Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Mi fún Un?
“Mò ń fẹ́ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, Ta ló yẹ kó dẹnu fífẹ́ kọra wọn, ṣé ọkùnrin ni àbí obìnrin?”—Laura.a
ÀÌPẸ́ yìí lo ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé ọmọkùnrin yẹn tàbí kó ti ṣe díẹ̀ tó o ti mọ̀ ọ́n, ó sì wù ẹ́ pé kẹ́ ẹ jọ máa fẹ́ra yín. Ó dá ẹ lójú pé ohun tóun náà ń rò nìyẹn, àti pé ńṣe lẹ̀rù kàn ń bà á tàbí kó jẹ́ pé ojú ló ń tì í tí ò fi fẹ́ lahùn. O wá ń dà á rò pé bóyá ni ò ní dáa kó o kọ́kọ́ lọ sọ fún un.b
Kó o tó sọ fún un, jẹ́ ká ronú lórí bọ́rọ̀ náà ṣe máa rí lójú àwọn tó yí ẹ ká, ìyẹn àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà ládùúgbò. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ládùúgbò tìẹ, ojúṣe àwọn òbí ẹ ni láti wá ọkọ fún ẹ?c Lóòótọ́, o lè rò pé ìwọ fúnra ẹ ló yẹ kó o pinnu ohun tó o máa ṣe lórí ọ̀ràn ìfẹ́sọ́nà àti ìgbéyàwó o. Síbẹ̀, ó yẹ káwọn Kristẹni gbìyànjú láti yẹra fún ohun tó bá lè mú kí wọ́n kan déédéé fara gbún àwọn ẹlòmíràn. Ó sì tún yẹ kí wọ́n ronú lórí bí ọ̀rọ̀ náà á ṣe rí lójú àwọn ẹbí àti ará.
Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ló ti bójú mu fáwọn méjèèjì láti kọ́kọ́ jọ sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì ṣàdéhùn lórí ìfẹ́rasọ́nà kí wọ́n tó wá pinnu bóyá káwọn ṣègbéyàwó. Ṣé ó lòdì bó bá jẹ́ pé obìnrin ló kọ́kọ́ sọ fún ọkùnrin pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó yẹ ká ronú nípa bí ọ̀ràn náà á ṣe kan àwọn aráalé àtàwọn ará àdúgbò. Ṣé ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ á jọ wọ́n lójú tàbí kó bí wọn nínú?
Báwo ni Bíbélì tún ṣe là ẹ́ lọ́yẹ̀ lórí bóyá ó lòdì bó bá jẹ́ pé obìnrin ló kọ́kọ́ sọ fún ọkùnrin pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, obìnrin olùbẹ̀rù Ọlọ́run kan tó ń jẹ́ Rúùtù lọ bá ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bóásì sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó. Jèhófà Ọlọ́run sì jẹ́ kí ọ̀ràn náà bọ́ sí i! (Rúùtù 3:1-13) Rúùtù kì í ṣe ọmọdé ṣá o; opó ni, nítorí náà wọ́n lè gbé e níyàwó. Bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe eré oge ló fẹ́ kóun àti Bóásì jọ máa ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, kò rú èyíkéyìí nínú òfin Ọlọ́run lórí ìgbéyàwó.—Diutarónómì 25:5-10.
Bóyá ìwọ náà ti dàgbà tó ẹni tó tó ronú nípa ìgbéyàwó tọ́kàn rẹ sì wà lára ọ̀dọ́kùnrin kan báyìí. Síbẹ̀ náà, ó gbẹgẹ́ láti dédé sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ẹnì kan tí nǹkan tó ń ṣe ẹ́ ò ṣe, ó léwu. Ńṣe ló dà bíi kó o yọ ọkàn rẹ jáde kó o sì gbé e lé ẹlòmíì lọ́wọ́. Ṣé á mú u dání dáadáa àbí á kàn jù ú sílẹ̀? Ọ̀nà tó dáa jù tó o fi lè yẹra fún ìtìjú àti ìbànújẹ́ ọkàn tí ò yẹ kó bá ẹ ni pé kó o tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì.
