ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 1/8 ojú ìwé 14-15
  • Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Agbára Tí Ń Ṣiṣẹ́
  • Onírúurú Ọ̀nà Ti Ẹ̀mí Mímọ́ Gbà Ń Ṣiṣẹ́
  • Ìsapá Agbára Ọlọ́run Lórí Wa
  • Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run?
    Jí!—2006
  • Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Kristẹni ní Ọ̀rúndún Kìíní ó Sì Ń Darí Àwa Náà Lónìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 1/8 ojú ìwé 14-15

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run?

“Wàyí o, nígbà tí a batisí gbogbo ènìyàn, a batisí jésù pẹ̀lú, bí ó sì ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ní ìrí ti ara bí àdàbà bà lé e, ohùn kan sì jáde wá láti inú ọ̀run pé: ‘Ìwọ ni ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.’”—Lúùkù 3:21, 22.

NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá àwùjọ àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí sọ̀rọ̀ ní Gíríìsì ìgbàanì, ó pe Ọlọ́run ní “Olúwa ọ̀run àti ti ilẹ̀ ayé.” Pọ́ọ̀lù sọ pé, Ọlọ́run yìí, tí ó “dá ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀,” tí ó sì “fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” (Ìṣe 17:24-28) Báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣàṣepé gbogbo èyí? Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ ni.

Bíbélì tún ṣàlàyé pé, Ọlọ́run ní “ọ̀pọ̀ yanturu okun . . . alágbára gíga, àti . . . pé òun ní okun inú nínú agbára.” (Aísáyà 40:26) Dájúdájú, Ọlọ́run ló dá gbogbo àgbáálá ayé, tí ń fi okun alágbára gíga àti agbára rẹ̀ hàn.

Agbára Tí Ń Ṣiṣẹ́

Kò ní fi bẹ́ẹ̀ tọ́ láti sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ni agbára Ọlọ́run. Nítorí pé agbára lè fara sin, tàbí kí ó wà nínú ẹnì kan tàbí nínú nǹkan kan láìṣiṣẹ́, bí irú agbára tí a lo iná mànàmáná láti fi pa mọ́ sínú bátìrì kan tí a kò lò. Àmọ́, Ìwé Mímọ́ fi ẹ̀mí Ọlọ́run hàn bí èyí tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́, bí ohun kan tó dà bí agbára iná mànàmáná tí ń lọ síwá sẹ́yìn nínú bátìrì tí a ń lò lọ́wọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Nítorí náà, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni agbára tí ó fi ń ṣe nǹkan, ìyẹn ni ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀.

Nígbà mìíràn, Bíbélì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́ bí ohun tí ń dá ṣe àwọn iṣẹ́ kan fúnra rẹ̀ tàbí tí ó wà ní àgbègbè mìíràn yàtọ̀ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 28:19, 20; Lúùkù 3:21, 22; Ìṣe 8:39; 13:4; 15:28, 29) Àwọn tó ka irú àwọn àyọkà bẹ́ẹ̀ gbà pé ẹ̀mí mímọ́ dá wà lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí Ọlọ́run. Èé ṣe tí Ìwé Mímọ́ fi lo irú ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹni kan tí ó dá wà lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí Ọlọ́run ni?

Ọlọ́run Olódùmarè wà ní ipò tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀. Òun jẹ́ ẹ̀mí, agbára ìmòye wa sì kéré ju èyí tí ó lè rí i lọ. (Jòhánù 4:24) Bíbélì sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ń gbé nínú ọ̀run, ó sì ń wo ìran ènìyàn láti ibẹ̀. (Sáàmù 33:13, 14) Èyí yéni. Ẹlẹ́dàá gbọ́dọ̀ lọ́lá ju àwọn irin iṣẹ́ rẹ̀ lọ. Ó mọ ìlò wọn dáadáa, ó ń fi wọ́n ṣiṣẹ́, ó ṣe wọ́n, ó sì ń ṣàkóso wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

Láti inú ibùgbé rẹ̀ tí a kò lè fojú rí, Ọlọ́run lè mú kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà àti níbikíbi. Nítorí náà, òun kò ní láti wà ní ibi tí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ bá ti ń ṣiṣẹ́. Ó lè rán ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ kan. (Sáàmù 104:30) Èyí lè rọrùn láti lóye fún àwọn ènìyàn òde òní tí wọ́n ní ìhùmọ̀ abẹ́rọṣiṣẹ́ látòkèèrè lọ́wọ́ láti darí àwọn ẹ̀rọ tí a ń lò nínú ilé. Lónìí, a mọ̀ nípa agbára àwọn ipá tí a kò lè fojú rí tí àwọn nǹkan bí iná mànàmáná tàbí iná tí ń jó fòfò ń ní. Bákan náà, Ọlọ́run lè ṣe ohunkóhun tí ó bá fẹ́ ṣe láìkúrò lójú kan nípasẹ̀ ipá mímọ́ tàbí ẹ̀mí rẹ̀ tí a kò lè fojú rí.—Aísáyà 55:11.

