Báwo Ni Ìwà Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà Ṣe Máa Kásẹ̀ Nílẹ̀?
ẸNI tó ń darí eré bọ́ọ̀lù ní pápá ìṣeré kan nílẹ̀ Sípéènì dá eré bọ́ọ̀lù náà dúró lójijì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn òǹwòran ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí agbábọ́ọ̀lù kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kamẹrúùnù débi pé agbábọ́ọ̀lù náà fẹ́ bínú kúrò lórí pápá. Nílẹ̀ Rọ́ṣíà, ńṣe ni ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn ará Éṣíà, àtàwọn ará Látìn Amẹ́ríkà túbọ̀ ń peléke sí i. Ìwà ìkà táwọn kan hù sáwọn ẹ̀yà míì níbẹ̀ pọ̀ gan-an lọ́dún 2004, ó sì tún wá pọ̀ sí i gan-an lọ́dún 2005 débi pé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó irínwó ó dín mẹ́fà [394]. Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìdámẹ́ta àwọn ará Éṣíà àtàwọn aláwọ̀ dúdú tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà pé ọ̀ràn kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ló jẹ́ kíṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn. Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi hàn pé ìṣòro náà kárí ayé.
Ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà fi ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà hàn burú jura wọn lọ, ó bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn tó máa ń bu èèyàn títí dórí àwọn tó máa ń gbìyànjú láti pa odindi ẹ̀yà run tí ìjọba á sì tì wọ́n lẹ́yìn. Kí ni olórí ohun tó ń fa ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà? Báwo la ó ṣe yẹra fún irú ìwà bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti máa retí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí gbogbo aráyé yóò máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà? Bíbélì jẹ́ ká lóye ọ̀rọ̀ yìí dáadáa.
Ìninilára àti Ìkórìíra
Bíbélì sọ pé: “Ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Abájọ tó fi jẹ́ pé ohun tó máa ń múnú àwọn kan dùn jù lọ ni pé kí wọ́n máa ni àwọn ẹlòmíràn lára. Bíbélì tún sọ pé: “Wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú; ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà.”—Oníwàásù 4:1.
Bíbélì tún fi hàn pé ìwà káwọn èèyàn kórìíra ẹ̀yà mìíràn jẹ́ ohun tó ti wà tipẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kejìdínlógún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Fáráò kan nílẹ̀ Íjíbítì pe Jékọ́bù tó jẹ́ Hébérù pé kí òun àti agbo ilé rẹ̀ tó pọ̀ gan-an wá máa gbé nílẹ̀ Íjíbítì. Nígbà tó yá, àwọn àjèjì yìí bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ gan-an, ẹ̀rú sì wá ń ba Fáráò mìíràn tó jẹ lẹ́yìn ìyẹn. Nítorí bẹ́ẹ̀, ìtàn náà sọ pé: “Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: ‘Ẹ wò ó! Àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pọ̀ níye jù wá, wọ́n sì jẹ́ alágbára ńlá jù wá lọ. Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a ta ọgbọ́n fún wọn, kí wọ́n má bàa di púpọ̀.‘ . . . Nítorí náà, wọ́n yan àwọn olórí tí ń fipá múni ṣòpò lé wọn lórí fún ète níni wọ́n lára nínú ẹrù ìnira tí wọ́n ń rù.” (Ẹ́kísódù 1:9-11) Àwọn ará Íjíbítì tún pàṣẹ pé gbogbo ọmọkùnrin táwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí gbọ́dọ̀ di pípa.—Ẹ́kísódù 1:15, 16.
Kí Ni Olórí Ohun Tó Fa Ìwà Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà?