Fi Ọgbọ́n Ṣe É
Ó rọrùn láti dẹni tó ń fọ̀rọ̀ ìfẹ́ lálàá ọ̀sán gangan. O tiẹ̀ lè máa fọkàn yàwòrán ọjọ́ ìgbéyàwó yín àti bẹ́ ẹ ó ṣe máa gbé pọ̀ bíi tọkọtaya. Àmọ́ ṣá, bó ti wù kí irú àwọn àlá ọ̀sán gangan báyìí dùn mọ́ ẹ tó, ìrònú asán ni wọ́n. Wọ́n lè mú káwọn nǹkan tó ga jù tí kò sì sí bọ́wọ́ ẹ ṣe lè tẹ̀ wọ́n máa wù ẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” (Òwe 13:12) Àwọn àlá ọ̀sán gangan yìí tún lè mú kó o máa ṣe nǹkan láìronú jinlẹ̀. Àmọ́, Òwe 14:15 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Jíjẹ́ afọgbọ́nhùwà túmọ̀ sí kéèyàn lè lo làákàyè kó sì lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Báwo lo ṣe lè wá fi ọgbọ́n hùwà nígbà tí ìfẹ́ ẹnì kan bá ti kó sí ẹ lórí?
Kọ́kọ́ gbìyànjú láti “fi ìmọ̀ hùwà.” (Òwe 13:16) Ńṣe ló dà bí ohun tí ọ̀dọ́bìnrin kan sọ pé, “ká sòótọ́, o ò lè nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan àyàfi tó o bá tó mọ̀ ọ́n.” Kó o tó jẹ́ kí ìfẹ́ ẹnì kan wọ̀ ẹ́ lọ́kàn, máa kíyè sí bó ṣe ń hùwà àti bó ṣe ń sọ̀rọ̀. Ṣàkíyèsí bó ṣe máa ń ṣe sáwọn èèyàn. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sọ pé: “Wádìí nípa ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ àti lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà tó mọ̀ ọ́n dáadáa.” Ǹjẹ́ àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ Kristẹni ń “ròyìn rẹ̀ dáadáa?” (Ìṣe 16:2) Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Isabel tún dábàá pé, “á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kẹ́ ẹ jọ máa jáde pẹ̀lú àwọn míì kó o sì gbìyànjú láti mọ àwọn ẹbí rẹ̀.” Wàá lè ṣàkíyèsí ẹ̀ dáadáa láìsì wàhálà púpọ̀ tẹ́ ẹ bá wà láàárín èrò.
Ó lè gba àkókò àti sùúrù kó o tó lè mọ ẹnì kan lọ́nà yìí. Ṣùgbọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí àwọn ìwà, ìṣesí àti àwọn ànímọ́ tá á jẹ́ kí èrò ọ̀kan rẹ lágbára sí i tàbí kó yí padà. Òwe 20:11 sọ pé: “Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin [tàbí ọ̀dọ́kùnrin] kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.” Bẹ́ẹ̀ ni, bó pẹ́ bó yá, àwọn ìṣe ẹ̀ á jẹ́ kó o mọ irú èèyàn tó jẹ́ gan-an.
Nítorí náà, bó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o lọ la ohun tó wà lọ́kàn ẹ mọ́lẹ̀ fún un, fi ọgbọ́n ki èrò yẹn wọ̀. Tó o bá yára jù tóun náà sì gbà, o lè wá rí i lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé kò yẹ lẹ́ni téèyàn ń bá ṣègbéyàwó.d Tó bá sì ti di pé ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ àárín yín tán, á dun ọmọkùnrin yẹn tó o bá wá sọ pé o ò ṣe mọ́, ó tiẹ̀ lè dùn ún kọjá bó ṣe yẹ.
Irú Ẹni Tó O Fẹ́ Kó Mọ̀ Ẹ́ Sí
Ó ṣeé ṣe kí ọmọkùnrin yìí ti máa ṣàkíyèsí ìwọ náà! Ṣé àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́ràn tó o ní ń yọ lára ẹ bó o ṣe ń ṣe? Isabel sọ pé: “Mo ti ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ni kì í múra dáadáa. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí ṣàkíyèsí ẹ, o ní láti máa múra lọ́nà tó dáa.” Láìka irú oge táráyé ń ṣe báyìí sí, bó o bá ń wọ “aṣọ tí ó wà létòletò . . . , pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú” wàá wu ọkùnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run.—1 Tímótì 2:9.
