Ojú Ìwòye Bíbélì
Ìṣọ̀kan Ìjọsìn Nínú Ìgbéyàwó—Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì
ÌDÍLÉ kan jókòó, wọ́n fẹ́ jẹun alẹ́. Bí bàbá ti ń gbàdúrà, ni ìyá náà ń gba tirẹ̀ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sọ́lọ́run mìíràn. Nínú ìdílé mí-ìn, ìyàwó ń jọ́sìn ní ṣọ́ọ̀ṣì, ṣùgbọ́n sínágọ́gù lọkọ ń lọ. Àwọn ìdílé wà tí òbí kan ti ń kọ́ àwọn ọmọ nípa Bàbá Kérésì, ṣùgbọ́n tí òbí kejì ń sọ fún wọn nípa Hánúkà.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí ti wí, irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti wọ́pọ̀ báyìí, torí pé àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ń fẹ́ àwọn tí wọn ò jọ ṣẹ̀sìn kan náà. Ìwádìí kan fi hàn pé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìpín mọ́kànlélógún nínú ìpín ọgọ́rùn-ún àwọn Kátólíìkì ló ń fẹ́ àwọn tí wọn ò jọ ṣẹ̀sìn kan náà báyìí; iye àwọn tí ń ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Mormon jẹ́ ìpín ọgbọ̀n nínú ìpín ọgọ́rùn-ún; láàárín àwọn Mùsùlùmí, ó jẹ́ ìpín ogójì nínú ìpín ọgọ́rùn-ún; àti láàárín àwọn Júù, ó lé ní ìdajì gbogbo wọn. Nítorí ìjà ẹ̀sìn tó ti ń dalẹ̀ rú fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn kan gbà pé fífẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn mí-ìn fi hàn pé a ti ṣẹ́gun àìráragba-nǹkan-sí. Òǹkọ̀wé kan nínú ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Ṣe ló yẹ ká máa kókìkí ìgbéyàwó èyíkéyìí tó bá wáyé láàárín àwọn méjì tí ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.” Ṣé ojú tí Bíbélì fi ń wò ó nìyí?
Ó yẹ fún àfiyèsí pé Bíbélì kò ṣètìlẹyìn fún ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò gbé ìran kan ga ju òmíràn lọ. Àpọ́sítélì Pétérù kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa kókó yìí, ohun tó sọ rèé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Lẹ́sẹ̀ kan náà, Bíbélì kọ́ni pé àwọn tí ń fòtítọ́ sin Jèhófà ní láti ṣe ìgbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Èé ṣe?
Ète Ìgbéyàwó
Ọlọ́run pète pé kí ìgbéyàwó jẹ́ ìdè àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Nígbà tí Ọlọ́run dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, kì í kàn-án ṣe ọ̀ràn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ nìkan ló ní lọ́kàn. Nígbà tí Jèhófà gbé iṣẹ́ títọ́mọ àti bíbójútó ilé ayé lé tọkọtaya àkọ́kọ́ lọ́wọ́, ó fi hàn pé wọ́n ní láti máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀ tímọ́tímọ́ láti mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Nípa fífọwọ́sowọ́pọ̀ nínú sísin Ọlọ́run lọ́nà yìí, kì í ṣe kìkì ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ nìkan ni ọkùnrin àti obìnrin yóò gbádùn, ṣùgbọ́n wọn yóò tún gbádùn àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́, tó sì wà pẹ́ títí.—Fi wé Málákì 2:14.
Jésù mẹ́nu kan ọ̀ràn àjọṣepọ̀ yìí nígbà tó sọ àwọn ọ̀rọ̀ táa mọ̀ bí ẹní mowó náà, pé: “Wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:6) Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ni Jésù lò nígbà tó fi ìdè ìgbéyàwó wé àjàgà tó so ẹranko méjì pọ̀ bí wọ́n ti jọ ń wọ́ ẹrù kan. Sáà fojú inú wo bí ara yóò ti máa ni àwọn ẹranko méjì táa so pọ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n ń fa ara wọn lọ síhà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀! Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn tí kò bá ṣe ìgbéyàwó nínú ẹ̀sìn tòótọ́ lè rí i pé ara ń ni àwọn gan-an bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì, ṣùgbọ́n tí ẹnì kejì wọn ń gbé nǹkan gba ọ̀nà mí-ìn. Ó bá a mu wẹ́kú, nígbà tí Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:14.
Irú Ìgbéyàwó Tó Dáa Jù
Ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́ lè fún ìgbéyàwó lókun gan-an. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Jíjọ́sìn pa pọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ànímọ́ pàtàkì tí ń so ìdílé aláyọ̀, tó gbámúṣé pọ̀.” Oníwàásù 4:9, 10 sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn. Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.”
