ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 12/8 ojú ìwé 4-7
  • Báwo Ni Jésù Ṣe Rí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Jésù Ṣe Rí?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ìtàn Sọ
  • Bíbélì àti Ìrísí Jésù
  • Jésù Kì Í Ṣe Aláìlera
  • Ìrísí Rẹ̀ Ha Já Mọ́ Nǹkan Bí?
  • Báwo Ni Jésù Ṣe Rí Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Báwo Ni Jésù Ṣe Rí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ta Ni Jésù Kristi?
    Jí!—1998
  • “Ẹ Wò Ó! Ọkunrin Naa!”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 12/8 ojú ìwé 4-7

Báwo Ni Jésù Ṣe Rí?

ÀWỌN ohun bíi mélòó kan nípa gan-an lórí ohun tí ìtàn sọ nípa bí Jésù ṣe rí. Àwọn ohun tó fà á nìyẹn tí ìyàtọ̀ fi pọ̀ nínú bí àwọn ayàwòrán ṣe ń yà á.

Ohun méjì tó ń fà á ni àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè ẹni àti sáà tí wọ́n ya àwòrán náà. Ní àfikún, àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn àwọn ayàwòrán náà àti àwọn tó gbéṣẹ́ fún wọn ní ipa lórí bí wọ́n ṣe ya Jésù.

Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni àwọn olókìkí ayàwòrán, bíi Michelangelo, Rembrandt, àti Rubens, ti ń fún ìrísí Kristi ní àfiyèsí púpọ̀. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi àwọn àmì ìṣàpẹẹrẹ àti ìméfò gbé àwọn àwòrán tí wọ́n ń yà lárugẹ, ti nípa púpọ̀ lórí èrò gbogbo gbòò nípa bí Jésù ṣe rí. Àmọ́, kí ni ìpìlẹ̀ àwòrán tí wọ́n yà?

Ohun Tí Ìtàn Sọ

A sábà máa ń yàwòrán Jésù bí ọ̀dọ́mọdé “Olùṣọ́ Àgùntàn Rere,” tí ó ní irun lílọ́ tí kò gùn tàbí èyí tó gùn, nínú àwọn àwòrán tí a ti yà ṣáájú ìgbà ayé Constantine, Olú Ọba Róòmù, tí ó gbé ayé láti ọdún 280 sí 337 Sànmánì Tiwa. Àmọ́, ìwé Art Through the Ages sọ nípa èyí pé: “A lè tọpa ọ̀rọ̀ náà, Olùṣọ́ Àgùntàn Rere, tí ó jẹ́ àkọlé kan, padà sẹ́yìn láti orí [ìbọ̀rìṣà] Àtayébáyé ilẹ̀ Gíríìsì dé orí iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Íjíbítì, àmọ́, ó ti wá di ọ̀rọ̀ tí a fi ń ṣàpèjúwe àwọn onígbàgbọ́ tí ń dáàbò bo agbo Kristẹni nísinsìnyí.”

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ipa tí ìbọ̀rìṣà ní yìí wá ń fara hàn sí i. Ìwé náà ṣàfikún pé: “A lè tètè ronú pé Jésù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òrìṣà ilẹ̀ Mẹditaréníà, pàápàá Helios (Apollo), ọlọ́run oòrùn [tí wọ́n wá ń ya ìmọ́lẹ̀ roboto orí rẹ̀ sórí Jésù àti lẹ́yìn náà sórí “àwọn ẹni mímọ́”], tàbí pé ó jẹ́ Sol Invictus (Oòrùn Tí Kò Ṣeé Ṣẹ́gun), tí àwọn ará Róòmù yà bí ẹni tó ti ìlà oòrùn wá.” Nínú iyàrá kan tí wọ́n fi ṣe itẹ́ òkú nísàlẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Pétérù Mímọ́ ní Róòmù, wọ́n ya Jésù bí Apollo “tí ń gun kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin oòrùn lọ sí ọ̀run.”