Àwọn ẹ̀sìn ayé kò ṣe ohunkóhun láti paná ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kan ti ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà láti ta ko níni àwọn ẹlòmíràn lára, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ẹ̀sìn ayé máa ń gbárùkù ti àwọn aninilára. Bí nǹkan ṣe rí gẹ́lẹ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà kan nìyẹn, níbi tí òfin ti fàyè gba kí wọ́n máa tẹ àwọn aláwọ̀ dúdú lórí ba, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tún máa ń pa wọ́n láìbófinmu. Kódà àwọn òfin tó sọ pé àwọn aláwọ̀ funfun kò gbọ́dọ̀ fẹ́ aláwọ̀ dúdú wà níbẹ̀ títí di ọdún 1967. Bọ́rọ̀ ṣe rí ní Gúúsù Áfíríkà náà nìyẹn lákòókò tí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà gbòde kan níbẹ̀, àkókò yẹn làwọn ẹ̀yà kan tí kò pọ̀ rárá gbé onírúurú òfin kalẹ̀ láti fi hàn pé àwọn lọ̀gá, títí kan èyí tó sọ pé aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ dúdú kò gbọ́dọ̀ fẹ́ ara wọn. Nínú gbogbo àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu kàn yìí, àwọn kan tí kò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá wà lára àwọn tó ń ṣagbátẹrù ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà yìí.
Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ olórí ohun tó fa ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Ó ṣàlàyé ìdí táwọn ẹ̀yà kan fi máa ń ni àwọn ẹ̀yà mìíràn lára. Ó sọ pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni. Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.” (1 Jòhánù 4:8, 20) Gbólóhùn yìí jẹ́ ká mọ olórí ohun tó fà á táwọn ẹ̀yà kan fi máa ń kórìíra àwọn ẹ̀yà mìíràn. Àwọn èèyàn ń hu ìwà yìí, yálà àwọn tó pe ara wọn ní onísìn ni o tàbí àwọn tí kì í ṣe ẹ̀sìn kankan. Ohun tó sì fà á ni pé wọn ò mọ Ọlọ́run, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ìmọ̀ Ọlọ́run ni Olórí Ohun Tó Lè Mú Kí Gbogbo Ẹ̀yà Wà Níṣọ̀kan
Báwo ni mímọ Ọlọ́run kéèyàn sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe lè mú kí gbogbo ẹ̀yà wà níṣọ̀kan? Ìmọ̀ wo ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe ìpalára fáwọn tó dà bíi pé wọ́n yàtọ̀ sí wọn? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni Bàbá gbogbo èèyàn. Ó ní: “Ní ti gidi, fún àwa, Ọlọ́run kan ní ń bẹ, Baba, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ohun gbogbo ti wá.” (1 Kọ́ríńtì 8:6) Ó tún sọ síwájú sí i pé: “Láti ara ọkùnrin kan ni ó sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 17:26) Nípa bẹ́ẹ̀, tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni gbogbo èèyàn jẹ́ síra wọn.
Ńṣe ló yẹ kí gbogbo ẹ̀yà máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run jẹ́ káwọn wà láàyè, àmọ́ gbogbo wọn ló tún ní ohun kan tó yẹ kí wọ́n kábàámọ̀ rẹ̀ o, ìyẹn ni pé ẹni tó jẹ́ baba ńlá wọn kò ṣe ohun tó dáa. Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé.” Nípa bẹ́ẹ̀, “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23; 5:12) Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó dá ohun gbogbo lónírúurú, kò sí ẹni méjì tó rí bákan náà gẹ́lẹ́. Síbẹ̀, Ọlọ́run ò dá ẹ̀yà kankan lọ́nà tí wọ́n á fi rò pé àwọn sàn ju àwọn mìíràn lọ. Èrò tó gba ayé kan, tó ń mú kí ẹnì kan máa rò pé ẹ̀yà tòun sàn ju ẹ̀yà tàwọn mìíràn lọ, yàtọ̀ pátápátá sóhun tí Ìwé Mímọ́ sọ. Láìsí àní-àní, ìmọ̀ tí à ń gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run máa ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn wà níṣọ̀kan.
