ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 1/8 ojú ìwé 26-28
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Láìsí Àwọn Òbí Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Láìsí Àwọn Òbí Mi?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ta Ni Yóò Bójú Tó Mi?’
  • Ẹrù Iṣẹ́ Ìdílé
  • Gbígbọ́ Bùkátà Ara Rẹ
  • Kíkojú Ìpèníjà Náà
  • Mo Ṣe Ní Láti Wà Láìní Òbí?
    Jí!—1998
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wà Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹ̀gbọ́n Àtàwọn Àbúrò Mi?
    Jí!—2010
  • Báwo Lọ̀rọ̀ Èmi àti Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Mi Ṣe Lè Wọ̀ Dáadáa?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Bá A Ṣe Lè Máa Tọ́jú Àwọn Àgbàlagbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 1/8 ojú ìwé 26-28

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pe . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Láìsí Àwọn Òbí Mi?

“Nígbà ti mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́ta tí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin, àwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀. Ẹnì kìíní-kejì wọ́n sapá gidigidi nílé ẹjọ́ kí òun lè kó wa sọ́dọ̀, níkẹyìn, a wá wà lọ́dọ̀ màmá mi. Bí ó ti wù kí ó rí, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi pinnu láti lọ gbé lọ́dọ̀ baba mi nígbà tí mo di ọmọ ọdún méje.”—Horacio.

NÍ ỌDÚN díẹ̀ lẹ́yìn náà, baba Horacio àti àlè rẹ̀ sá lọ—wọn já Horacio àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sílẹ̀. Horacio sọ pé: “Bí mo ṣe di olórí ìdílé kan tí ó ní èmi, ẹ̀gbọ́n mi ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ọbàkan mi ọmọ ọdún méjìlá—tí ó pinnu láti máa bá wa gbé nínú nìyẹn ní ọmọ ọdún méjìdínlógún.”

Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kan tí a kọ ṣáájú èyí ti fi hàn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọ̀dọ́ káàkiri àgbáyé ni ó bá ara wọ́n nípò ẹni tí kò lóbìí.a Bí ti Horacio, wọ́n ti já àwọn ọ̀dọ́ kan sílẹ̀. Àmọ́, òbí àwọn mìíràn ti kú tàbí kí ogun tàbí àjálù ti ya wọ́n nípa. Ohun yòówù kí ọ̀ràn náà jẹ́, wíwà ní ipò ẹni tí kò lóbìí lè jẹ́ ìṣòro, ó sì lè dani lórí rú. Ó tún lè gbé ẹrù iṣẹ́ kíkọyọyọ lé ọ lọ́wọ́.

‘Ta Ni Yóò Bójú Tó Mi?’

Bí o ṣe lè ṣàṣeyọrí sinmi lórí ọjọ́ orí àti ipò tí o wà. Dájúdájú, ipò nǹkan yóò túbọ̀ ṣòro gan-an bí o bá ṣì wà lọ́mọdé tàbí tí o bá wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ọ̀dọ́langba. Kódà, ó lè jẹ́ pé wọn ò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá ní ìwọ nìkan. Ó lè jẹ́ arákùnrin tàbí arábìnrin àwọn òbí rẹ, ó sì lè jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin ni yóò fẹ́ mú ọ sọ́dọ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka bíbójútó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó sí apá kan ìjọsìn wọn. (Jákọ́bù 1:27; 2:15-17) Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ sì máa ń ṣe ìrànlọ́wọ́ lọ́pọ̀ ìgbà. Fún àpẹẹrẹ, Horacio àti àwọn arábìnrin rẹ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọn sì ń lọ sí àwọn ìpàdé wọn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti pàdé ìdílé Kristẹni kan tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ràn wọ́n lọ́wọ́. Horacio sọ pé: “Mo mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà àti àbójútó rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ lójoojúmọ́ o! A ń bù kún wa nípasẹ̀ ìdílé kan tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí nínú ìjọ tí wọ́n sì ní àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ wa. Kí a kúkú sọ pé wọ́n gbà wá ṣọmọ ni, láìdà bí ti tẹ́lẹ̀, a wá ní ìmọ̀lára pé a jẹ́ ara ìdílé kan, èyí tí a lè fọkàn tán nínú ohunkóhun.”

Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ọ̀dọ́ ni ó ń rìnnà kore bẹ́ẹ̀. Ètò Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ròyìn pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọdé tí wọn kò léèyàn ni a máa ń mú lọ sí àwọn ìdílé tí a ti ń fìyà jẹ wọ́n, tí a ń fagbára mú wọn ṣiṣẹ́ láìsí èrè tàbí àǹfààní kankan fún wọn láti ní ìlọsíwájú, a sì ń lò wọ́n fún iṣẹ́ aṣẹ́wó tàbí kí a sọ wọ́n dẹrú pàápàá.” Nítorí náà, bí o bá ní ẹnì kan tí ń bójú tó ọ níwọ̀nba, ńṣe ni kí o máa dúpẹ́.

