Wọ́n Lé Wa Kúrò Nílùú Lọ sí Siberia!
BÍ VASILY KALIN ṢE SỌ Ọ́
Bí o bá rí ọkùnrin kan tó ń fara balẹ̀ ka Bíbélì nígbà tí ariwo bọ́ǹbù ń sọ lálá, ǹjẹ́ o kò ní fẹ́ mọ ohun tó mú kó lè fara balẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ohun tí bàbá mi rí nìyẹn ní ohun tí ó lé ní ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta sẹ́yìn.
OṢÙ July ọdún 1942 ni, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ṣì le gan-an. Bí àwọn aṣáájú ogun ilẹ̀ Germany ṣe ń kọjá ní Vilshanitsa, tó jẹ́ abúlé bàbá mi, ní Ukraine, ó tẹsẹ̀ dúró ní ilé àwọn arúgbó kan ládùúgbò. Àwọn bọ́ǹbù ń bú gbàù lọ́tùn-ún lósì, síbẹ̀ ọkùnrin náà jókòó sídìí ààrò, ó ń se àgbàdo mélòó kan, bẹ́ẹ̀ ló sì ń ka Bíbélì.
Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà ni wọ́n bí mi, nítòsí ìlú Ivano-Frankivs’k rírẹwà tó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Ukraine, tó jẹ́ ara Soviet Union nígbà yẹn. Nígbà tó yá, bàbá mi wá sọ fún mi nípa ìrírí mánigbàgbé tó ní nígbà tó pàdé ọkùnrin yẹn tó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti nípa àwọn ohun bíbanilẹ́rù tó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọdún tí ogun náà fi jà. Gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ti mú kí ó rẹ àwọn ènìyàn náà tẹnutẹnu, ó sì kó ṣìbáṣìbo bá wọn, ọ̀pọ̀ lára wọn sì ń ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ló dé tí ìwà burúkú fi pọ̀ tó báyìí? Kí ló dé tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ fi ń kú? Kí ló dé tí Ọlọ́run fàyè gbà á? Kí ló dé? Kí ló dé? Kí ló dé?’
Ìjíròrò tó wáyé láàárín bàbá mi àti ọkùnrin arúgbó náà pẹ́, wọ́n sì sojú abẹ níkòó lórí àwọn ìbéèrè tó jọ ìwọ̀nyẹn. Ọkùnrin náà ń ṣí Bíbélì rẹ̀ láti ibì kan sí òmíràn, ó sì ń fi ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ti ń rú Bàbá lójú tipẹ́tipẹ́ hàn án. Ó ṣàlàyé pé ète Ọlọ́run ni láti fòpin sí gbogbo ogun ní àkókò tó yàn kalẹ̀ àti pé ilẹ̀ ayé yóò di párádísè ẹlẹ́wà.—Sáàmù 46:9; Aísáyà 2:4; Ìṣípayá 21:3, 4.
Bàbá mi sáré wálé, ó sì fi ìtara sọ pé: “Ǹjẹ́ kò yà yín lẹ́nu? Lẹ́yìn tí mo bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jíròrò lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ojú mi ti là! Mo ti rí òtítọ́!” Bàbá sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò pa Ìjọ Kátólíìkì jẹ rí, àwọn àlùfáà kò fìgbà kan rí dáhùn àwọn ìbéèrè òun. Nítorí náà, Bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, màmá mi náà kò sì gbẹ́yìn. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí fi kọ́ àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì péré nígbà náà, àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, tí ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún méje tí èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni bọ́ǹbù kan fọ́ ilé wọn, tó fi jẹ́ iyàrá kan péré ni wọ́n ń rí lò níbẹ̀.
Inú ìdílé ńlá ọlọ́mọbìnrin mẹ́fà àti ọmọkùnrin kan ni a bí màmá mi sí. Bàbá rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olówó àdúgbò wọn, ó sì fọwọ́ gidi mú àṣẹ tó bá pa àti ipò rẹ̀ láwùjọ. Nítorí náà, àwọn ẹbí kọ́kọ́ ṣàtakò nípa ẹ̀sìn tí ìdílé mi ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, ọ̀pọ̀ lára àwọn alátakò wọ̀nyí pa àwọn àṣà ìsìn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, bíi lílo ère ìsìn, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn òbí mi nínú ìsìn tòótọ́.
