ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 3/8 ojú ìwé 10-16
  • Àádọ́ta Ọdún Lábẹ́ Ìgbonimọ́lẹ̀ Ìjọba Oníkùmọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àádọ́ta Ọdún Lábẹ́ Ìgbonimọ́lẹ̀ Ìjọba Oníkùmọ̀
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Ṣèpinnu Tipátipá
  • Díẹ̀ Ló Kù Kí Ọwọ́ Bà Mí
  • Àwọn Ìgbòkègbodò Lẹ́yìn Ogun
  • Lẹ́tà Tí A Kọ sí Stalin
  • Inúnibíni Ń Le Sí I
  • Ìgbésí Ayé Le Koko ní Siberia
  • Nǹkan Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Yí Padà ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
  • Ẹlẹ́rìí Olùṣòtítọ́
  • Ìtúsílẹ̀ àti Ìrìn Àjò Padà Sílé
  • Mo Kó sí Ìyọnu ní Estonia
  • Àjọ KGB Dójú Sọ Wá
  • A Tẹ́ Ebi Tẹ̀mí Lọ́rùn
  • Ìgbésí Ayé Kristẹni Tó Tẹ́ni Lọ́rùn
  • Mo Borí Ìṣòro Tíì Bá Dí Mi Lọ́wọ́ Láti Sin Ọlọ́run
    Jí!—2005
  • Ìsìn Tí Ilẹ̀ Soviet Dojú Àtakò Kọ
    Jí!—2001
  • Ìlérí Tí Mo Múra Tán Láti Mú Ṣẹ
    Jí!—1998
  • Ǹjẹ́ O Mọyì Òmìnira Ìsìn Bí?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 3/8 ojú ìwé 10-16

Àádọ́ta Ọdún Lábẹ́ Ìgbonimọ́lẹ̀ Ìjọba Oníkùmọ̀

Bí Lembit Toom ṣe sọ ọ́

Ní 1951, wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára ní Siberia. Wọ́n kó wa lọ sí àgọ́ kan tó jìnnà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà sókè Ọ̀gangan Ilẹ̀ Olótùútù Nini. Iṣẹ́ atánnilókun la ń ṣe níbẹ̀, òtútù ń mú gan-an, ibi tí a ń gbé kò sì sunwọ̀n. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí mo ṣe dé ibẹ̀ àti ìdí tí ìjìyà wa kì í fi í ṣe lórí asán.

BÀBÁ mi jẹ́ ẹni tí a kà sí olóye ènìyàn ní Estonia, orílẹ̀-èdè àgbègbè Baltic níbi tí wọ́n bí mi sí ní March 10, 1924. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní àwọn ọdún tó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀, ó ń bójú tó oko ìdílé wa ní Järvamaa ní àárín gbùngbùn Estonia. Ìdílé ńlá ọlọ́mọ mẹ́sàn-án ni ìdílé wa, ẹlẹ́sìn Luther ni wa, èmi ni mo sì kéré jù. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni Bàbá kú.

Lọ́dún tó tẹ̀ lé e ni mo jáde ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ní September 1939, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀, wọ́n pe Erich, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, sínú iṣẹ́ ológun, n kò sì lè lọ sí ilé ẹ̀kọ́ mọ́. Lẹ́yìn náà, ní 1940, Estonia dara pọ̀ mọ́ Soviet Union, lẹ́yìn tí ọdún kan sì kọjá, àwọn ará Germany gba Estonia. Wọ́n fi Erich sẹ́wọ̀n, àmọ́ wọ́n tú u sílẹ̀ ní August 1941, wọ́n sì dá a padà sí Estonia. Ní 1942, mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀.

Ìgbà tí mo lọ sí ilé fún ọdún Kérésìmesì ní 1943 ni, Leida, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin sọ fún mi pé dókítà tí ń tọ́jú ìdílé wa bá òun sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Ó fún un ní àwọn ìwé kéékèèké díẹ̀ tí Watch Tower Bible and Tract Society ṣe. Mo kà wọ́n, mo sì wá Dókítà Artur Indus kàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun ló wá bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Mo Ṣèpinnu Tipátipá

Láàárín àkókò náà, ogun tí ń jà láàárín Germany àti Soviet Union ń le sí i. Nígbà tó fi máa di February 1944, àwọn ará Rọ́ṣíà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ibodè Estonia. Wọ́n yan Erich mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Germany, èmi pẹ̀lú rí ìwé gbà láti wá wọ iṣẹ́ ológun. Mo gbà gbọ́ pé òfin Ọlọ́run ka pípa ọmọnìkejì wa léèwọ̀, Dókítà Indus sì sọ pé òun yóò wá ibì kan fún mi tí mo lè sá pa mọ́ sí títí ogun náà yóò fi parí.

