ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 8/8 ojú ìwé 23-25
  • Kí Ló Dé Tí Mọ́mì Fi Ń Ṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Dé Tí Mọ́mì Fi Ń Ṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Dé Tí Òbí Mi Fi Ń Ṣàìsàn?
  • Ìmọ̀lára Tí Ń Bani Nínú Jẹ́
  • Ohun Tí O Lè Ṣe
  • Dídúró Déédéé Nípa Tẹ̀mí
  • Bí Òbí Mi Bá Ń Mutí Lámujù Tó Sì Ń Lòògùn Olóró Ńkọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà á Bí Dádì Tàbí Mọ́mì Bá Kú?
    Jí!—2009
  • Ṣé Bí Mo Ṣe Ń Kẹ́dùn Dáa Báyìí?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Bí Àwọn Òbí Mi Kò Bá Fara Mọ́ Ìgbéyàwó Mi Ń Kọ́?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 8/8 ojú ìwé 23-25

Kí Ló Dé Tí Mọ́mì Fi Ń Ṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀?

Àrùn jẹjẹrẹ ló pa bàbá Al.a Ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa àjíǹde tí a ṣèlérí, tí Al ti kọ́, mú kó lè fara da àdánù náà bákan ṣá. Àmọ́, nígbà tí ìwádìí àwọn dókítà fi hàn pé ìyá rẹ̀ ní àrùn jẹjẹrẹ lára, ẹ̀rù tún bẹ̀rẹ̀ sí bà á. Èrò pé ìyá òun náà á tún kú mọ́ òun lójú dáyà já Al gan-an. Ó máa ń béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, ‘Kí ló ṣe wá jẹ́ ìyá mi làìsàn tún kì mọ́lẹ̀?’

GẸ́GẸ́ bí Ọ̀mọ̀wé Leonard Felder ṣe sọ, “ó lé ní ọgọ́ta mílíọ̀nù àwọn ará Amẹ́ríkà tí . . . ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ràn ń ṣàìsàn tàbí kó jẹ́ abirùn.” Felder fi kún un pé: “Lójoojúmọ́ ayé yìí, ó ń tó ẹnì kan lára òṣìṣẹ́ mẹ́rin ní Amẹ́ríkà tó tún ń tẹ́wọ́ gbé ẹrù iṣẹ́ bíbójútó òbí tí ń ṣàìsàn” tàbí ẹlòmíràn kan tí ó fẹ́ràn. Bí o bá bá ara rẹ nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ ló ń ṣẹlẹ̀ sí. Bó ti wù kó rí, ẹ̀rù á máa bà ẹ́ á sì máa dùn ẹ́ tí o bá ń rí ẹnì tí o nífẹ̀ẹ́ tó ń ṣàìsàn. Báwo lo ṣe lè fara dà á?

Kí Ló Dé Tí Òbí Mi Fi Ń Ṣàìsàn?

Òwe 15:13 sọ pé: “Nítorí ìrora ọkàn-àyà, ìdààmú máa ń bá ẹ̀mí.” Kò sí ohun tó burú nínú mímí ìmí ẹ̀dùn bí òbí rẹ bá ń ṣàìsàn. Fún àpẹẹrẹ, o lè lérò pé ìwọ lo lẹ̀bi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí òbí rẹ. Bóyá bí orogún ni ìwọ àti òbí rẹ náà ń ṣe síra yín. Bóyá ẹ ti jọ jiyàn lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì. Nígbà tí ara òbí náà kò wá yá nísinsìnyí, o lè máa rò pé ẹ̀bi rẹ ni. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbọ́nmi-si-omi-ò-to tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé ń fa àìfararọ, òun kọ́ ló sábà ń fa àìsàn tó le. Pákáǹleke àti àwọn èdèkòyedè pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lè ṣẹlẹ̀ nínú agbo ilé àwọn Kristẹni tí wọ́n tilẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn pàápàá. Nítorí náà, kò sí ìdí tí wàá fi máa dẹrù ẹ̀bi ru ara rẹ, bíi pé ìwọ lo kó àìsàn bá òbí rẹ.

Lọ́rọ̀ kan, ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ló fa àìsàn mọ́mì tàbí dádì ẹ. (Róòmù 5:12) Ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́ yẹn ló fà á tí “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.”—Róòmù 8:22.

Ìmọ̀lára Tí Ń Bani Nínú Jẹ́

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, o lè máa dààmú kí o sì máa ṣàníyàn. Àrùn lupus, àrùn kan tó máa ń ba ara jẹ́, ń ṣe màmá Terri. Terri sọ pé: “Ìgbàkigbà tí mi ò bá sí nílé, mo máa ń dààmú bóyá ara Mọ́mì balẹ̀. Mi ò lè fọkàn sí nǹkan tí mo ń ṣe. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí mi ò ti fẹ́ kó ṣèyọnu, mi ò jẹ́ kó mọ ẹ̀dùn ọkàn mi.”

