ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 10/8 ojú ìwé 31
  • Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Ènìyàn Fi Ń Kọ̀ Láti Gbẹ̀jẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Ènìyàn Fi Ń Kọ̀ Láti Gbẹ̀jẹ̀
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ó Pẹ́ Tí Ìfàjẹ̀sínilára Ti Ń Fa Arukutu
    Jí!—2000
Jí!—1998
g98 10/8 ojú ìwé 31

Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Ènìyàn Fi Ń Kọ̀ Láti Gbẹ̀jẹ̀

NÍNÚ ìdájọ́ kan tí a sọ pé ó jẹ́ pàtàkì, ilé ẹjọ́ kan ní Ontario sọ pé Ẹgbẹ́ Alágbèélébùú Pupa ti ilẹ̀ Kánádà ló jẹ́ kí àwọn méjì kan—tí wọ́n gba ẹ̀jẹ̀ tí ó lárùn, tí ẹnì kan ṣoṣo fi tọrẹ—kó fáírọ́ọ̀sì HIV. Adájọ́ Stephen Borins sọ pé: “Bí ohun tí ó burú gan-an bí ẹ̀jẹ̀ tí ó lárùn bá ń wu ẹ̀mí àwọn tí ń gbà á léwu, ó yẹ kí a tètè wá nǹkan ṣe sí i.”

Ní àwọn ọdún 1980, nǹkan bí 1,200 ará Kánádà ló kó fáírọ́ọ̀sì HIV, àwọn 12,000 mìíràn sì kó àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele C—tí gbígba ẹ̀jẹ̀ àti àwọn èròjà ẹ̀jẹ̀ tí ó lárùn fa gbogbo rẹ̀. Láti lè dín iye àwọn tí ń kó àwọn àrùn náà kù, wọ́n túbọ̀ ń fìṣọ́ra yẹ àwọn tí ń fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ wò dáadáa. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ẹni tó wá fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ ló ń sọ òtítọ́ nípa irú àwọn tí wọ́n ti bá sùn sẹ́yìn. Fún àpẹẹrẹ, ìwádìí kan ní United States fi hàn pé ọ̀kan lára 50 ẹni tó wá fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ ni kì í sọ nípa àwọn kókó eléwu, bí ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ tàbí bíbá aṣẹ́wó sùn.

Ohun tó tún ń dá kún ìṣòro náà ni pé àṣìṣe ń wà nínú ọ̀nà tí a ń gbà ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, “bí ẹnì kan bá fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ nígbà tí kò tí ì tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí ó kó àrùn HIV, àwọn àyẹ̀wò tí a bá ṣe kò lè fi àwọn fáírọ́ọ̀sì náà hàn. Ní ti àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele C, ‘àkókò tí a kò fi lè rí àrùn’ yìí lè pẹ́ tó oṣù méjì.”

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, iye àwọn ará Kánádà tí ń fẹ́ láti fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ—tàbí tí ń fẹ́ gbà á—ti dín kù gan-an. Akọ̀ròyìn Paul Schratz kọ̀wé pé: “Ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé, bí iye àwọn tí ń fẹ́ láti fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ ti ń dín kù, tí iye àwọn tí kò lè fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ sì ń pọ̀ sí i, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣíwájú nípa ìwádìí nípa àfirọ́pò ẹ̀jẹ̀.”

Ó dùn mọ́ni nínú pé, ìwé ìròyìn The Toronto Star ròyìn pé láàárín ọdún kan láìpẹ́ yìí, nǹkan bí 40 ènìyàn “tí a gbà sí àwọn ilé ìwòsàn ní Kánádà purọ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn nítorí pé wọn kò fẹ́ gba ẹ̀jẹ̀ sára.” Ìwádìí fi hàn pé nǹkan bí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Kánádà ni yóò fara mọ́ àwọn àfirọ́pò ẹ̀jẹ̀ dípò ẹ̀jẹ̀ tí a fi tọrẹ. Nítorí náà, gbígba ẹ̀jẹ̀ sára kì í tún ṣe ọ̀ràn ìsìn lásán mọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́