Lọ́jọ́ kan, ọlọ́pàá kọ́ńsítébù kan àti olórí àjọ aláàbò ìlú ládùúgbò wá sí oko wa. Wọ́n ti gbàṣẹ láti wá mú mi látàrí pé wọ́n fura pé mo ń gbìyànjú láti sá fún iṣẹ́ ológun. Mo mọ̀ nígbà yẹn pé mo ní láti sá kúrò ní ilé bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óò fimú dánrin àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ilẹ̀ Germany.

Mo sá pa mọ́ sí oko ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láti mú ìgbàgbọ́ mi lókun, mo máa ń ka Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Watch Tower Society bí mo bá ti lè ṣe tó níbi tí mo sá pa mọ́ sí. Lálẹ́ ọjọ́ kan, mo yọ́ lọ sí ilé láti lọ kó oúnjẹ díẹ̀. Àwọn sójà Germany kún ilé, nítorí pé Erich, ẹ̀gbọ́n mi mú díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá sílé láti lo ìsinmi ọjọ́ bíi mélòó kan. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, mo bá Erich sọ̀rọ̀ ní bòókẹ́lẹ́ níbi tí a ti máa ń pakà. Ìgbà yẹn ni mo rí i gbẹ̀yìn.

Díẹ̀ Ló Kù Kí Ọwọ́ Bà Mí

Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, lẹ́yìn tí mo padà sí oko tí mo sá pa mọ́ sí náà, wọ́n ṣígun wá síbẹ̀. Ọlọ́pàá kọ́ńsítébù àdúgbò náà àti àwọn ọkùnrin láti àjọ aláàbò ìlú wá nítorí ìròyìn kan tí wọ́n gbọ́ pé ẹnì kan sá pa mọ́ sí oko náà. Mo rá pálá wọ pàlàpálá abẹ́ ilé náà, kò sì pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ìró àwọn bàtà àmùtán onírin-lábẹ́ lókè orí mi. Ọ̀gá ọlọ́pàá náà fi ìbọn àgbétèjìká halẹ̀ mọ́ àgbẹ̀ náà, ó sì ń kígbe pé: “Ọkùnrin kan sá pa mọ́ sínú ilé yìí! Báwo la ṣe lè dé pàlàpálá abẹ́ ilé yìí?” Mo rí ìtànṣán iná tí wọ́n tàn tí wọn fi ń wá mi. Mo sún sẹ́yìn díẹ̀, mo sì dọ̀bálẹ̀ síbẹ̀ láìmira. Lẹ́yìn tí wọ́n lọ, mo ṣì wà nínú pàlàpálá náà fún ìgbà díẹ̀ láti rí i dájú pé ewu ti lọ.

Kí ilẹ̀ tó mọ́, mo kúrò ní ilé náà, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé wọn kò rí mi mú. Àwọn Kristẹni ará bá mi wá ibòmíràn tí mo sá pa mọ́ sí, níbi tí mo wà títí ìṣàkóso Germany fi parí. Lẹ́yìn náà, mo gbọ́ pé wọ́n ti pa kọ́ńsítébù yẹn àti olórí àjọ aláàbò ìlú náà, ó sì dájú pé àwọn ajagun-abẹ́lẹ̀ ará Rọ́ṣíà ló pa wọ́n. Ní June 19, 1944, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi, Leida, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin pẹ̀lú sì di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ìjọba Soviet tún gba àkóso Estonia padà láti June 1944, ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, mo lómìnira láti padà sílé láti lọ ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ oko. Àmọ́ ní November, láìpẹ́ lẹ́yìn tí mo padà dé, wọ́n pàṣẹ fún mi láti wá wọṣẹ́ ológun ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Pẹ̀lú ìgboyà, mo wàásù láìṣojo fún ìgbìmọ̀ tí ń gbani síṣẹ́ ológun. Wọ́n sọ fún mi pé ètò ìjọba Soviet kò fẹ́ gbọ́ nǹkan kan nípa ohun tí mo gbà gbọ́ àti pé olúkúlùkù ló gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ológun. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, fún gbogbo àkókò tó kù tí wọ́n fi jagun náà, n kò wọ iṣẹ́ ológun, mo sì gbájú mọ́ ṣíṣèrànwọ́ láti máa pèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi.

