Ó Lé Lógójì Ọdún Táa Fi Wà Lábẹ́ Ìfòfindè Ìjọba Alájọgbé-bùkátà
GẸ́GẸ́ BÍ MIKHAIL VASILEVICH SAVITSKII TI SỌ Ọ́
Ilé Ìṣọ́ April 1, 1956, ròyìn pé ní April 1, 7, àti 8, ọdún 1951, ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni a “lé kúrò nílùú.” Ilé Ìṣọ́ náà ṣàlàyé pé: “Ọjọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà kò lè gbàgbé láé lọjọ́ wọ̀nyẹn jẹ́. Ọjọ́ mẹ́ta wọ̀nyí ló jẹ́ pé gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n rí ní Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Ukraine, White Rọ́ṣíà [Belarus], Bessarabia, Moldavia, Latvia, Lithuania àti Estonia—tí iye wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún méje lọ́kùnrin àti lóbìnrin . . . ni wọ́n fi kẹ̀kẹ́ ẹrù kó lọ sí àwọn ibùdókọ̀ rélùwéè, tí wọ́n sì tibẹ̀ fi ọkọ̀ rélùwéè tí wọ́n fi ń kó ẹran ọ̀sìn kó wọn, kí wọ́n tó lọ já wọn sọ́nà jíjìn réré.”
NÍ April 8, 1951, wọ́n kó ìyàwó mi, ọmọkùnrin mi ọmọ oṣù mẹ́sàn-án, àwọn òbí mi, àbúrò mi ọkùnrin, àti ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn kúrò nílé wọn ní ìlú Ternopol’, Ukraine, àti àyíká rẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n kó wọn dà sínú àwọn ọkọ̀ rélùwéè tí wọ́n fi ń kó ẹran ọ̀sìn, wọ́n rìnrìn àjò fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì. Níkẹyìn, wọ́n já wọn sínú igbó tó wà lẹ́bàá ilẹ̀ olótùútù nini ti Siberia tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Adágún Baikal.
Kí ló dé tí mi ò fi sí lára àwọn tí wọ́n kó lọ? Kí n tó ṣàlàyé ibi tí mo wà nígbà yẹn àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa lẹ́yìn náà, ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín nípa bí mo ṣe di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Òtítọ́ Bíbélì Dé Ọ̀dọ̀ Wa
Ní September 1947, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré, méjì lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé wa ní abúlé kékeré náà, Slaviatin, tó wà ní nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà sí Ternopol’. Bí èmi àti Màmá mi ti jókòó táa ń fetí sí àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí—tí ọ̀kan lára wọn ń jẹ́ Maria—mo mọ̀ pé kì í kàn-án ṣe ẹ̀sìn mìíràn lásán nìyí. Wọ́n ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wọn, wọ́n sì dáhùn àwọn ìbéèrè wa nípa Bíbélì lọ́nà tó ṣe kedere.
Mo gbà gbọ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, ṣùgbọ́n ọ̀ràn ṣọ́ọ̀ṣì ti sú mi. Baba àgbà máa ń sọ pé: “Àwọn àlùfáà máa ń fi ọ̀rọ̀ ìdálóró nínú ọ̀run àpáàdì dáyà já àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà alára kò bẹ̀rù nǹkan kan. Wọ́n kàn ń ja àwọn òtòṣì lólè tí wọ́n sì ń tàn wọ́n jẹ ni.” Mo rántí ìwà ipá tí wọ́n hù sí àwọn ará Poland tí ń gbé lábúlé wa àti bí wọ́n ṣe tiná bọ ilé wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì. Ó ṣeni ní háà pé àlùfáà Kátólíìkì tí í ṣe Gíríìkì ló ṣètò ìgbóguntini yìí. Lẹ́yìn náà, mo rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n pa, mo sì ń ṣàníyàn láti mọ èrèdí irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀.
Ìgbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ló tó wá bẹ̀rẹ̀ sí yé mi. Mo kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìpìlẹ̀ òtítọ́ Bíbélì, títí kan òtítọ́ náà pé kò sí ọ̀run àpáàdì oníná, àti pé Sátánì Èṣù ló ń lo ẹ̀sìn èké láti máa gbé ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ ga. Látìgbàdégbà, màá dúró díẹ̀ lẹ́nu ìdákẹ́kọ̀ọ́ mi, màá sì gbàdúrà ìdúpẹ́ àtọkànwá sí Jèhófà nítorí ohun tí mo ń kọ́. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàjọpín àwọn òtítọ́ Bíbélì wọ̀nyí pẹ̀lú Stakh, àbúrò mi ọkùnrin, inú mi sì dùn gan-an nígbà tó tẹ́wọ́ gbà á.
Fífi Ohun Tí Mo Ń Kọ́ Ṣèwà Hù
Mo rí i pé ó pọndandan láti ṣe àwọn ìyípadà kan, mo sì jáwọ́ nínú sìgá mímu lójú-ẹsẹ̀. Ó tún yé mi pé ó pọndandan láti máa pàdé pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn yòókù fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Fún ìdí yìí, mo máa ń rin ìrìn kìlómítà mẹ́wàá gba inú ẹgàn kí n tó dé ibi ìkọ̀kọ̀ táa ti ń ṣèpàdé. Nígbà mìíràn, kìkì àwọn obìnrin díẹ̀ ló máa lè wá sípàdé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò tíì ṣe batisí, èmi ni wọ́n máa sọ pé kó darí ìpàdé.
Níní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ léwu, ẹni táa bá sì ká a mọ́ lọ́wọ́ lè fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n jura. Síbẹ̀, mo fẹ́ ní àwọn ìwé tèmi. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bá ọ̀kan lára àwọn aládùúgbò wa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ rí, ṣùgbọ́n nítorí ìbẹ̀rù, ó jáwọ́, ó sì wa yẹ̀pẹ̀ bo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ nínú ọgbà rẹ̀. Ọpẹ́ mi sí Jèhófà mà pọ̀ o, nígbà tí ọkùnrin náà hú gbogbo ìwé àti ìwé ìròyìn rẹ̀ síta, tó sì gbà láti kó wọn fún mi! Mo kó wọn pa mọ́ sínú àwọn ilé tí Baba mi ti ń sin oyin, ibi tí kò jọ pé ẹnikẹ́ni máa tú ilé dé.
Ní July 1949, mo ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi. Ọjọ́ yìí ni mo láyọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Ẹlẹ́rìí tó ṣe batisí ìkọ̀kọ̀ náà tẹnu mọ́ ọn pé kò rọrùn láti jẹ́ Kristẹni tòótọ́ àti pé ọ̀pọ̀ àdánwò ń bẹ níwájú. Kò pẹ́ tí mo fi rí i pé òdodo lọ̀rọ̀ tó sọ! Síbẹ̀, ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí táa ti batisí bẹ̀rẹ̀ tayọ̀tayọ̀. Oṣù méjì lẹ́yìn batisí mi, mo gbé Maria níyàwó, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn méjì tó fojú èmi àti Màmá mi mọ òtítọ́.
Àdánwò Mi Àkọ́kọ́ Dé Lójijì
Ní April 16, 1950, ṣe ni mo ń bọ̀ nílé láti ìlú kékeré náà, Podgaitsi, nígbà tí àwọn sójà ṣàdédé yọ sí mi, tí wọ́n sì rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo ń kó lọ sọ́dọ̀ àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Wọ́n mú mi. Ní àwọn ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ fi wà ní àtìmọ́lé, ṣe ni wọ́n ń lù mí ní kóńdó, wọn kò jẹ́ kí n jẹun, wọn kò sì jẹ́ kí n sùn. Wọ́n tún pàṣẹ pé kí n máa kúrú kí n máa ga, wọ́n ní kí n káwọ́ lérí ṣe é nígbà ọgọ́rùn-ún, mi ò lè ṣe é parí tí ẹ̀mí mi fi fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́. Lẹ́yìn èyí, wọ́n sọ mí sínú àjà-ilẹ̀ tó tutù nini fún wákàtí mẹ́rìnlélógún.
