Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Bí Àwọn Òbí Mi Kò Bá Fara Mọ́ Ìgbéyàwó Mi Ń Kọ́?
Lakesha àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ń gbèrò láti ṣègbéyàwó, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ kò fọwọ́ sí i. Lakesha wí pé: “N ó di ọmọ ọdún 19 lọ́dún yìí, ṣùgbọ́n mọ́mì mi ń rin kinkin pé kí a dúró kí n pé ọmọ ọdún 21.”
BÍ O bá ti ń wéwèé láti ṣègbéyàwó, ó wulẹ̀ bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí o fẹ́ kí àwọn òbí rẹ bá ọ yọ̀. Ó lè dà ọ́ láàmú bí àwọn òbí rẹ kò bá fẹ́ kí o fẹ́ ẹni tí o yàn láti bá ṣègbéyàwó. Kí ló yẹ kí o ṣe? Ṣé kí o ṣàìka ìfẹ́ inú wọn sí, kí o sì máa bá ètò ìgbéyàwó tí o ń ṣe lọ ní tìrẹ?a
Èyí lè jẹ́ ìdẹwò kan bí o bá ti dàgbà, tí o sì lè ṣègbéyàwó tó bófin mu láìsí ìfọwọ́sí àwọn òbí rẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, Bíbélì kò la ọjọ́ orí kankan sílẹ̀ ní ti bíbọ̀wọ̀ fún àwọn òbí ẹni àti bíbọlá fún wọn. (Òwe 1:8) Bí o kò bá sì ka èrò wọn sí, o lè ṣe ìbàjẹ́ tí kò ní tán bọ̀rọ̀ fún ipò ìbátan ìwọ pẹ̀lú wọn. Síwájú sí i, ó ṣeé ṣe—bóyá kí ó tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀—pé kí àwọn òbí rẹ ní àwọn ìdí fífẹsẹ̀múlẹ̀ láti ṣàìfaramọ́ ìgbéyàwó rẹ.
Ọjọ́ Orí Wo Ni Ẹnì Kan Ti Kéré Jù?
Bí àpẹẹrẹ, ṣe àwọn òbí rẹ ń sọ fún ọ pé o ti kéré jù láti ṣègbéyàwó ni? Ó dára, Bíbélì kò fi ọjọ́ orí kíkéré jù fún ìgbéyàwó lélẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dámọ̀ràn pé, kí ẹnì kan tó ṣègbéyàwó, ó gbọ́dọ̀ ti “ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe”—àwọn ọdún lẹ́yìn ìgbà ìbàlágà, nígbà tí ìfẹ́ ọkàn fún ìbálòpọ̀ mú hánhán. (Kọ́ríńtì Kíní 7:36) Èé ṣe? Nítorí pé irú àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìdàgbàdénú nípa ti ìmọ̀lára, ìkóra-ẹni-níjàánu, àti àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tó pọn dandan láti ṣàṣeyọrí bíbójútó ìgbésí ayé ìdílé dàgbà ni.—Fi wé Kọ́ríńtì Kíní 13:11; Gálátíà 5:22, 23.
Nígbà tí Dale, ọmọ 20 ọdún, fẹ́ ṣègbéyàwó, ìdààmú bá a nítorí pé àwọn òbí rẹ̀ kò fara mọ́ ọn. Ó ní: “Wọ́n sọ pé mo ti kéré jù, n kò sì nírìírí. Mo rò pé èmi àti àfẹ́sọ́nà mi ti ṣe tán, a sì lè máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i lẹ́yìn ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n àwọn òbí mi fẹ́ láti rí àrídájú pé kì í ṣe ìmọ̀lára lásán ló ń sún mi hùwà. Wọ́n bi mí ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Mo ha ti gbára dì láti bójú tó ṣíṣe àwọn ìpinnu ojoojúmọ́, àwọn ìnáwó, ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa pípèsè fún ìdílé ní ti ohun ìní, ní ti ìmọ̀lára, àti ní ti ẹ̀mí bí? Mo ha ti gbára dì láti di òbí bí? Mo ha ti kẹ́kọ̀ọ́ bí a ti í jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ ní gidi bí? Mo ha ti lóye àwọn ohun tí ó jẹ́ àìní alábàáṣègbéyàwó kan ní gidi bí? Wọ́n lérò pé ó yẹ kí n mọ ara mi dunjú bí àgbàlagbà kan kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó àgbàlagbà míràn.
