Nígbà Tí Ìrètí àti Ìfẹ́ Bá Pòórá
ỌMỌBÌNRIN ọlọ́dún 17 kan, tó jẹ́ ará Kánádà, ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tó mú kí ó fẹ́ kú. Lára àwọn ohun tó kọ ni: ‘Ìmọ̀lára ìnìkanwà àti ìbẹ̀rù nípa ọjọ́ ọ̀la mi; ìmọ̀lára àìkúnjú òṣùwọ̀n tó àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi; ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé; bíba ìpele ozone jẹ́; mo burẹ́wà gan-an, nítorí náà, n kò ní rọ́kọ fẹ́, n ó sì máa dá wà; n kò rò pé ohun kan wà tí mo lè torí rẹ̀ máa wà láàyè, nítorí náà, kò sí ìdí láti máa wá a kiri; ikú mi yóò gba gbogbo ẹni tó kù lọ́wọ́ wàhálà; ẹnikẹ́ni kò ní pa mí lára mọ́ láé.’
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ìwọ̀nyí jẹ́ ìdí tí àwọn ọ̀dọ́ fi ń pa ara wọn? Ní Kánádà, “yàtọ̀ sí àwọn tí ìjàǹbá ohun ìrìnnà ń pa, àwọn tí ń pa ara wọn ló tún wọ́ pọ̀ jù lọ láàárín wọn.”—The Globe and Mail.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Riaz Hassan, láti Yunifásítì Flinders ní Gúúsù Ọsirélíà, kọ ọ́ nínú ìwé ìròyìn ìwádìí rẹ̀ tó pè ní “Ìwàláàyè Tí A Ké Kúrú: Ọ̀ràn Nípa Bí Àwọn Èwe Ṣe Ń Pa Ara Wọn” pé: “Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ipò inú àwùjọ ló nípa lórí ọ̀ràn náà, tó sì jọ pé ó ti nípa gidigidi lórí bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń pa ara wọn. Àwọn ọ̀dọ́ tí kò ríṣẹ́ ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ; àwọn ìyípadà nínú ìdílé ará Ọsirélíà; lílo oògùn àti ìjoògùnyó tí ń pọ̀ sí i; ìwà ipá àwọn ọ̀dọ́ tí ń pọ̀ sí i; ìlera ọpọlọ; àti àìdọ́gba tí ń pọ̀ sí i láàárín ‘òmìnira àfẹnusọ’ àti ìdáǹkanṣe tí a fi ń dánra wò.” Ìròyìn ìwádìí náà sọ síwájú pé, àbájáde ọ̀pọ̀ ìwádìí ti fi ìmọ̀lára àìnírètí nípa ọjọ́ ọ̀la hàn, ó sì tọ́ka sí i pé, “ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń bẹ̀rù, ojora sì ń mú wọn nípa ọjọ́ ọ̀la wọn àti ti ayé lápapọ̀. Ohun tí wọ́n ń rí ni ayé kan tí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan sọ dahoro, tí gbogbo àyíká rẹ̀ sì bà jẹ́, àwùjọ kan tí ìwà ọmọlúwàbí kò sí, tí ìmọ̀ ẹ̀rọ sì ti pọ̀ kọjá agbára ènìyàn, tí àìríṣẹ́ṣe sì gbalẹ̀ kan.”
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìíkiri èrò ara ìlú kan tì a ṣe láàárín àwọn ọlọ́dún 16 sí 24 ṣe fi hàn, àlàfo tí ń pọ̀ sí i láàárín ọlọ́rọ̀ àti tálákà, iye àwọn òbí anìkàntọ́mọ tí ń pọ̀ sí i, ìlò ìbọn tí ń gbilẹ̀ sí i, bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, àti “àìnígbẹkẹ̀lé nínú ọjọ́ ọ̀la lápapọ̀,” jẹ́ àfikún ìdí tí àwọn ènìyàn fi ń pa ara wọn.
Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, ní United States, “ó ṣeé ṣe kí bí ìbọn ṣe wà rẹpẹtẹ jẹ́ ìdí pàtàkì jù lọ [tí àwọn èwe fi ń pa ara wọn]. Ìwádìí kan, tó fi àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n fọwọ́ ara wọn pa ara wọn, láìsí ẹ̀rí pé wọ́n ní àrùn ọpọlọ kankan, wé àwọn ọmọ tí kò pa ara wọn, rí ìyàtọ̀ kan ṣoṣo: ìbọn kan wà ní kíkì nínú ilé. Ká gbàgbé èrò pé ìbọn kì í dá ènìyàn pa.” Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló sì ní ìbọn kíkì nínú ilé!