Bíbélì tún rọ àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni pé kí wọ́n “di àpẹẹrẹ . . . nínú ọ̀rọ̀ sísọ.” (1 Tímótì 4:12) Ọ̀nà tó ò ń gbà sọ̀rọ̀ ń sọ púpọ̀ nípa ẹ. Kí ló yẹ kó o ṣe nígbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀ fún ẹ láti bá ọmọkùnrin náà sọ̀rọ̀? Tójú bá ń tì í, ara rẹ̀ lè máà lélẹ̀, kó máa gbọ̀n. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Abbie sọ pé, “O lè kọ́kọ́ ti ọ̀rọ̀ sí i kó o sì rí bá á ṣe ṣe.”
Báwo ni wàá ṣe bẹ̀rẹ̀? Tó o bá kàn ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuruwu, ó lè rò pé tìẹ nìkan ló ń yé ẹ àti pé o ò láròjinlẹ̀. Bíbélì dá a lábàá pé ‘kí á má ṣe máa mójú tó ire ara wa nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara ẹni nìkan, ṣùgbọ́n ire tàwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ (Fílípì 2:4) Ó lè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ láìmikàn bó o bá wulẹ̀ béèrè àwọn ìbéèrè bíi mélòó kan nípa rẹ̀ àti àwọn nǹkan tó máa ń wù ú.
Kò ní dáa kó máa fi “ètè èké” tàbí “àgálámàṣà” pọ́n ọn lé lákòókò yẹn. (Sáàmù 120:2) Ọkùnrin kan tó ní ìfòyemọ̀ á mọ̀ pé ńṣe lò ń ga òun. Bákan náà, má tìtorí pé o rò pé irú àwọn ọ̀rọ̀ kan á wù ú gbọ́ kó o wá máa sọ irú ẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì pàápàá tẹ́ ẹ bá ti ń bọ́rọ̀ débi àwọn nǹkan tó túbọ̀ ṣe pàtàkì, tẹ́ ẹ sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí tẹ́nì kọ̀ọ̀kan yín á fi ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe. Máa hùwà bí Ọlọ́run ṣe dá ọ, ìyẹn ni pé kó o máa fi tinútinú ṣe nǹkan tó o bá ń ṣe, máa sọ òótọ́ kó o sì jẹ́ kó mọ bó o ṣe rí gan-an. Nígbà tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ lo máa lè mọ̀ bóyá bákan náà lẹ̀yin méjèèjì ṣe fẹ́ lo ìgbésí ayé yín.
Bí Ò Bá Fi Hàn Pé Òun Nífẹ̀ẹ́ Rẹ Ńkọ́?
Lẹ́yìn tó o ti ṣe àwọn ohun tó bójú mu tó yẹ kó o ṣe yìí, tó bá pàpà ṣẹlẹ̀ pé iná ìfẹ́ ò tíì ràn láàárín yín ńkọ́? Bóyá ọ̀sẹ̀ mélóò kan tàbí oṣù mélòó kan pàápàá ti kọjá lọ tí kò sì dà bíi pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ. Ṣé wàá kàn gbà pé ojú ló ń tì í ni? O lè bi ara rẹ léèrè pé: ‘Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ náà ló ń bẹ̀rù tó, ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣè tán láti gbéyàwó? Tí n bá tiẹ̀ fẹ́ ẹ, ṣé á lè léwájú gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé àbí á máa retí pé èmi ló yẹ kí n léwájú?’ (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ìbéèrè míì tó tún yẹ kó o ronú lé lórí ni pé, ‘Ṣé ojú ló ń tì í lóòótọ́ àbí kò nífẹ̀ẹ́ sí ká máa fẹ́ra wa ni?’ Ó lè ṣòro láti gbà pé kò nífẹ̀ẹ́ sí kẹ́ ẹ máa fẹ́ra yín ni. Ṣùgbọ́n tó o bá gba kámú, o ò ní kó ara ẹ sí ìtìjú tó lè bá ẹ tó o bá lọ dẹnu ìfẹ́ kọ ẹni tí ìfẹ́ rẹ kò sí lọ́kàn ẹ̀.