Àmọ́, àwòrán tí ó fi í hàn bí ọ̀dọ́mọdé yìí kò tọ́jọ́. Adolphe Didron sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ìwé rẹ̀ náà, Christian Iconography, pé: “Àwòrán Kristi tí a ti kọ́kọ́ yà bí ọ̀dọ́mọdé ń gbó sí i láti ọ̀rúndún kan sí òmíràn . . . bí ìsìn Kristẹni fúnra rẹ̀ ṣe ń pẹ́ sí i.”

Ìwé kan tí a kọ ní ọ̀rúndún kẹtàlá tí a sọ pé ó jẹ́ lẹ́tà tí ẹnì kan tí ń jẹ́ Publius Lentulus kọ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Róòmù ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe rí, ó sọ pé ó ní “irun aláwọ̀ ilẹ̀ tí ó mọ́, tí ó ṣe jọ̀lọ̀mì dé ìtòsí etí rẹ̀, àmọ́ láti ibi etí rẹ̀, ó lọ́ sínú, ó dúdú díẹ̀, ó ń dán gan-an, ó ṣẹ́jọ lé èjìká rẹ̀; ó là á láàárín . . . , ó ní irùngbọ̀n tí ó jẹ́ àwọ̀ irun rẹ̀, tí kò gùn jù ṣùgbọ́n tí ó ṣe sanransanran níbi ààgbọ̀n; . . . ẹyinjú rẹ̀ jẹ́ aláwọ̀ eérú . . . ó sì ṣe kedere.” Àwòrán tí kò ṣeé gbà gbọ́ yìí wá ní ipa lórí àwọn ayàwòrán púpọ̀ lẹ́yìn náà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Sáà kọ̀ọ̀kan ń ṣe irú Kristi tí ó fẹ́.”

Bákan náà, ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹ̀yà àti ìsìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń gbà yà á. Àwọn àwòrán ìsìn láti ọ̀dọ̀ àwọn míṣọ́nnárì Áfíríkà, Amẹ́ríkà, àti Éṣíà yàwòrán Kristi bí onírun gígùn láti ìhà Ìwọ̀ Oòrùn; ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà sọ pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ṣá, wọ́n máa ń fi “àṣà àdúgbò” kún ìrísí rẹ̀.

Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì pẹ̀lú ní àwọn ayàwòrán tiwọn, àwọn wọ̀nyí náà ní bí wọ́n ṣe yàwòrán Kristi. F. M. Godfrey sọ nínú ìwé rẹ̀ Christ and the Apostles—The Changing Forms of Religious Imagery pé: “Kristi tí ó nírìísí oníròbìnújẹ́ tí Rembrandt yà jẹ́ èrò tí àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ní nípa rẹ̀ pé ó jẹ́ oníròbìnújẹ́, aláraṣíṣì, ẹni líle, . . . àwòrán Pùròtẹ́sítáǹtì kan tí ó jẹ́ afiǹkandura-ẹni, tí ń ronú.” Ó sọ pé, èyí hàn nínú “bí Ó ṣe rù hangogo, tí kò sí ẹran lára rẹ̀, ‘ẹni rírẹlẹ̀, tí ń ṣojú àánú àti ẹni tí ìrònú bá’ èyí tí [Rembrandt] gbé èròǹgbà ìtàn akọni Kristẹni lé.”

Bí ó ti wù kí ó rí, a óò rí i nísinsìnyí pé Kristi tí àwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù sábà máa ń yà bí ẹni tí ara rẹ̀ kò le, tí ìmọ́lẹ̀ roboto wà lórí rẹ̀, tí ó rí bí obìnrin, tí ó jẹ́ oníròbìnújẹ́, tí ó fajú ro, tí irun rẹ̀ gùn kò rí bẹ́ẹ̀. Ní gidi, ó yàtọ̀ sí Jésù tí a kọ nípa rẹ̀ nínú Bíbélì.