Ìbẹ̀rù tó wà àti àwùjọ wa tí kì í bìkítà lè ti àwọn ọ̀dọ́ tó bá fẹ́ sí ìhà pípa ara wọn. Ronú lórí èyí: Ìwọ̀n ìwà ipá tí a hù sí àwọn ọmọ ọlọ́dún 12 sí 19 lé ní ìlọ́po méjì èyí tí a hù sí àwọn ènìyàn lápapọ̀. Bí ìwé ìròyìn Maclean’s ṣe sọ, àwọn ìwádìí fi hàn pé, “àwọn ọ̀dọ́bìnrin ọlọ́dún 14 sí 24 ló ṣeé ṣe kí a kọ lù jù. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn obìnrin ní ń gbéjà kò wọ́n, tí wọ́n sì ń pa wọ́n jù.” Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Ìwọ̀nyí àti àwọn ìbẹ̀rù mìíràn “ń dín ìgbẹ́kẹ̀lé àti èrò àìséwu tí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí ní kù.” Nínú ìwádìí kan, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdámẹ́ta àwọn tí wọ́n yí ìfipábáni-lòpọ̀ dá, tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, tí wọ́n ti ronú láti pa ara wọn.
Ìròyìn kan láti New Zealand tún gbé apá mìíràn nínú ìdí tí àwọn ọ̀dọ́ fi ń pa ara wọn jáde, nígbà tí ó wí pé: “Ìlànà ìwà híhù onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì tí ń gbilẹ̀ lágbàáyé, èyí tó ń fi bí ẹnì kan ṣe lọ́rọ̀ tó, bí ojú rẹ̀ ṣe ń dán tó, àti agbára tó ní, díwọ̀n àṣeyọrí rẹ̀ nínú ìgbésí ayé, ń mú kí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ka ara wọn sí aláìníláárí àti ẹni tí àwùjọ ti ta nù.” Láfikún sí i, ìwé ìròyìn The Futurist sọ pé: “[Àwọn èwe] ní ìfẹ́ àdánidá sí títẹ́ àìní ẹni lọ́rùn lójú ẹsẹ̀, wọ́n ń fẹ́ gbogbo nǹkan, wọ́n sì ń fẹ́ ẹ kíákíá. Àwọn ètò tí wọ́n yàn láàyò jù lórí tẹlifíṣọ̀n ni àwọn eré olórin nípa àjọṣe ẹ̀dá. Wọ́n ń fẹ́ kí àyíká wọn kún fún irú àwọn ènìyàn tí ojú wọn ń dán bákan náà, tí ń wọ aṣọ tó lòde, tó ní owó púpọ̀ àti iyì, tí kò sì ní láti ṣiṣẹ́ àṣekára lọ títí.” Ó jọ pé bí irú ìrètí tí kò bọ́gbọ́n mu, tí ọwọ́ kò sì lè tẹ̀ bẹ́ẹ̀, ṣe pọ̀ tó lásán ń fa ìjákulẹ̀ dé àyè kan, ó sì lè yọrí sí pípa ara ẹni.
Ànímọ́ Tí Ń Gbẹ̀mí Là Kẹ̀?
Shakespeare kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ ń tuni nínú bí oòrùn tó ràn lẹ́yìn òjò.” Bíbélì wí pé: “Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (1 Kọ́ríńtì 13:8) Ojútùú pàtàkì kan fún ìtẹ̀sí àwọn ọ̀dọ́ láti pa ara wọn wà nínú ànímọ́ yẹn—bí wọ́n ṣe ń yánhànhàn láti rí ìfẹ́ àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gbà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The American Medical Association Encyclopedia of Medicine sọ pé: “Àwọn tí ń pa ara wọn sábà máa ń lérò ìnìkanwà gan-an, níní àǹfààní láti bá ẹnì kan tí ń tẹ́tí sílẹ̀, tí ń gba tẹni rò, tó sì ń lóye ẹni sọ̀rọ̀, sì máa ń tó nígbà mìíràn láti dènà ìwà àìnírètí náà.”
Lọ́nà kíkàmàmà, àwọn èwe máa ń fẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́ wọn, kí wọ́n sì nímọ̀lára pé àwọn bẹ́gbẹ́ mu. Ojoojúmọ́ ni ó sì ń ṣòro sí i láti tẹ́ ìfẹ́ wọn yìí lọ́rùn nínú ayé aláìnífẹ̀ẹ́ tí ń fa ìparun yìí—ayé kan tí wọn kò ti lágbára láti dápinnu ṣe. Bí àwọn òbí ṣe ń torí bí ìdílé ṣe tú ká tàbí ìkọ̀sílẹ̀ pa àwọn ọ̀dọ́ tì, tún lè jẹ́ abájọ kan tí ń fa kí àwọn ọ̀dọ́ máa pa ara wọn. Onírúurú ọ̀nà sì ni ìpatì yìí ń gbà yọ.
Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn àwọn òbí tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbélé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Iṣẹ́ ti lè de Màmá àti Bàbá mọ́lẹ̀ tàbí kí àwọn eré ìnàjú tí kò kan àwọn ọmọ ti gbà wọ́n lákòókò. Ohun tí wọ́n ń pẹ́ sọ fún àwọn ọmọ jẹ́ pípa wọ́n tì ní kedere. Olókìkí akọ̀ròyìn tó tún jẹ́ olùwádìí náà, Hugh Mackay, sọ pé, “àwọn òbí túbọ̀ ń gbọ́ tara wọn jù. Wọ́n ń fi ara wọn sípò àkọ́kọ́ láti máa gbádùn ọ̀nà ìgbésí ayé wọn nìṣó. . . . Ní ṣàkó, àwọn ènìyàn kò fi bẹ́ẹ̀ ka àwọn ọmọ sí mọ́. . . . Ìgbésí ayé le, àwọn ènìyàn sì ń gbájú mọ́ ti ara wọn lọ́nà kan sí i.”
Nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní èrò pé àwọn jẹ́ akíkanjú lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ lè máà fẹ́ kí a rí àwọn bí ẹni tí ń ṣètọ́jú. Akọ̀ròyìn Kate Legge sọ ọ́ lọ́nà dídán mọ́rán pé: “Àwọn ọkùnrin tó nífẹ̀ẹ́ sí ìsìnrú ìlú máa ń yan àwọn iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tàbí panápaná láàyò dípò àwọn iṣẹ́ ìṣàbójútó . . . Wọ́n ń yan àwọn iṣẹ́ àṣeyọrí alágbára, tí kò gba ọ̀rọ̀ sísọ lọ títí, ti gbígbógunti àwọn nǹkan tó ṣeé rí láàyò ju àwọn iṣẹ́ tó kan àjọṣe àti àbójútó àwọn ẹlòmíràn.” Ó sì dájú pé, ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ tó ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn nínú jù lọ lóde òní ni jíjẹ́ òbí. Àìkúnjú-òṣùwọ̀n jíjẹ́ òbí túmọ̀ sí pípa ọmọ tì. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin náà lè ní èrò òdì nípa ara rẹ̀, kí ó sì ṣàìní òye àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìwé ìròyìn The Education Digest wí pé: “Bí àwọn ọmọ kò bá ní èrò rere nípa ara wọn, wọn kò lè ní ìpìlẹ̀ tí wọ́n lè gbé ṣíṣe ìpinnu tí yóò ṣe wọ́n láǹfààní lé lórí.”
Ó Lè Yọrí sí Àìnírètí
Àwọn olùwádìí gbà pé àìnírètí jẹ́ kókó abájọ pàtàkì kan nínú ìpara-ẹni náà. Gail Mason, tí ń kọ̀wé nípa bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń pa ara wọn ní Ọsirélíà, sọ pé: “A gbà pé àìnírètí bá èrò pípa ara ẹni tan ju ìsoríkọ́ lọ. Nígbà mìíràn, a ń ka àìnírètí sí ọ̀kan lára àwọn àmì ìsoríkọ́. . . . Ó sábà máa ń fara hàn bí èrò ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́ pátápátá nípa ọjọ́ ọ̀la àwọn ọ̀dọ́, ní pàtàkì, nípa ipò ìṣúnná wọn lọ́jọ́ iwájú: ní ìwọ̀n tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ le, ó ń jẹ́ ti àìnírètí nípa ipò àgbáyé.”
Àwọn àpẹẹrẹ àìṣòdodo tí àwọn aṣáájú ìlú ń fi lélẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ kò fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti mú ìlànà ìhùwà àti ìwà rere tiwọn náà dára sí i. Ìwà náà wá jẹ́ ti pé, “Èmi ṣe ní láti máa ṣèyọnu?” Ìwé ìròyìn Harper’s Magazine sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe lágbára láti ṣàwárí ìwà àgàbàgebè tó pé: “Pẹ̀lú ọgbọ́n féfé tí àwọn ọ̀dọ́ fi lè ṣàwárí ìwà àgàbàgebè, wọ́n jáfáfá láti mọ nǹkan—àmọ́ bí ti ìwé kọ́. Ohun tí wọ́n já fáfá tó bẹ́ẹ̀ láti mọ̀ ni àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ tí ń wá láti inú ayé tí wọ́n ti ní láti máa gbọ́ bùkátà ara wọn.” Kí sì ni àwọn àmì wọ̀nyí ń sọ? Òǹkọ̀wé Stephanie Dowrick sọ pé: “A ní ìsọfúnni nípa bí ó ṣe yẹ kí a gbé ayé lọ́wọ́ ju ti ìgbàkigbà rí lọ. A kò lọ́lá tó báyìí rí, a kò mọ̀wé tó báyìí rí, síbẹ̀, ibi gbogbo ni àìsírètí wà.” Kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn àpẹẹrẹ rere láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí nínú ìṣèlú àti ìsìn. Dowrick béèrè àwọn ìbéèrè pàtàkì mélòó kan: “Báwo ni a ṣe lè rí ọgbọ́n, ìmárabápòmu, kí a sì rí ìtumọ̀ pàápàá nínú ìjìyà tí a kò mọ̀dí rẹ̀? Báwo ni a ṣe lè ní ìfẹ́ nínú àyíká tó kún fún ìmọtara-ẹni-nìkan, ọ̀rọ̀ rírùn àti ìwọra?”