Àwọn àlùfáà ń dẹ àwọn ènìyàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí lójúkojú. Àbájáde rẹ̀ ni pé, àwọn ará àdúgbò máa ń fọ́ fèrèsé ilé àwọn òbí mi, wọ́n sì máa ń halẹ̀ mọ́ wọn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn òbí mi ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn nìṣó. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n fi máa bí mi ní ọdún 1947, ìdílé wa ti ń jọ́sìn Jèhófà ní ẹ̀mí àti òtítọ́.—Jòhánù 4:24.
Wọ́n Lé Wa Kúrò Nílùú
Mi ò jẹ́ gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìdájí April 8, 1951, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́rin péré ni mí nígbà náà. Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n kó ajá dání wọlé wa wá. Wọ́n fi ìwé àṣẹ tí wọ́n fi ń léni kúrò nílùú hàn wá, wọ́n sì tú ilé wa wò. Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n gbé ìbọn atamátàsé lọ́wọ́ àti ajá oríṣiríṣi wà lẹ́nu ọ̀nà wa, bẹ́ẹ̀ làwọn ọkùnrin tó wọṣọ ológun jókòó sórí tábìlì wa, wọ́n ń dúró dè wá bí a ti ń yára palẹ̀ ẹrù wa mọ́ láti fi ìlú sílẹ̀ láàárín wákàtí méjì tí wọ́n fún wa. Mi ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, mo wá bẹ̀rẹ̀ sì sunkún.
Wọ́n pàṣẹ fún àwọn òbí mi láti buwọ́ lu ìwé kan tí ó sọ pé wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ àti pé wọn kò ní bá wọn ṣe pọ̀ mọ́. Bí wọ́n bá buwọ́ lù ú, wọn yóò fi wọ́n sílẹ̀ láti máa gbé ilé wọn àti orílẹ̀-èdè wọn. Ṣùgbọ́n Bàbá fìgboyà sọ pé: “Ó dá mi lójú pé ibi yòówù kí ẹ kó wa lọ, Jèhófà, Ọlọ́run wa, yóò wà pẹ̀lú wa.”
Ọ̀gá ológun náà rọ̀ ọ́ pé: “Ro ti ìdílé ẹ, ro ti àwọn ọmọ ẹ. Nítorí kì í ṣe ibi eré ìnàjú la ń kó yín lọ. Ìhà àríwá jíjìnnà réré la ń kóo yín lọ, níbi tí òjò dídì kì í ti í dá, ibi tí àwọn béárì ńláńlá ti ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri òpópó.”
Ohun tó ń ba gbogbo ènìyàn lẹ́rù, tó sì ṣàjèjì ni ọ̀rọ̀ náà “Siberia” jẹ́ nígbà yẹn. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí a ní fún Jèhófà lágbára ju ìbẹ̀rù ohun tí a kò mọ̀ lọ. Wọ́n kó ẹrù wa sínú ọmọlanke kan, wọ́n sì kó wa lọ sí àárín ìlú níbi tí wọ́n ti kó àwa àti ogún tàbí ọgbọ̀n ìdílé mìíràn sínú àwọn ọkọ̀ ojú irin akẹ́rù. A gbéra, ó di inú igbó kìjikìji, tàbí aginjù Siberia.
A rí àwọn ọkọ̀ ojú irin mìíràn tó kó àwọn tí a lé kúrò nílùú ní àwọn ibùdókọ̀ ojú irin tí a gbà kọjá, a sì rí ohun tí wọ́n kọ sára àwọn ọkọ̀ náà tó kà pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ló Wà Nínú Ọkọ̀ Yìí.” Ẹ̀rí aláìlẹ́gbẹ́ kan ni èyí jẹ́, níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí àti ìdílé wọn ni a lé lọ sí àwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìhà àríwá àti ìlà oòrùn jíjìnnà réré.
