé: “Mo kábàámọ̀ pé mo jẹ́ kí ìfẹ́ ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ mi kó sí mi lórí, tí mo sì n fìyà jẹ ara mi.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn, ọ̀dọ́bìnrin kan lè lọ bá ọ̀dọ́kùnrin kan, kí ó sì sọ bí ìmọ̀lára rẹ̀ ṣe rí nípa rẹ̀ fún un, kì í ṣe gbogbo ọ̀dọ́bìnrin ló lè fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, a ó kà á sí ohun tí kò tọ́ tàbí tí ó tilẹ̀ ń yani lẹ́nu pé kí ọmọbìnrin gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. Nígbà náà, kí ni o lè ṣe bí ìfẹ́ ẹnì kan tí kò nífẹ̀ẹ́ rẹ bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bá kó sí ọ lórí?
Gbígbé Ìmọ̀lára Rẹ Yẹ̀ Wò
Kọ́kọ́ fara balẹ̀ gbìyànjú láti gbé ìmọ̀lára rẹ yẹ̀ wò, kí o sì mọ ohun tí o ń ṣe. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn.” (Òwe 28:26) Èé ṣe? Nítorí pé lọ́pọ̀ ìgbà ni ìpinnu wa máa ń tàn wá jẹ. (Jeremáyà 17:9) Àti pé ohun tó jọ ìfẹ́ lójú wa sábà máa ń jẹ́ ohun mìíràn. Huda sọ pé: “Mo nílò àfiyèsí àti ìfẹ́. Mo nílò ẹni tí yóò nífẹ̀ẹ́ mi, tí yóò sì bìkítà fún mi. Wọn kò fi ìfẹ́ hàn sí mi láti ìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé. Ìyẹn ní ipa lórí mi gan-an.” Bí o bá wá láti ìdílé tí kò ti sí ìfẹ́ tàbí tí wọ́n ti ń fìyà jẹni, ó ṣeé ṣe kí o máa yán hànhàn fún ìfẹ́ àti àfiyèsí. Ṣùgbọ́n nínífẹ̀ẹ́ takọtabo sí ẹnì kan ló ha gbọ́dọ̀ jẹ́ ojútùú rẹ̀ bí?
Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn tí inú wọn kì í dùn, tí wọ́n sì ń nímọ̀lára ìdáwà kì í sábà jẹ́ ojúlówó alábàágbéyàwó. Wọ́n ń kó wọnú ìdè ìgbéyàwó pẹ̀lú ìrètí láti rí ohun tí wọ́n lérò pé àwọn nílò gan-an. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ayọ̀ tòótọ́ ń wá láti inú fífúnni, kì í ṣe láti inú rírígbà. (Ìṣe 20:35) Obìnrin kan wà ní ìgbáradì dáadáa láti bójú tó ọ̀ràn ìgbéyàwó bí ó bá ní ìtẹ́lọ́rùn nípa ara rẹ̀, tí ‘kì í mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’—Fílípì 2:4.
Bí ara rẹ kò bá gba wíwà láìgbéyàwó mọ́, o lè tètè hùwà padà lọ́nà àṣejù sí àfiyèsí èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà kejì. Nígbà mìíràn, àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí ló máa ń ru ìfẹ́ sókè nínú ọ̀dọ́bìnrin kan láti nífẹ̀ẹ́ takọtabo. Àwọn àwùjọ ènìyàn kan máa ń tẹnu mọ́ kí ọmọbìnrin kan lọ sílé ọkọ gbàrà tí ó bá ti dàgbà tó láti relé ọkọ. Ìwé Women in the Middle East sọ pé: “Bí obìnrin kan bá ń sún mọ́ ọgbọ̀n ọdún tí ó sì jẹ́ àpọ́n síbẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò máa kọ àwọn ẹbí rẹ̀ lóminú gidigidi.” Nítorí pé ó kan iyì ẹbí, bàbá kan lè gbìyànjú láti fi àwọn ọmọbìnrin rẹ fún ọkọ bí ó ti wù kí wọ́n kéré tó.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìlànà Bíbélì gbọ́dọ̀ borí ti àṣà àdúgbò. Ìwé Mímọ́ sì rọ àwọn ọ̀dọ́ láti dúró di ìgbà tí wọ́n “bá ti ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe” kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Àmọ́, bí o bá ronú pé àwọn ọ̀rẹ́ tàbí òbí rẹ ń fìtínà rẹ jù láti ṣègbéyàwó ńkọ́? Bíbélì wí fún wa pé, ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì oníwà-bí-Ọlọ́run náà mú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ wá sábẹ́ ìbúra pé, ‘kí wọ́n má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú òun, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.’ (Orin Sólómọ́nì 2:7) Bóyá sísọ̀rọ̀ jáde lọ́nà tí ó ṣe ṣàkó bẹ́ẹ̀ yẹn lè mú ìyọrísí wá, ní pàtàkì bí àwọn òbí rẹ bá jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run.