Kristẹni tọkọtaya yóò wà níṣọ̀kan nípa tara àti nípa tẹ̀mí bí wọ́n bá fi ọ̀ràn ìjọsìn sí ipò àtàtà nínú ìgbésí ayé wọn. Bí wọ́n ti ń gbàdúrà pọ̀, tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀, tí wọ́n ń pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n sì ń ṣàjọpín ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmí-ìn, ṣe ni wọ́n ń mú ìdè tẹ̀mí tó túbọ̀ ń mú kí wọ́n sún mọ́ra tímọ́tímọ́ dàgbà nínú ìgbéyàwó wọn. Kristẹni obìnrin kan sọ pé: “Ìjọsìn tòótọ́ ni ọ̀nà ìyè. Mi ò tilẹ̀ lè ronú àtifẹ́ ẹnì kan tí kò ní ojú ìwòye mi nípa ohun tó pinnu irú ẹni tí mo jẹ́.”—Fi wé Máàkù 3:35.
Àwọn tó bá ṣe ìgbéyàwó “nínú Olúwa” lè retí pé kí ọkọ tàbí aya wọ́n máa fara wé ìwà Jésù. Àwọn Kristẹni ọkọ ní láti máa hùwà sí aya wọn bí Jésù ti fi tìfẹ́tìfẹ́ hùwà sí ìjọ. Àwọn Kristẹni aya ní láti máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:25, 29, 33) Àwọn Kristẹni ń ṣe èyí, kì í ṣe kìkì nítorí pé wọ́n fẹ́ máa mú inú ọkọ tàbí aya wọn dùn nìkan ni, ṣùgbọ́n nítorí pé wọ́n fẹ́ máa mú inú Ọlọ́run dùn, ẹni tó sọ pé àwọn tọkọtaya yóò jíhìn fóun nípa irú ìwà tí wọ́n hù síra wọn.—Málákì 2:13, 14; 1 Pétérù 3:1-7.
Gbígba ohun kan náà gbọ́ tún máa ń ran àwọn tọkọtaya Kristẹni lọ́wọ́ láti yanjú èdè-àìyedè ní ìtùnbí-ìnùbí. Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara [wọn] nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Láìka ìyàtọ̀ nínú ohun táa fẹ́ sí, tọkọtaya tó wà níṣọ̀kan nínú ìgbàgbọ́ máa ń yíjú sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ àjọgbà fún yíyanjú aáwọ̀ èyíkéyìí. (2 Tímótì 3:16, 17) Lọ́nà yìí, wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n ní “èrò inú kan náà.”—1 Kọ́ríńtì 1:10; 2 Kọ́ríńtì 13:11; Fílípì 4:2.
Òòfà Ìfẹ́ àti Àwọn Ìlànà Àjọgbà
A gbà pé kìkì ṣíṣe ẹ̀sìn kan náà kò tó láti gbé ìbátan kan ró. Ó tún yẹ kí òòfà ìfẹ́ wà láàárín tọ̀túntòsì. (Orin Sólómọ́nì 3:5; 4:7, 9; 5:10) Ṣùgbọ́n kí ìgbéyàwó tó lè wà pẹ́ títí, àwọn ìlànà àjọgbà ṣe kókó. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà Are You the One for Me? ti wí “ó máa ń rọrùn jù lọ fáwọn tọkọtaya tó jùmọ̀ ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà kan náà láti ní ìbátan aláyọ̀, tó wà ní ìṣọ̀kan, tó sì wà pẹ́ títí.”
Ó ṣeni láàánú pé, ó lè di ẹ̀yìn ìgbéyàwó kí àwọn èèyàn tí ọkàn wọn fà síra tó máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyàtọ̀ gidi tó wà láàárín wọn. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o ra ilé kan ní pàtàkì nítorí pé ó wù ẹ́ lójú. Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ìgbà tóo kó dénú ilé náà lo tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé ìpìlẹ̀ ahẹrẹpẹ ni ilé náà ní. Pẹ̀lú ìpìlẹ̀ yọ́gẹyọ̀gẹ ilé náà, gbogbo ẹwà ilé náà di òtúbáńtẹ́. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọkàn èèyàn lè fà sí ẹnì kan tó ń ṣe ẹ̀sìn mìíràn, tó jọ pé ìwà wọ́n bára mu—àmọ́ lẹ́yìn ìgbéyàwó, ìbátan náà lè kún fún àwọn àlèébù.
Ronú nípa àwọn ìṣòro lílekoko tó lè yọjú lẹ́yìn ìgbéyàwó tọkọtaya tí ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Ibo ni ìdílé yóò ti máa jọ́sìn? Ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn wo la ó fi kọ́ àwọn ọmọ? Ẹ̀sìn wo ni ìdílé yóò máa fi owó tì lẹ́yìn? Ǹjẹ́ ọkọ tàbí aya máa ranrí pé dandan ni kí òun lọ́wọ́ nínú àwọn ààtò kan tàbí kí òun bá wọn ṣe àwọn ọdún kan tí ẹnì kejì rẹ̀ kà sí ìbọ̀rìṣà? (Aísáyà 52:11) Gbogbo ìgbéyàwó ló ń béèrè pé kí ọkọ tàbí aya ṣe àwọn ìyípadà tó bọ́gbọ́n mu; àmọ́, fífi àwọn ìlànà Bíbélì báni dọ́rẹ̀ẹ́—àní torí kí ìgbéyàwó má bàa tú—kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.—Fi wé Diutarónómì 7:3, 4; Nehemáyà 13:26, 27.
