Èéṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí O Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ?
ÌYÈ ayérayé sinmi lórí ìfẹ́ wa fún Ọlọrun àti aládùúgbò. A sọ kókó yẹn jáde nígbà ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ kan tí ó wáyé ní nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn.
Ọkùnrin Ju kan tí ó mọ Òfin Mose dáradára béèrè lọ́wọ́ Jesu Kristi pé: “Kí ni èmi óò ṣe kí èmi kí ó lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Jesu fèsìpadà pé: “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? bí ìwọ ti kà á?” Ní fífa ọ̀rọ̀ yọ nínú Òfin náà, ọkùnrin náà wí pé: “Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ; àti ẹnìkejì rẹ bi araàrẹ.” “Ìwọ dáhùn rere,” ni Jesu wí. “Ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”—Luku 10:25-28.
Nígbà yẹn, olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Jesu béèrè pé: “Ta ni ha sì ni ẹnìkejì mi?” Dípò dídáhùn tààràtà, Jesu sọ ìtàn alákàwé kan nípa ọkùnrin Ju kan tí wọ́n dá lọ́nà, tí wọ́n lù, tí wọ́n sì fi sílẹ̀ ní àpaàpatán. Àwọn Ju méjì ń kọjá lọ—lákọ̀ọ́kọ́ àlùfáà kan àti lẹ́yìn náà ọmọ Lefi kan. Àwọn méjèèjì wo ipò Ju ẹlẹgbẹ́ wọ́n ṣùgbọ́n wọn kò ṣe ohun kan láti ràn án lọ́wọ́. Ará Samaria kan wá wá lẹ́yìn náà. Bí àánú ti ṣe é, ó di ojú ọgbẹ́ Ju tí a ṣálọ́gbẹ́ náà, ó mú un lọ sí ilé-èrò kan, ó sì pèsè fún àbójútó rẹ̀ síwájú síi.
Jesu béèrè lọ́wọ́ olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ pe: “Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, ta ni ìwọ rò pé í ṣe ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?” Ní kedere, aláàánú ará Samaria náà ni. Jesu tipa báyìí fihàn pé ìfẹ́ aládùúgbò tòótọ́ tayọ àwọn ààlà àwùjọ ẹ̀yà-ìran.—Luku 10:29-37.
Àìní Ìfẹ́ Aládùúgbò
Lónìí ìkóguntini tí ń ga síi wà láàárín àwọn ènìyàn àwùjọ ẹ̀yà-ìran ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Fún àpẹẹrẹ, láìpẹ́ yìí àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ alátìlẹyìn fún Nazi ní Germany la ọkùnrin kan mọ́lẹ̀ wọ́n sì fi bàtà àwọ̀dórúnkún wíwúwo wọn rìn lọ rìn bọ̀ lórí rẹ̀, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kán gbogbo egungun ìhà rẹ̀ tán. Wọ́n wá da ohun mímu ọlọ́tí líle púpọ̀ gan-an lé e lórí wọ́n sì dáná sun ún. Ọkùnrin tí wọ́n fi sílẹ̀ láti kú náà ni wọ́n gbóguntì nítorí pé wọ́n lérò pé Ju ni. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn kan, ilé kan nítòsí Hamburg ní a ju bọ́m̀bù sí, ní sísun àwọn ènìyàn mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tọ̀ ìlú Turkey jóná—ọ̀kan lára wọn sì jẹ́ ọmọdébìnrin ọlọ́dún mẹ́wàá.
Ní ilẹ̀ Balkan àti ìlà-oòrùn jíjìnnà, àwọn ogun àwùjọ ẹ̀yà-ìran ń gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí. Àwọn mìíràn kú nínú ìkọlura láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Bangladesh, India, àti Pakistan. Ní Africa pẹ̀lú, ìforígbárí láàárín ẹ̀yà àti ìran gba ẹ̀mí àwọn mìíràn síbẹ̀.
Ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn ni irú ìwà-ipá bẹ́ẹ̀ ti dẹ́rùbà tí wọn kì yóò sì ṣe ohun kan láti ṣèpalára fún aládùúgbò wọn. Níti tòótọ́, àwọn ìwọ́de gbígbòòrò ní Germany ti dẹ́bi fún ìwà-ipá àwùjọ ẹ̀yà-ìran níbẹ̀. Síbẹ̀, The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Àwọn mẹ́ḿbà èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ti gbogbo àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé wo ọ̀nà ìgbésí-ayé tiwọn gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó sàn ju ti àwọn aládùúgbò tí ó súnmọ́ wọn tímọ́tímọ́ pàápàá.” Irú àwọn ojú-ìwòye báwọ̀nyí ń ṣèdíwọ́ fún ìfẹ́ aládùúgbò. Ǹjẹ́ a ha lè ṣe ohunkóhun nípa èyí bí, pàápàá níwọ̀n bí Jesu ti sọ pé ìwàláàyè sinmi lórí ìfẹ́ fún Ọlọrun àti aládùúgbò?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Cover: Jules Pelcog/Die Heilige Schrift
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Aláàánú Ará Samaria/The Doré Bible Illustrations/Dover Publications, Inc.