Lóòótọ́, dídáwà láìsí àwọn òbí rẹ jẹ́ àdánù ńlá. Inú sì lè máa bí ọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá fún àìrí wọn láti bójú tó ọ. Kí ẹbí kan tàbí ẹ̀gbọ́n kan wá máa sọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe fún ọ lè túbọ̀ mú ìbínú rẹ pọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n, má ṣe fi ìkanra mọ́ àwọn tí ń gbìyànjú láti bójú tó ọ. Bíbélì sọ pé: “Ṣọ́ra kí ìhónú má bàa dẹ ọ́ lọ sínú [ìwà] ìpẹ̀gàn . . . Ṣọ́ra kí o má ṣe yíjú sí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́.” (Jóòbù 36:18, 21) Rántí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin tí ń jẹ́ Ẹ́sítérì nínú Bíbélì. Módékáì, ìbátan rẹ̀ kan ni ó wò ó dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ òrukàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Módékáì kì í ṣe bàbá rẹ̀ gan-an, síbẹ̀ ó ‘gbé àwọn àṣẹ kalẹ̀ fún un,’ tí òun sì pa mọ́, kódà nígbà tí ó dàgbà! (Ẹ́sítérì 2:7, 15, 20) Gbìyànjú láti jẹ́ onígbọràn, kí o sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. Yóò mú kí pákáǹleke rọlẹ̀, yóò sì mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ dẹrùn fún gbogbo ẹni tí ọ̀ràn kàn.

Ẹrù Iṣẹ́ Ìdílé

Bí o bá ní ẹ̀gbọ́n kan—tàbí tí ìwọ fúnra rẹ bá dàgbà tó—bóyá ó lè ṣeé ṣe kí ìwọ àti àwọn alájọbí rẹ máa dá gbé. O lè wá bá ara rẹ ní ipò olórí ìdílé—ẹrù iṣẹ́ kan tí ń tánni lókun lèyí sì jẹ́ o! Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n bá ara wọn nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ ti ṣe iṣẹ́ títayọlọ́lá ti títọ́ àwọn alájọbí wọn.

Dájúdájú, o lè ní láti bá àwọn ìmọ̀lára ìbínú jà. Rírántí pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ, tí o sì ń bìkítà nípa wọn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ni ojú ìwòye tí ó dára. Kíka iṣẹ́ bíbójútó wọn sí iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún ọ tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an. Ó ṣe tán, a pàṣẹ fún àwọn Kristẹni láti máa pèsè fún àwọn tí ń ṣe tiwọn. (1 Tímótì 5:8) Ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí o gbìyànjú láti ṣe baba tàbí ìyá fún àwọn alájọbí rẹ tó, o kò lè di òbí wọn ni ti gidi.

Kò bọ́gbọ́n mu láti retí pé kí àwọn alájọbí rẹ máa ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe sí àwọn òbí rẹ sí ọ. Ní ti tòótọ́, yóò gba àkókò díẹ̀ kí wọ́n tó sinmẹ̀dọ̀ láti kà ọ́ sí ẹni tí àwọn lè bọ̀wọ̀ fún ní ti gidi. Ní báyìí ná, gbìyànjú láti má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Yẹra fún “ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú.” Nípasẹ̀ àpẹẹrẹ tìrẹ, kọ́ àwọn alájọbí rẹ bí ẹ óò ṣe ‘jẹ́ onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, tí ẹ óò sì máa dárí ji ara yín fàlàlà.’—Éfésù 4:31, 32.

Horacio kò jiyàn pé òun lè ṣe àṣìṣe, ó sọ pe: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, n kì í gba gbẹ̀rẹ́ fún àwọn alájọbí mi rárá. Àmọ́, ìyẹn dáàbò bò wá dé àyè kan, a sì ń hu ìwà tí ó tọ́ lójú Jèhófà.”

Gbígbọ́ Bùkátà Ara Rẹ

Láìsí àní-àní, bí àwọn òbí rẹ kò bá sí nítòsí láti bójú tó ọ, gbígbọ́ bùkátà ara rẹ ni yóò jẹ́ olórí àníyàn rẹ. Bóyá àwọn àgbàlagbà díẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni lè ṣèrànwọ́ fún ìwọ àti àwọn alájọbí rẹ, bí o bá ní, láti kọ́ bí a ṣe ń dáná, bí a ṣe ń tún ilé ṣe àti bí a ṣe ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí o gbọ́dọ̀ máa bójú tó nísinsìnyí. Síbẹ̀, kí ni ẹ óò ṣe láti lówó lọ́wọ́? Ó lè jẹ́ pé kò sí ọ̀nà àbájáde kankan fún ọ ju kí o sapá láti wáṣẹ́.