Ète tí wọ́n fi firú ìyà bẹ́ẹ̀ jẹ mí ni kí n má bàa lágbára àtijanpata, kó lè túbọ̀ rọrùn láti lù mí lẹ́nu gbọ́rọ̀. Wọ́n béèrè pé: “Níbo lo ti rí ìwé wọ̀nyí, àwọn wo sì ni o fẹ́ lọ kó wọn fún?” Mo kọ̀ láti tú àṣírí èyíkéyìí. Nígbà náà ni wọ́n ka abala òfin tí wọn yóò fi ṣẹjọ́ mi sí etígbọ̀ọ́ mi. Ó kà pé ẹni tó bá ń pín ìwé tí ń tako ìjọba Soviet kiri, tàbí tó ní in lọ́wọ́, yóò gba ìdájọ́ ikú tàbí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.
Wọ́n béèrè pé: “Èwo lo yàn nínú méjèèjì?”
Mo fèsì pé: “Mi ò yan ìkankan, ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àti pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo fara mọ́ ohun yòówù tó bá yọ̀ǹda.”
Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí wọ́n tú mi sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ méje. Ìrírí yẹn jẹ́ kí n rí i pé òótọ́ ni ìlérí Jèhófà tó sọ pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5.
Nígbà tí mo máa padà délé, ara mi kò yá rárá, ṣùgbọ́n Baba mi gbé mi lọ sọ́dọ̀ dókítà, kò sì pẹ́ ti ara mi fi yá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Baba kì í ṣe ẹ̀sìn tí àwa yòókù nínú ìdílé rẹ̀ ń ṣe, ó ń tì wá lẹ́yìn nínú ìjọsìn wa.
Ìfisẹ́wọ̀n àti Ìgbèkùn
Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, wọ́n fẹ́ fi túlààsì mú mi wọ ẹgbẹ́ ológun Soviet. Mo ṣàlàyé pé ẹ̀rí ọkàn mi kọ̀ ọ́. (Aísáyà 2:4) Síbẹ̀, ní February 1951, wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin fún mi, wọ́n sì fi mí ránṣẹ́ sí ẹ̀wọ̀n kan tó wà ní ìlú Ternopol’. Nígbà tó ṣe, wọ́n fi mí ránṣẹ́ sí ẹ̀wọ̀n kan tó wà ní L’viv, ìlú ńlá kan tó wà ní nǹkan bí ọgọ́fà kìlómítà sí Ternopol’. Ìgbà tí mo ń ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀ ni mo gbọ́ pé wọ́n ti kó ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí lọ sí Siberia.
Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1951, wọ́n kó àwa kan ré kọjá Siberia, wọ́n kó wa dé iyàn-níyàn Ìlà Oòrùn Jíjìnnà Réré. Oṣù kan gbáko la fi rìnrìn àjò—ìrìn àjò ẹgbẹ̀rún mọ̀kánlá kìlómítà—a la àgbègbè mọ́kànlá kọjá, tí ó jẹ́ pé òǹkà àkókò wọ́n yàtọ̀ síra! Lẹ́yìn ohun tó lé lọ́sẹ̀ méjì táa fi wà nínú rélùwéè, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo la dúró lọ́nà níbì kan tí wọ́n ti gbà wá láyè láti wẹ̀. Ìyẹn jẹ́ níbi balùwẹ̀ gbogbo gbòò kan ní ìlú Novosibirsk, ní Siberia.
Níbẹ̀, láàárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáǹtìrẹrẹ, mo gbọ́ tí ọkùnrin kan sọ lóhùn rara pé: “Ẹbí Jónádábù wo ló wà níhìn-ín?” A ń lo orúkọ náà “Jónádábù” nígbà yẹn láti fi dá àwọn tó ní ìrètí ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé mọ̀. (2 Ọba 10:15-17; Sáàmù 37:11, 29) Kíá ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n mélòó kan fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí. Ṣe la ń fò fẹ̀rẹ̀ fáyọ̀ báa ti ń kí ara wa!
