Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Èmi àti Ẹni Tí Ọ̀nà Rẹ̀ Jìn Ṣe Lè Máa Fẹ́ra Wa Sọ́nà?
“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kó àwọn kan tí wọ́n wá ṣe ìpàdé àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà padà lọ sí òtẹ́ẹ̀lì tí a fi wọ́n wọ̀ sí ni. Mo ti fẹ́ máa lọ sílé, àmọ́ bí mo ṣe fẹ́ máa lọ ni àwọn mìíràn tún yọ. Nítorí náà, mo dúró láti bá wọn sọ̀rọ̀, ibẹ̀ ni mo ti rí Odette. A tún rìn pàdéra lákòókò mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀ náà. A pinnu láti máa kọ̀wé síra, lẹ́yìn ọdún mélòó kan tí a ti di ojúlùmọ̀ ara wa nípasẹ̀ lẹ́tà, a bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́rasọ́nà.”—Tony.
AYÉ ti lu jára. Ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, ètò ìrìnnà ojú òfuurufú tí kò wọ́n, dídé tí tẹlifóònù dé ibi gbogbo lágbàáyé, ètò ìfìwéráńṣẹ́ ayára-bí-àṣá, àti ìsokọ́ra alátagbà Internet ti mú kí àwọn ohun tuntun kan wá ṣeé ṣe ní ti ọ̀ràn ìfẹ́. Àti pé ní ọ̀nà púpọ̀, èrò fífẹ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jìn tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà pàápàá sọ́nà lè dà bí èyí tó fani mọ́ra—pàápàá tó bá jọ pé àtirí ẹnì kan fẹ́ nítòsí kò ní lè ṣeé ṣe.
Fífẹ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jìn sọ́nà ti jẹ́ ìbùkún fún àwọn kan. Tony sọ pé: “A ti ń bá ìgbéyàwó aláyọ̀ bọ̀ fún ọdún mẹ́rìndínlógún.” Àwọn kan tilẹ̀ lè jiyàn pé fífẹ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jìn sọ́nà ní àǹfààní jíjẹ́ kí àwọn méjèèjì mọ ara wọn láìsí pé ẹwà gbé wọn dè. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ohun yòówù kí àǹfààní ibẹ̀ jẹ́, fífẹ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jìn sọ́nà máa ń ní àwọn ìpèníjà àrà ọ̀tọ̀ kan nínú.
Mímọ Ara Yín
Ó dára jù láti mọ̀ nípa ẹni tí o ń ronú àtifẹ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọkọ kan tí ń jẹ́ Frank ṣe sọ láti inú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun fúnra rẹ̀, “kò rọrùn láti mọ ẹni tó jẹ́ gan-an, ‘ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.’” (1 Pétérù 3:4) Doug, Kristẹni mìíràn tó fẹ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jìn, sọ pé: “Tí mo bá ronú nípa rẹ̀, mo wá mọ̀ pé a kò mọ ara wa dáadáa.”
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe ní ti gidi láti mọ ẹni tí ń gbé ibi tó fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà jìnnà síni? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ ó lè gba ìsapá àrà ọ̀tọ̀. Doug sọ pé: “A kò ní owó tí a lè máa fi tẹ ara wa láago, nítorí náà, a máa ń kọ lẹ́tà síra wa lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀.” Ṣùgbọ́n, kíkọ lẹ́tà kò tó Joanne àti Frank. Joanne sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, a máa ń kọ lẹ́tà síra wa, a sì gbìyànjú títẹ ara wa láago. Nígbà tó yá, Frank fi rédíò tí ń gbohùn sílẹ̀ ránṣẹ́ sí mi. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la máa ń gbohùn sórí kásẹ́ẹ̀tì.”