Àwọn Ìgbòkègbodò Lẹ́yìn Ogun

Nígbà tí ogun náà parí ní May 1945, tí wọ́n sì dárí ji àwọn tí wọ́n ṣòdì sí wọn délẹ̀délẹ̀, mo padà sí ilé ẹ̀kọ́. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1946, mo parí èrò sí pé ṣíṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Estonia kò ní gbè mí lọ́jọ́ iwájú, níwọ̀n bí ètò àjùmọ̀ni tí ìjọba Soviet ń lò ti nípa lórí òwò àdáni. Nítorí náà, mo fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàjọpín ní kíkún sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà.

Lábẹ́ ìṣàkóso Soviet, a kò lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní gbangba mọ́. Ní gidi, wọ́n ti bẹ́gi dínà kíkàn sí Watch Tower Society nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́. Nítorí náà, mo fi ògbólógbòó ẹ̀rọ aṣẹ̀dà-ìwé kan tí mo ní ṣẹ̀dà ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a tọ́jú pa mọ́. A tún sa ipá wa láti máa ṣe àwọn ìpàdé ìjọ.

Inúnibíni tí àjọ KGB (Àjọ Ààbò Orílẹ̀-Èdè Soviet) ṣe sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ ní August 1948. Wọ́n mú márùn-ún lára àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ náà, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n, ìyẹn tètè fi hàn pé àjọ KGB fẹ́ kó gbogbo wa. A gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni-mẹ́rin kalẹ̀ láti máa ṣètò iṣẹ́ ìwàásù náà, kí a máa fún àwọn Kristẹni ará níṣìírí, kí a sì máa ran àwọn tó wà lẹ́wọ̀n lọ́wọ́. Nítorí pé mo ṣì ní òmìnira díẹ̀ láti máa káàkiri, wọ́n lò mí láti máa kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa.

A kọ lẹ́tà kan tí ó ní déètì September 22, 1948, ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ Soviet ní Estonia, èyí tí ń fi hàn pé a kò gbà pẹ̀lú ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ó ṣàpèjúwe ètò àjọ wa àti ète iṣẹ́ wa, ó sì béèrè pé kí wọ́n tú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n sílẹ̀. Kí ni àbájáde rẹ̀? Wọ́n tún kó àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i. Ní December 16, 1948, a tún kọ lẹ́tà mìíràn sí Ìgbìmọ̀ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ SSR ti Estonia pé kí wọ́n tú ẹjọ́ náà ká, kí wọ́n sì tú àwọn arákùnrin wa sílẹ̀. Àwọn ẹ̀dà lẹ́tà náà àti àwọn mìíràn ṣì wà ní ìpamọ́ níbi àkójọ àwọn ìwé ti ìlú ńlá Tallinn.

Ó léwu láti rìnrìn àjò, nítorí pé a kò lè gba àwọn ìwé àṣẹ ìwọ̀lú tó yẹ kí a ní. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a gun alùpùpù ńlá kan tí ó ní ilé lẹ́gbẹ̀ẹ́, tí a rà lọ́wọ́ ọ̀gá sójà ará Rọ́ṣíà kan, lọ́ ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ tó wà ní Aravete, Otepää, Tallinn, Tartu, àti Võru. A máa ń fi ìwúrí pè é ní Kẹ̀kẹ́ Ogun.

Lẹ́tà Tí A Kọ sí Stalin

Ní June 1, 1949, a kọ ìwé mìíràn sí ilé iṣẹ́ gíga jù lọ ti Ìjọba Àjọni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Estonia àti sí Nikolay Shvernik, alága Ìgbìmọ̀ Lọ́gàálọ́gàá Ilé Aṣòfin Gíga Jù Lọ ní Ilẹ̀ Soviet. Ìwé tí a rí ẹ̀dà rẹ̀ gbà láti ibi àkójọ ìwé ti Tallinn yìí ní òǹtẹ̀ Nikolay Shvernik lára, èyí tí ó fi hàn pé ó rí i gbà, ó sì fi ẹ̀dà kan ránṣẹ́ sí Joseph Stalin, olórí ìjọba Soviet Union. Apá tó kẹ́yìn nínú rẹ̀ kà pé:

“A fẹ́ kí ẹ tú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n àti pé kí ẹ dáwọ́ inúnibíni tí ẹ ń ṣe sí wọn dúró. Ẹ fún ètò àjọ Jèhófà Ọlọ́run, tí ń lo Watchtower Bible and Tract Society, láyè láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Jèhófà fún gbogbo olùgbé Soviet Union láìsídìíwọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ Jèhófà yóò pa Soviet Union àti Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì run pátápátá.