Bíbélì àti Ìrísí Jésù

Gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run,” Jésù kò ní àbùkù kankan, nítorí náà, kò sí iyè méjì pé arẹwà ọkùnrin ni. (Jòhánù 1:29; Hébérù 7:26) Ó sì dájú pé kò ní máa fìgbà gbogbo ní ìrísí ẹni tó fajú ro bí wọ́n ti máa ń yà á nínú àwọn àwòrán tí ó gbajúmọ̀. Lóòótọ́ ni ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nínú ìgbésí ayé rẹ̀, àmọ́ ìwà rẹ̀ lápapọ̀ dà bíi ti Bàbá rẹ̀, “Ọlọ́run aláyọ̀.”—1 Tímótì 1:11; Lúùkù 10:21; Hébérù 1:3.

Ǹjẹ́ irun Jésù gùn? Àwọn Násírì nìkan ni kò gbọ́dọ̀ gé irun wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì, Jésù kì í sì í ṣe Násírì. Nítorí náà, kò sí iyè méjì pé ńṣe ló máa ń gẹ irun rẹ̀ bíi ti àwọn ọkùnrin Júù yòókù. (Númérì 6:2-7) Ó tún gbádùn mímu wáìnì níwọ̀nba tí ó bá wà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, èyí sì fìdí èrò náà múlẹ̀ pé onínúdídùn ni. (Lúùkù 7:34) Àní, ó ṣe wáìnì nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu níbi àsè ìgbéyàwó kan ní Kánà ti Gálílì. (Jòhánù 2:1-11) Ẹ̀rí sì wà pé ó dá irùngbọ̀n sí, àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa ìjìyà rẹ̀ sì jẹ́rìí sí i.—Aísáyà 50:6.

Àwọ̀ ara Jésù àti àbùdá rẹ̀ ńkọ́? Ó ṣeé ṣe kí ó dà bíi ti àwọn Júù. Ó lè ti jogún àwọn àbùdá yìí lára Màríà, ìyá rẹ̀ tó jẹ́ Júù. Júù ni àwọn baba ńlá rẹ̀, ní ìlà ìdílé Hébérù. Nítorí náà, ó lè jẹ́ pé àwọ̀ àti àbùdá tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn Júù ni Jésù ní.

Kódà, tí Jésù bá wà láàárín àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pàápàá, kò jọ pé ìrísí rẹ̀ yàtọ̀ gan-an, nítorí ńṣe ni Júdásì fẹnu kò ó lẹ́nu kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí ó fẹ́ fà á lé lọ́wọ́ lè dá a mọ̀. Èyí fi hàn pé ekukáká ni a fi lè dá Jésù mọ̀ láàárín èrò. Ó sì ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, nítorí pé, ó kéré tán, nígbà kan, ó rìnrìn àjò láti Gálílì lọ sí Jerúsálẹ́mù láìsí ẹni tó dá a mọ̀.—Máàkù 14:44; Jòhánù 7:10, 11.

Àmọ́, àwọn kan sọ pé Jésù ní láti jẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ kò le. Èé ṣe tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó nílò ẹnì kan tí yóò bá a gbé òpó igi oró rẹ̀. Bákan náà, òun ló kọ́kọ́ kú lára àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí a kàn mọ́ igi.—Lúùkù 23:26; Jòhánù 19:17, 32, 33.

Jésù Kì Í Ṣe Aláìlera

Lòdì sí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, Bíbélì kò ṣàpèjúwe Jésù bí ẹni tí ara rẹ̀ kò le tàbí tí ń ṣe bí obìnrin. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé nígbà tí ó wà ní èwe pàápàá, ó “ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n àti ní ìdàgbàsókè ti ara-ìyára àti ní níní ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.” (Lúùkù 2:52) Apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú ọgbọ̀n ọdún ló fi ṣe káfíńtà. Kò jọ pé ẹnì kan tó rí hẹ́gẹhẹ̀gẹ tàbí tí kò lera lè ṣe irú iṣẹ́ yẹn, ní pàtàkì ní sáà yẹn tí kò sí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tí kì í jẹ́ kí a lo agbára jù. (Máàkù 6:3) Bákan náà, Jésù lé màlúù, àgùntàn, àti àwọn onípàṣípààrọ̀ owó jáde nínú tẹ́ńpìlì, ó sì sojú àwọn tábìlì àwọn onípàṣípààrọ̀ owó náà dé. (Jòhánù 2:14, 15) Èyí pẹ̀lú fi hàn pé ó lókun, ó sì lágbára.