Ìgbòkègbodò Tẹ̀mí Nínú Ẹ̀wọ̀n
Nígbà táa wà ní Novosibirsk, a fohùn ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ àdììtú kan táa lè máa fi dá ara wa mọ̀ nígbà táa bá dé ibi táa ń lọ. Ọgbà ẹ̀wọ̀n kan náà ni wọ́n kó wa lọ ní Òkun Japan, tí kò jìnnà sí Vladivostok. Níbẹ̀, a ṣètò àwọn ìpàdé déédéé fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wíwà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àgbàlagbà tó dàgbà dénú wọ̀nyí, táa dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún, fún mi lókun nípa tẹ̀mí ní tòótọ́. Wọ́n ń darí àwọn ìpàdé wa nígbà tó bá yí kàn wọ́n, wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, wọ́n sì ń mẹ́nu kan àwọn kókó tí wọ́n bá rántí láti inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́.
Wọ́n á béèrè ìbéèrè, àwọn ará á sì dáhùn. Púpọ̀ nínú wa yóò já bébà àpò sìmẹ́ǹtì, a ó sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ táa gbọ́ sí i. A óò tọ́jú àwọn bébà náà, a ó dì wọ́n pọ̀, olúkúlùkù yóò sì fi ṣe àkójọ ìwé tirẹ̀. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, wọ́n kó àwọn táa dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún lọ sí àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní ìpẹ̀kun àríwá Siberia. Wọ́n fi àwa arákùnrin mẹ́ta táa jẹ́ ọ̀dọ́ ránṣẹ́ sí Nakhodka, ìlú kan tó wà nítòsí, tí kò tó àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta [650] kìlómítà sí Japan. Ọdún méjì ni mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yẹn.
Nígbà mìíràn, a máa ń rí ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ gbà. Fún ọ̀pọ̀ oṣù, èyí ni oúnjẹ tẹ̀mí tí a óò máa jẹ. Nígbà tó ṣe, a tún ń rí lẹ́tà gbà. Lẹ́tà àkọ́kọ́ tí mo rí gbà látọ̀dọ̀ ìdílé mi (tó ti wà ní ìgbèkùn nígbà náà) mú kí n da omijé lójú. Gẹ́gẹ́ bí Ilé Ìṣọ́ tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ti sọ, lẹ́tà náà ṣàlàyé pé wọ́n ya bo ilé Àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n sì sọ fún àwọn ìdílé pé kí wọ́n kó jáde kíá, láàárín wákàtí méjì péré.
Èmi àti Ìdílé Mi Tún Wà Pa Pọ̀ Lẹ́ẹ̀kan Sí I
Wọ́n tú mi sílẹ̀ ní December 1952, lẹ́yìn tí mo ṣe ọdún méjì lára ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìn tí wọ́n dá fún mi. Mo lọ dara pọ̀ mọ́ ìdílé mi ní abúlé Gadaley nítòsí ìlú Tulun, ní Siberia, níbi tí wọ́n kó wọn lọ. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ ọ́, inú mi dùn gan-an láti wà pẹ̀lú wọn lẹ́ẹ̀kan sí i—Ivan, ọmọkùnrin mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́ta, Anna, ọmọbìnrin mi sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọdún méjì. Ṣùgbọ́n, òmìnira mi ní ààlà. Àwọn aláṣẹ àdúgbò gbẹ́sẹ̀ lé ìwé àṣẹ ìrìn àjò mi, wọ́n sì ń ṣọ́ mi tọwọ́ tẹsẹ̀. N kò lè rìn ju ìrìn àjò kìlómítà mẹ́ta sílé. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbà mí láyè láti gun ẹṣin lọ sọ́jà ní ìlú Tulun. Pẹ̀lú ìṣọ́ra, mo yọ́ dé ọ̀dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí níbẹ̀.
Nígbà yẹn, a ní ọmọbìnrin méjì, Anna àti Nadia, àti ọmọkùnrin méjì, Ivan àti Kolya. Ní ọdún 1958, a bí ọmọkùnrin mìíràn, táa sọ orúkọ rẹ̀ ní Volodya. Nígbà tó di 1961, a bí ọmọbìnrin mìíràn, táa sọ orúkọ rẹ̀ ní Galia.