A ṣàkọsílẹ̀ kíkó tí wọ́n kó Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì lé wọn kúrò nílùú ní oṣù April 1951 yìí dáadáa. Òpìtàn Walter Kolarz kọ nípa rẹ̀ nínú ìwé rẹ̀ Religion in the Soviet Union pé: “Èyí kò fòpin sí wíwà ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí’ ní Rọ́ṣíà, ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ apá tuntun kan nínú ìgbòkègbodò yíyí tí wọ́n ń yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà. Wọ́n tilẹ̀ tún ń gbìyànjú láti tan ìgbàgbọ́ wọn kálẹ̀ nígbàkígbà tí wọ́n bá dúró ní àwọn ibùdókọ̀ nígbà tí wọ́n ń kúrò nílùú. Lílé wọn kúrò nílùú ni ohun tó dára jù tí Ìjọba ilẹ̀ Soviet lè ṣe fún wọn láti lè mú kí wọ́n tan ìgbàgbọ́ wọn káàkiri. A mú ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí’ jáde wá sí gbangba láti inú àdádó tí wọ́n wà ní abúlé wọn, àní bí èyí bá tilẹ̀ jẹ́ ibi ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti àgọ́ ìmúniṣiṣẹ́ ẹrú.”
Nǹkan ṣẹnure fún ìdílé mi, nítorí pé wọ́n jẹ́ kí a kó oúnjẹ díẹ̀ dání—ìyẹ̀fun, àgbàdo, àti ẹ̀wà. Wọ́n tilẹ̀ jẹ́ kí bàbá mi àgbà pa ẹlẹ́dẹ̀ dání, òun sì ni àwa àti Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn rí jẹ. Bí a ti ń lọ lọ́nà ni orin àtọkànwá ń sọ lálá láti inú àwọn ọkọ̀ náà. Jèhófà fún wa ní okun láti forí tì í.—Òwe 18:10.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí a fi rìnrìn àjò la Rọ́ṣíà kọjá, níkẹyìn, a sì dé Siberia jíjìnnà réré, tí ó jẹ́ àdádó, tí ó sì tutù nini. Wọ́n kó wa lọ sí ibùdókọ̀ Toreya ní ẹkùn ilẹ̀ Chunsk ní àgbègbè Irkutsk. Wọ́n kó wa láti ibẹ̀ lọ sínú igbó kìjikìji ní abúlé kékeré kan, tí àkọsílẹ̀ wa pè ní “ibùdó ayérayé.” Wẹ́kú ni ẹrù ìdílé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún wọnú ọkọ̀ akẹ́rù lórí yìnyín kan, katakata kan sì ń wọ́ ọ gba àárín ẹrẹ̀ lọ. Nǹkan bí ogún ìdílé ni wọ́n kó lọ sí bárékè àwọn ológun, tí ó ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ gígùn tí a kò fi nǹkan là. Àwọn aláṣẹ ti kìlọ̀ fún àwọn ará àdúgbò náà pé ẹni tí à ń sá fún ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ènìyàn bẹ̀rù wa, wọn kò sì fẹ́ mọ̀ wá rárá.
Iṣẹ́ ní Ìgbèkùn
Gígé igi lulẹ̀ ni iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí sì jẹ́ lábẹ́ ipò tí kò rọgbọ rárá. Ọwọ́ lásán ni a fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́—gígé gẹdú lulẹ̀, gígé wọn sí àpólà, kíkó wọn sínú ọmọlanke, àti lẹ́yìn náà, kíkó wọn sínú ọkọ̀ ojú irin. Àwọn kòkòrò kantíkantí tó ń ṣù ràn-ìn káàkiri, tí èèyàn ò sì lè sá fún tún mú kí nǹkan burú sí i. Ìyà jẹ bàbá mi gan-an. Gbogbo ara rẹ̀ ló lé, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà gan-an pé kó ran òun lọ́wọ́ láti forí tì í. Ṣùgbọ́n lójú gbogbo ìṣòro náà, ọ̀pọ̀ jù lọ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìgbàgbọ́ wọn kò mì.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n kó wa lọ sí ìlú Irkutsk, níbi tí ìdílé wa ti ń gbé nínú ọgbà kan tó jẹ́ ilé ẹ̀wọ̀n tẹ́lẹ̀ rí, a sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìṣebíríkì kan. Ọwọ́ lásán ni a fi ń kó bíríkì jáde nínú àwọn ààrò ìṣebíríkì gbígbóná, tó tóbi, ìgbà gbogbo ni iṣẹ́ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣe sì ń pọ̀ sí i, débi tí àwọn ọmọ fi ní láti máa ran àwọn òbí wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè parí ìpín iṣẹ́ wọn. Èyí mú wa rántí iṣẹ́ ẹrú tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ní Íjíbítì ìgbàanì.—Ẹ́kísódù 5:9-16.