Láàárín ọdún mẹ́ta ààbọ̀ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibùsọ̀ ló rìn dé nígbà tí ó ń wàásù káàkiri. Síbẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò dámọ̀ràn rí pé kí ó “sinmi díẹ̀.” Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù ló wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí díẹ̀ lára wọn jẹ́ apẹja tí wọ́n lẹ́mìí iṣẹ́ pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.”—Máàkù 6:31.

Ní gidi, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopædia tí M’Clintock àti Strong ṣe sọ pé, “gbogbo ìtàn ìjíhìnrere látòkè délẹ̀ ló fi hàn pé ara [Jésù] le, ó sì lókunra.” Kí ló wá fà á tí ó fi nílò ẹnì kan láti bá a gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ló sì fà á tó ṣe kú ṣáájú àwọn méjì tí wọ́n kàn mọ́ igi pẹ̀lú rẹ̀?

Kókó pàtàkì kan ni wàhálà-ọkàn lílégbákan. Bí àkókò tí wọn óò pa Jésù ṣe ń sún mọ́, ó wí pé: “Ní tòótọ́, mo ní ìbatisí kan tí a ó fi batisí mi, ẹ sì wo bí wàhálà-ọkàn ti bá mi tó títí yóò fi parí!” (Lúùkù 12:50) Wàhálà-ọkàn yìí di “ìroragógó” ní alẹ́ ọjọ́ tí ó lò kẹ́yìn: “Bí ó ti wà nínú ìroragógó, ó ń bá a lọ ní títúbọ̀ fi taratara gbàdúrà; òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀.” (Lúùkù 22:44) Jésù mọ̀ pé dídi ìwà títọ́ òun mú dójú ikú ni yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún aráyé láti rí ìyè ayérayé. Ẹrù tí ó nira gbáà nìyẹn! (Mátíù 20:18, 19, 28) Ó tún mọ̀ pé àwọn ènìyàn Ọlọ́run yóò pa òun bí “ẹni ègún.” Nípa bẹ́ẹ̀, àníyàn rẹ̀ ni pé èyí lè fa ẹ̀gàn wá sórí Bàbá rẹ̀.—Gálátíà 3:13; Sáàmù 40:6, 7; Ìṣe 8:32.

Lẹ́yìn tí a fi í hàn, wọ́n hùwà òǹrorò sí i lọ́pọ̀lọpọ̀. Nígbà ìgbẹ́jọ́ awúrúju kan tí a ṣe láàárín òru, àwọn ọ̀gá-ọ̀gá ní ilẹ̀ náà fi í ṣẹ̀sín, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n sì gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Láti mú kí ìgbẹ́jọ́ ti òru lè dà bí èyí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, wọ́n tún ṣe ìgbẹ́jọ́ mìíràn ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì. Pílátù ló gbọ́ ẹjọ́ Jésù; lẹ́yìn náà Hẹ́rọ́dù, tí òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fi í ṣe yẹ̀yẹ́; àti lẹ́yìn náà, Pílátù tún béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Níkẹyìn, Pílátù ní kí wọ́n fi pàṣán lù ú. Èyí kì í sì í ṣe ọ̀ràn nínani ní pàṣán lásán. Ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ nípa bí àwọn ará Róòmù ṣe ń nani ní pàṣán pé:

“Ohun tí a sábà máa ń lò ni kòbókò tẹ́ẹ́rẹ́ . . . tí ó ní àwọn awọ aláhunpọ̀ tí gígùn wọn kò bára dọ́gba, tí a wá so àwọn irin ródóródó kéékèèké tàbí àwọn egungun àgùntàn mímú bérébéré mọ́. . . . Bí àwọn ọmọ ogun Róòmù ti ń fagbára na ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lẹ́yìn léraléra, àwọn irin ródóródó náà yóò mú kí ẹ̀yìn rẹ̀ dáranjẹ̀ jíjìn, kòbókò náà àti àwọn egungun àgùntàn yóò sì bẹ́ awọ ara náà àti àwọn ẹran ìsàlẹ̀ awọ. Bí wọ́n sì ti ń nà án, ara tí ń bẹ́ náà yóò ya kan àwọn ìṣù ẹran tí ó wà lára egungun, yóò sì sọ ara rẹ̀ di yánnayànna, yóò sì máa ṣẹ̀jẹ̀.”