Òwe 12:25 sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba.” Ìsoríkọ́ sábà máa ń ṣe àwọn èwe tí wọ́n ní ìṣòro yìí. Terri sọ pé ọkàn òun ń gbọgbẹ́ bí òun ṣe ń rí i tí ìyá òun kò lè ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mọ́. Ohun tó ń dá kún àìfararọ náà ni pé lọ́pọ̀ ìgbà ló máa di ọ̀ràn-anyàn fún àwọn èwe—pàápàá àwọn ọmọbìnrin—láti gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ sí i. Ọ̀jọ̀gbọ́n Bruce Compas sọ pé, “àwọn ẹrù iṣẹ́ ìdílé, bíi títọ́jú ilé àti títọ́jú àwọn àbúrò, máa ń wọ àwọn obìnrin lọ́rùn èyí sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí tí iṣẹ́ wọ̀nyẹn ju ohun tí agbára wọ́n lè gbé lọ, ó sì ń ṣèdíwọ́ fún bó ṣe yẹ kí wọ́n bá ẹgbẹ́ mu sí.” Àwọn ọ̀dọ́langba kan wá ń yí sí yíya ara wọn sọ́tọ̀, wọ́n á máa gbọ́ àwọn orin tó ń múni ronú tó sì ń múni sorí kọ́.—Òwe 18:1.

Ìbẹ̀rù pé òbí ẹni lè kú tún wọ́pọ̀. Terri nìkan làwọn òbí rẹ̀ bí, ìyá rẹ̀ nìkan ló sì ń dá tọ́ ọ. Gbogbo ìgbà tí ìyá Terri bá ti lọ sí ilé ìwòsàn ni Terri máa ń sunkún, ẹ̀rù á máa bà á pé ìyá òun ò ní dé mọ́. Terri sọ pé: “Èmi àti ẹ̀ nìkan náà ni. Mi ò fẹ́ kí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kú.” Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Martha náà sọ pé: “Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni mí, àmọ́ ẹ̀rù ṣì máa ń bà mí pé àwọn òbí mi lè kú. Ìmọ̀lára ìdáwà yóò sọ mí dìdàkudà gbáà.” Ìṣòro oorun, àlá tí ń dẹ́rù bani, àti àṣà jíjẹun lọ́nà òdì ni àwọn ohun mìíràn tó sábà máa ń ṣeni tí àìsàn bá ń ṣe òbí ẹni.

Ohun Tí O Lè Ṣe

Bó ti wù kó dà bíi pé nǹkan ṣòro tó nísinsìnyí, o lè forí tì í! Bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù àti ohun tó ń dà ẹ́ láàmú fún àwọn òbí rẹ. Báwo ni ohun tó ń ṣe òbí ẹ ṣe le tó gan-an? Ǹjẹ́ ara rẹ̀ ṣì lè yá? Ètò wo ni wọ́n ti ṣe nípa gbígbọ́ bùkátà ẹ tó bá ṣẹlẹ̀ pé ara òbí ẹ ò yá síbẹ̀? Ó ha ṣeé ṣe pé kí irú ohun kan náà ṣe ìwọ alára lọ́jọ́ iwájú? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í rọrùn fún àwọn òbí láti máa sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, bí o bá fara balẹ̀ tí o sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ní kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́, wọ́n lè sa gbogbo ipá wọn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí wọ́n sì fún ẹ níṣìírí.

Bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀lára tí ń gbéni ró tí o ní pẹ̀lú. Al rántí pé òun kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó gbọ́ pé àrùn jẹjẹrẹ ló ń pa ìyá òun lọ. Ó sọ pé: “Mi ò sọ bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó fún un. Mo mọ̀ pé ó fẹ́ gbọ́ kí n sọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba kan, ara ń tì mí láti sọ irú èrò bẹ́ẹ̀ fún un. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló kú, mo ń dá ara mi lẹ́bi nísinsìnyí nítorí pé mi ò lo àǹfààní tí mo ní. Mo kábàámọ̀ ohun tí mo ṣe yẹn nítorí pé òun ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé mi.” Má ṣàìjẹ́ kí àwọn òbí rẹ mọ bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó.

Bó bá ṣeé ṣe, ṣèwádìí nípa àìsàn òbí ẹ. (Òwe 18:15) Bóyá dókítà ìdílé yín lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nípa rẹ̀. Bí wọ́n bá ṣàlàyé dáadáa fún ẹ yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ agbatẹnirò, onísùúrù, àti olóye. Ó sì lè ṣèrànwọ́ láti múra ẹ sílẹ̀ fún ìyípadà èyíkéyìí tó lè ṣẹlẹ̀ lára òbí rẹ, bí àpá, irun ríre, tàbí àárẹ̀.