Ó hàn gbangba pé Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń ṣiṣẹ́ kára, wọn kì í sì í ṣàbòsí, wọ́n kì í ṣe “ọ̀tá àwọn ènìyàn,” bí wọ́n ṣe sọ pé wọ́n jẹ́. A ṣàkíyèsí pé èyíkéyìí lára Àwọn Ẹlẹ́rìí kò fojú di àwọn aláṣẹ, Àwọn Ẹlẹ́rìí kò sì gbéjà ko ìpinnu àwọn aláṣẹ. Kódà, ọ̀pọ̀ ènìyàn wá nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn wọn.
Ipò Wa Nípa Tẹ̀mí
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń tú ẹrù Àwọn Ẹlẹ́rìí léraléra—kí a tó lé wọn kúrò nílùú, nígbà tí wọ́n ń lọ lọ́nà, àti níbi tí a lé wọn lọ—ọ̀pọ̀ lára wọn rọ́nà fi àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Bíbélì pàápàá pa mọ́. Nígbà tó yá, wọ́n fi ọwọ́ àti àwọn ohun èlò mìíràn dà wọ́n kọ. A ń ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé nínú bárékè náà. Tí alákòóso bárékè náà bá wọlé tó rí i pé àwa bí mélòó kan tí a kóra jọ ń kọrin, yóò pàṣẹ pé kí a dákẹ́. Àá sì dákẹ́. Ṣùgbọ́n tó bá ti jáde lọ sí bárékè tó tẹ̀ lé e, àá tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin wa lọ. Kò ṣeé ṣe láti pa wa lẹ́nu orin kíkọ mọ́.
Iṣẹ́ ìwàásù wa kò sì dáwọ́ dúró. Gbogbo ènìyàn ni Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń bá sọ̀rọ̀, níbikíbi tí wọ́n bá wà. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin àti àwọn òbí mi sábà máa ń sọ fún mi bí àwọn ṣe ń lè bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ Bíbélì. A dúpẹ́ fún èyí, òtítọ́ Bíbélì wá bẹ̀rẹ̀ sí yí àwọn aláìlábòsí ènìyàn lọ́kàn padà díẹ̀díẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950, àwọn ènìyàn ti mọ̀ nípa Ìjọba Jèhófà ní Irkutsk àti àgbègbè rẹ̀.
Lákọ̀ọ́kọ́, ńṣe ni a ka Àwọn Ẹlẹ́rìí sí ọ̀tá ìjọba, ṣùgbọ́n ó wá di mímọ̀ lábẹ́ òfin pé ètò àjọ wa jẹ́ ti ìsìn látòkè délẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn aláṣẹ gbìyànjú láti dá iṣẹ́ wa dúró. Nítorí náà, àwa ìdílé méjì tàbí mẹ́ta péré la máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n má baà mọ̀. Wọ́n tú ilé àwọn ènìyàn wò fínnífínní ní ìdájí ọjọ́ kan ní February 1952. Wọ́n kó Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́wàá lẹ́yìn náà, wọ́n sì kó àwa yòókù lọ sí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n kó ìdílé wa lọ sí abúlé Iskra, tí iye àwọn tí ń gbé ibẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún, ó sì wà ní nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà sí ìlú Irkutsk.
Fíforítì Í Bí Ipò Nǹkan Ṣe Ń Yí Padà
Àwọn olórí abúlé náà gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, èyí sì yà wá lẹ́nu. Àwọn ènìyàn náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀—àwọn mélòó kan tilẹ̀ jáde wá ràn wá lọ́wọ́. Ìdílé wa ló jẹ́ ìkẹta tí wọ́n fi wọ̀ sí iyàrá kékeré kan náà tí ó fẹ̀ ní nǹkan bí mítà mẹ́tàdínlógún níbùú lóròó. Àtùpà elépo òyìnbó nìkan ni iná tí a ní.
Wọ́n dìbò lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì. Àwọn òbí mi sọ pé àwọn ti dìbò fún Ìjọba Ọlọ́run, ó sì dájú pé ọ̀rọ̀ wọn kò yé àwọn ènìyàn náà. Nítorí náà, inú ìtìmọ́lé ni àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa tó ti dàgbà wà ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ènìyàn bí mélòó kan béèrè nípa àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́, èyí sì fún ìdílé mi láǹfààní dáadáa láti sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo tí aráyé ní.
