ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 7/8 ojú ìwé 9
  • Ǹjẹ́ Àlá Lásán Ni Ìlera Pípé Jẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Àlá Lásán Ni Ìlera Pípé Jẹ́?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbọ́ Lọ́wọ́ Àìsàn
  • Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Àìsàn Ò Ní Sí Mọ́!
    Jí!—2007
  • Ìlera fún Gbogbo Èèyàn—Láìpẹ́!
    Jí!—2001
  • Ohun Tí “Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà” Ṣèlérí
    Jí!—2005
  • Aráyé Ń Fẹ́ Ìlera Tó Jíire!
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 7/8 ojú ìwé 9

Ǹjẹ́ Àlá Lásán Ni Ìlera Pípé Jẹ́?

ǸJẸ́ o ti ṣàìsàn tó le gan-an rí tàbí kí o ṣe iṣẹ́ abẹ kan? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí o túbọ̀ mọyì ìwàláàyè nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n ipò tó wù kí ìlera rẹ wà, ǹjẹ́ o gbà gbọ́ pé ènìyàn lè ní ìlera pípé? Èyí lè dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe bí a bá tàrò bí àwọn àìsàn tí ń sọni di aláìlágbára bí jẹjẹrẹ tàbí àrùn ọkàn-àyà ṣe gbilẹ̀ tó. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ wa ń ṣàìsàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, ìlera pátápátá kì í ṣe àlá lásán kan.

A dá ènìyàn láti gbádùn ara dídá ṣáṣá, a kò dá a láti máa bá àìsàn àti ikú wọ ìdìmú. Nítorí náà, láti mú àìsàn àti ikú kúrò, Jèhófà pèsè ìpìlẹ̀ fún ìlera pípé àti ìyè ayérayé nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù. “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Àwọn ènìyàn tó bá ń gbé títí láé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí kò ní máa bá àìsàn àti ọjọ́ ogbó wọ ìdìmú. Nípa bẹ́ẹ̀, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àìsàn?

Bíbọ́ Lọ́wọ́ Àìsàn

Bí Jésù Kristi ṣe wo àwọn aláìsàn sàn jẹ́ àpẹẹrẹ kan. A sọ nípa irú ìwòsàn bẹ́ẹ̀ pé: “Àwọn afọ́jú ń padà ríran, àwọn arọ sì ń rìn káàkiri, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití sì ń gbọ́ràn, a sì ń gbé àwọn òkú dìde, a sì ń polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.” (Mátíù 11:3-5) Lóòótọ́, gbogbo àwọn aláìlera tó lọ sọ́dọ̀ Jésù “ni a mú lára dá ṣáṣá.” (Mátíù 14:36) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, “ogunlọ́gọ̀ náà . . . ṣe kàyéfì bí wọ́n ti rí tí àwọn odi ń sọ̀rọ̀, tí àwọn arọ sì ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran, wọ́n sì yin Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.”—Mátíù 15:31.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnikẹ́ni kò lè ṣe ìwòsàn bí ìwọ̀nyí lónìí, a lè ní ìdánilójú pé lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, a óò gbé aráyé sí ipò ìjẹ́pípé, a óò wò wọ́n sàn lọ́wọ́ gbogbo àrùn ọpọlọ àti ti ara. A ṣàkọsílẹ̀ ìlérí Ọlọ́run nínú Ìṣípayá 21:3, 4 pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Finú wòye bí ayé kan tí a kò ti nílò ilé iṣẹ́ apòògùn tàbí àwọn ilé ìwòsàn, iṣẹ́ abẹ, tàbí ìtọ́jú ìṣègùn kankan yóò ṣe rí! Síwájú sí i, nínú Párádísè tí a mú bọ̀ sípò, ìsoríkọ́ àti gbogbo àrùn ọpọlọ yóò di nǹkan àtijọ́. Ìgbésí ayé yóò jẹ́ aláyọ̀; ìmọ̀lára ayọ̀ yóò sì wà títí. Dájúdájú, agbára Ọlọ́run, tí kò láàlà, yóò mú àwọn ọ̀nà ìmúbọ̀sípò inú ara ṣiṣẹ́, àǹfààní ìràpadà yóò sì mú àwọn ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá. “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

Ẹ wo irú ìrètí àgbàyanu tí ó jẹ́—láti gbádùn ìlera pípé ti ara àti ti ẹ̀mí lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run! Máa fojú sọ́nà fún àwọn ìbùkún ayé tuntun ti Ọlọ́run, bí o ti ń gbé ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì gbígbámúṣé nísinsìnyí. Kí Jèhófà ‘fi ohun rere tẹ́ ọ lọ́rùn ní ìgbà ayé rẹ, kí ìgbà èwe rẹ sì máa sọ ara rẹ̀ dọ̀tun gẹ́gẹ́ bí ti idì’!—Sáàmù 103:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́