ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/22 ojú ìwé 23-24
  • Ǹjẹ́ O Mọyì Òmìnira Ìsìn Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọyì Òmìnira Ìsìn Bí?
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àádọ́ta Ọdún Lábẹ́ Ìgbonimọ́lẹ̀ Ìjọba Oníkùmọ̀
    Jí!—1999
  • Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà ní Ìlà Oòrùn Europe
    Jí!—1997
  • Ilẹ̀ Soviet Gbógun Ti Ìsìn
    Jí!—2001
  • Àádọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn Ni Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí í ‘Rántí Ẹlẹ́dàá Mi Atóbilọ́lá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 4/22 ojú ìwé 23-24

Ǹjẹ́ O Mọyì Òmìnira Ìsìn Bí?

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyin Jí! ní Estonia

PÄRNU jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó jẹ́ ibùdókọ̀ àti ibi ìgbafẹ́ ní orílẹ̀-èdè Estonia kékeré ti Baltic, tí ó jẹ́ orílẹ̀-èdè Soviet Union tẹ́lẹ̀. Iye àwọn ènìyàn tí ń gbé ìlú náà lé ní 50,000. Àwọn ènìyàn náà ń gbádùn òmìnira láti ṣe ìsìn tí ó bá wù wọ́n nísinsìnyí—òmìnira tí wọn kò ní ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn. Ní June 17, 1995, Pärnu Leht, ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò kan, sọ pé Pärnu ní ìsìn 11, àti pé ìwé agbéròyìnjáde náà wéwèé láti tẹ ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ kan jáde nípa wọn.

Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ ṣàlàyé pé: “A óò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjọ tí ó hàn gbangba pé ìgbòkègbodò rẹ̀ ti nípa lórí gbogbo wa—àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa—tí wọ́n ń ṣe ìpàdé wọn nísinsìnyí ní gbọ̀ngàn ilé ìpọntí kan. . . . Ní ọdún 1931, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bẹ̀rẹ̀ sí í pe ara wọn ní Ẹlẹ́rìí Jehofa, orúkọ tí wọ́n ṣì ń jẹ́ títí di òní yìí nìyẹn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń bẹ ní gbogbo àgbáyé ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ márùn-ún lọ. Tallinn ni orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Estonia wà.”

Àpilẹ̀kọ náà ń bá a lọ pé: “Wọ́n dá ìjọ àwọn olùpolongo Jehofa sílẹ̀ ní Pärnu ní ọdún kan àbọ̀ sẹ́yìn. Ní ìbẹ̀rẹ̀, gbogbo wọ́n jẹ́ 25; nísinsìnyí, wọ́n ti di 120 . . .

“Àwọn ènìyàn tí wọ́n kọ́kọ́ fara hàn wuni ní ti gidi. Àwọn ènìyàn—tí ọ̀pọ̀ lára wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tọkọtaya—jẹ́ oníwà bí ọ̀rẹ́, tí ń múra dáradára, tí wọn kì í sì í ṣe ọlọ́kàn líle. Ó yani lẹ́nu pé àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ gan-an, nítorí pé kò rọrùn fún ọmọdé kan láti jókòó jẹ́ẹ́ sójú kan fún wákàtí kan àti àbọ̀—ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.”

Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde náà ń ṣàpèjúwe bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe yàtọ̀ sí àwọn ìsìn míràn, ó sọ pé: “Wọ́n ń tẹnu mọ́ Paradise tí ń bẹ́ níwájú. Ó tún jẹ́ ohun àgbàyanu láti rí i bí ìjọ náà ti mọ Bibeli dáadáa tó, wọ́n sì máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí ó bá ṣeé ṣe.” Ní ìparí, àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Àwọn 120 ènìyàn yẹn, tí wọ́n jẹ́ olùpolongo Jehofa, ti ṣe ìpinnu wọn; ó sì dá wọn lójú pé òun ni èyí tí ó tọ̀nà. Ìgbàgbọ́ wọn àti ìpolongo rẹ̀ ni ó jẹ wọ́n lógún jù lọ.”