Ó ṣe kedere pé Jésù kò ní lókun mọ́ kí ó tó di pé ó ṣubú lábẹ́ òpó wíwúwo tí ó gbé. Ní gidi, ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ pé: “Hílàhílo tí àwọn Júù àti àwọn ará Róòmù kó bá Jésù àti lílù tí wọ́n ti lù ú nílùkilù, tí wọn kò sì fún un lóúnjẹ àti omi, tí wọn kò sì jẹ́ kó sùn dá kún rírẹ̀ tí ó rẹ̀ ẹ́. Nítorí náà, kódà kí wọ́n tó kan Jésù mọ́ àgbélébùú gan-an, ipò tí ó wà kò dára rárá, ó sì lè ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.”

Ìrísí Rẹ̀ Ha Já Mọ́ Nǹkan Bí?

Láti orí àwòrán ayédèrú tí Lentulus yà dé orí àwọn àwòrán tí àwọn olókìkí àgbà ayàwòrán yà dé orí àwọn fèrèsé aláwọ̀ kíkọmànà, ó jọ pé ohun tó bá ṣe yòòyòòyò ló ń jọ Kirisẹ́ńdọ̀mù lójú. Bíṣọ́ọ̀bù àgbà ti Turin, tí Aṣọ Ìsìnkú Turin tó fa àríyànjiyàn wà níkàáwọ́ rẹ̀, sọ pé: “Ó yẹ kí a pa agbára àrà ọ̀tọ̀ tí ń múni rántí ìṣẹ̀lẹ̀, èyí tí àwòrán Jésù Kristi ní mọ́.”

Síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dìídì fo irú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ “tí ń múni rántí ìṣẹ̀lẹ̀” nípa ìrísí Jésù. Èé ṣe? Wọ́n lè gbé ọkàn wa kúrò nínú ohun tí ó túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun—ìmọ̀ Bíbélì. (Jòhánù 17:3) Jésù fúnra rẹ̀—tí ó jẹ́ àwòkọ́ṣe fún wa gan-an—“kì í wo ìrísí òde àwọn ènìyàn,” bẹ́ẹ̀ ni kò kà á sí bàbàrà. (Mátíù 22:16; fi wé Gálátíà 2:6.) Títẹnu mọ́ ìrísí Jésù nígbà tí àwọn ìwé Ìhìnrere tí ó ní ìmísí kò sọ nípa rẹ̀ já sí títako ìjẹ́pàtàkì àwọn ìwé náà. Ní ti gidi, gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí, Jésù kò tilẹ̀ dà bí ẹ̀dá ènìyàn mọ́.a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àmọ́ ṣá o, kò sí ohun tó burú nínú lílo àwọn àwòrán tí ó ní Jésù nínú tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èyí sábà máa ń wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society. Àmọ́, kì í ṣe pé a ń gbìyànjú láti mú kí ẹni tí ń wò ó máa gbọ̀n jìnnìjìnnì, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣètìlẹ́yìn fún àwọn èròǹgbà, àmì, tàbí ìjọsìn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Kristi aláìlera, aláraṣíṣì tí àwọn ayàwòrán ní Kirisẹ́ńdọ̀mù yà, ní ìfiwéra pẹ̀lú àwòrán Jésù tí a gbé karí àkọsílẹ̀ Bíbélì

[Credit Line]

Jésù tó ń wàásù ní Òkun Gálílì láti ọwọ́ Gustave Doré

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́