ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 8/8 ojú ìwé 25-28
  • Ibà Dengue—Ibà Tí Ń Ṣe Ẹni Tí Ẹ̀fọn Bá Jẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibà Dengue—Ibà Tí Ń Ṣe Ẹni Tí Ẹ̀fọn Bá Jẹ
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ibà Dengue?
  • “Ìdá Méjì Nínú Márùn-ún Aráyé” Wà Nínú Ewu
  • Àwọn Ewu Ibà DHF
  • Dídáàbòbo Ìdílé Rẹ
  • Àwọn Ìgbésẹ̀ Aṣèdíwọ́ fún Àrùn
  • Kí Ló Dé Tí Wọ́n Tún Fi Ń Padà Wá?
    Jí!—2003
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
  • Àwọn Àrùn Tí Kòkòrò Ń gbé Kiri Ìṣòro Tí Ń Gbilẹ̀
    Jí!—2003
  • Bí Àìsàn Ibà Bá Ń ṣe Ọmọ Rẹ
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 8/8 ojú ìwé 25-28

Ibà Dengue—Ibà Tí Ń Ṣe Ẹni Tí Ẹ̀fọn Bá Jẹ

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Philippines

Ẹ̀FỌN kan bà lé ọwọ́ ọmọdébìnrin náà láìmọ̀. Ẹ̀fọn náà yára ki ẹnu bọ ara ọmọ náà, ó sì ń fa ẹ̀jẹ̀ láti inú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kò pẹ́ ni ìyá ọmọ náà bojú wo ọmọ rẹ̀, ó sì rí ẹ̀fọn náà. Lọ́gán, ó ti fò lọ. Ṣé ibi tí ó parí sí nìyẹn? Kò dájú. Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀fọn náà ti lọ, àmọ́ ó ti pọ àwọn kòkòrò burúkú kan tí ó lè kó àrùn bá ọmọ náà sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ níwọ̀nba àkókò tí ó fi tẹnu bọ̀ ọ́ lára yẹn.

Láàárín ọ̀sẹ̀ méjì, òtútù, ẹ̀fọ́rí, ẹ̀yìn ojú ríro, oríkèé ríro lárojù, àti akọ ibà bẹ̀rẹ̀ sí bá ọmọ náà fínra. Orí àìsàn náà ló wà tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lé ròrò, tí ó sì rẹ̀ ẹ́ tọwọ́tẹsẹ̀. Ibà dengue, tí ó máa ń ṣe ẹni tí ẹ̀fọn bá jẹ, ti kì í mọ́lẹ̀.

Síbẹ̀síbẹ̀, àrùn náà lè yí sí oríṣi tí ó túbọ̀ burú, tí ń jẹ́ ibà dengue ṣẹ̀jẹ̀ṣẹ̀jẹ̀ (DHF), pàápàá bí ibà dengue bá ti ṣe ọmọ náà rí. Pẹ̀lú ìyẹn, àwọn òpójẹ̀ wẹ́wẹ́ yóò máa jò, èyí yóò sì fa kí àwọ ara máa ṣẹ̀jẹ̀. Ó lè máa ṣẹ̀jẹ̀ sínú. Bí wọn kò bá tọ́jú ẹni tí àìsàn náà ń ṣe dáadáa, ó lè má lè gbéra mọ́ páàpáà, kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ má sì lọ kiri ara mọ́, ó sì lè tètè kú.

Kí tilẹ̀ ni ibà dengue gan-an? Ǹjẹ́ ó lè ṣe ọ́? Báwo ni o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí a wò ó láwòfín.

Kí Ni Ibà Dengue?

Ibà dengue, tí a tún ń pè ní ibà wórawóra, wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àìsàn tí ó lè ṣeni bí ẹ̀fọn bá jẹni. Ní gidi, fáírọ́ọ̀sì kan ní ń fa àìsàn náà. Ẹ̀fọn tí ó ní àrùn náà lára (ìyẹn ni pé, ẹ̀fọn tí ó ti jẹ ẹnì kan tí ó ní àrùn náà lára) ń ní fáírọ́ọ̀sì náà nínú ẹṣẹ́ tí itọ́ rẹ̀ ti ń wá. Nígbà tí ó bá ń fa ẹ̀jẹ̀ ènìyàn, ó máa ń pọ fáírọ́ọ̀sì náà sára ènìyàn.

