Ilà Ẹ̀rẹ̀kẹ́—‘Àmì Ìdánimọ̀’ Tí Ń Parẹ́ Lọ ní Nàìjíríà
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ
LÓWÙÚRỌ̀ ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọdún 1960 ń parí lọ, Danjuma tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà tọ bàbá rẹ̀ lọ, ó ní kí ó kọ ilà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Igala fi ń yangàn fún òun lọ́ràn-anyàn. Danjuma ronú pé òun kò lè fara da yẹ̀yẹ́ tí àwọn ẹlẹgbẹ́ òun nílé ẹ̀kọ́ ń fi òun ṣe mọ́, nítorí pé òun kò kọ ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Igala ṣì wà ní ọmọdé jòjòló tí ẹnu abẹ kò ní fò wọ́n láyà ni wọ́n máa ń bu ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ náà fún wọn, àwọn ọmọdékùnrin náà wo ilà náà bí àmì ìgboyà. Wọ́n ka àwọn tí kò bá bu ilà sí ojo ènìyàn tí ẹnu abẹ ń já láyà.
Ṣáájú àkókò yẹn, bàbá Danjuma kò gbà láti bu ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún ọmọ rẹ̀. Àmọ́, nítorí pé ọmọ náà fòòró ẹ̀mí rẹ̀ níwọ̀n bí ọmọ náà ti ní in lọ́kàn láti fi hàn pé òun gbóyà, bàbá náà mú abẹ lówùúrọ̀ ọjọ́ yẹn, ó sì bu ilà jíjinlẹ̀ mẹ́ta tó dà bí àbàjà sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọmọ náà.
Bàbá Danjuma mọ̀ pé ohun tó wà nídìí ilà náà kò fi bẹ́ẹ̀ kan ọ̀ràn ìgboyà. Ṣùgbọ́n pé ilà náà yóò wá di àmì ìdánimọ̀ nígbà tó bá jinná. Yóò jẹ́ ‘àmì ìdánimọ̀’ tí kò lè parẹ́, tí kò lè sọ nù, tí a kò sì lè yí. Yóò mú kí ọmọ rẹ̀ di ẹni tí àwọn ẹbí rẹ̀ dá mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tí ó mú kí ó tóótun láti gbádùn àwọn ẹ̀tọ́ àti àǹfààní tí ọmọ ilẹ̀ Igala ní. Àmọ́, ilà náà yóò tún fìyàtọ̀ sáàárín òun àti àwọn ẹ̀yà mìíràn tí iye wọ́n fi àádọ́ta lé ní igba ní Nàìjíríà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Áfíríkà nìkan kọ́ ni ọ̀ràn àmì àti ilà ti ń ṣẹlẹ̀, ó ti wà ní ilẹ̀ náà lọ́jọ́ tó ti pẹ́. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì náà, Herodotus, kọ̀wé nípa àwọn ará Caria tí ń gbé ní Íjíbítì ní ọ̀rúndún karùn-ún Ṣááju Sànmánì Tiwa pé: “[Wọ́n] fi abẹ kọ ilà síwájú orí wọn, nítorí èyí, wọ́n ń fi hàn pé àwọn kì í ṣe ará Íjíbítì bí kò ṣe àjèjì.” Àwọn ère orí tí a fi idẹ ṣe ní Ifẹ̀, Nàìjíríà, ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] ọdún sẹ́yìn ní ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kà sí ilà ẹ̀yà. Wọ́n tún máa ń ya ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn iṣẹ́ ọnà tí a gbẹ́ láyé àtijọ́ ní ilẹ̀ Ìbíní ní Nàìjíríà.
Kì í ṣe gbogbo ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ la kọ nítorí àtimọ ẹ̀yà ẹni. Tẹ́lẹ̀ rí, àwọn ilà kan jẹ mọ́ àwọn irúnmọlẹ̀ àti ẹ̀sìn, wọn kò sì tí ì yí padà. Àwọn mìíràn jẹ́ àmì ipò tí a wà níbìílẹ̀ ẹni. Aájò ẹwà ni a sì ń fi àwọn mìíràn ṣe.
Oríṣiríṣi ni ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ tí àwọn ògbóǹtagí olóòlà ládùúgbò máa ń kọ fún àwọn ènìyàn. Àwọn kan máa ń tẹ́ẹ́rẹ́, nígbà tí a máa ń bu àwọn kan jinlẹ̀ tí a óò sì fi ìka fẹ̀ wọ́n. Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń fi osùn kun ojú àpá náà. Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní irú ilà tí wọ́n máa ń kọ. Fún àpẹẹrẹ, ilà kọ̀ọ̀kan tí a kọ lóròó sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì ni a fi ń dá àwọn ọmọ Òǹdó mọ̀ lọ́kùnrin lóbìnrin. Àbàjà mẹ́ta la fi ń dá àwọn ọmọ Ọ̀yọ́ mọ̀. Bí àwọn tí wọ́n mọ ilà bá ti wo ojú ẹnì kan, wọn ó ti mọ ẹ̀yà, ìlú, tàbí ìdílé tí ẹni náà ti wá.