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò fẹ́ dúró, a sún ìgbéyàwó wa síwájú kí a lè yọ̀ǹda àkókò fún ara wa láti dàgbà dénú. Nígbà tí a wá ṣègbéyàwó níkẹyìn, a bẹ̀rẹ̀ ipò ìbátan náà pẹ̀lú ìpìlẹ̀ tí ó sàn jù, tí a sì túbọ̀ tóótun láti ṣètìlẹ́yìn fún ìgbéyàwó náà.”
Nígbà Tí Ìsìn Tó Yàtọ̀ Bá Jẹ́ Kókó Ọ̀ràn Náà
Nígbà tí Terri kó wọnú ọ̀ràn ìfẹ́ pẹ̀lú ọkùnrin kan tí ìsìn rẹ̀ yàtọ̀, ó ń bá a ròde láṣìírí. Lẹ́yìn tí wọ́n kéde ìwéwèé wọn láti ṣègbéyàwó, ó ba Terri nínú jẹ́ láti rí i pé mọ́mì òun kò fọwọ́ sí ìgbéyàwó náà. Terri dárò pé: “N kò fẹ́ kí mọ́mì lérò báyìí nípa mi. Mo fẹ́ kí a ní ìbátan ìyá àti ọmọ síbẹ̀.”
Ṣùgbọ́n ta ní ń dí ìbátan yẹn lọ́wọ́ ní gidi? Ìyá Terri ha jẹ́ amúnibínú tàbí aláìgbatẹnirò bí? Rárá, ó wulẹ̀ ń rọ̀ mọ́ ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún àwọn Kristẹni láti ṣe ìgbéyàwó “kìkì nínú Olúwa” ni. (Kọ́ríńtì Kíní 7:39) Ní gidi, Bíbélì pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ mọ́ra sábẹ́ àjàgà pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” (Kọ́ríńtì Kejì 6:14, 15) Èé ṣe tó fi rí bẹ́ẹ̀?
Ìdí kan ni pé, ìṣọ̀kan ní ti ìsìn jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú ìgbéyàwó aláyọ̀ tó kẹ́sẹ járí. Àwọn ògbóǹkangí sọ pé àwọn másùnmáwo àti pákáǹleke tó wọ́pọ̀ nínú ìgbéyàwó àwọn onísìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdí kan tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì ni bí ó ṣe ṣeé ṣe tó láti mú kí a fi àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn ẹni báni dọ́rẹ̀ẹ́—tàbí láti pa wọ́n tì pátápátá. Kódà, ká ní alábàáṣègbéyàwó kan kò dí ọ̀ràn ìjọsìn rẹ lọ́wọ́, ìwọ yóò ṣì ní láti máa bá ìmọ̀lára tí kò bára dé wọ̀yá ìjà, nítorí pé o kò ní lè ṣàjọpín àwọn ìdánilójú àtọkànwá rẹ pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ha jọ ohun tí a nílò fún ayọ̀ kíkún nínú ìgbéyàwó bí?
Nítorí náà, Terri ní ìpinnu kan tí kò rọrùn láti ṣe. Terri wí pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, ṣùgbọ́n n kò fẹ́ fi ọ̀rẹ́kùnrin mi sílẹ̀.” Kò wulẹ̀ lè ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe méjèèjì pa pọ̀. O kò lè fi ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run báni dọ́rẹ̀ẹ́, kí o sì máa gbádùn ojú rere àti ìbùkún rẹ̀ nìṣó.
Àmọ́, bóyá àwọn òbí rẹ kò fara mọ́ pé kí o bá Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ kan pàtó ṣègbéyàwó. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí o fi àìdọ́gba so pọ̀ mọ́ra sábẹ́ àjàgà pẹ̀lú onígbàgbọ́ kan? Bẹ́ẹ̀ ni, bí ẹni yẹn kò bá bá ọ ṣàjọpín àwọn ìlépa tẹ̀mí tàbí ìfọkànsìn kan náà fún Ọlọ́run. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, tàbí bí àwọn ará nínú ìjọ rẹ̀ kò bá “ròyìn rẹ̀ dáradára,” lọ́nà títọ́, àwọn òbí rẹ lè dààmú nípa bíbá tí o fẹ́ bá ẹni náà ṣègbéyàwó.—Ìṣe 16:2.