Bí Ọlọ́run Ṣe Bìkítà fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
Àwọn kan rò pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń ṣojúsàájú nítorí pé ó ṣojú rere sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì tún kọ́ wọn pé kí wọ́n má ṣe bá àwọn orílẹ̀-èdè yòókù da nǹkan pọ̀. (Ẹ́kísódù 34:12) Nígbà kan, Ọlọ́run yan orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí àkànṣe ìní rẹ̀ nítorí ìgbàgbọ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Ábúráhámù tó jẹ́ baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì ìgbàanì, òun ló ń yan àwọn tó ń darí wọn tó sì tún fún wọn láwọn òfin tí wọ́n á máa tẹ̀ lé. Lákòókò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ lé ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí, àwọn èèyàn yòókù rí i pé àwọn ẹ̀yà tí Ọlọ́run ń ṣàkóso yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹ̀yà tí èèyàn ń ṣàkóso wọn láwọn ibòmíràn. Jèhófà tún kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì pé rírúbọ ṣe pàtàkì kí àjọṣe àárín èèyàn àti Ọlọ́run lè dán mọ́rán padà. Nípa báyìí, bíbá tí Jèhófà bá Ísírẹ́lì lò yẹn ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè láǹfààní. Ìyẹn sì bá ohun tó sọ fún Ábúráhámù mu gẹ́ẹ́, ó ní: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.
Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Júù ni Ọlọ́run tún fún láǹfààní láti gba àkọsílẹ̀ mímọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì tún láǹfààní láti jẹ́ orílẹ̀-èdè tá a bí Mèsáyà sí. Síbẹ̀ Ọlọ́run ṣe èyí fún àǹfààní gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé. Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí Ọlọ́run fún àwọn Júù ní àwọn àlàyé tó múnú ẹni dùn nínú, èyí tó sọ nípa bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí gbogbo ẹ̀yà bá rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. Ó ní: “Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà àti sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀‘ . . . Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́. Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:2-4.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù Kristi fúnra rẹ̀ wàásù fáwọn Júù, ó tún sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Kò sí orílẹ̀-èdè kan tí kò ní gbọ́ ìhìn rere náà. Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa gan-an lélẹ̀ nínú bó ṣe ń bá gbogbo ẹ̀yà lò láìṣe ojúṣàájú. “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Àwọn òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì tún fi hàn pé ó bìkítà fún gbogbo orílẹ̀-èdè. Kíyè sí i pé, kì í ṣe pé káwọn àjèjì máa gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ni Òfin náà sọ, ó tún sọ pé: “Kí àtìpó tí ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín dà bí ọmọ ìbílẹ̀ yín; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ, nítorí ẹ di àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì.” (Léfítíkù 19:34) Ọ̀pọ̀ lára àwọn òfin Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa fi inúure hàn sáwọn àjèjì tó ń gbé láàárín wọn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Bóásì, baba ńlá Jésù, rí àjèjì obìnrin kan tó jẹ́ tálákà níbi tó ti ń pèéṣẹ́, ó ṣe ohun tó bá ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run kọ́ ọ mu. Ó rí i dájú pé àwọn olùkórè fi ọ̀pọ̀ ọkà sílẹ̀ fún obìnrin náà láti kó lọ sílé.—Rúùtù 2:1, 10, 16.
Jésù Kọ́ Wa Láti Jẹ́ Onínúure
Jésù fi ìmọ̀ Ọlọ́run hàn wá ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Ó jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ onínúure sáwọn èèyàn tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tiwọn. Ìgbà kan wà tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá obìnrin ará Samáríà kan fọ̀rọ̀ wérọ̀. Àwọn ará Samáríà jẹ́ ẹ̀yà kan tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù kórìíra, ìyẹn ló mú kó ya obìnrin náà lẹ́nu. Lákòókò tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀ yìí, Jésù fi tìfẹ́tìfẹ́ ran obìnrin náà lọ́wọ́ láti mọ ohun tó lè ṣe tí yóò fi jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 4:7-14.
