ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/06 ojú ìwé 30-31
  • Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?
  • Dida Ẹmi Mimọ Mọyatọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • ‘Ni Orukọ Ẹmi Mímọ́’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ẹ̀mí Mímọ́—Ipá Agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun
    Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 7/06 ojú ìwé 30-31

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run?

KÍ NI ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run? Nínú àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ Bíbélì, ó sọ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, tá a tún túmọ̀ sí “ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run,” “ń lọ síwá-sẹ́yìn lójú omi.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Bíbélì sọ pé nígbà tí Jésù ń ṣèrìbọmi, Ọlọ́run wà ní “ọ̀run,” àti pé ẹ̀mí mímọ́ “ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá” sórí Jésù. (Mátíù 3:16, 17) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù sọ pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ “olùrànlọ́wọ́.”—Jòhánù 14:16.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, àtàwọn míì bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti mú káwọn kan gbà pé bí Ọlọ́run, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ṣe jẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan náà ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe jẹ́ ẹnì kan. Kódà, láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn kan lára àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì tọ́mọ ìjọ pọ̀ sí jù lọ ti máa ń sọ pé ẹnì kan ni ẹ̀mí mímọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ táwọn olórí ẹ̀sìn ti ń fi ẹ̀kọ́ yìí kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn, ọ̀pọ̀ lára wọn lọ̀ràn náà ò tíì yé, àwọn kan ò sì gba ẹ̀kọ́ náà gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tó wáyé láìpẹ́ yìí fi hàn pé bá a bá kó ọgọ́rùn-ún èèyàn jọ lára àwọn tá a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, mọ́kànlélọ́gọ́ta ló gbà gbọ́ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run “kò dá wà bí ẹnì kan, ńṣe ló wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ agbára Ọlọ́run àti àpẹẹrẹ pé Ọlọ́run wà níbì kan.” Àmọ́, kí ni Bíbélì sọ?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Láìka ohun táwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni sí, ó di dandan kí ẹni tó ń fi àìṣẹ̀tàn ka Bíbélì gbà pé ẹ̀mí mímọ́ yàtọ̀ sí báwọn olórí ẹ̀sìn ṣe ń ṣàlàyé ẹ̀ fáwọn ọmọ ìjọ pé ó jẹ́ ẹnì kan. Gbé àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì yìí yẹ̀ wò ná.

1. Nígbà tí Màríà, ìyá Jésù lọ sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì tó jẹ́ ìbátan rẹ̀, Bíbélì sọ pé ọmọ inú ilé ọlẹ̀ Èlísábẹ́tì sọ kúlú, “Èlísábẹ́tì sì kún fún ẹ̀mí mímọ́.” (Lúùkù 1:41) Ṣó wá mọ́gbọ́n dání láti sọ pé ẹnì kan á “kún” fún ẹlòmíì?

2. Nígbà tí Jòhánù Oníbatisí ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé Jésù ni ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn òun, ó ṣàlàyé fún wọn pé: “Èmi, ní tèmi, ń fi omi batisí yín . . . , ṣùgbọ́n ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi lágbára jù mí lọ, ẹni tí èmi kò tó láti bọ́ sálúbàtà rẹ̀ kúrò. Ẹni yẹn yóò fi ẹ̀mí mímọ́ . . . batisí yín.” (Mátíù 3:11) Bó bá jẹ́ pé ẹnì kan ni ẹ̀mí mímọ́ ni, kò dájú pé Jòhánù á sọ pé a ó fi í batisí àwọn èèyàn.

3. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù lọ sílé ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù kan àti ìdílé rẹ̀, ó sọ pé Ọlọ́run ti fi “ẹ̀mí mímọ́ àti agbára” yan Jésù. (Ìṣe 10:38) Láìpẹ́ sígbà náà, “ẹ̀mí mímọ́ bà lé” àwọn ará ilé ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lèyí ṣe ní kàyéfì “nítorí pé ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ ni a ń tú jáde sórí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú.” (Ìṣe 10:44, 45) A tún rí i níbí yìí pé èdè tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe ẹ̀mí mímọ́ ò jọ èyí tá a fi lè perí ẹnì kan.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí kì í ṣe èèyàn bíi pé èèyàn ló jẹ́. Lára àwọn àpẹẹrẹ tá a rí tọ́ka sí ni bó ṣe sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, ẹ̀ṣẹ̀, ikú àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí. (Òwe 8:1-9:6; Róòmù 5:14, 17, 21; 6:12) Jésù alára sọ pé “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀,” tàbí rere tó máa ń wá látinú fífi ọgbọ́n ṣe nǹkan. (Lúùkù 7:35) Ó dájú pé ọgbọ́n kì í ṣe ẹnì kan tó bímọ ní tòótọ́! Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan kìkì nítorí pé Bíbélì máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ láwọn ìgbà míì pé ó ṣe ohun tá a retí pé kéèyàn ṣe.

Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?

Bíbélì sọ pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ agbára Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́. Nítorí èyí, Bíbélì kan tó túmọ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù lọ́nà tó péye, pe ẹ̀mí mímọ́ ní “ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Kò síbi téèyàn ṣí nínú Bíbélì tí kò bá àlàyé tó fara mọ́ èrò yìí pàdé.—Míkà 3:8; Lúùkù 1:35; Ìṣe 10:38.

Èyí táwọn èèyàn sì máa ń sọ ní gbogbo gbòò pé kò síbi tí Ọlọ́run ò sí nígbàkigbà yẹn ò bá Bíbélì mu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí, ló jẹ́ “ibi àfìdímúlẹ̀” tàbí ibùgbé rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 8:39; 2 Kíróníkà 6:39) Ìwé Mímọ́ tún sọ̀rọ̀ nípa ibi pàtó kan tí Ọlọ́run ń gbé tó sì tún jẹ́ pé ibẹ̀ ni “ìtẹ́” rẹ̀ wà. (1 Àwọn Ọba 22:19; Aísáyà 6:1; Dáníẹ́lì 7:9; Ìṣípayá 4:1-3) Àmọ́ ṣá o, láti “ibi àfìdímúlẹ̀” yìí, kò sí kọ́lọ́fín ibi tí kò lè nawọ́ ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ yìí dé ní gbogbo ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí tó fi dé gbogbo orí ilẹ̀ ayé ńbí.—Sáàmù 139:7.

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún lọ́dún 1879, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, Charles L. Ives, ṣàpèjúwe tó bá a mu wẹ́kú nípa bí Ọlọ́run ṣe lè lo agbára rẹ̀ láti ibi pàtó tó wà. Ó kọ̀wé pé: “Bí àpẹẹrẹ, a lè sọ pé, ‘Ṣí wíńdò yẹn, kí oòrùn lè wọlé wá.’ Kì í ṣe pé a ní in lọ́kàn pé kí oòrùn wọlé wá bí èèyàn ẹlẹ́ran ara, ṣùgbọ́n kí ìtànṣán tó ti inú oòrùn jáde wá tàn sínú ilé là ń sọ.” Bákan náà, kò sídìí fún Ọlọ́run láti máa rìnrìn àjò lọ sáwọn ibi tó bá ti fẹ́ lo ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀. Ẹnu kó lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lè ṣiṣẹ́ dé gbogbo ibi táwọn ẹ̀dá Ọlọ́run wà ni. Bó o bá mọ̀ ní ti gidi pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ lílágbára tí Ọlọ́run ń lò, wàá ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà á mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?

◼ Ṣé Bíbélì fi kọ́ni pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan?—Ìṣe 10:44, 45.

◼ Kí ni ẹ̀mí mímọ́?—Jẹ́nẹ́sísì 1:2.

◼ Ibo ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè ṣiṣẹ́ dé?—Sáàmù 139:7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́