Ojú Ìwòye Bíbélì
Ìjábá Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Yóò Ha Pa Ayé Wa Run Bí?
NÍ March 12, 1998, àwọn àkọlé ìwé ìròyìn, tẹlifíṣọ̀n, àti àwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet jákèjádò ayé gbé ìròyìn pé lálà fẹ́ lu, wọ́n wí pé: “A kò lè sọ pé pílánẹ́ẹ̀tì kékeré kan tí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ kìlómítà kan àti ààbọ̀, tí ń já bọ̀, kò ní já lu Ilẹ̀ Ayé.” Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì àti àwọn ọ̀gbẹ̀rì jà raburabu láti mọ irú ewu náà gan-an tó ń bọ̀. Àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà yára parí èrò sí pé kò lè já lu ayé.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lákòókò tí gbogbo nǹkan ń jà rànyìn náà, a ṣàkíyèsí ohun tuntun kan. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Ohun arabaríbí jù lọ nípa ìdágìrì èké náà lè jẹ́ pé, bó ti wù kí ó dáyà foni tó, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò ṣe bí pé ohun bàbàrà kan ni. Èrò pé kí àwa tí a wà lórí Ilẹ̀ Ayé máa wọ̀nà fún rírí irú ohun bẹ́ẹ̀ tí ń pọ̀ sí i—kí a sì máa múra sílẹ̀ láti ṣe ohun kan nípa wọn—yóò ti di àṣerégèé ní ọdún mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sẹ́yìn, àmọ́ ní báyìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn òṣèlú kan pàápàá lérò pé bí ewu náà bá tilẹ̀ kéré, kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré.”
Àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà kan gbà gbọ́ pé nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run tó tóbi tó láti fa àjálù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ló ń fò fẹ̀rẹ̀ kọjá níbi tí ilẹ̀ ayé ń yípo tàbí tí wọ́n ń sún mọ́ ọn. Àwọn olùwádìí sọ pé, kódà, bí èyí tí ó kéré díẹ̀ lára wọ́n bá kọ lu ilẹ̀ ayé, bí yóò ṣe bú gbàù yóò dà bí ìgbà tí ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé púpọ̀ bá bú lẹ́ẹ̀kan náà. Àjálù ńlá ni irú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn yóò yọrí sí fún pílánẹ́ẹ̀tì wa àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀, ènìyàn àti ẹranko.
Èrò ti Ẹlẹ́dàá àgbáálá ayé, Jèhófà Ọlọ́run, ni a kì í sábà kà sí nínú irú àsọtẹ́lẹ̀ àti ìwéwèé eléwu bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 8:3; Òwe 8:27) Kedere ni ó sọ nípa ìfẹ́ àti ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé àti ìràn ènìyàn nínú Bíbélì. Òun yóò ha jẹ́ kí àjálù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé pa ayé wa run bí?
Àgbáálá Ayé Tó Wà Lábẹ́ Ìdarí Ọlọ́run
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá alágbára ńlá gbogbo tí ó dá àgbáyé, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé òun nìkan ló ní agbára láti darí àwọn agbára tí ń ṣàkóso àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run. Ọlọ́gbọ́n Sólómọ́nì Ọba sọ pé, “ìfòyemọ̀ ni” Jèhófà “fi fìdí ọ̀run múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Òwe 3:19) Wòlíì Jeremáyà polongo pé, Ọlọ́run ni “Ẹni tí ó na àwọn ọ̀run nípasẹ̀ òye rẹ̀.”—Jeremáyà 51:15.
Jèhófà ló mú kí àwọn òfin àti agbára tí ń gbé àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run kiri wà, títí kan àwọn ìràwọ̀, àwọn pílánẹ́ẹ̀tì, àwọn ìràwọ̀ onírù, àti àwọn pílánẹ́ẹ̀tì kéékèèké. (Aísáyà 40:26) Àmọ́ ṣá o, ó jọ pé ó ń jẹ́ kí àwọn ìràwọ̀ àti pílánẹ́ẹ̀tì la àyípoyípo àdánidá wọn tí a pè lọ́nà àfiwé ní ìbí, ìwàláàyè, àti ikú wọn kọjá láìsí pé ó ń dá sí ọ̀ràn náà nígbà gbogbo. Èyí ní àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run tí ń forí gbárí lọ́nà bíburújáì nínú. Àpẹẹrẹ lọ́ọ́lọ́ọ́ kan ni ìforígbárí tó ṣẹlẹ̀ ní July 1994 nígbà tí àwọn àfọ́kù ìràwọ̀ onírù Shoemaker-Levy 9 já lu pílánẹ́ẹ̀tì Júpítà.