Àìṣàbòsí ni Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Náà
Ọ̀nà yòówù kí ẹ máa gbà kàn sí ara yín, ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ aláìlábòsí. Kristẹni aya kan tí ń jẹ́ Ester sọ pé: “Bí o bá purọ́, yóò hàn tó bá yá, yóò sì nípa lórí àjọṣe náà. Ẹ má ṣe tan ara yín jẹ. Má ṣe tan ara rẹ jẹ. Bí o kò bá gbà pẹ̀lú ohun kan, má kàn fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ẹ jọ sọ ọ́.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni ní ìmọ̀ràn tó dára pé: “Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”—Éfésù 4:25; fi wé Hébérù 13:18.
Àwọn ohun wo ló yẹ kí ẹ rí i dájú pé ẹ sọ̀rọ̀ lé lórí? Gbogbo àwọn tí ń fẹ́ ara wọn sọ́nà ní láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan bíi góńgó ẹni, ọmọ, àwọn ọ̀ràn owó, àti ìlera. Síbẹ̀, àwọn ọ̀ràn kan wà tí ó lè nílò àfiyèsí pàtàkì. Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan—tàbí ẹ̀yin méjèèjì—yóò kó kúrò níbi tó wà bí ẹ bá ṣègbéyàwó. Ṣé ìwọ yóò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ àti pé ṣe o lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti ní ti ìmọ̀lára? Báwo lo ṣe mọ̀? Ṣé o ti kó lọ síbòmíràn rí àbí ṣé o ti fi ìdílé rẹ sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ rí? Ẹni tí Joanne fẹ́ fẹ́ nífẹ̀ẹ́ pé kí àwọn méjèèjì yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sìn ní orílé-iṣẹ́ Watch Tower Society, àwọn tí ń ṣe ìwé ìròyìn yìí. Joanne rántí pé: “Ó béèrè bí mo bá lè gbé inú iyàrá kékeré kan, láìní owó púpọ̀. A sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa.”
Bí ó bá jẹ́ ẹnì kan tó wà ní orílẹ̀-èdè mìíràn lò ń fẹ́ sọ́nà, ǹjẹ́ ìwọ yóò lè mú ara bá àṣà ìbílẹ̀ ibòmíràn mu? Frank béèrè pé: “Ǹjẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ti ń gbádùn ìgbésí ayé tí ẹnì kejì rẹ̀ ń gbé láti ọjọ́ dé ọjọ́? Ìgbà tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àjọṣe náà ni kí ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun pàtàkì wọ̀nyí. Bí ẹ bá ṣe tètè mọ̀ nípa rẹ̀ sí ni yóò fi gbè yín sí—kí ó tó wọ̀ yín lára àti kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí náwó púpọ̀.” Ó dájú pé gbígbé àárín àwọn tí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ lójoojúmọ́ yàtọ̀ sí rírìnrìn-àjò afẹ́ lọ síbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan péré. Ǹjẹ́ yóò béèrè pé kí o kọ́ èdè mìíràn? Ǹjẹ́ ìwọ yóò lè mú ara bá àwọn ìyàtọ̀ ńlá tí ó wà nínú ọ̀nà ìgbésí ayé ibẹ̀ mu? Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ṣé àṣà ìbílẹ̀ náà lo nífẹ̀ẹ́ sí bóyá kì í ṣe ẹni náà gan-an? Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ lè máà tọ́jọ́. Ṣùgbọ́n ìgbéyàwó ń so ẹni méjì pa pọ̀ títí lọ.—Mátíù 19:6.
Tony ṣàlàyé pé: “Ọmọge kan tí mo mọ̀ ní orílẹ̀-èdè mìíràn fẹ́ ará Caribbean kan. Ṣùgbọ́n ìgbésí ayé ní erékùṣù kò rọgbọ fún un. Ooru kì í yé mú níbẹ̀, ó sì máa ń ṣàìsàn. Oúnjẹ wọn yàtọ̀, aáyun ìdílé rẹ̀ sì máa ń yun ún. Nítorí náà, wọ́n gbìyànjú láti lọ máa gbé ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ ronú pé ìfẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì ti gba àwọn ènìyàn lọ́kàn jù níbẹ̀, aáyun ìṣọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tó ń gbádùn tẹ́lẹ̀ láàárín ìdílé àti àwọn aládùúgbò ń yun ún. Nísinsìnyí, wọ́n ti pínyà; ọkọ ń gbé orílẹ̀-èdè tirẹ̀, ìyàwó náà ń gbé orílẹ̀-èdè tirẹ̀. Àwọn ọmọ wọn méjèèjì pàdánù ìfẹ́ àti àbójútó àwọn òbí méjèèjì.”