Wàá rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ wa tó kàn, wọ́n sì lè yà ọ́ lẹ́nu.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń bẹ̀rù, ojora sì ń mú wọn nípa ọjọ́ ọ̀la wọn àti ti ayé lápapọ̀”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
“Níní àǹfààní láti bá ẹnì kan tí ń tẹ́tí sílẹ̀, tí ń gba tẹni rò, tó sì ń lóye ẹni sọ̀rọ̀, máa ń tó nígbà mìíràn láti dènà ìwà àìnírètí náà”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Àmì Díẹ̀ Tí Ń Ṣáájú Pípa Ara Ẹni
• Ìṣòro àìlèsùn, àìlèjẹun
• Ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ àti àìbẹ́gbẹ́ṣe, níní ìtẹ̀sí ṣíṣèjàǹbá
• Sísá kúrò nílé
• Ìyípadà gbígbàfiyèsí nínú ìrísí
• Ìjoògùnyó tàbí ìmutípara tàbí méjèèjì
• Ìdàrú ọkàn àti ìkanra
• Sísọ̀rọ̀ nípa ikú; àwọn àkọsílẹ̀ nípa ìṣera-ẹni-léṣe; yíyàwòrán tí ń fìwà ipá hàn, ní pàtàkì, ìwà ipá sí ara ẹni
• Ìmọ̀lára ẹ̀bi
• Àìnírètí, ìdàníyàn, ìsoríkọ́, sísunkún lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan
• Kíkó ohun ìní ẹni tọrọ
• Àìlèpọkànpọ̀ fún àkókò pípẹ́
• Àìnífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìgbòkègbodò gbígbádùnmọ́ni
• Ṣíṣe àríwísí ara ẹni
• Ṣíṣe ìṣekúṣe
• Ìlọsílẹ̀ òjijì nínú iṣẹ́ ilé ìwé, ìṣòro lílọ sílé ìwé
• Wíwọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tàbí ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta
• Ayọ̀ àyọ̀jù lẹ́yìn ìsoríkọ́
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìrànwọ́ Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Pọndandan
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The American Medical Association Encyclopedia of Medicine sọ pé, “àrùn ọpọlọ ló ń fa èyí tó lé ní ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún ìpara-ẹni.” Ó mẹ́nu ba àwọn àrùn ọpọlọ bí ìsoríkọ́ bíburújáì (nǹkan bí ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún), ìsínwín (nǹkan bí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún), fífi ọtí mímu pàrònú (nǹkan bí ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún), ànímọ́ ìhùwà àìbẹ́gbẹ́mu (nǹkan bí ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún), àti oríṣi àìṣiṣẹ́ déédéé ọpọlọ kan (ó dín díẹ̀ ní ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún). Ó gbani nímọ̀ràn pé: “A gbọ́dọ̀ fọwọ́ dan-indan-in mú gbogbo ìgbìyànjú láti para ẹni. Ìpín 20 sí 30 lára àwọn ènìyàn tí ń gbìyànjú láti pa ara wọn ló tún ń gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ọdún kan.” Dókítà Jan Fawcett kọ̀wé pé: “Lára àwọn ènìyàn tí ń pa ara wọn [ní United States], àwọn tí kò dé ọ̀dọ̀ òṣìṣẹ́ ìlera ọpọlọ rí ní ń kó ìpín tó lé ní 50 nínú ọgọ́rùn-ún.” Ìwé mìíràn sọ pé: “Apá tó ṣe pàtàkì jù nínú ìtọ́jú ni pé, kí ẹni náà lọ rí oníṣègùn ọpọlọ kan bí ó bá ti lè yá tó láti ràn án lọ́wọ́, láti borí ìsoríkọ́ tí ń fà á.”
A gbé e karí ìwé Teens in Crisis (American Association of School Administrators) àti ìwé Depression and Suicide in Children and Adolescents, tí Philip G. Patros àti Tonia K. Shamoo kọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìfẹ́ ọlọ́yàyà àti ìyọ́nú lè ran èwe kan lọ́wọ́ láti mọyì ìwàláàyè