ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 12/8 ojú ìwé 3
  • Ta Ni Jésù Kristi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Jésù Kristi?
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Jésù Ṣe Rí?
    Jí!—1998
  • Báwo Ni Jésù Ṣe Rí Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Báwo Ni Jésù Ṣe Rí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 12/8 ojú ìwé 3

Ta Ni Jésù Kristi?

Ní sáà yìí nínú ọdún ni àwọn ènìyàn máa ń ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ jákèjádò ayé. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn gbà gbọ́ pé December 25 ni wọ́n bí Jésù Kristi ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn. Nínú àwọn àwòrán àti iṣẹ́ ọnà, wọ́n yà á bí ọmọ ọwọ́ kan tí ó wà ní ibùjẹ ẹran. Àmọ́, kò sí iyè méjì pé ó dàgbà di géńdé, ó sì lo ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àti ààbọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.

ÌWỌ ha ti ronú rí nípa ìrísí Jésù nígbà tí ó dàgbà bí? Irú àwọ̀ wo ló ní? Ǹjẹ́ ó taagun, tí ó sì jojú ní gbèsè, àbí ó rí hẹ́gẹhẹ̀gẹ bí aláàárẹ̀, bí onírúurú àwọn ayàwòrán ṣe máa ń yà á láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá? Ṣé ó máa ń fá irùngbọ̀n rẹ̀ ni àbí ó máa ń dá a sí? Ṣé irun rẹ̀ gùn?

Bákan náà, ṣé ohun kan wà, bí ìmọ́lẹ̀ rìbìtì tó tàn yí ká orí Jésù bí àwọn ayàwòrán kan ṣe máa ń yà á, tí ó fi í hàn bí ẹni mímọ́? Àbí bó ṣe rí gan-an yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe yàwòrán rẹ̀ yìí—pé kò sí ohunkóhun lára rẹ̀ tó mú kó yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn, pé tó bá tilẹ̀ wà láàárín èrò, ekukáká ni a fi lè dá a mọ̀ yàtọ̀?

Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn òpìtàn ayé àti àwọn ayàwòrán ti ń gbé oríṣiríṣi èrò tí kò ṣọ̀kan kalẹ̀ nípa ìrísí Jésù. Láfikún sí i, ìròyìn láti ẹnu àwọn tí wọ́n fojú rí Jésù, èyí tí àwọn tí wọ́n kọ Bíbélì, tí wọ́n gbé láyé ní ọ̀rúndún kìíní, tí wọ́n bá Jésù ṣe wọléwọ̀de kọ, ti pèsè àwọn ẹ̀rí tó múná dóko.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì ju bí ó ṣe rí lọ nìwọ̀nyí: Ta ni Jésù Kristi ní gidi? Ipa wo ló kó nínú ète Ọlọ́run? Ǹjẹ́ ó ti ṣàṣeparí ipa yẹn? Ta ni ó jẹ́ lónìí, ibo ló sì wà? Ǹjẹ́ ó ní ipò tí ó ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi nípa lórí gbogbo aráyé, àti àwọn tí wọ́n ti kú pàápàá?

Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ kí a gbé ẹ̀rí tí ó wà nípa ìrísí Jésù yẹ̀ wò. Báwo ló ṣe rí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́