Fífẹ́ ẹni tó wá láti ibi tó jìnnà gan-an, bóyá níbi tí ọ̀nà ìgbésí ayé ti yàtọ̀ sí tìrẹ, ní ìṣòro mìíràn nínú. Ṣé o ti ṣe tán láti kojú ìnáwó púpọ̀ tó tan mọ́ rírìnrìn-àjò àti ìfìsọfúnni-ránṣẹ́? Lydia rántí pé: “Phil máa ń dápàárá pé a ní láti ṣe ìgbéyàwó nítorí pé owó tí òun ti ná sórí títẹ̀ mí láago pọ̀ gan-an, ṣùgbọ́n nísinsìnyí owó títẹ ìyá mi láago ni a ń san!” Bí ọ̀rọ̀ ọmọ bá wọ̀ ọ́ ńkọ́? Bí àwọn kan tí ń dàgbà, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa àwọn ẹbí wọn, wọn kò tilẹ̀ lè bá wọn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù nítorí pé èdè wọn kò dọ́gba! A ò sọ pé irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ kò ṣeé borí. Ṣùgbọ́n a ní láti ro ohun tí kíkó wọnú irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ yóò gbà.—Fi wé Lúùkù 14:28.
Irú Ènìyàn Wo Ló Jẹ́ Ní Gidi?
Báwo ni o ṣe lè sọ bí ọ̀rẹ́ rẹ kì í bá fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, tí kì í sì í ṣe ẹlẹ́tàn? Mátíù 7:17 sọ pé: “Gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde.” Nítorí náà, irú àwọn nǹkan wo ló máa ń ṣe? Ǹjẹ́ àwọn ohun tó máa ń sọ bá ìwà tó ń hù mu? Ǹjẹ́ àwọn ohun tó ti ṣe sẹ́yìn ti àwọn góńgó rẹ̀ ọjọ́ iwájú lẹ́yìn? Ester ṣàlàyé pé: “Ohun tí a kọ́kọ́ rí nípa ara wa ni góńgó olúkúlùkù wa nípa tẹ̀mí. Ó ti ń sìn bí ajíhìnrere alákòókò kíkún fún ọdún mẹ́jọ, ìyẹn sì fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé òtítọ́ ló sọ pé òun yóò máa bá a lọ.”
Ṣùgbọ́n ká ní ó jọ pé ẹni tí o ń fẹ́ sọ́nà máa ń yẹ nǹkan sílẹ̀. Má ṣe fi ojú pa ọ̀ràn náà rẹ́ kí o wulẹ̀ retí pé nǹkan yóò tò. Wádìí síwájú sí i! Béèrè pé KÍ LÓ FÀ Á? Òwe kan sọ pé: “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yóò fà á jáde.” (Òwe 20:5) Òmíràn kìlọ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.