“Èyí ni a ń béèrè pé kí ẹ ṣe nítorí Jèhófà Ọlọ́run àti Ọba Ìjọba rẹ̀, Jésù Kristi, àti nítorí gbogbo àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí ẹ fi sẹ́wọ̀n.

“A buwọ́ lù ú: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Estonia (June 1, 1949).”

Inúnibíni Ń Le Sí I

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1950, ẹnì kan tó dé láti Germany fún wa ní ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ mẹ́ta. Kí gbogbo àwọn Kristẹni ará wa lè jàǹfààní oúnjẹ tẹ̀mí yìí, a pinnu pé a óò ṣètò fún àpéjọ kan ní July 24, 1950, ní abà koríko gbígbẹ tí ó jẹ́ ti akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan nítòsí abúlé Otepää. Àmọ́, lọ́nà kan ṣáá, ohun tí a fẹ́ ṣe dé etígbọ̀ọ́ àjọ KGB, wọ́n sì múra láti kó àwọn ènìyàn gan-an.

Wọ́n gbé ọkọ̀ àgbárìgo méjì tí àwọn sójà kún inú rẹ̀ sí ibùdókọ̀ ojú irin ní Palupera, níbi tí àwọn ará ti máa sọ̀ kalẹ̀. Ní àfikún sí i, sójà kan tí ó gbé rédíò alátagbà dání dúró sí títì tó lọ sí Otepää àti Palupera, tí kò jìnnà púpọ̀ sí ibi àpéjọ náà. Nígbà tí àwọn arákùnrin kan tí a ń retí kò tètè dé, a fura pé ọ̀rọ̀ náà ti lu.

Mo mú Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi, Ella Kikas, dání a sì gbé alùpùpù lọ sí ibùdókọ̀ ojú irin tí ó wà ní èbúté èrò kẹta sí Palupera. Ọkọ̀ ojú irin náà ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ni, nítorí náà èmi gba ibì kan wọlé, Ella sì gba òdì kejì wọlé, a sáré lá inú ọkọ̀ náà kọjá, a sì ń kígbe pé kí gbogbo wọ́n bọ́ sílẹ̀. Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí bọ́ sílẹ̀, a ṣètò láti ṣe ìpàdé wa ní abà mìíràn lọ́jọ́ kejì. Bí ìwéwèé àjọ KGB láti kó Àwọn Ẹlẹ́rìí tó pọ̀ gan-an ṣe forí ṣánpọ́n nìyẹn.

Àmọ́, ní oṣù méjì lẹ́yìn ìpàdé náà, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ènìyàn gan-an. Wọ́n mú èmi àti àwọn mẹ́ta yòókù tí a jọ wà nínú ìgbìmọ̀ tí ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní Estonia lọ fún ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò ní September 22, 1950. Wọ́n tì wá mọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n àjọ KGB ní Tallinn ní Òpópónà Pagari fún oṣù mẹ́jọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n kó wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n gbogbo gbòò ní Òpópónà Kalda, tí wọ́n ń pè ní Battery. Wọ́n tì wá mọ́ ibẹ̀ fún oṣù mẹ́ta. Bí a bá fi ibi tí wọ́n wá tì wá mọ́ lórí Òkun Baltic yìí wéra pẹ̀lú ọgbà ẹ̀wọ̀n àjọ KGB tí wọ́n ti jù wá sí àjà ilẹ̀, ńṣe ló dà bí ibi ìgbádùn ìsinmi.

Ìgbésí Ayé Le Koko ní Siberia

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n ju èmi àti Harri Ennika, Aleksander Härm, Albert Kose, àti Leonhard Kriibi sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá ní àgọ́ kan níbi jíjìnnà ní Noril’sk, Siberia. Oṣù méjì ni oòrùn kò fi wọ̀ níbẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, nígbà òtútù pẹ̀lú, oṣù méjì ni kò fi yọrí kọjá ibi tí ó jọ pé ilẹ̀ òun òfuurufú ti pàdé.