Àwọn KGB (Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba) sábà máa ń wá gbé mi, wọ́n á sì máa lù mí lẹ́nu gbọ́rọ̀. Ète wọn ni láti gba ìsọfúnni nípa ìjọ lọ́wọ́ mi, kò tán síbẹ̀ o, wọ́n tún fẹ́ kí àwọn èèyàn máa fura pé mo ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn. Fún ìdí yìí, wọ́n á gbé mi lọ sí ilé àrójẹ tó dáa gan-an, wọ́n á wá gbìyànjú láti ya fọ́tò mi, bí mo ti ń rẹ́rìn-ín, tí èmi àtàwọn jọ ń jẹ̀gbádùn. Ṣùgbọ́n mo rí ọgbọ́nkọ́gbọ́n wọn, nítorí náà ṣe ni mo máa ń dijú mọ́rí nígbàkigbà táa bá jọ wà pa pọ̀. Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá wá gbé mi ni mo máa ń sọ gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ fún àwọn ará. Fún ìdí yìí, kò sígbà kan tí àwọn ará kọminú nípa ìdúróṣinṣin mi.
A Ń Kàn Sí Àwọn Tó Wà Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n
Ní ọ̀pọ̀ ọdún tó ti kọjá wọ̀nyí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n. Lákòókò yìí, ìgbà gbogbo la ń kàn sáwọn ará tó wà lẹ́wọ̀n, táa ń fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣọwọ́ sí wọn. Báwo la ṣe ń ṣe é? Nígbà tí wọ́n bá tú àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n máa ń sọ fún wa nípa ọ̀nà táa lè gbà yọ́ kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọlé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣọ́ ibẹ̀ lójú méjèèjì. Fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, ó ṣeé ṣe fún wa láti fi àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé ńlá táa gbà láti Poland àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣọwọ́ sí àwọn ará tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni arábìnrin wa ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ṣe iṣẹ́ àṣekára nídìí ṣíṣàdàkọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sínú ìwé tó kéré tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tó fi jẹ́ pé odindi ìwé ìròyìn á ṣeé fi pamọ́ sínú ohun tó kéré tó ilé ìṣáná! Lọ́dún 1991, nígbà tí a kò sí lábẹ́ ìfòfindè mọ́, tí a sì ń rí àwọn ìwé ìròyìn aláwọ̀ mèremère gbà, ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wa sọ pé: “A ó di ẹni ìgbàgbé báyìí.” Ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àní bí èèyàn tilẹ̀ gbàgbé, Jèhófà kò lè gbàgbé iṣẹ́ irú àwọn ẹni adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ láé!—Hébérù 6:10.
Ìṣípòpadà àti Àwọn Àjálù
Ní apá ìgbẹ̀yìn ọdún 1967, wọ́n lọ tú ilé àbúrò mi ọkùnrin ní Irkutsk. Wọ́n rí sinimá àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀. Wọ́n ló jẹ̀bi, nítorí náà wọ́n ní kó lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta jura. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wá tú ilé wa, wọn ò rí nǹkan kan. Síbẹ̀, àwọn aláṣẹ sọ pé ó dá àwọn lójú pé ọwọ́ wa ò mọ́, nítorí náà ó di dandan kí ìdílé mi ṣí kúrò lágbègbè yẹn. A ṣí lọ síbì kan tó tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] kìlómítà síhà ìwọ̀ oòrùn ìlú Nevinnomyssk lágbègbè Caucasus. Níbẹ̀, ọwọ́ wá dí nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí aláìjẹ́ bí àṣà.
Àjálù kan já lù wá lọ́jọ́ àkọ́kọ́ táwọn ọmọléèwé gba ìsinmi ní June 1969. Nígbà tí Kolya, ọmọkùnrin wa ọmọ ọdún méjìlá, fẹ́ lọ mú bọ́ọ̀lù nítòsí òpó iná ẹ̀lẹ́tíríìkì alágbára gíga, iná náà gbé e. Ìpín àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ara rẹ̀ ló jóná. Ní ọsibítù, ó yíjú sí mi, ó sì béèrè pé: “Ṣé a óò tún lè jọ lọ sí erékùṣù mọ́ báyìí?” (Ó ń sọ̀rọ̀ nípa erékùṣù kan táa sábà máa ń gbafẹ́ lọ.) Mo sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Kolya, a óò tún padà lọ sí erékùṣù yẹn. Nígbà tí Jésù Kristi bá jí ẹ dìde sí ìyè, dájúdájú, a ó lọ sí erékùṣù yẹn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń kú lọ, ó ń kọ ọkàn lára àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run tó fẹ́ràn gan-an, èyí tó máa ń fẹ́ láti fi kàkàkí rẹ̀ kọ nígbà tó bá ń bá ẹgbẹ́ akọrin ìjọ kọrin. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló kú, kò sì mikàn nípa ìrètí rẹ̀ nípa àjíǹde.