Oríṣiríṣi Ìṣarasíhùwà
Bí àwọn ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ olúkúlùkù ṣe yàtọ̀ síra gan-an, tí ìdí tí a fi kọ wọ́n sì ṣe yàtọ̀ síra ni ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn nípa wọn ṣe yàtọ̀ síra. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fi ilà wọn yangàn. Olóòtú ìròyìn kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn Daily Times ti Nàìjíríà sọ pé: “Àwọn kan ka ilà náà sí àmì ìfẹ́ ìbílẹ̀ wọn. Ó ń mú kí wọ́n nímọ̀lára pé àwọn jẹ́ ọmọ ọkọ.”
Èrò Jimoh, ọmọ Nàìjíríà kan, nìyẹn, tí ó sọ pé: “N kì í tijú nítorí ilà àbàjà Ọ̀yọ́ tí mo kọ, ó wulẹ̀ ń fi hàn pé ọmọ Yorùbá gidi tó wá láti ìlú Aláàfin ni mí ni.” Ó tún sọ bí ilà náà ṣe gba ẹ̀mí rẹ̀ là ní 1967, nígbà Ogun Abẹ́lé Nàìjíríà pé: “Wọ́n kógun ti ilé tí mo ń gbé nígbà yẹn, . . . wọ́n sì pa gbogbo [àwọn yòókù] níbẹ̀. Àwọn apààyàn náà kò ṣe mí ní jàǹbá nítorí ilà tí mo kọ.”
Àwọn mìíràn kórìíra ilà kíkọ. Tajudeen sọ nípa ilà tó kọ sójú pé: “N kò nífẹ̀ẹ́ sí i páàpáà, ègbé ni fún ọjọ́ tí wọ́n kọ ọ́ fún mi.” Ọmọdébìnrin ọ̀dọ́langba kan sì dúpẹ́ pé ìyá rẹ̀ kò jẹ́ kí wọ́n wa ilà sójú rẹ̀ ní kékeré. Ó sọ pé: “Ká ní wọ́n kọlà fún mi ni, màá gbèrò àtigbẹ̀mí ara mi.”
Kíkojú Ìfiniṣẹ̀sín
Wọ́n ń fi Danjuma, tí a mẹ́nu kan níbẹ̀rẹ̀, ṣẹ̀sín nítorí pé kò kọ ilà. Òdì kejì rẹ̀ ni ọ̀ràn náà sábà máa ń jẹ́. Ó lé ní ọdún márùndínláàádọ́ta sẹ́yìn tí G. T. Basden kọ nínú ìwé rẹ̀ Niger Ibos pé: “Àṣà kíkọlà ẹ̀rẹ̀kẹ́ àti fífín ara ti ń kásẹ̀ nílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin . . . ni inú wọn yóò dùn pé a kò kọ [ilà] fún wọn. Ohun tí ó kà sí ìyangàn nígbà tó wà láàárín àwọn ènìyàn ẹ̀yà rẹ̀ wá di ohun tí ń bí i nínú, nítorí pé ńṣe ni wọ́n ń fi í ṣẹ̀sín tí wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ ní àwọn apá ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.”
Bí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe rí lóde òní nìyẹn. Ajai, tó gba oyè nínú ẹ̀kọ́ ìrònú òun ìhùwà ní Yunifásítì Èkó, ṣèwádìí nípa ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ ní Nàìjíríà lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ó sọ pé: “Lóde òní, àwọn tí wọ́n kọ ilà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ mọ́, wọ́n sì máa ń pàdé àwọn ènìyàn tó máa ń fi wọ́n ṣẹ̀sín, pàápàá ní àwọn ìlú ńlá bí Èkó. Fún àpẹẹrẹ, a sábà máa ń gbọ́ tí àwọn ènìyàn máa ń pe ẹnì kan ní orúkọ oyè sójà náà, kọ́nẹ́ẹ̀lì, tí a óò sì wá rí i pé ẹni náà kì í ṣe sójà ṣùgbọ́n iye ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ bá iye okùn oyè tó wà lára aṣọ kọ́nẹ́ẹ̀lì nínú iṣẹ́ Ológun dọ́gba. A máa ń pe àwọn ènìyàn kan ní ẹkùn nítorí ilà tí wọ́n wà sẹ́rẹ̀kẹ́, a sì máa ń pe àwọn kan ní abomijé ayérayé lẹ́rẹ̀kẹ́. . . . Ro irú ohun tí èyí ń ṣe sí iyì tí ẹnì kan ní.”