Ní August 1951, a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa àkọ́kọ́ láti Tallinn sí Noril’sk nínú ọkọ̀ ojú irin. A rìnrìn àjò ẹgbàáta kìlómítà, a gba Pskov, St. Petersburg (Leningrad tẹ́lẹ̀ rí), Perm’, Yekaterinburg (Sverdlovsk tẹ́lẹ̀ rí), Novosibirsk, àti Krasnoyarsk kọjá, lórí Odò Yenisey. Níkẹyìn, ní ìbẹ̀rẹ̀ October, a wọ ọkọ̀ ojú omi akẹ́rù kan ní Krasnoyarsk, wọ́n sì fi ọkọ̀ mìíràn fà á lọ sí ibi tó jìnnà ju ẹgbẹ̀jọ kìlómítà lọ ní ìhà àríwá. Ọ̀sẹ̀ méjì ni a lò ká tó dé ìlú Dudinka, tó jìnnà gan-an lókè Àgbègbè Ilẹ̀ Olótùútù Nini. Ní Dudinka ni wọ́n tún ti kó wa sínú ọkọ̀ ojú irin mìíràn fún ọgọ́fà kìlómítà nínú ipele kejì ìrìn àjò wa lọ sí Noril’sk. Láti ibùdókọ̀ ojú irin Noril’sk, a fẹsẹ̀ rin ìrìn kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó kẹ́yìn lọ sí àgọ́ tí a ó ti ṣiṣẹ́ lẹ́yìn ìlú nínú òjò dídì.

Níwọ̀n bí wọ́n ti jí aṣọ òtútù mi nígbà tí a wà nínú ọkọ̀ ojú omi akẹ́rù, kóòtù tí a ń wọ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn kan ṣoṣo, fìlà kan, àti sálúbàtà ni mo ní. Ọ̀sẹ̀ púpọ̀ tí a lò nínú ìrìn àjò láti Tallinn ti sọ wá di aláìlera, wọn kò sì fún wa ní ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀ tó tọ́ sí wa lóòjọ́. Nítorí èyí, àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan dá kú. A ń tọ́jú wọn títí àwọn ẹṣin fi dé, a sì gbé wọn sórí ọmọlanke tí ẹṣin ń fà.

Nígbà tí a dé àgọ́ náà, wọ́n kọ orúkọ wa sílẹ̀, wọ́n kó wa lọ sí ilé ìwẹ̀ olómi gbígbóná kan, wọ́n sì fún wa ní oúnjẹ tó tọ́ sí wa lọ́jọ́ náà. Bárékè náà lọ́ wọ́ọ́rọ́, kò sì pẹ́ tí oorun fi gbé mi lọ. Àmọ́, ìrora gógó tí eewo tó sọ mí nínú etí fà mú kí n ta jí láàárín òru. Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n fún mi ní egbòogi, wọn kò sì jẹ́ kí n ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n inú bí àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí pé n kò lè ṣiṣẹ́, wọ́n sì lù mí. Wọ́n jù mí sí àhámọ́ àdáwà fún oṣù kan, wọ́n ní mo “ń da àgọ́ rú.” Mo dúpẹ́ pé wọ́n kó egbòogi tí wọ́n kọ fún mi ní ibi ìtọ́jú aláìsàn wá fún mi, àkókò tí mo lò nínú àhámọ́ àdáwà náà jẹ́ kí ara mi yá.

Ìgbà òtútù tí a kọ́kọ́ nírìírí rẹ̀ ní àgọ́ náà ló le jù. Iṣẹ́ wa, tó sábà máa ń jẹ́ gbígbẹ́ ilẹ̀ láti wa ògidì irin tútù, le gan-an, ìwọ̀nba oúnjẹ tí wọ́n sì ń fún wa kò dára rárá. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í rí àmì àrùn àìsí fítámì C lára, wọ́n fún wa ní abẹ́rẹ́ fítámì C láti lé àrùn náà lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, inú wa dùn pé a pàdé ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa láti Moldova, Poland, àti Ukraine ní àgọ́ náà.

Nǹkan Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Yí Padà ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n

Ní ìgbà ìrúwé ọdún 1952, àwọn ẹlẹ́wọ̀n bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìwọ̀nba owó oṣù, tó mú kí a lè máa ra oúnjẹ ní àfikún sí oúnjẹ wa. Bákan náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí kan bẹ̀rẹ̀ sí rí oúnjẹ tí a gbé sínú páálí gbà, èyí tí a fi ọgbọ́n ṣe ìsàlẹ̀ rẹ̀ lọ́nà tí a fi ń lè fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa mọ́ sínú rẹ̀. Nígbà kan, Ẹlẹ́rìí kan láti Moldova rí agolo ọ̀rá ẹlẹ́dẹ̀ kan gbà. Bí ó ti jẹ ọ̀rá ẹlẹ́dẹ̀ náà tán, ó rí awọ abonú ẹlẹ́dẹ̀ kan. Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ mẹ́ta ló wà nínú rẹ̀!

