Jẹ́ Amẹ̀tọ́mẹ̀yẹ Bí O Bá Ń Yan Eré Ìnàjú
Ipa wo ni eré ìnàjú ń ní lórí àwọn ọmọdé? Ó dá Alvin Poussaint, onímọ̀ ẹ̀kọ́ tó tún jẹ́ dókítà, tó ti wà pẹ̀lú àwọn ọmọdé fún nǹkan bí 30 ọdún, lójú pé, wíwo àwọn fíìmù tó ní ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá nínú ń kọ́ àwọn èwe pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ bẹ́tọ̀ọ́ mu. Ó tún mẹ́nu ba ewu mìíràn pé: “Mo ti rí àwọn ọmọdé tí wọ́n ti ibi irú ìran bẹ́ẹ̀ dé, tí wọ́n wá di ẹni tí ẹ̀rù ń bà—tàbí oníjàgídíjàgan pẹrẹwu. Mo ti rí àwọn mìíràn tí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí hùwà ọmọdé bí rírọ̀mọ́ni tàbí mímùka tàbí títọ̀sílé.” Gẹ́gẹ́ bí dókítà yìí ṣe sọ, àwọn ògbógi ti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tó lè fa irú ìwà wọ̀nyí—lára wọn ni fífìyàjẹni tàbí bíbáni-ṣèṣekúṣe tàbí gbígbé ní àgbègbè tí ogun ti ń jà. Ó ṣàlàyé pé: “Kò sí ẹni tí yóò mọ̀ọ́mọ̀ fi ọmọ kan sí irú ipò wọ̀nyí nínú wa, síbẹ̀ a kò gbégbèésẹ̀ láti dí wọn lọ́wọ́ wíwo àwọn ìran tí ń fi àwọn ohun tí kò ní wù wá kí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn wọ̀nyí hàn lórí ẹ̀rọ.”
Àwọn Kristẹni ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti máa ṣe yíyàn, kí wọ́n sì rí i dájú pé eré ìnàjú tí àwọn ń yàn kò ṣẹ̀ sí àwọn ìlànà Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 11:5 sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò . . . Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.”—Kólósè 3:5, 8.
Nítorí náà, ó yẹ kí àwọn òbí ṣọ́ra, kí wọ́n rí sí i pé eré ìnàjú tí wọ́n ń yàn fún àwọn ọmọ wọn—àti fún àwọn alára—kò gbé “àwọn iṣẹ́ ti ara” lárugẹ. (Gálátíà 5:19-21) Ó yẹ kí wọ́n jẹ́ amẹ̀tọ́mẹ̀yẹ, kí wọ́n máa ṣàgbéyẹ̀wò bí eré ìnàjú tí wọ́n yàn ṣe níye lórí tó àti bí ó ṣe pọ̀ tó.—Éfésù 5:15-17.