O lè rò pé o rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ìfẹ́ ẹ wà lọ́kàn rẹ̀. O lè rò pé ó kàn ń jáfara láti sọ ohun tó wà nínú ẹ̀ ni, àti pé tó o bá ṣe bí ẹni fún un níṣìírí, á lahùn. Ó lè rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ tó o bá sọ pé wàá lọ dẹnu kọ ọ́, o gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó léwu o. Ó yẹ kó o ronú dáadáa lórí ohun tó o máa sọ, àti ìgbà tó dáa láti sọ ọ́ pàápàá.
Bí àpẹẹrẹ, o lè pinnu láti sọ fún un pé wàá fẹ́ kẹ́ ẹ mọwọ́ ara yín dípò tí wàá kàn fi là á mọ́lẹ̀ pé “ìfẹ́ rẹ̀ wà lọ́kàn” rẹ. Lákòókò tí kò sí gìrìgìrì àti níbi tara ẹ̀yin méjèèjì bá ti balẹ̀, o kàn lè sọ fún un pé wàá fẹ́ kẹ́ ẹ mọra dáadáa. Má mikàn tó bá dà bíi pé ọ̀rọ̀ yẹn kọ́ ẹ lẹ́nu. Ìmọ̀lára tó o fi sọ ọ̀rọ̀ yẹn lè jẹ́ kó yé e kọjá ibi tó ò sọ ọ́ dé. Rántí pé nǹkan tó o tíì sọ ni pé ó wù ẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra yín sọ́nà, kì í ṣe pé o tíì dẹnu ìgbéyàwó kọ ọ́ o. Síbẹ̀síbẹ̀, ó lè yà á lẹ́nu láti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí náà fún un láyè láti ronú lórí nǹkan tó o bá a sọ.
Tó o bá ti mọ ọmọkùnrin yìí lóòótọ́, tó o sì ti rí i fúnra ẹ pé onínúure ni àti pé ó máa ń gba tẹlòmíràn rò, kò yẹ kẹ́rù máa bà ọ́ pé ó lè gbé ẹ ní ìdáàmù tàbí kó fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Ṣùgbọ́n kí ló yẹ kó o ṣe tó bá sọ pé kò sọ́nà níbẹ̀, àmọ́ tí kò sọ ọ́ lọ́nà tó lè fa ìbínú? Báwo ló sì ṣe yẹ kí ọmọkùnrin kan ṣe bí ọmọbìnrin kan bá dẹnu irú ẹ̀ kọ ọ́? Àpilẹkọ kan tó ń bọ̀ lọ́nà yóò dáhùn ìbéèrè yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́bìnrin ni àpilẹ̀kọ yìí ń bá wí ní tààràtà, àwọn ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ lè ran àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti àwọn míì tó ń ronú àtiní àfẹ́sọ́nà pẹ̀lú lọ́wọ́.
c Gbogbo àwọn tí òbí bá yan ọkọ tàbí ìyàwó fún kọ́ ni ìgbéyàwó wọn máa ń níṣòro o. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì, àwọn òbí ló ṣètò ìgbéyàwó Ísákì àti Rèbékà, Ísákì sì “kó sínú ìfẹ́ fún” un. (Jẹ́nẹ́sísì 24:67) Kí wá la rí kọ́ nínú ìyẹn? Má tètè máa rọ́ àwọn àṣà ìbílẹ̀ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí wọn ò bá ti ta ko òfin Ọlọ́run.—Ìṣe 5:29.
d Orí 28 sí 31 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá ẹnì kan dáa láti fi ṣe ọkọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Tó o bá kíyè sí bó ṣe ń hùwà, ó lè yí bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe rí lọ́kàn ẹ padà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Tí ìfẹ́ ẹnì kan bá wà lọ́kàn ẹ, fọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbàlagbà tí wọ́n mọ̀ ọ́n tí wọ́n sì ṣeé fọkàn tán