Nígbà tí Stalin kú, ní March 5, 1953, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà lọ́nà gbígbàfiyèsí ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Lákọ̀ọ́kọ́, ìdaṣẹ́sílẹ̀ àti arukutu ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n béèrè pé kí wọ́n tú àwọn sílẹ̀. Wọ́n rán àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun láti wá paná rẹ̀. Ní Noril’sk, ọgọ́fà ẹlẹ́wọ̀n ni wọ́n pa nígbà kan tí arukutu ṣẹlẹ̀; àmọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí kò kópa nínú rẹ̀, wọn kò sì pa ẹnikẹ́ni lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò pa wọ́n lára. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1953, a kò ṣiṣẹ́ ní ibi ìwakùsà ògidì irin tútù náà fún ọ̀sẹ̀ méjì. Lẹ́yìn náà, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í rọrùn sí i ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Wọ́n tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀, wọ́n sì dín iye ọdún tí àwọn mìíràn yóò lò lẹ́wọ̀n kù.

Ẹlẹ́rìí Olùṣòtítọ́

Lẹ́yìn yánpọnyánrin tó ṣẹlẹ̀ ní àgọ́ yìí, wọ́n gbé mi lọ sí àgọ́ kan ní ìhà gúúsù nítòsí ìlú ńlá Tayshet, ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Irkutsk. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé Artur Indus, tó ti kọ́kọ́ bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kọ̀ láti ṣe dókítà fún wọn ní àgọ́ náà, kàkà bẹ́ẹ̀, ó yàn láti gba iṣẹ́ tó túbọ̀ gba agbára. Ó ṣàlàyé pé: “Ẹ̀rí-ọkàn mi kò jẹ́ kí n fọwọ́ sí pé kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ara wọ́n dá, tí wọ́n gbé ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, gba ìsinmi pé ara wọn kò dá nígbà tí a ń fipá mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ara wọn kò dá ní gidi láti ṣiṣẹ́.”

Arákùnrin Indus ti rù, ó sì ń ṣàìsàn nígbà yẹn, níwọ̀n bí kì í ti í ṣe iṣẹ́ alágbára púpọ̀ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Síbẹ̀, ó sọ fún mi pé òun rò pé ìjìyà òun ti fọ ọkàn-àyà òun mọ́ nípa tẹ̀mí. Ó tó nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí a fi wà pọ̀. Nígbà tó yá, wọ́n mú un lọ sí ilé ìwòsàn tó wà ní àgọ́ náà, níbi tó kú sí ní January 1954. Sàréè rẹ̀ tí kò lórúkọ lára wà níbì kan nínú igbó tó wà lóde àgbègbè ilẹ̀ olótùútù nini náà. Ó kú bí Kristẹni olódodo, ó sì ń retí àjíǹde.

Ìtúsílẹ̀ àti Ìrìn Àjò Padà Sílé

Ní 1956, wọ́n rán Ìgbìmọ̀ Lọ́gàálọ́gàá Ilé Aṣòfin Gíga Jù Lọ kan ní Ilẹ̀ Soviet Union sí àgọ́ wa láti ṣàtúnyẹ̀wò fáìlì àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Nígbà tí mo dé iwájú ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe náà, ọ̀gá ológun tó jẹ́ olórí níbẹ̀ béèrè pé: “Kí lo máa ṣe tí a bá tú ọ sílẹ̀?”

Mo fèsì pé: “Tó bá dìgbà náà, a óò máa rí i.”

Wọ́n ní kí n jáde nínú iyàrá náà, nígbà tí wọ́n sì pè mí padà, ọ̀gá ológun náà sọ pé: “Ìwọ ni ọ̀tá tó burú jù lọ tí Soviet Union ní—ọ̀tá ètò ìṣèlú àti ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ni ọ́.” Àmọ́, ó tún sọ pé: “A óò tú ọ sílẹ̀, ṣùgbọ́n a kò ní padà lẹ́yìn ẹ.” Wọ́n tú mi sílẹ̀ ní July 26, 1956.

Ọjọ́ méjì ni mo fi ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí ará Ukraine ní Suyetikha, abúlé kan nítòsí Tayshet, níbi tí wọ́n kó wọn nígbèkùn sí ní 1951. Lẹ́yìn náà, mo lo ọjọ́ mẹ́rin ní àgbègbè Tomsk, nítòsí ibi tí wọ́n fi Màmá sí nígbèkùn. Láti ibùdókọ̀ ojú irin, mo rin ìrìn ogún kìlómítà lọ sí abúlé Grigoryevka. Ibẹ̀ ni mo ti rí ipò tí ó tilẹ̀ burú ju èyí tí ọ̀pọ̀ lára wa wà nínú àwọn àgọ́ lọ! Wọ́n ti tú Leida, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n Kazakhstan, ó sì ti wá sí àgbègbè yẹn ní oṣù mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn kí ó lè wà pẹ̀lú Màmá. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí wọ́n ti gba ìwé àṣẹ tí ó ní fún ìrìn àjò kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, kò tí ì lè padà sí Estonia.