Mẹ́rin ni oríṣi fáírọ́ọ̀sì ibà dengue tó wà. Pé oríṣi kan ṣeni kò túmọ̀ sí pé a ti bọ́ lọ́wọ́ oríṣi mẹ́ta yòókù. Lẹ́yìn tí oríṣi kan bá ṣe ẹnì kan, bí ẹ̀fọn tí ó ní oríṣi mìíràn lára bá tún jẹ ẹni náà, ó lè yọrí sí ibà DHF.

“Ìdá Méjì Nínú Márùn-ún Aráyé” Wà Nínú Ewu

Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ti sọ, ibà dengue ń wu bílíọ̀nù 2.5 ènìyàn, “ìdá méjì nínú márùn-ún aráyé” léwu. Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Ó lé ní 100 orílẹ̀-èdè ilẹ̀ olóoru àti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká tí wọ́n ti ròyìn pé ibà dengue ń ṣe àwọn ènìyàn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ni a sì ti ròyìn pé ó ń bá fínra lọ́dọọdún, tí ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ó ń ṣe sì jẹ́ ọmọdé.”

A kò mọ ìgbà tí ibà dengue kọ́kọ́ bẹ́ sílẹ̀ dájú. Ó lè jẹ́ ibà dengue ni ìròyìn kan tí ó dá lórí “ibà orúnkún” ní Cairo ní 1779 ń tọ́ka sí. Láti ìgbà yẹn ni a ti ń gbọ́ nípa ibà dengue káàkiri ayé. Pàápàá jù lọ láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì ni ibà dengue ti ní ipa pàtàkì kan lórí ìlera ènìyàn, bẹ̀rẹ̀ láti Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà. Onírúurú fáírọ́ọ̀sì náà bẹ̀rẹ̀ sí káàkiri, èyí sì ń yọrí sí oríṣi ibà ṣẹ̀jẹ̀ṣẹ̀jẹ̀ tí ó túbọ̀ burú náà. Ìwé kan tí àjọ WHO ṣe sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ tí ibà ṣẹ̀jẹ̀ṣẹ̀jẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní Éṣíà, ní gidi jẹ́, ní Manila ní 1954.” Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, pàápàá jù lọ, Thailand, Vietnam, Malaysia, àti àwọn àgbègbè tí ó sún mọ́ wọn. Àkọ́kọ́ tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà yìí pa iye ènìyàn tí ó jẹ́ ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún sí ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ibẹ̀, àmọ́ bí a ti ń mọ ohun púpọ̀ sí i nípa àrùn náà, iye náà ń dín kù.

Láti àwọn ọdún 1960, àìjáramọ́ àwọn ètò àtimú ẹ̀fọn tí ń gbé fáírọ́ọ̀sì náà kiri kúrò ti dá kún pípọ̀ tí ibà dengue ń pọ̀ sí i. Bí ibà dengue ti tàn kálẹ̀ ni ibà DHF ti tàn kálẹ̀. Orílẹ̀-èdè 9 péré ni ó ti jà ṣáájú 1970, àmọ́ nígbà tí ó fi di 1995, ó ti di orílẹ̀-èdè 41. Àjọ WHO fojú díwọ̀n pé, lọ́dọọdún, àwọn 500,000 tí ibà DHF ń ṣe ní a ní láti dá dúró sí ilé ìwòsàn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò fi bẹ́ẹ̀ mọ àrùn náà ní àwọn ilẹ̀ tí kì í ṣe olóoru, nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, àwọn tí wọ́n rìnrìn àjò lọ sí àwọn àgbègbè tí wọ́n ti lè kó àrùn náà, ti kó o, wọ́n sì ti gbé e wá sí ìlú wọn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ọdún 1996 ń parí lọ, ìwé ìròyìn náà, The New York Times, sọ nípa àwọn tí ibà dengue ṣe ní United States—ní Massachusetts, New York, Oregon, àti Texas.