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n fẹ́ fi túláàsì mú Ivan, ọmọkùnrin wa ẹni ogún ọdún wọ ẹgbẹ́ ológun. Nígbà tó kọ̀, tó lóun ò ní wọ ẹgbẹ́ ogun, wọ́n mú un, ó sì ṣe ọdún mẹ́ta lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Lọ́dún 1971, wọ́n fẹ́ fi túláàsì mú èmi náà wọ ẹgbẹ́ ológun, wọ́n tún sọ pé àwọn máa jù mí sẹ́wọ̀n bí mo bá kọ̀. Wọ́n fi ẹjọ́ mi falẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù. Láàárín àkókò yìí ni àrùn jẹjẹrẹ kọlu ìyàwó mi, ó sì ń fẹ́ àbójútó. Wọ́n tìtorí èyí tú ẹjọ́ mi ká. Maria kú ní ọdún 1972. Ó jẹ́ olóòótọ́ alábàákẹ́gbẹ́ mi, ó dúró ṣinṣin ti Jèhófà títí dọjọ́ ikú rẹ̀.
Ìdílé Wa Tàn Káàkiri
Lọ́dún 1973, mo fẹ́ Nina ṣaya. Baba rẹ̀ lé e kúrò nílé lọ́dún 1960 torí pé ó di Ẹlẹ́rìí. Ó jẹ́ òjíṣẹ́ onítara, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arábìnrin tó ṣe iṣẹ́ àṣekára nídìí ṣíṣàdàkọ àwọn ìwé ìròyìn fún àwọn tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Àwọn ọmọ mi pẹ̀lú fẹ́ràn rẹ̀.
Ọkàn àwọn aláṣẹ kò balẹ̀ nítorí ìgbòkègbodò wà ní ìlú Nevinnomyssk, wọ́n sì rọ̀ wá pé ká fi ibẹ̀ sílẹ̀. Nítorí náà, lọ́dún 1975, èmi àti ìyàwó mi àtàwọn ọmọbìnrin mi ṣí lọ sí àgbègbè gúúsù Caucasus ní Georgia. Ní àkókò kan náà, àwọn ọmọkùnrin mi, Ivan àti Volodya, ṣí lọ sí Dzhambul ní ìhà gúúsù ààlà Kazakstan.
Ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní Georgia ni. A ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà nínú àti láyìíká Gagra àti Sukhumi ní Etí Òkun Dúdú, lẹ́yìn ọdún kan a sì batisí Àwọn Ẹlẹ́rìí tuntun mẹ́wàá nínú odò kan tó wà lórí òkè. Láìpẹ́ làwọn aláṣẹ tún yarí o, wọ́n ní àfira, ká káńgárá wa, ìyẹn la tún fi ṣí, ó di ìlà oòrùn Georgia. Níbẹ̀, a jára mọ́ṣẹ́ wíwá àwọn ẹni bí àgùntàn, Jèhófà sì fi èrè sí iṣẹ́ wa.
A ń pàdé pọ̀ ní àwọn àwùjọ kéékèèké. Ìṣòro èdè ń bẹ, níwọ̀n bí a kò ti gbọ́ èdè Georgia, àwọn ará Georgia kan kò sì gbọ́ èdè Rọ́ṣíà dáadáa. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ará Rọ́ṣíà nìkan là ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n, láìpẹ́ iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni lédè Georgia tẹ̀ síwájú, a sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run ní Georgia báyìí.