Mo Kó sí Ìyọnu ní Estonia

Láìpẹ́, mo padà dé ilé ní Estonia, mo sì lọ sí oko àwọn òbí mi tààràtà. Mo rí i pé bí àwọn ènìyàn ti ń sọ káàkiri ní Siberia pé ìjọba ti ba gbogbo ilé wa jẹ́ ló rí gẹ́lẹ́! Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, àrùn rọpárọsẹ̀ kọ lù mí. Mo pẹ́ gan-an ní ilé ìwòsàn, mo sì ń gba ìtọ́jú lọ lẹ́yìn tí mo kúrò níbẹ̀. Títí di òní yìí, ńṣe ni mo ń ṣánsẹ̀ rìn.

Láìpẹ́, mo rí iṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tí mo bá ṣiṣẹ́ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1943, Ilé Iṣẹ́ Oníkoríko Gbígbẹ ní Lehtse. Mo rí ilé kan gbà nípasẹ̀ wọn, nígbà tí Màmá àti Leida sì padà dé láti ìgbèkùn ní December 1956, ọ̀dọ̀ mi ni wọ́n ń gbé ní Lehtse.

Ní November 1957, mo fẹ́ Ella Kikas, tí òun náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ̀wọ̀n kan ní Siberia dé. Ní oṣù méjì lẹ́yìn náà, a kó lọ sí Tartu, níbi tí a ti rí ibi kékeré kan háyà ní ilé ẹnì kan. Níkẹyìn mo rí iṣẹ́ ọkọ̀ wíwà ní Ilé Iṣẹ́ Ẹgbẹ́ Aláfọwọ́sowọ́pọ̀ Aláràjẹ ti Àgbègbè Tartu.

Nígbà tí mo wà ní Siberia, mo túmọ̀ àwọn àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ìṣọ́ láti èdè Russian sí Estonian, mo sì kó wọn wá sílé. Lẹ́yìn náà, a rí ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada gbà, a tún tú òun náà sí èdè Estonian. A wá fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tẹ àwọn ẹ̀dà ìwé náà. Láàárín àkókò kan náà, àjọ KGB ń bá ìfimúfínlẹ̀ wọn lọ. Níwọ̀n bí a ti mọ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣọ́ ìrìnsí ẹni, a sábà máa ń wà lójúfò, a sì máa ń ṣọ́ra, bí àwọn ẹran tí a ń dọdẹ.

Àjọ KGB Dójú Sọ Wá

Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960, àjọ KGB ṣètò ìgbétáásì bíba Àwọn Ẹlẹ́rìí lórúkọ jẹ́. Èmi àti ìyàwó mi ni wọ́n dójú sọ ní pàtàkì. Àwọn ìwé ìròyìn bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn àpilẹ̀kọ tí ń bani lórúkọ jẹ́ jáde, wọ́n sì dẹ́bi fún wa lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n. Ẹ̀ẹ̀mejì ni àjọ KGB ṣe ìpàdé ìtagbangba níbi iṣẹ́ mi. Bákan náà, àwọn ògbógi eléré orí ìtàgé ṣe eré ìfiniṣẹ̀fẹ̀ nípa mi ní Ilé Ìwòran Estonia ní Tallinn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ náà mú mi rántí àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì pé: “Àwọn tí ó jókòó sí ẹnubodè bẹ̀rẹ̀ sí fún ọ̀ràn mi ní àfiyèsí, èmi sì ni ẹṣin ọ̀rọ̀ orin àwọn tí ń mu ọtí tí ń pani.”—Sáàmù 69:12.

Gbogbo ìsapá wọn láti dójú tì wá ń bá a lọ títí di ọdún 1965 tí wọ́n ṣe ìpàdé tó kẹ́yìn, ní Ilé Àbójútó Ìlera Àwọn Òṣìṣẹ́ ní Tartu. Èmi àti Ella wà níbẹ̀, àwọn aṣojú àjọ KGB wà níbẹ̀ àti èrò rẹpẹtẹ. Ní àwọn ìgbà bíi mélòó kan tí wọ́n béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ella, àtẹ́wọ́ ni àwọn èrò ń pa. Ó wà hàn sí wa pé ẹ̀yìn wa ni àwọn èrò náà wà. Ojú ti àwọn aṣojú àjọ KGB, ohun tí wọ́n rí tó ṣẹlẹ̀ sì bí wọn nínú.