Ṣé ilé ìwòsàn ni òbí ẹ náà wà? Nígbà náà, máa túra ká, kí o sì máa gbé e ró tí o bá lọ wò ó. Jẹ́ kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yín kún fún ọ̀yàyà dáadáa. Sọ fún un nípa iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ àti àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. (Fi wé Òwe 25:25.) Bó bá jẹ́ orílẹ̀-èdè tí a ti retí pé kí àwọn ẹbí máa gbọ́únjẹ kí wọ́n sì máa ṣe àwọn nǹkan mìíràn fún aláìsàn lẹ ń gbé, ṣe ipa tìẹ níbẹ̀ láìṣàròyé. Mímúra nigín-nigín yóò ṣí òbí rẹ lórí, yóò sì tún sọ ohun tó dára nípa rẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn àti àwọn dókítà. Èyí lè mú kí ìtọ́jú tí òbí rẹ ń gbà gbé pẹ́ẹ́lí sí i.b

Ṣé ara òbí rẹ ń yá nílé? Nígbà náà, sa ipá rẹ láti ṣètọ́jú rẹ̀. Yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe èyí tó pọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ ilé. Gbìyànjú láti fara wé Jèhófà nípa lílo ara rẹ “pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni.” (Jákọ́bù 1:5) Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ẹ̀mí ọ̀yàyà, ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára, àti ẹ̀mí àìṣàròyé hàn.

Òtítọ́ ni pé o ṣì ní àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ láti ṣe. Gbìyànjú láti ya àkókò sọ́tọ̀ fún un, nítorí pé ẹ̀kọ́ rẹ ṣe pàtàkì síbẹ̀. Bó bá ṣeé ṣe, fi àkókò díẹ̀ sílẹ̀ fún ìsinmi àti eré ìtura. (Oníwàásù 4:6) Èyí á mára tù ọ́, á sì jẹ́ kí o lè ran òbí rẹ lọ́wọ́ dáadáa. Níkẹyìn, má ṣe máa ya ara rẹ sọ́tọ̀. Lo àǹfààní ìtìlẹ́yìn àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ. (Gálátíà 6:2) Terri sọ pé: “Ìjọ wá di ìdílé mi. Ìgbà gbogbo ni àwọn alàgbà ń fẹ́ láti bá mi sọ̀rọ̀ àti láti fún mi níṣìírí. Mi ò jẹ́ gbàgbé ìyẹn.”

Dídúró Déédéé Nípa Tẹ̀mí

Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú gbogbo rẹ̀ ni dídúró déédéé nípa tẹ̀mí. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, bíi kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sí àwọn ìpàdé, àti wíwàásù fún àwọn ẹlòmíràn. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Ní àwọn oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, Terri máa ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láti fi kún ipa tó ń kó nínú ìgbòkègbodò ìjíhìnrere. Ó fi kún un pé: “Mọ́mì sábà máa ń fún mi níṣìírí pé kí n máa múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ kí n sì máa lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìyẹn wá ṣàǹfààní fún àwa méjèèjì. Níwọ̀n bí kò ti lè lọ sí ìpàdé bó ṣe fẹ́, mo túbọ̀ máa ń tẹ́tí sílẹ̀ gan-an kí n bàa lè sọ àwọn ohun tí mo gbọ́ fún un tó bá yá. Ó gbára lé mi láti máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún un nígbà tí kò lè lọ.”

Àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn The New York Times ṣàlàyé ẹ̀ dáadáa nígbà tó sọ nípa òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan tí “ń ṣe kàyéfì léraléra nípa bí àwọn ọmọ ṣe ń dàgbà dénú, tí wọ́n tilẹ̀ ń ṣàṣeyọrí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn òbí wọn ń kó hílàhílo bá wọn.” Ó sọ pé: “Wọ́n ń lo àwọn òye kan tí wọn kò mọ̀ pé àwọn ní . . . Bí wọ́n bá lè la hílàhílo yìí já, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n lè là já.”

Ìwọ náà lè la àkókò ìṣòro yìí já. Fún àpẹẹrẹ, ara ìyá Terri ti yá tó láti tọ́jú ara rẹ̀. Bí àkókò ṣe ń lọ, bóyá ara àwọn òbí tìẹ náà á yá. Ṣùgbọ́n ní báyìí ná, má gbàgbé pé Jèhófà, Ọ̀rẹ́ rẹ tí ń bẹ lọ́run, ń tì ọ́ lẹ́yìn. Òun ni “Olùgbọ́ àdúrà,” yóò sì tẹ́tí sí igbe ẹ̀bẹ̀ rẹ. (Sáàmù 65:2) Yóò fún ìwọ—àti òbí rẹ tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run—ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” kí o lè forí tì í.—2 Kọ́ríńtì 4:7; Sáàmù 41:3.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Àpilẹ̀kọ “Ṣiṣebẹwo Sọdọ Alaisan Kan—Bi A Ṣe Le Ṣeranlọwọ,” tó wà nínú Jí!, October 8, 1991, ní àwọn àbá mélòó kan tó gbéṣẹ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

“Ìgbàkigbà tí mi ò bá sí nílé, mo máa ń dààmú bóyá ara Mọ́mì balẹ̀”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ṣíṣèwádìí nípa àìsàn tó ń ṣe òbí rẹ lè mú ọ gbára dì láti ṣèrànwọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́