Ìyàtọ̀ Ẹ̀yà Tàbí Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Ńkọ́?
Àwọn òbí Lynn ṣàtakò nítorí ìdí kan tí ó yàtọ̀: Ó fẹ́ fẹ́ ọkùnrin kan láti inú ẹ̀yà míràn. Kí ni Bíbélì fi kọ́ni nípa èyí? Ó sọ fún wa pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,” àti pé “láti ara ọkùnrin kan ni ó . . . ti ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 10:34, 35; 17:26) Àwọn ẹ̀dá ènìyàn ní orírun kan náà, wọ́n sì níye lórí lọ́gbọọgba lójú Ọlọ́run.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí gbogbo àwọn lọ́kọláya ń ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn,” ó ṣeé ṣe kí àwọn tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ síra ní àfikún ìpèníjà. (Kọ́ríńtì Kíní 7:28) Èé ṣe? Nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú ayé òde òní tí ó kún fún ìkórìíra kò tẹ́wọ́ gba èrò Ọlọ́run nípa ẹ̀yà. Nígbà tí ìgbéyàwó àwọn tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ síra ti ń gbilẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ ìhà Ìwọ̀ Oòrùn mélòó kan, àwọn àgbègbè kan wà tí àwọn lọ́kọláya tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ síra ṣì ń kojú ẹ̀tanú mímú hánhán. Nítorí náà, àwọn òbí rẹ lè fòyà pé o kò lágbára tó láti kojú irú pákáǹleke bẹ́ẹ̀.
Lynn sọ pé: “Àwọn òbí mi rò pé yóò ni wá lára.” Lọ́nà ọlọgbọ́n, Lynn bọ̀wọ̀ fún èrò wọn, kò sì sáré kó wọnú ìgbéyàwó. Bí àwọn òbí rẹ̀ ṣe kíyè sí ìdàgbàdénú Lynn, tí wọ́n sì túbọ̀ di ojúlùmọ̀ ọkùnrin tí ó nífẹ̀ẹ́ náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìgbọ́kànlé dídájú pé Lynn lè kojú pákáǹleke ìgbéyàwó yìí. Lynn wí pé: “Ní kété tí wọ́n rí i pé a lè láyọ̀ pa pọ̀ ní tòótọ́, wọ́n bá wa yọ̀.”
Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà míràn, ọ̀ràn náà kì í ṣe ti ẹ̀yà, bí kò ṣe ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí rẹ máa ṣàníyàn pé, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó lè wá ṣòro fún ọ láti gbádùn àjùmọ̀gbé pẹ̀lú ẹnì kan tí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀, àwọn ìfojúsọ́nà rẹ̀, àti àwọn oúnjẹ, orin, àti eré ìnàjú tó yàn láàyò yàtọ̀ púpọ̀ sí tìrẹ. Ohun tó wù kí ipò náà jẹ́, bíbá ẹnì kan tí ẹ̀yà tàbí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀ yàtọ̀ ṣègbéyàwó lè mú àwọn ìpèníjà ńlá wá. O ha tóótun láti kojú wọn ní gidi bí?
Bí Ó Bá Jọ Pé Àtakò Òbí Kan Kò Bọ́gbọ́n Mu
Ṣùgbọ́n bí o bá rò pé àwọn òbí rẹ kò gba tìrẹ rò rárá nípa àtakò náà ńkọ́? Ọ̀dọ́bìnrin kan tí ń jẹ́ Faith sọ nípa ìyá rẹ̀ pé: “Mọ́mì ti ṣe ìkọ̀sílẹ̀ nígbà mélòó kan. Ó sọ pé o kò lè mọ ẹni tí o fẹ́ títí di ìgbà tó bá ti pẹ́ jù. Ó gbà gbọ́ dájú pé n kò lè láyọ̀ nínú ìgbéyàwó.” Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí tí ìgbéyàwó tiwọn fúnra wọn kò láyọ̀ kì í lè bojú wo ìgbéyàwó ọmọ wọn láìjẹ́ kí èrò tiwọn nípa lórí rẹ̀. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn òbí ń ní àwọn ìdí tí ń múni ṣe kàyéfì fún títako ìgbéyàwó ọmọ wọn, bí ìfẹ́ ọkàn láti máa darí ìgbésí ayé ọmọ náà nìṣó.