Lọ́dún 1979, nítorí ìyọlẹ́nu àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB, ẹni tó gbà mí síṣẹ́ sọ pé wọn ò fẹ́ mi mọ́ lórílẹ̀-èdè àwọn. Ìgbà yẹn ni jàǹbá ọkọ̀ kan ṣẹlẹ̀ tó gbẹ̀mí Nadia ọmọbìnrin mi àti ọmọbìnrin rẹ̀. Ìyá mi kú gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Jèhófà ní Nevinnomyssk lọ́dún tó ṣáájú, baba mi àti àbúrò mi ọkùnrin nìkan ló wá ń jùmọ̀ gbé. Nítorí náà, a pinnu láti padà sí ibẹ̀.
Àwọn Ìbùkún Tí Ìfaradà Mú Wá
Ní Nevinnomyssk, a ń bá a lọ ní pípèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lábẹ́lẹ̀. Nígbà kan, ní nǹkan bí ọdún 1985, tí àwọn aláṣẹ ké sí mi, mo sọ fún wọn pé mo lálàá pé mo ń fi àwọn ìwé ìròyìn wa pamọ́. Ó pa wọ́n lẹ́rìn-ín. Bí mo ti ń fi ibẹ̀ sílẹ̀, ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Àdúrà mi ni pé kí o má ṣe lálàá mọ́ pé o ń fi àwọn ìwé yín pamọ́.” Ó wá fi kún un pé: “Láìpẹ́, ìwọ yóò pàtẹ àwọn ìwé náà sínú pẹpẹ ìkówèésí rẹ, ìwọ àti ìyàwó rẹ yóò sì máa lọ sípàdé ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, pẹ̀lú Bíbélì lọ́wọ́.”
Lọ́dún 1989, inú wa bàjẹ́ nígbà tí àrùn ìwúlé iṣan ẹ̀jẹ̀ nínú ọpọlọ pa Anna, ọmọbìnrin mi. Ẹni ọdún méjìdínlógójì péré ni. Ní ọdún kan náà, ní August, Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Nevinnomyssk háyà rélùwéè kan, wọ́n sì rìnrìn àjò lọ sí ìlú Warsaw, ní Poland, láti lọ ṣe àpéjọpọ̀ àgbáyé. Ó lé ní 60,366 tó pésẹ̀, títí kan ẹgbẹẹgbẹ̀rún láti ilẹ̀ Soviet Union. Àlá ló jọ lójú wa! Ní ohun tó dín sí ọdún méjì lẹ́yìn náà, ní March 27, 1991, mo ní àǹfààní láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ márùn-ún, tí wọ́n jẹ́ ọlọ́jọ́ pípẹ́ ní ilẹ̀ Soviet Union, tó fọwọ́ sí ìwé mánigbàgbé náà ní Moscow, tó fìdí ètò àjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà múlẹ̀ lábẹ́ òfin!
Inú mi dùn pé àwọn ọmọ mi tó wà láàyè ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà. Mo sì ń wọ̀nà fún ayé tuntun Ọlọ́run, nígbà tí màá lè rí Anna, Nadia àti ọmọbìnrin rẹ̀ àti Kolya lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà tí a bá jí i dìde, màá mú ìlérí mi ṣẹ, màá mú un lọ sí erékùṣù táa jọ máa ń ṣeré lọ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
Ní báyìí ná, ẹ wo bí mo ti láyọ̀ tó láti rí ìtẹ̀síwájú yíyára kánkán tí òtítọ́ Bíbélì ń ní ní ilẹ̀ gbígbòòrò yìí! Inú mi dùn gan-an sí ìpín mi nínú ìgbésí ayé, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún jíjẹ́ kí n di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ó dá mi lójú gbangba pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Sáàmù 34:8, tó sọ pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di i.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ọdún tí mo dara pọ̀ mọ́ ìdílé mi ní Tulun
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Lókè: Baba mi àti àwọn ọmọ mi lóde ilé wa ní Tulun, Siberia
Òkè lápá ọ̀tún: Nadia ọmọbìnrin mi àti ọmọbìnrin rẹ̀ tí àwọn méjèèjì kú nínú jàǹbá ọkọ̀
Ọ̀tún: Fọ́tò ìdílé táa yà lọ́dún 1968