Láàárín ọdún mẹ́rin tí a fi gbé abúlé Iskra, kò sí Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn tí a lè bá kẹ́gbẹ́ nítòsí. Kí a tó lè jáde ní abúlé náà, a ní láti gba àkànṣe àṣẹ ìjáde lọ́wọ́ alákòóso ibẹ̀, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé wọn ò fẹ́ ká wà láàárín àwọn ènìyàn yòókù ni wọ́n ṣe lé wa kúrò nílùú. Síbẹ̀, ìgbà gbogbo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń gbìyànjú láti dé ọ̀dọ̀ ara wọn kí wọ́n lè ṣàjọpín oúnjẹ tẹ̀mí èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ rí gbà.
Lẹ́yìn tí Stalin kú ní ọdún 1953, wọ́n dín iye ọdún tí a bù fún gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí tí a fi sẹ́wọ̀n kù láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ọdún mẹ́wàá. Àwọn tó sì wà ní Siberia kò nílò àkànṣe ìwé ẹ̀rí èyíkéyìí mọ́ kí wọ́n tó lè máa rìn fàlàlà káàkiri. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò pẹ́ tí àwọn aláṣẹ tún bẹ̀rẹ̀ sí tú ilé kiri, wọ́n sì ń kó Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n bá ri pé wọ́n ní Bíbélì tàbí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n ṣe àwọn àkànṣe àgọ́ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n sì kó nǹkan bí irínwó arákùnrin àti igba arábìnrin síbẹ̀ ní àgbègbè Irkutsk.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ń gbọ́ nípa ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó ń ṣẹlẹ̀ ní Soviet Union. Nípa bẹ́ẹ̀, láàárín agbedeméjì ọdún 1956 sí February 1957, àwọn ará fọwọ́ sí ìwé ẹ̀bẹ̀ kan tí wọ́n kọ nítorí tiwa ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè mọ́kàndínnígba tí wọ́n ṣe jákèjádò ayé. Àròpọ̀ 462,936 ènìyàn tó pésẹ̀ fọwọ́ sí ìwé ẹ̀bẹ̀ tí wọ́n kọ sí olórí ìjọba Soviet nígbà náà Nikolay A. Bulganin. Lára àwọn ohun tí ìwé ẹ̀bẹ̀ náà béèrè fún ni pé kí wọ́n tú wa sílẹ̀, kí wọ́n sì “gbà wá láyè láti máa gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kí a sì máa tẹ̀ ẹ́ jáde lédè Russian, Ukrainian àti ní àwọn èdè mìíràn tí a bá ri pé ó yẹ, àti àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì mìíràn tí àwọn ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò jákèjádò ayé.”
Láàárín àkókò yẹn, wọ́n ti kó ìdílé wa lọ sí abúlé Khudyakovo tó jìn sí ìgboro gan-an, tí ó tó nǹkan bí ogún kìlómítà sí Irkutsk. Ọdún méje la fi gbé ibẹ̀. Ní 1960, Fyodor, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, gbéra lọ sí Irkutsk, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin kejì sì gbéyàwó lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin sì lọ pẹ̀lú. Nígbà tó di ọdún 1962, wọ́n mú Fyodor, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù.
Ìdàgbàsókè Mi Nípa Tẹ̀mí
Láti abúlé wa, Khudyakovo, ìrìn nǹkan bí ogún kìlómítà la máa fẹsẹ̀ rìn tàbí kí a gun kẹ̀kẹ́ láti débi tí a ti ń pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí náà, a gbìyànjú láti kó lọ sí Irkutsk kí a má baà jìnnà sí Àwọn Ẹlẹ́rìí tó kù. Àmọ́, olórí àgbègbè tí a ń gbé náà kò fọwọ́ sí kíkólọ wa, ó sì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti máà jẹ́ kí a kó lọ. Àmọ́, nígbà tó pẹ́ díẹ̀, ọkùnrin náà túbọ̀ wá ń ṣe dáadáa sí wa, a sì kó lọ sí abúlé Pivovarikha, nǹkan bí kìlómítà mẹ́wàá sí Irkutsk. Ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà níbẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun níbẹ̀. Ní Pivovarikha, ètò wà fún onírúurú àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti àwọn arákùnrin tí ń bójú tó àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Inú mi dùn gan-an!