Jésù tún kọ́ wa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn tó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn nígbà tó sọ àkàwé ará Samáríà onínúure. Ọkùnrin yìí rí Júù kan táwọn ọlọ́ṣà dá lọ́nà tí wọ́n sì ṣá lọ́gbẹ́ gan-an. Ará Samáríà yìí ì bá ti rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé: ‘Kí ni mo fẹ́ ran Júù lọ́wọ́ fún? Àwọn Júù tó jẹ́ pé wọ́n kórìíra àwọn èèyàn mi.’ Àmọ́ Jésù jẹ́ ká rí i pé èrò tí ará Samáríà yẹn ní nípa àwọn àjèjì yàtọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn mìíràn tí kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkùnrin tí wọ́n ṣá lọ́gbẹ́ yìí, síbẹ̀ “àánú ṣe” ará Samáríà náà, ó sì ran Júù yìí lọ́wọ́ gan-an. Jésù parí àkàwé yìí nípa sísọ pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa ṣe bákan náà pẹ̀lú.—Lúùkù 10:30-37.
Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́ àwọn tó fẹ́ kí inú Ọlọ́run dùn sáwọn ni pé kí wọ́n yí ìwà wọn padà, kí wọ́n sì máa fara wé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá àwọn èèyàn lò. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a, níbi tí kò ti sí Gíríìkì tàbí Júù, ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, Síkítíánì . . . Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:9-14.
Ǹjẹ́ Ìmọ̀ Ọlọ́run Máa Ń Yí Àwọn Èèyàn Padà?
Ǹjẹ́ mímọ Jèhófà Ọlọ́run máa ń mú káwọn èèyàn yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá àwọn ẹ̀yà mìíràn lò padà? Wo àpẹẹrẹ ará Éṣíà kan tó wá gbé ní Kánádà, inú rẹ̀ kò dùn rárá nígbà táwọn ará ibẹ̀ ń yẹra fún un tí wọn kò sì bá a da nǹkan pọ̀. Nígbà tó yá, ó rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Níkẹyìn, ó kọ̀wé ìmọrírì sí wọn pé: ‘Aláwọ̀ funfun tó jẹ́ èèyàn àtàtà àti onínúure ni yín. Nígbà tí mo rí i pé ẹ yàtọ̀ pátápátá sáwọn aláwọ̀ funfun yòókù, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tó lè fà á. Mo rò ó títí, mo wá rí i pé Ẹlẹ́rìí Ọlọ́run ni yín. Nǹkan kan ní láti wà nínú Bíbélì. Nígbà tí mo dé ìpàdé yín, mo rí àwọn èèyàn funfun, àwọn èèyàn dúdú àtàwọn èèyàn pupa tí ọkàn gbogbo wọn ní àwọ̀ kan náà, ìyẹn ni pè kò sí ìkórìíra kankan lọ́kàn wọn, nítorí pé arákùnrin àti arábìnrin ni gbogbo wọn. Mo ti wá mọ ẹni tó jẹ́ kí wọ́n di irú èèyàn àtàtà bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run yín ni.’
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tí “ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 11:9) Kódà lákòókò tá a wà yìí, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń nímùúṣẹ, nítorí pé ìjọsìn tòótọ́ ti mú kí àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n ti ń lọ sí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù báyìí “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” wà níṣọ̀kan. (Ìṣípayá 7:9) Wọ́n ń retí àkókò tí ìfẹ́ yóò rọ́pò ìkórìíra láàárín àwọn èèyàn káàkiri ayé. Èyí á sì wá mú kí ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù nímùúṣẹ láìpẹ́, ìlérí náà ni pé: “A ó . . . bù kún gbogbo àwọn ìdílé ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 3:25.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Òfin Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì tó ń gbé láàárín wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àkàwé ará Samáríà onínúure?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ọlọ́run ò dá ẹ̀yà kankan lọ́nà tí wọ́n á fi rò pé àwọn sàn ju àwọn mìíràn lọ