Lójúkoojú
Síbẹ̀, ohun díẹ̀ péré ni o lè mọ̀ nípa ẹnì kan nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ tàbí tẹlifóònù. Ó dùn mọ́ni pé àpọ́sítélì Jòhánù kọ àwọn lẹ́tà mélòó kan sí àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn lẹ́tà wọ̀nyí ṣe púpọ̀ láti fún ìdè ìfẹ́ni tó wà láàárín wọn lókun, Jòhánù sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní ohun púpọ̀ láti kọ̀wé rẹ̀ sí yín, èmi kò fẹ́ láti fi pépà àti yíǹkì kọ ọ́, ṣùgbọ́n mo ní ìrètí láti wá sọ́dọ̀ yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ ní ojúkoojú.” (2 Jòhánù 12) Bákan náà, kò sí ohun tó dára ju lílo àkókò pẹ̀lú ẹnì kan fúnra rẹ. Ó tilẹ̀ lè bọ́gbọ́n mu kí ọ̀kan lára yín gbéra lọ sí ibi tí ẹnì kejì ń gbé fún ìgbà díẹ̀ kí ẹ bàa lè wà nítòsí ara yín. Èyí yóò tún jẹ́ kí ẹni tó gbéra lọ sí apá ọ̀dọ̀ ẹnì kejì mọ bí ojú ọjọ́ ṣe rí àti bí ipò ìgbésí ayé ṣe rí níbi tí ó lè wá di ibùgbé rẹ̀ tuntun náà.
Báwo ni ẹ ṣe lè lo àkókò yín pa pọ̀ lọ́nà tó dára? Ẹ ṣe ohun tí yóò mú kí ẹnì kìíní mọ bí ànímọ́ ẹnì kejì ti rí. Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀. Ẹ ṣàkíyèsí ara yín nígbà tí ẹ bá ń kópa ní àwọn ìpàdé ìjọ àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹ ṣe àwọn iṣẹ́ ilé bíi títọ́jú ilé àti rírajà pa pọ̀. Rírí bí ẹnì kejì ṣe ń hùwà nínú ipò àìfararọ nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ ti dí lè sọ nǹkan kan fúnni.a
Ó tún yẹ kí o lo àkókò pẹ̀lú àwọn tí yóò wá di àna rẹ. Wá ọ̀nà láti ní ipò ìbátan tó dára pẹ̀lú wọn. Ó ṣetán, bí ẹ̀yin méjèèjì bá fẹ́ ara yín, wọn óò di ìdílé rẹ. Ǹjẹ́ o mọ̀ wọ́n? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yín wọ̀? Joanne gbani nímọ̀ràn pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, ó dára kí ìdílé méjèèjì pàdé pọ̀.” Tony sọ síwájú sí i pé: “Bí ọ̀rẹ́ rẹ ṣe ń hùwà sí àwọn ará ilé rẹ̀ ló ṣe máa hùwà sí ẹ.”
Yálà ẹ ń ríra lójúkoojú tàbí ẹ ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù tàbí ẹ ń kọ lẹ́tà síra nígbà tí ẹ ń fẹ́ra sọ́nà, má ṣe kánjú ṣèpinnu. (Òwe 21:5) Bí ó bá ṣe kedere pé fífẹ́ ara yín kò ní ṣeé ṣe, nígbà náà, yóò bọ́gbọ́n mu kí ẹ jíròrò nípa fífòpin sí ìfẹ́rasọ́nà náà. (Òwe 22:3) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó wulẹ̀ lè jẹ́ pé ẹ nílò àkókò sí i láti sọ òkodoro ọ̀rọ̀, kí ẹ má sì ṣàbòsí.
Fífẹ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jìn gan-an sọ́nà lè ṣòro, àmọ́, ó tún lè ṣàǹfààní. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀ràn tó gbàrònú ni. Ṣọ́ra. Ẹ gbìyànjú láti mọ ara yín. Lẹ́yìn náà, bí ẹ bá pinnu láti fẹ́ ara yín, ìfẹ́rasọ́nà yín yóò jẹ́ àkókò tí ẹ ó mọyì, kì í ṣe èyí tí ẹ ó kábàámọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí ìsọfúnni síwájú sí i nípa ìfẹ́sọ́nà, wo ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, ojú ìwé 255 sí 260, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ rí i dájú pé ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan bíi góńgó ẹni, ọmọ, àti àwọn ọ̀ràn owó nígbà tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àjọṣe náà