Ẹ̀rí tí a wà jáde nínú ilẹ̀ wà nípa àwọn àpáta ńlá-ńlá tí ń já lu ilẹ̀ ayé láti gbalasa òfuurufú nínú ìtàn tó ti wà ṣáájú wíwà ènìyàn. Àmọ́, irú ohun bẹ́ẹ̀ yóò ha ṣẹlẹ̀ sí pílánẹ́ẹ̀tì ilẹ̀ ayé wa bí? Fún àpẹẹrẹ, kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí pílánẹ́ẹ̀tì kékeré tí ó fẹ̀ ní kìlómítà kan àti ààbọ̀ bá forí sọ ilẹ̀ ayé? Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà náà, Jack Hills, sọ pé ipa tí yóò ní yóò tú agbára ńlá jáde, èyí tí ó fi àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ìgbà ju ti bọ́ǹbù tó fọ́ Hiroshima túútúú. Bí ó bá já lu òkun, ìrugùdù omi yóò kún bo gbogbo etíkun. Hills sọ pé: “Omi ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ tí àwọn ìlú wà tẹ́lẹ̀.” Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìṣẹ̀lẹ̀ àfinúrò bíburújáì ń fi hàn pé a óò pa ìran ènìyàn run yán-ányán-án. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ìparun yìí ṣe bá ìfẹ́ tí Ẹlẹ́dàá wa ní fún ilẹ̀ ayé mu? Bíbélì sọ pé pílánẹ́ẹ̀tì yìí ní ipò pàtàkì kan nínú ète Jèhófà.
Ilẹ̀ Ayé Wa—A Dá A fún Ète Kan
Onísáàmù náà sọ nípa pílánẹ́ẹ̀tì wa pé: “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sáàmù 115:16) Aísáyà ṣàpèjúwe Jèhófà bí “Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé . . . , òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Ilẹ̀ ayé ni ogún tí Jèhófà fún aráyé. Níwọ̀n bí Ẹlẹ́dàá wa sì ti ní ọjọ́ ọ̀la ayérayé fún àwọn olùbẹ̀rù-Ọlọ́run lọ́kàn, ilẹ̀ ayé yóò wà títí láé bí ibùgbé ayérayé wọn. Sáàmù 104:5 mú un dá wa lójú pé: “[Jèhófà] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.”
Lóòótọ́, Ọlọ́run ti gba àwọn àjálù ńlá kan láyè láti já lu pílánẹ́ẹ̀tì wa, ó sì ti ṣekú pa ọ̀pọ̀ ènìyàn. Díẹ̀ lára àwọn àjálù wọ̀nyí—bí ogun, ìyàn, àti àjàkálẹ̀ àrùn—ló jẹ́ ìwà ìwọra, ìwà òmùgọ̀, àti ìwà òǹrorò ènìyàn ló fà á lódindi tàbí lápá kan. (Oníwàásù 8:9) Àwọn mìíràn—bí ìsẹ̀lẹ̀, ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín, ìkún omi, àti ìjì—ni ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí àdánidá tí aráyé kò lóye rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ fà. Ní ìyàtọ̀ sí ète Ọlọ́run látètèkọ́ṣe, ìran ènìyàn kò pé mọ́; wọ́n ti di ẹlẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa kò lè gbára lé ààbò Ọlọ́run láti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun tí a pè ní ìjábá àdánidá ní àkókò yìí.
Àmọ́, kò tíì ṣẹlẹ̀ rí kí Jèhófà fàyè gba kí ewu wu wíwà ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Láti ìgbà tí a ti dá ènìyàn, àwọn ìtàn tó fìdí múlẹ̀ kò sọ nípa àjálù àdánidá kankan tí ó wu wíwà gbogbo aráyé léwu.a
Ó Dájú Pé Ìran Ènìyàn Yóò Máa Wà Nìṣó
Ó ti jẹ́ ète Ẹlẹ́dàá wa láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ènìyàn pé kí ènìyàn ‘kún ilẹ̀ ayé, kí ó sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 9:1) Ó ṣèlérí pé, “àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:9, 11, 22, 29) Jèhófà sọ nípa àwọn ìlérí rẹ̀ pé: “Ìpinnu tèmi ni yóò dúró, gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe.”—Aísáyà 46:10; 55:11; Sáàmù 135:6.
Bíbélì kò sọ pé àjálù ibi ráńpẹ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ń fà kì yóò ṣẹlẹ̀ rárá. Àmọ́, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà kò ní jẹ́ kí ìjábá ọ̀gbálẹ̀gbáràwé èyíkéyìí jin ète tí ó sọ pé òun ní fún ilẹ̀ ayé àti aráyé lẹ́sẹ̀. Lórí ìpìlẹ̀ àwọn ìlérí Bíbélì, a lè ní ìdánilójú pé ènìyàn yóò máa gbé nínú pílánẹ́ẹ̀tì wa títí láé—bẹ́ẹ̀ ni, ìran ènìyàn yóò fi ṣe ilé fún àkókò tí ó lọ kánrin!—Oníwàásù 1:4; 2 Pétérù 3:13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìkún Omi ọjọ́ Nóà jẹ́ ọ̀nà kan tí Ọlọ́run gbà mú ìdájọ́ ṣẹ, àmọ́ Jèhófà rí i dájú pé àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko kan là á já.—Jẹ́nẹ́sísì 6:17-21.