Ìfẹ́ tí mo ní sí òtítọ́ Bíbélì ti pọ̀ gan-an nígbà yẹn, mo sì fẹ́ ṣèrìbọmi. Ní August 1965, èrò ọkàn mi ṣẹ nígbà tí mo ṣèrìbọmi nínú Odò Olkhe kékeré, níbi tí ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí tuntun ti máa ń ṣèrìbọmi lákòókò yẹn. Lójú ẹni tó wulẹ̀ ń wòran lásán, ńṣe ló jọ pé fàájì la ń ṣe tí a sì ń lúwẹ̀ẹ́ nínú odò. Àìpẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé iṣẹ́ àkọ́kọ́ lé mi lọ́wọ́ láti ṣe alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ní November 1965, ìdùnnú tún ṣubú lu ayọ̀ wa nígbà tí Fyodor tẹ̀wọ̀n dé.
Bí Iṣẹ́ Náà Ṣe Ń Tẹ̀ Síwájú
Ní 1965, wọ́n pe gbogbo àwa tí wọ́n lé kúrò nílùú jọ, wọ́n sì kéde fún wa pé a ní ẹ̀tọ́ láti rìn fàlàlà lọ síbikíbi tí a bá fẹ́, èyí sì fòpin sí wíwà wa ní “ibùdó ayérayé.” Ǹjẹ́ ẹ mọ bí inú wa ṣe dùn tó? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wa ti ṣí lọ sí àwọn apá ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè náà, àwọn mìíràn pinnu láti dúró síbi tí Jèhófà ti bù kún wa tí ó sì ń tì wá lẹ́yìn nínú ìdàgbàsókè àti ìgbòkègbodò tẹ̀mí wa. Ọ̀pọ̀ lára wa ti tọ́ ọmọ, ọmọ-ọmọ, àti ọmọ ìran kẹta ní Siberia, tó ti wá di ibi tí kì í bani lẹ́rù mọ́.
Ní 1967, mo pàdé Maria, ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n lé ìdílé òun náà lọ sí Siberia láti Ukraine. Nígbà tí a wà lọ́mọdé, abúlé Vilshanitsa la jọ ń gbé ní Ukraine. A ṣègbéyàwó ní ọdún 1968, Ọlọ́run sì fi ọmọkùnrin kan, Yaroslav, àti ọmọbìnrin kan, Oksana, ta wá lọ́rẹ lẹ́yìn náà.
A máa ń lo àkókò tí a bá ń sìnkú àti àkókò tí a bá ń ṣègbéyàwó láti pàdé lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ fún ìkẹ́gbẹ́pọ̀ nípa tẹ̀mí. A tún máa ń lo àkókò wọ̀nyí láti ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wa tó wá síbẹ̀ àmọ́ tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn ẹ̀ṣọ́ ìjọba máa ń wá síbi ayẹyẹ wọ̀nyí, níbi tí a ti ń fi Bíbélì wàásù ní gbangba nípa ìrètí àjíǹde tàbí ìpèsè ètò ìgbéyàwó tó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá àti àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú nínú ayé tuntun rẹ̀.
Nígbà kan, ó kù díẹ̀ kí n parí ọ̀rọ̀ ìsìnkú kan tí mo ń sọ lọ́wọ́ ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan bá dé, àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ ṣí lẹ́ẹ̀kan náà, ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tó wà nínú rẹ̀ bọ́ọ́lẹ̀, ó ní kí n wọnú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà. Ẹ̀rù ò bà mí. A kì í kúkú ṣe ọ̀daràn, a wulẹ̀ jẹ́ olùgba-Ọlọ́run-gbọ́ ni. Bí ó ti wù kí ó rí, ìròyìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn ará ìjọ wa ńbẹ lápò mi. Wọ́n lè torí èyí fàṣẹ gbé mi. Nítorí náà, mo béèrè bí wọ́n bá lè jẹ́ kí n fún ìyàwó mi lówó kí n tó bá wọn lọ. Nítorí èyí, mo rọra mú àpamọ́wọ́ mi àti àwọn ìròyìn ìjọ fún un níṣojú wọn.