Mímọ Ohun Tí Ń Ṣẹlẹ̀ Ní Gidi
Síbẹ̀, bó pẹ́, bó yá, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní gidi nípa ẹni tí o lérò pé o nífẹ̀ẹ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè má rọrùn, ó sì lè pa ìmọ̀lára rẹ lára. Ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́ ṣí wa létí pé: “Ra òtítọ́, má sì tà á.” (Òwe 23:23) Bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ìdí gidi kan ha wà tí ìfẹ́ rẹ̀ fi ń kó sí mi lórí? Báwo ni mo ṣe mọ ẹni yìí tó? Kí ni mo mọ̀ nípa ìrònú, ìmọ̀lára, èrò, ìwà, ìwà ọmọlúwàbí, agbára ìṣeǹkan, ẹ̀bùn àbínibí, àti irú ìgbésí ayé tí ó ń gbé?’
Ohun mìíràn tí o tún ní láti ronú lé ni bóyá ẹni náà fi hàn lọ́nàkọnà pé òun gba tìrẹ ní gidi. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ṣi inú rere tàbí ìwà bí ọ̀rẹ́ lásán túmọ̀ bí nǹkan mìíràn. Huda sọ pé: “Ọmọkùnrin náà ń gbìyànjú láti jẹ́ onínúrere ni, àmọ́ mo túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ sí pé ó gba tèmi ni nítorí ohun tí mo ń fẹ́ nìyẹn. Lẹ́yìn tí mo wá mọ̀ pé kò gba tèmi, mo nímọ̀lára àìjámọ́ǹkan. Mo nímọ̀lára pé n kò lẹ́tọ̀ọ́ sí àfiyèsí rẹ̀ àti pé nǹkan kan ń ṣe mí.”
Bóyá ìwọ pẹ̀lú ti ní irú ìmọ̀lára kan náà nítorí irú ohun kan náà tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ. Àmọ́, mọ̀ pé gbígbà tí ẹni yìí kò gba tìrẹ kò túmọ̀ sí pé ẹlòmíràn kò ní gba tìrẹ. Ó ṣe tán, òun nìkan kọ́ ni ọkùnrin tó wà láyé!
Bíborí Ìpalára Náà
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó lè pẹ́ díẹ̀ kí o tó borí ìpalára tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìmọ̀lára rẹ náà. Kí ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Ohun kan ni láti sọ̀rọ̀ síta kí o sì fi àṣírí han “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́” kan—Kristẹni kan tí ó dàgbà dénú tí yóò tẹ́tí sí ọ. (Òwe 17:17) Bóyá àgbàlagbà obìnrin kan wà tí o lè bá sọ̀rọ̀ nínú ìjọ. Àwọn Kristẹni òbí pẹ̀lú lè kó ipa pàtàkì nínú ṣíṣèrànwọ́ àti ìtìlẹ́yìn. Zeina rántí pé: “Obìnrin Kristẹni kan tí ó wà nínú ìjọ wa ṣàkíyèsí ìrora ọkàn mi, ó sì dàgbà dénú tó láti ràn mí lọ́wọ́. Ara tù mí nígbà tí mo wà pẹ̀lú rẹ̀, mo sì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Ó rọ̀ mí láti sọ fún àwọn òbí mi. Nítorí náà, mo sọ fún wọn, wọ́n lóye mi, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́.”
Rántí agbára àdúrà pẹ̀lú. (Sáàmù 55:22) Huda sọ pé: “Àwọn àdúrà tí mo gbà sí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn ìrora tí mo ń ní. Mo tún ka àwọn àpilẹ̀kọ tí ń ṣèrànlọ́wọ́ nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!” Ní àfikún, ó ṣe pàtàkì pé kí o má ya ara rẹ sọ́tọ̀. (Òwe 18:1) Máa bá àwọn ẹlòmíràn ṣe. Zeina rántí pé: “Ohun mìíràn tí ó ràn mí lọ́wọ́ ni pé, mo máa ń wá nǹkan ṣe, mo sì di aṣáájú ọ̀nà [ajíhìnrere alákòókò kíkún]. Mo tún mú kí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ mi pẹ̀lú àwọn obìnrin mìíràn nínú ìjọ pọ̀ sí i. Èyí ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.”
Bíbélì sọ nípa “ìgbà nínífẹ̀ẹ́,” bí àkókò sì ti ń lọ, o lè wá pàdé ẹni tí yóò nífẹ̀ẹ́ rẹ bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Oníwàásù 3:8) Jèhófà Ọlọ́run dá ìfẹ́-ọkàn láti gbádùn ìfẹ́ tí ó wà nínú ìgbéyàwó mọ́ ènìyàn, bó pẹ́, bó yá, ìwọ pẹ̀lú lè wá gbádùn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Atóbilọ́lá Olùṣẹ̀dá ṣe yìí. Ní báyìí ná, o kò ṣe máa gbádùn àwọn ọdún tí o fi wà ní àpọ́n, tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, ó wà “láìní àníyàn”? (1 Kọ́ríńtì 7:32-34) Bí ó ti wù kí ó rí, o lè ní ìdánilójú ìmúṣẹ ìlérí Bíbélì náà pé: “Ìwọ [Jèhófà] ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Sáàmù 145:16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ padà láti bo àṣírí àwọn tí ọ̀ràn kàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Nígbà mìíràn, a máa ń ṣi inú rere túmọ̀ bí nǹkan mìíràn