Èrò yìí ti lè ṣòro láti lóye ní àkókò tí a kọ Bíbélì. Láìsí àní-àní, sísọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́ bí ipá tí ó dá nìkan wà ran àwọn òǹkàwé lọ́wọ́ láti lóye bí Ọlọ́run ṣe ń lo agbára rẹ̀ bí òun fúnra rẹ̀ kò tilẹ̀ sí ní ibi ti nǹkan náà ti ń ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Bíbélì bá ń sọ nípa ẹ̀mí mímọ́ pé ó ṣe èyí tàbí ìyẹn, ohun tó ń sọ ni pé, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti ṣetán láti dáwọ́lé nǹkan kan tàbí láti fi agbára rẹ̀ mú kí ẹnì kan tàbí àwọn nǹkan kan ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

Onírúurú Ọ̀nà Ti Ẹ̀mí Mímọ́ Gbà Ń Ṣiṣẹ́

Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ṣẹ̀dá gbogbo ohun abẹ̀mí àti èyí tí kò lẹ́mìí. (Sáàmù 33:6) Ọlọ́run tún lò ó láti fi àkúnya omi pa ìran ènìyàn tó jẹ́ oníwà ipá àti aláìní ìrònúpìwàdà run. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-22) Ipá ìṣiṣẹ́ yìí kan náà ni Ọlọ́run lò láti ta àtaré ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ tí ó níye lórí gan-an sínú ilé ọlẹ̀ Màríà wúńdíá tí ó jẹ́ Júù.—Lúùkù 1:35.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ̀mí náà máa ń fún àwọn ènìyàn lágbára láti fìgboyà sọ òtítọ́ láìṣojo níwájú àwọn ọ̀tá, tí èyí sì sábà máa ń já sí fífi ẹ̀mí wọn wewu. (Míkà 3:8) Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wé mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ pàápàá tún wà nínú Bíbélì, níbi tí a ti fún àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin ni àkànṣe òye tàbí ìmọ̀ nípasẹ̀ ipá yìí. Níwọ̀n bí kò ti sí ẹ̀dá ènìyàn tí ó lè sọ bí ọjọ́ iwájú yóò ṣe rí ní pàtó, èyí jẹ́ ọ̀nà títayọ kan tí ẹ̀mí náà ń gbà ṣiṣẹ́.—2 Pétérù 1:20, 21.

Ẹ̀mí náà tún lè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan lágbára lọ́nà ìyanu. Fún àpẹẹrẹ, nípasẹ̀ ipá yìí, Jésù darí àwọn ipá ìṣẹ̀dá, ó ṣe ìwòsàn, ó tún jí òkú dìde pàápàá. (Lúùkù 4:18-21; 8:22-26, 49-56; 9:11) Ẹ̀mí náà ni a lò láti ṣètò àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí ó sì fún wọn lágbára láti sìn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí fún Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé.—Ìṣe 1:8; 2:1-47; Róòmù 15:18, 19; 1 Kọ́ríńtì 12:4-11.

Ìsapá Agbára Ọlọ́run Lórí Wa

Ó ha ṣeé ṣe fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọn jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí láti gba agbára láti inú orísun tí kò láàlà yìí bí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọlọ́run ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ tí ó tó fún wọn láti lóye ìfẹ́ rẹ̀ kí wọ́n sì ṣe é. Ó ń fi ẹ̀mí rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n ń fi òtítọ́ inú béèrè fún un nípasẹ̀ àdúrà, tí wọ́n ní ìsúnniṣe tí ó tọ́ látọkànwá, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (1 Kọ́ríńtì 2:10-16) Ẹ̀mí yẹn lè fún àwọn ènìyàn aláìpé ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” tí yóò mú kí wọ́n lè fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run láìka àwọn ìdènà sí. Dájúdájú, ó jẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run láti rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà, kí ó sì máa wà pẹ̀lú wọn títí láé.—2 Kọ́ríńtì 4:7; Lúùkù 11:13; Ìṣe 15:8; Éfésù 4:30.

Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò lo okun onípá gíga yìí láti fòpin sí àìṣèdájọ́ òdodo àti ìjìyà tí ó wà nínú ayé búburú yìí, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ orúkọ ńlá rẹ̀ di mímọ́. Ẹ̀mí mímọ́ yóò ní ipa tí ó dára lórí gbogbo àgbáyé, èso rẹ̀ yóò sì hàn kedere fún gbogbo ènìyàn láti rí, èyí yóò sì fi ògo fún Olùdásílẹ̀ rẹ̀.—Gálátíà 5:22, 23; Ìṣípayá 21:3, 4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́