Ọdún 1974 ni èmi àti Maria bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní kọ̀rọ̀ iyàrá wa. Nítorí pé ọmọkùnrin wa ṣì kéré, alaalẹ́ ni a máa ń ṣe é kí ó má bàa mọ̀ nípa rẹ̀. Àmọ́, nítorí pé ó fẹ́ tọ pinpin, ó díbọ́n bíi pé òun ń sùn, ó sì ń yọjú wo ohun tí a ń ṣe. Nígbà kan, ó sọ pé: “Mo mọ àwọn tó ń ṣe ìwé ìròyìn nípa Ọlọ́run.” Ẹ̀rù bà wá díẹ̀, ṣùgbọ́n a sábà máa ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà dáàbò bo ìdílé wa nínú iṣẹ́ pàtàkì yìí.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọkàn àwọn aláṣẹ wá tutù sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nítorí náà a ṣètò láti ṣe ìpàdé ńlá kan ní gbọ̀ngàn ìwòran eré orí ìtàgé àti ìṣefàájì ti Mir ní ìlú Usol’ye-Sibirskoye. A mú un dá àwọn aláṣẹ ìlú lójú pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìkẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni ni lájorí ète tí a fi ń ṣe àwọn ìpàdé wa. Ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn tó kóra jọ ní January 1990, wọ́n kún inú gbọ̀ngàn náà, àwọn ará ìlú sì ṣàkíyèsí ohun tí ń lọ.
Nígbà tí a parí ìpàdé náà, oníròyìn kan béèrè pé, “Ìgbà wo lẹ kọ́ àwọn ọmọ yín?” Ó ya òun àti àwọn àlejò yòókù lẹ́nu pé àwọn ọmọ ń fetí sílẹ̀ ní gbogbo wákàtí mẹ́rin tí a lò níbi ìpàdé ìtagbangba tí a kọ́kọ́ ṣe yìí. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n gbé àpilẹ̀kọ kan tó gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáde nínú ìwé ìròyìn kan ládùúgbò náà. Ó sọ pé: “Ó dájú pé a lè rí nǹkan kọ́ lára [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà].”
Yíyọ̀ Nínú Ìgbòòrò Kíkọyọyọ
Ní 1991, a ṣe ìpàdé méje ní Soviet Union, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rin àti igba ó lé méjìléláàádọ́ta ènìyàn [74,252] ló wá síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí àwọn ilẹ̀ Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí gba òmìnira, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kí n lọ sí Moscow. Wọ́n bi mí níbẹ̀ bí ó bá ṣeé ṣe fún mi láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ìjọba náà. Yaroslav ti gbéyàwó, ó sì ti bímọ kan, ọ̀dọ́langba sì ni Oksana nígbà yẹn. Nítorí náà, ní 1993, èmi àti Maria bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún wa ní Moscow. Lọ́dún yẹn kan náà, wọ́n yàn mí láti jẹ́ olùṣekòkárí Ibùdó Ìdarí Ètò Àjọ Ẹlẹ́kùnjẹkùn ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.
Ní báyìí, èmi àti Maria ti ń ṣiṣẹ́ ní ilé ẹ̀ka wa tuntun tó wà lóde St. Petersburg. Mo kà á sí ohun iyì láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin olùṣòtítọ́ mìíràn tí ń bójú tó àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà tí iye wọn ń pọ̀ sí i ní Rọ́ṣíà. Lónìí, ó lé ní 260,000 Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àwọn ilẹ̀ Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí, àwọn ti Rọ́ṣíà sì lé ní 100,000!
Lọ́pọ̀ ìgbà, èmi àti Maria máa ń ronú nípa àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n tí wọ́n ń bá ìṣòtítọ́ wọn lọ nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba wọn ní Siberia, ibi tó ti di ibùgbé wa ọ̀wọ́n. Lónìí, a máa ń ṣe àwọn ìpàdé ńlá níbẹ̀ déédéé, nǹkan bí ẹgbẹ̀wá Ẹlẹ́rìí ló ń ṣiṣẹ́ lójú méjèèjì ní Irkutsk àti àgbègbè rẹ̀. Ní gidi, àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 60:22 pẹ̀lú ń ní ìmúṣẹ ní apá ibẹ̀ pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Èmi àti bàbá mi, ìdílé wa, àti àwọn mìíràn tí wọ́n lé kúrò nílùú lọ sí Irkutsk ní 1959
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn ọmọdé níbi tí wọ́n lé wọn lọ ní Iskra
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ọdún tí a ṣègbéyàwó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Èmi àti Maria lónìí