Kì í ṣe gbogbo ènìyàn Pärnu ni àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ń wéwèé ní ìlú ńlá náà lórí ìsìn, dùn mọ́. Ní July 8, 1995, ìwé agbéròyìnjáde Pärnu Leht ròyìn pé: “A óò fẹ́ láti tẹ ìwé ẹ̀sùn kan, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ̀rẹ̀ òpó ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ tuntun, tí a rí gbà láti ọ̀dọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́rin.” Àwọn aṣojú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Estonia, Ṣọ́ọ̀ṣì Ajíhìnrere ti Luther ní Estonia, Ṣọ́ọ̀ṣì Ìparapọ̀ Kristian Ajíhìnrere àti Onítẹ̀bọmi ti Estonia àti àwọn Onítẹ̀bọmi, àti Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì ti Estonia, ló fọwọ́ sí ìwé ẹ̀sùn, tàbí lẹ́tà yìí, tí a fi ṣọwọ́ sí ìwé agbéròyìnjáde náà.

Àwọn aṣojú ìsìn mẹ́rin yìí ṣàròyé pé: “Ó dà bí ohun tí ó ṣàjèjì pátápátá sí wa pé ẹ bẹ̀rẹ̀ ọ̀wọ́ náà pẹ̀lú àpilẹ̀kọ kan nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.” Síwájú sí i, wọ́n sọ pé: “Nípa ọ̀ràn ọ̀wọ́ yìí, a óò fẹ́ láti sọ pé a kà á sí ohun tí kò ní ṣeé ṣe láti jẹ́ kí ìwé agbéròyìnjáde Pärnu Leht fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò.”

Àwọn aṣojú ìsìn náà parí ọ̀rọ̀ pé: “Ní àwùjọ tí ọkàn ọ̀pọ̀ ènìyàn ti dàrú nítorí ìkìmọ́lẹ̀ gbígbèrú tí kò tẹ́ àwọn ènìyàn lọ́rùn tí ń wá láti ọ̀dọ̀ onírúurú ìsìn àti ẹ̀yà ìsìn tuntun tí wọ́n ń polongo ‘jíjẹ́ ẹni ti ẹ̀mí,’ a rí i pé ó yẹ kí àwọn ìtẹ̀jáde ronú nípa ipò tí ìsìn wà ní àdúgbò, kí wọ́n sì lè mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àtayébáyé àti àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀yà ìsìn àti ti àwọn aláṣerégèé. Àwọn mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì ti Estonia, tí ń ṣojú fún àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristian tí ń gbádùn àjọṣepọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, gbọ́dọ̀ lè pèsè amọ̀nà tí ó ṣe kedere tó lórí ọ̀ràn yìí.”

Bí ó ti wù kí ó rí, òǹkọ̀wé agbéròyìnjáde Pärnu Leht gbé èrò tí ń múni ronú jinlẹ̀ yìí jáde, lẹ́yìn lẹ́tà yìí, pé: “Kì í ṣe gbogbo ohun tí a bá rò pé ó tọ́ ló máa ń tọ́. Ojú ìwòye àti èrò Ọlọrun nípa àwọn ìjọ wọ̀nyí sì lè máa jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú ojú ìwòye àwọn ṣọ́ọ̀ṣì pàtàkì-pàtàkì mẹ́rin wọ̀nyí, tàbí kí ó jẹ́ pé bákan náà ni. Kò sí ẹni tí ó pé tán nínú wa, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ní àwọn àṣà tí ó ti wà fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún pàápàá kò pé.”

Kí ni èrò rẹ nípa ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn tí ó yí padà sí ìsìn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ ti Soviet Union tẹ́lẹ̀? Ó dá wa lójú pé àwọn ènìyàn tí ń wá òtítọ́ níbi gbogbo mọrírì òmìnira ìsìn tí àwọn ènìyàn ń gbádùn níbẹ̀.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

FINLAND

Helsinki

Òkun Baltic

ESTONIA

Tallinn

Pärnu

LATVIA

Riga

LITHUANIA

Vilnius

RỌ́ṢÍÀ

St. Petersburg

Moscow

BELARUS

Minsk

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Pärnu

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́