A Tẹ́ Ebi Tẹ̀mí Lọ́rùn

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kọ́múníìsì gbìyànjú láti dá pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa dúró, lẹ́yìn nǹkan bí ọdún 1965, a lè pèsè èyí tí ó tó dé ìwọ̀n kan fún àwọn Kristẹni ará wa. Bí ó ti wù kí ó rí, iṣẹ́ títúmọ̀ ìwé àti títẹ̀ ẹ́ níkọ̀kọ̀ ní àwọn ibi tí a sá pa mọ́ sí ń béèrè àkókò àti agbára púpọ̀. Nígbà kan tí aṣojú àjọ KGB kan ń sọ nípa iṣẹ́ tí mo ń ṣe lábẹ́lẹ̀ àti ọ̀nà tí mo ń gbà kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kiri, ó sọ fún mi pé: “Toom, ńṣe lo dà bí ajádìí àpò.”

Bí ó ti wù kí ó rí, bòókẹ́lẹ́ ni a ń ṣe àwọn ìpàdé wa àti ní ẹgbẹẹgbẹ́. A sì ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́nà aláìjẹ́-bí-àṣà. Àwọn ará wa ní láti máa wà ní ìmúrasílẹ̀ nígbàkigbà nítorí àwọn tí wọ́n ń wá tú ilé wò. Nítorí náà, a ní láti tọ́jú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Watch Tower Society tìṣọ́ratìṣọ́ra. Síbẹ̀, lábẹ́ àwọn ipò tí a wà yìí pàápàá, a ṣàwárí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì, wọ́n sì mú ìdúró wọn níhà Ìjọba Ọlọ́run.

Nígbà tí Olórí Ìjọba Soviet, Mikhail Gorbachev bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe rẹ̀ ní àwọn ọdún 1980, a ní òmìnira púpọ̀ sí i láti sin Ọlọ́run. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní 1991, Soviet Union di kélekèle, a sì fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìdámọ̀ lábẹ́ òfin. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, a ní ìjọ mẹ́rin ní Tartu, láìpẹ́ yìí ni a sì parí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwa náà. Ó ti lé ní ẹgbọ̀kàndínlógún [3,800] Ẹlẹ́rìí tí ń ṣàjọpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ní Estonia báyìí, ní ìfiwéra pẹ̀lú bóyá nǹkan bí ogójì tàbí àádọ́ta tó wà níbẹ̀ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní ohun tí ó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn.

Ìgbésí Ayé Kristẹni Tó Tẹ́ni Lọ́rùn

N kò fìgbà kan ṣiyè méjì rí pé bóyá mo ṣe ìpinnu tó tọ́ nígbà tí mo mú ìdúró mi láti sin Jèhófà. Mo bojú wẹ̀yìn, ọkàn mi sì kún fún ìtẹ́lọ́rùn gidigidi, inú mi dùn láti rí i pé ètò àjọ Jèhófà ń tẹ̀ síwájú tokuntokun àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ṣì wà tí wọ́n fẹ́ láti sin Jèhófà.

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ìfẹ́ àti ààbò rẹ̀ ti mú kí èmi àti ìyàwó mi la ọ̀pọ̀ ọdún wọ̀nyí já. Níní in lọ́kàn pé ètò òdodo Jèhófà ti sún mọ́lé ti fún wa lókun nípa tẹ̀mí. Dájúdájú, bí a ti ń ronú nípa bí iye àwọn tí ń sin Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i lọ́nà àgbàyanu, a ní ìdánilójú pé ìyà tí a jẹ kì í ṣe lórí asán.—Hébérù 6:10; 2 Pétérù 3:11, 12.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwòrán ilẹ̀ kan tí a sàmì ìrìn àjò olóṣù-méjì tí a rìn láti Tallinn lọ sí àgọ́ Noril’sk olórúkọ burúkú náà sí

Tallinn

Pskov

St. Petersburg

Perm’

Yekaterinburg

Novosibirsk

Krasnoyarsk

Dudinka

Noril’sk

ILẸ̀ OLÓTÙÚTÙ-NINI

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Artur Indus, Kristẹni ajẹ́rìíkú tó lágbára

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní Siberia, 1956. Èmi ni mo ṣìkẹrin láti apá òsì ní ìlà ẹ̀yìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Èmi àti ìyàwó mi, níwájú orílé-iṣẹ́ àjọ KGB níbi tí wọ́n ti sábà máa ń fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́