Àwọn Ewu Ibà DHF

Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, ibà DHF jẹ́ oríṣi ibà dengue tí ń wu ìwàláàyè léwu. Ọ̀kan lára àwọn ewu ibà DHF ni pé ó máa ń tan àwọn ènìyàn láti ronú pé kò fi bẹ́ẹ̀ le. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń ṣì í pè ní àrùn gágá. Bí ó ti wù kí ó rí, sísún ohun tí a óò ṣe nípa rẹ̀ síwájú lè mú kí àìsàn náà le sí i dé ibi tí ìwọ̀n èròjà platelet inú ẹ̀jẹ̀ yóò fi tètè dín kù, yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀jẹ̀ (sínú tàbí nídìí eyín, imú, tàbí ní awọ ara), ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ yóò sì lọ sílẹ̀. Aláìsàn náà lè wó kalẹ̀. Ìgbà tí ìdílé rẹ̀ bá fi máa mọ̀ pé ohun tí ń ṣe é le gan-an, yóò ti máa di pé kò lè gbéra mọ́ páàpáà. Wọn yóò sáré gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Nígbà tí wọ́n bá fi dé ọ̀hún, àwọn dókítà yóò rí i pé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kò lọ káàkiri ara mọ́. Nítorí bí ọ̀ràn rẹ̀ ti le gan-an, wọ́n yóò ṣètò láti fa àfirọ́pò ohun olómi sí i lára.

Dídáàbòbo Ìdílé Rẹ

Kí ni a lè ṣe láti dín àwọn aburú tí àrùn yìí ń ṣe kù? Bí ìdílé rẹ bá ń gbé ibi tí ibà dengue ti gbalẹ̀ kan, tí akọ ibà sì ṣe ẹnì kan nínú ìdílé rẹ ju ọjọ́ kan lọ, ìdílé yín gbọ́dọ̀ hùwà ọlọgbọ́n nípa lílọ rí dókítà. Èyí ṣe pàtàkì gan-an bí ẹni tí ara rẹ̀ kò yá náà bá ń rí àwọn àmì mìíràn tí ń bá ibà dengue rìn bí, ará lílé ròrò tàbí iṣan àti oríkèé ríro tàbí ẹ̀yìn ojú ríro.

Dókítà lè ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ẹni náà. Ó lè jẹ́ ìtọ́jú ráńpẹ́ ni ẹni tí ibà dengue tí kò mú ìṣẹ̀jẹ̀ dání ń ṣe nílò. Àmọ́ bí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ibà DHF ni, dókítà lè dámọ̀ràn bíbaralẹ̀ lo ohun olómi. Àwọn àpòpọ̀ àtẹnujẹ fún ìdápadà omi ara, bí àwọn tí a ń lò fún àrùn ìgbẹ́ gbuuru, tàbí, bí ọ̀ràn náà bá le gan-an, fífa àfirọ́pò àpòpọ̀ olómi ti Ringer síni lára, àpòpọ̀ oníyọ̀ tàbí àwọn mìíràn, wà lára ìwọ̀nyí. Bí kò bá lè gbéra páàpáà, dókítà lè júwe àwọn egbòogi kan tí yóò jẹ́ kí agbára ìgbékiri ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lè ròkè, kí ìwọ̀n èròjà platelet inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lè padà sípò.

Bí ó bá ń ṣẹ̀jẹ̀ gan-an, àwọn dókítà lè ní ìtẹ̀sí láti dámọ̀ràn ìfàjẹ̀sínilára. Àwọn kan lè yára dámọ̀ràn èyí láìronú nípa ohun mìíràn tí wọ́n lè ṣe. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, yàtọ̀ sí pé èyí kì í sábà ṣe ohun tí ó pọndandan, ó lòdì sí òfin Ọlọ́run. (Ìṣe 15:29) Ìrírí ti fi hàn pé ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtọ́jú ni láti lo àwọn ohun olómi dáradára láti ìgbà tí àìsàn náà ti bẹ̀rẹ̀. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ aláìsàn àti dókítà nínú ọ̀ràn yìí lè ṣèrànwọ́ láti mú ìforígbárí nípa ọ̀ràn ìfàjẹ̀sínilára kúrò. Èyí wá tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì gbígbégbèésẹ̀ láìjáfara nígbà tí ẹnì kan bá fura pé ibà DHF ń ṣe òun.—Wo àpótí náà, “Àmì Wo Ni A Máa Ń Rí?”