Ó lè jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ ni a ti ń fara da ìpèníjà tó gbóná jù. Samuel nìkan ló kọ ilà ní kíláàsì rẹ̀. Ó sọ pé: “Wọ́n máa ń fi mí ṣẹ̀sín gan-an ní ilé ẹ̀kọ́. Àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ní ilé ẹ̀kọ́ máa ń pè mí ní ‘ọ̀nà rélùwéè’ àti ‘ọmọ tí ọ̀nà rélùwéè wà lójú rẹ̀ yẹn.’ Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń fi mí ṣẹ̀sín, wọn ó sì na ìka mẹ́ta sókè. Mo máa ń nímọ̀lára pé n kò já mọ́ nǹkankan.”
Báwo ló ṣe borí rẹ̀? Samuel ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Lọ́jọ́ kan, ẹ̀sín náà le gan-an débi pé mo tọ olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè lọ, mo sì bi í léèrè bó bá ṣeé ṣe láti pa ilà náà rẹ́. Ó ní iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi ń ṣàtúnṣe ibi tó bá dápàá lára ni wọ́n lè fi pa á rẹ́ àmọ́ kí n má ṣèyọnu nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló kọ ilà. Ó ní àìdàgbàdénú ló mú kí àwọn ojúgbà mi máa fi mí ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n tí a bá dàgbà, gbogbo ẹ̀sín náà yóò dópin. Ó tún sọ pé ilà náà kọ́ ló pinnu irú ẹni tí mo jẹ́ gan-an tàbí irú ẹni tí n ó dà.
“Ohun tó sọ yẹn mú inú mi dùn, n kò sì ní irú ìmọ̀lára tí kò dára tí mo ń ní nípa ilà náà mọ́. Àwọn ènìyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ nípa ilà mi mọ́. Kódà, tí wọ́n bá sọ nípa rẹ̀ pàápàá, ọ̀rọ̀ ẹ̀rín ni mo máa ń fi ṣe. Kò ba àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn jẹ́. Kì í ṣe ilà tí mo kọ ló ń mú kí àwọn ènìyàn fọ̀wọ̀ fún mi bíkòṣe ohun tí mo jẹ́.”
Àṣà Tí Ń Kógbá Wọlé
Nítorí pé àwọn ọmọdé la sábà máa ń kọ ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà tí wọ́n kọ ilà àdúgbò kò ní yíyàn tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ọ̀ràn náà. Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn náà bá bímọ, wọ́n gbọ́dọ̀ pinnu bóyá wọn ó kọ ilà fún àwọn ọmọ wọn.
Àwọn kan yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Times International ti Èkó ti sọ, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú kí wọ́n yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn kan ṣì kà á sí aájò ẹwà. Àwọn kan rò pé ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ lè jẹ́ kí a mọ àdúgbò tí ẹnì kan ti wá tó bá kan ọ̀ràn àtiṣe ojúrere. Ìdí mìíràn ni pé a ń lò ó lọ́nà ti àṣà láti fi mọ̀ láwùjọ pé ọmọ kan jẹ́ ọmọ ọkọ.”
Ṣùgbọ́n lóde òní, àwọn ìdí wọ̀nyí kò sọ ọ́ di ọ̀ràn-anyàn fún ọ̀pọ̀ òbí. Kódà, láàárín àwọn tí ń fi ilà wọn yangàn, díẹ̀ kéréje lára wọn ló ń fi ọmọ wọn sínú ewu gbígba ojú abẹ olóòlà. Èyí rí bẹ́ẹ̀ gan-an ní àwọn ìlú ńlá. Ìrora àti ewu kíkó àrùn pẹ̀lú ìfiniṣẹ̀sín àti ìyàsọ́tọ̀ tí ọmọ náà lè bá pàdé lọ́jọ́ iwájú jẹ́ kókó pàtàkì tí kì í jẹ́ kí àwọn òbí má kọ ilà fọ́mọ mọ́.
Ó ṣe kedere pé bí ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ ṣe gbalẹ̀, tí ó sì ṣètẹ́wọ́gbà tó ti ń kásẹ̀ nílẹ̀. Ó jọ pé lọ́jọ́ iwájú ní Nàìjíríà, ‘àmì ìdánimọ̀’ náà kò ní sí lójú àwọn ènìyàn mọ́ bíkòṣe nínú àpamọ́wọ́ wọn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ilà ẹ̀rẹ̀kẹ́ ń fi ẹ̀yà ẹni hàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àṣà ilà kíkọ ti ń parẹ́ lọ