Bí ó ti wu kí ó rí, iṣẹ́ kì í rọrùn láti rí fún àwọn ọ̀dọ́ tí kò kàwé púpọ̀, tí wọn kò ní ìrírí, tàbí tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ní òye iṣẹ́. Nítorí náà, bí ó bá ṣeé ṣe fún ọ láti jáde ní ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀—kódà, kò burú bí o bá lè kọ́ṣẹ́ sí i. Horacio sọ pé: “Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ṣiṣẹ́, a sì san owó ilé ẹ̀kọ́ tèmi àti ti ọbàkan mi.” Bí o bá ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀sẹ̀ ń gòkè àgbà, ó ṣeé ṣe kí o lo ọgbọ́n ara rẹ láti wáṣẹ́.—Wo “Dídá Iṣẹ́ Sílẹ̀ ní Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí Wọ́n Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Gòkè Àgbà,” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, October 22, 1994.

Kódà, o ṣeé ṣe kí ìjọba máa fún ọ lówó tí o bá ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ọrọ̀ ajé wọ́n ti dára. Lọ́pọ̀ ìgbà, a ń rí àwọn aṣojú ìjọba tàbí ti ilé iṣẹ́ àdáni tí a yà sọ́tọ̀ láti máa ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn ọmọ tí a já sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn aṣojú kan lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa rí oúnjẹ gbà tàbí kí wọ́n wá ilé fún ọ. Láìsí àní-àní, o gbọ́dọ̀ fi ọgbọ́n ná owó èyíkéyìí tí o bá rí gbà gẹ́gẹ́ bí ìrànlọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: ‘Owó jẹ́ fún ìdáàbòbò.’ (Oníwàásù 7:12) Bí o kò bá sì fi ìṣọ́ra wéwèé ìnáwó àti bí o ṣe ń ná an, ó lè “ṣe ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀ . . . a sì fò lọ.”—Òwe 23:4, 5.

Gbígbọ́ bùkátà ara rẹ lè máà jẹ́ ìṣòro bí o bá wà lábẹ́ àbójútó àgbàlagbà kan. Àmọ́, àkókò kan ń bọ̀ ní ọjọ́ iwájú, tí wàá ní láti gbọ́ bùkátà ara rẹ. Níwọ̀n bí o kò ti ní àwọn òbí tí yóò máa gbà ọ́ níyànjú nípa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́, ó lè gba ìsapá gidi fún ọ láti pọkàn pọ̀ sórí ẹ̀kọ́ rẹ. Àmọ̀ràn tí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì lórí ìlọsíwájú rẹ̀ nípa tẹ̀mí pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere,” tún ṣeé mú lò nínú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ. (1 Tímótì 4:15) Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò fi àpẹẹrẹ tí ó dára lélẹ̀ fún àwọn tó yí ọ ká, ìwọ pẹ̀lú yóò sì jàǹfààní.

Èyí tí ó ṣe pàtàkì ju gbogbo rẹ̀ lọ ni pípèsè fún ara rẹ nípa tẹ̀mí. Gbìyànjú láti ṣètòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò tẹ̀mí tí ẹ óò máa tẹ̀ lé déédéé. (Fílípì 3:16) Fún àpẹẹrẹ, ó jẹ́ àṣà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí àwọn ìdílé máa jíròrò ẹsẹ Bíbélì kọ̀ọ̀kan lójoojúmọ́. O kò ṣe fi èyí ṣe apá kan ìgbòkègbodò rẹ? Ìṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti di alágbára nípa tẹ̀mí.—Hébérù 10:24, 25.

Kíkojú Ìpèníjà Náà

Gbígbé láìsí àwọn òbí ẹni ṣòro, ṣùgbọ́n kò túmọ̀ sí pé a óò máa sorí kọ́ kiri, tí a kò sì ní láyọ̀ mọ́ nínú ìgbésí ayé. Ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni Paola nígbà tí ìyá rẹ kú ní ẹni ogún ọdún. Baba rẹ̀ kú nígbà tí Paola jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá. Obìnrin onínúure kan gba òun àti àwọn arábìnrin rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sílé. Ìgbésí ayé rẹ̀ ha ti di èyí tí kò láyọ̀ mọ́ bí? Rárá o. Paola sọ pé: “A lè má dà bí ìdílé gidi kan, àmọ́ a ń gbé ìgbésí ayé tí ó tẹ́nilọ́rùn. Ní gidi, ìfẹ́ tí a ní láàárín ara wa lágbára ju ti ọ̀pọ̀ ìdílé lọ.”

Irene tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Paola fi kún un pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a wà láìsí àwọn òbí wa, a ṣì dà bí àwọn ọ̀dọ́ yòókù gẹ́lẹ́.” Kí ni àmọ̀ràn rẹ̀ fún àwọn mìíràn tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀? “Má ṣe ronú pé o kò ní àǹfààní kankan.” Horacio náà sọ pé: “Ipò náà mú kí ń tètè dàgbàdénú.”

Pípàdánù àwọn òbí ẹni jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ń dunni jù tí a lè ronú lé lórí. Síbẹ̀, mọ̀ dájú pé, pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, o lè ṣàṣeyọrí, kí o sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Mo Ṣe Ní Láti Wà Láìní Òbí?,” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, December 8, 1998.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

O lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni alàgbà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́