Àwọn Ìgbésẹ̀ Aṣèdíwọ́ fún Àrùn

Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀fọn tí ń gbé ibà dengue kiri ni ẹ̀fọn Aedes aegypti. Irú ọ̀wọ́ yìí wọ́pọ̀ ní àwọn ilẹ̀ olóoru àti àwọn ilẹ̀ tí ó yí wọn ká lágbàáyé. (Wo àwòrán ilẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú àpilẹ̀kọ yìí.) Àwọn ẹ̀fọn Aedes aegypti máa ń di púpọ̀ ní àwọn àgbègbè tí ènìyàn ti pọ̀ gan-an. Pípa àwọn ẹ̀fọn náà ni ọ̀kan lára ọ̀nà ṣíṣekókó tí a lè fi dín àrùn náà kù.

Pípa ẹ̀fọn jákèjádò ayé kò rọrùn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ohun kan wà tí o lè ṣe láti dín ewu rẹ̀ kù láyìíká ilé rẹ. Inú omi ni abo ẹ̀fọn máa ń yé ẹyin sí. Tanwíjí rẹ̀ lè dàgbà nínú ohunkóhun tí ó bá lè gba omi dúró fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan, bí táyà tí a sọ síbì kan, agolo, ìgò, tàbí èèpo àgbọn. Kíkó irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ kúrò nílẹ̀ kò ní jẹ́ kí àwọn ẹ̀fọn ríbi pamọ. Ní àfikún, a dámọ̀ràn pé kí o máa dojú korobá tàbí ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ délẹ̀. Gbígbá omi tí ó dá rogún kúrò nínú gọ́tà yóò ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Ó dún mọ́ni pé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ìkẹ́kọ̀ọ́ 1997 sí 1998, ẹ̀ka ètò ìlera ní ilẹ̀ Philippines ní kí a má fi ìkòkò gbin òdòdó mọ́.

Bí ibà dengue bá ń ṣe ẹnì kan nínú ìdílé, ẹ gbégbèésẹ̀ tí kò ní jẹ́ kí àwọn ẹ̀fọn mìíràn, tí ó lè pọ àrùn náà sára ẹlòmíràn, tún jẹ ẹ́. Ilé tí wọ́n fi nẹ́ẹ̀tì sí dáradára tàbí tí wọ́n ti ń lo ẹ̀rọ amúlétutù lè jẹ́ ààbò.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára ńkọ́? Kò sí abẹ́rẹ́ àjẹsára fún un ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lórí ṣíṣe ọ̀kan, àmọ́ ohun tí ń ṣèdíwọ́ fún èyí ni pé ààbò pátápátá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀ yóò béèrè pé kí a gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó wà fún oríṣi ibà dengue mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ọ̀kan péré wulẹ̀ lè dá kún ewu níní ibà DHF ni. Àwọn olùwádìí nírètí pé àwọn lè ṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára kan tí yóò wúlò jáde ní ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá sí àsìkò yìí.

Àwọn olùwádìí kan ti ń gbìyànjú ọ̀nà mìíràn tí wọn óò gbé e gbà. Nípa yíyí apilẹ̀ àbùdá dà, wọ́n ronú pé àwọn lè ṣèdíwọ́ fún fáírọ́ọ̀sì ibà dengue kí ó má di rẹpẹtẹ nínú itọ́ ẹ̀fọn. Bí èyí bá ṣiṣẹ́ bí wọ́n ṣe wéwèé rẹ̀, irú àwọn ẹ̀fọn tí a yí apilẹ̀ àbùdá wọn dà bẹ́ẹ̀ yóò tàtaré ìgbógunti ibà dengue sórí àwọn ọmọ wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ díẹ̀, bí èyí yóò ṣe yọrí sí rere tó ni a ṣì ń wò.

Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, kò jọ pé ó rọrùn láti fòpin sí ibà dengue pátápátá. Àmọ́ gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ tí ó bọ́gbọ́n mu lè ran ìwọ àti àwọn tí o fẹ́ràn lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ìṣòro tí ń fi ẹ̀mí ẹni sínú ewu tí ibà dengue—ibà tí ń ṣe ẹni tí ẹ̀fọn bá jẹ—ń fà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]

Àmì Wo Ni A Máa Ń Rí?

Àwọn àmì ibà dengue àti ibà dengue ṣẹ̀jẹ̀ṣẹ̀jẹ̀ (DHF)

• Akọ ibà lójijì

• Ẹ̀fọ́rí tí ó burú jáìa

• Ẹ̀yìn ojú ríro

• Oríkèé àti iṣan ríro

• Ẹṣẹ́ lymph wíwú

• Ìléròrò

• Àìlókun-nínú

Àwọn àmì tí ó wọ́pọ̀ nínú ibà DHF

• Ṣíṣubú lójijì

• Awọ ara ṣíṣẹ̀jẹ̀

• Ìṣẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ara

• Òtútù, awọ ara títutù nini

• Àìbalẹ̀ ara

• Àìlègbéra páàpáà àti lílùkìkì ọkàn-àyà lọ́nà tí kò lera (àmì àìlègbéra páàpáà tí ibà dengue fà)

Má ṣe fi lílọ rí dókítà falẹ̀ bí o bá ń rí àwọn àmì wọ̀nyí. Àwọn ọmọdé ni wọ́n wà nínú ewu jù

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera sọ pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún egbòogi aspirin nítorí pé ó lè mú ìṣẹ̀jẹ̀ burú sí i.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]

Ìsọfúnni fún Àwọn Arìnrìn-Àjò

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ sí àwọn àgbègbè ilẹ̀ olóoru máa ń kó ibà dengue, àmọ́ ibà dengue ṣẹ̀jẹ̀ṣẹ̀jẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ sí nítorí èyí tí ó burú gan-an yìí sábà máa ń ṣe ènìyàn lẹ́yìn tí ibà dengue bá mú un lẹ́ẹ̀kejì. Àwọn àbá díẹ̀ tí ó ṣàǹfààní fún ààbò àwọn arìnrìn-àjò nìwọ̀nyí:

• Máa wọ ẹ̀wù alápá gígùn àti ṣòkòtò gígùn

• Máa fi oògùn tí ń lé ẹ̀fọn para

• Má ṣe lọ sí àwọn àgbègbè tí àwọn ènìyàn ti pọ̀ gan-an

• Dé sí ilé tí o lè ti fèrèsé rẹ̀, kí àwọn ẹ̀fọn má bàa wọlé

• Bí ibà bá ṣe ọ́ nígbà tí o padà sí ìlú rẹ, sọ ibi tí o rìnrìn àjò lọ fún dókítà

[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àgbègbè tí a ti ń rí ẹ̀fọn “Aedes aegypti,” ẹ̀fọn tí ń gbé ibà “dengue” kiri

Àwọn àgbègbè tí ibà “dengue” ti jà láìpẹ́ yìí

Àwọn àgbègbè tí wọ́n wà nínú ewu àjàkálẹ̀ ibà “dengue”

[Àwọn Credit Line]

Orísun ìsọfúnni: Centers for Disease Control and Prevention, 1997

© Dr. Leonard E. Munstermann/Fran Heyl Associates, NYC

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn ibi tí ẹ̀fọn ti lè pamọ ni (1) inú táyà tí a gbé síbì kan, (2) gọ́tà tí omi òjò ń gbà, (3) ìkòkò tí a gbin òdòdó sí, (4) korobá tàbí àwọn ohun ìbomi mìíràn, (5) àwọn agolo tí a jù nù, (6) àwọn àgbá

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

© Dr. Leonard E. Munstermann/Fran Heyl Associates, NYC

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́