Bí àwọn òbí rẹ kò bá fẹ́ gbọ́ àlàyé bíbọ́gbọ́nmu, kí ni o lè ṣe? Láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a lè ké sí àwọn alàgbà ìjọ fún ìrànlọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro ìdílé. Láìṣègbè, wọ́n lè ran àwọn mẹ́ńbà ìdílé lọ́wọ́ láti jíròrò lọ́nà onípẹ̀lẹ́tù, alálàáfíà, tí ó sì mú èso wá.—Jákọ́bù 3:18
Wíwá Àlàáfíà
Dájúdájú, ọ̀pọ̀ ìdí mìíràn, bí ọ̀ràn ìṣúnná tàbí ànímọ́ ìwà ẹni tí o fẹ́ bá ṣègbéyàwó náà, lè fa kí àwọn òbí rẹ má fara mọ́ ṣíṣègbéyàwó rẹ. Ní ayé tí àrùn AIDS àti àwọn àrùn míràn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré sì gbilẹ̀ yí, lọ́nà títọ́, àwọn òbí rẹ lè dàníyàn nípa ìlera rẹ, bí àfẹ́sọ́nà rẹ bá ti gbé ìgbésí ayé oníṣekúṣe sẹ́yìn, kí ó tó di Kristẹni.b
Níwọ̀n ìgbà tí o bá ṣì ń gbé abẹ́ òrùlé àwọn òbí rẹ, ẹrù iṣẹ́ rẹ ni láti mọ ọlá àṣẹ wọn lórí rẹ lámọ̀jẹ́wọ́. (Kólósè 3:20) Àmọ́, bí o bá tilẹ̀ ń dá gbé, tí o sì dàgbà tó láti dá àwọn ìpinnu ṣe fúnra rẹ, má ṣe yára máa kó àwọn ìdàníyàn àwọn òbí rẹ dà nù. Múra tán láti fetí sí wọn. (Òwe 23:22) Fara balẹ̀ gbé àwọn àbáyọrí tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ yọ látàrí ṣíṣègbéyàwó yẹ̀ wò.—Fi wé Lúùkù 14:28.
Lẹ́yìn tí o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, o lè wá pinnu pé o fẹ́ ṣègbéyàwó síbẹ̀. Lọ́nà àdánidá, ìwọ yóò ní láti gbé ẹrù irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ ní kíkún. (Gálátíà 6:5) Bí o bá ti ṣe gbogbo ìsapá láti ṣàgbéyẹ̀wò ojú ìwòye àwọn òbí rẹ, bóyá ó lè mú kí wọ́n ti ìpinnu rẹ lẹ́yìn, kódà bí wọ́n bá tilẹ̀ lọ́ra. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà síbẹ̀, gbìyànjú láti má kanra tàbí bínú. Rántí pé: Àwọn òbí rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ, wọ́n sì bìkítà nípa ayọ̀ rẹ ọjọ́ ọ̀la. Máa gbìyànjú nìṣó láti wà lálàáfíà pẹ̀lú wọn. Bí o ti ń ṣàṣeyọrí nínú ìgbéyàwó rẹ, ó ṣeé ṣe kí ìṣarasíhùwà wọn má le koko mọ́.
Lọ́nà míràn, bí o bá ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo ohun tí àwọn òbí rẹ ní láti sọ, tí o sì baralẹ̀ wo ara rẹ àti ẹni tí o ń hára gàgà láti bá ṣègbéyàwó náà kínníkínní, máà jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu bí o bá dórí ìpinnu yíyanilẹ́nu náà pé, ní àbárèbábọ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí rẹ̀ ti tọ̀nà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ìsọfúnni inú àpilẹ̀kọ yìí wà fún àwọn èwe ní àwọn ilẹ̀ tí ó ti jẹ́ àṣà pé kí ẹnì kan fúnra rẹ̀ yan ẹni tí yóò bá ṣègbéyàwó.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ṣíṣèrànwọ́ fún Àwọn Alárùn AIDS,” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, March 22, 1994.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn òbí rẹ lè rò pé o ti kéré jù láti ṣègbéyàwó