Kí àlàáfíà lè wà nínú ilé, ṣe ni àwọn tọkọtaya kan tí ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń dá ẹ̀sìn tiwọn ṣe. Ṣùgbọ́n, ó mà ṣe o, dídá ẹ̀sìn ẹni ṣe máa ń sọ ipò tẹ̀mí dasán nínú ìgbéyàwó. Kristẹni obìnrin kan tó fẹ́ ọkùnrin ẹlẹ́sìn mí-ìn sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pé ogójì ọdún báyìí táa ti ṣe ìgbéyàwó, ọkọ mi kò mọ̀ mí ní ti gidi.” Bẹ́ẹ̀ rèé, Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbéyàwó tí tọkọtaya ti ń jọ́sìn “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti ké e léwì, “okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò sì lè tètè fà já sí méjì.”—Jòhánù 4:23, 24; Oníwàásù 4:12.
Àwọn Ọmọ Ńkọ́?
Àwọn kan tí ń ronú nípa fífẹ́ ẹni tí ń ṣe ẹ̀sìn mìíràn lè nímọ̀lára pé àwọn lè fojú àwọn ọmọ mọ ẹ̀sìn méjèèjì, kí wọ́n sì jẹ́ kí àwọn ọmọ yan ẹ̀sìn tó wù wọ́n. Òtítọ́ ni, òbí méjèèjì ló ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin àti lọ́nà ìwà rere láti pèsè ìtọ́ni ẹ̀sìn, tó bá sì yá, àwọn ọmọ á wá ṣe ìpinnu tó wù wọ́n.a
Bíbélì fún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn “ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (Éfésù 6:1) Òwe 6:20 sọ ọ́ lọ́nà yìí: “Ìwọ ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́, má sì ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì.” Dípò fífi ìgbàgbọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kọ́ ọmọ, àwọn ọmọ táwọn òbí méjì tó ní ìgbàgbọ́ kan náà tọ́ dàgbà, máa ń wà níṣọ̀kan nínú ohun tí Bíbélì pè ní “Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan.”—Éfésù 4:5; Diutarónómì 11:19.
“Nínú Olúwa” Lóòótọ́
Bí títẹ̀lé àwọn ìlànà àjọgbà bá jẹ́ kókó pàtàkì nínú ìgbéyàwó tó yọrí sí rere, ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti wulẹ̀ fẹ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé Kristẹni lòun? Bíbélì dáhùn pé: “Ẹni tí ó bá sọ pé òun dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Jésù] wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe pẹ̀lú láti máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ẹni yẹn ti rìn.” (1 Jòhánù 2:6) Nípa báyìí, Kristẹni tó bá ń ronú àtigbéyàwó yóò wá Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó ń sapá láti tẹ̀ lé Jésù ní ti gidi. Irú àfẹ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ yóò ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, a ó sì ti batisí rẹ̀. Yóò ní irú àkópọ̀ ìwà onífẹ̀ẹ́ tí Jésù ní, yóò sì ní irú ìtara tó ní nínú wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bó ti rí nínú ọ̀ràn Jésù, ìgbésí ayé rẹ̀ yóò dá lé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Mátíù 6:33; 16:24; Lúùkù 8:1; Jòhánù 18:37.
Nípa fífi sùúrù dúró de ọkọ tàbí aya tó dáa láàárín àwọn olùjọsìn Ọlọ́run, àwọn tí ń ronú àtigbéyàwó ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú fífi ìfẹ́ Ọlọ́run sípò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí ìgbéyàwó túbọ̀ láyọ̀, kí ó sì túbọ̀ fini lọ́kàn balẹ̀.—Oníwàásù 7:8; Aísáyà 48:17, 18.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ojú-Ìwòye Bibeli: Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Yan Ìsìn Tiwọn Bí?” nínú Jí!, ti March 8, 1997, ojú ìwé 26 sí 27. Bákan náà, wo ojú ìwé 24 àti 25 nínú ìwé náà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́, tí Watchtower Bible and Tract Society of Pennsylvania, tẹ̀ jáde lọ́dún 1996.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Ìrànlọ́wọ́ Fáwọn Ìdílé Tí Ń Ṣe Ẹ̀sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Fún ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìdí, ọ̀pọ̀ tọkọtaya lóde òní ló ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn kan lè ti yàn láti fẹ́ ẹnì kan tí ń ṣe ẹ̀sìn mí-ìn. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló jẹ́ pé ẹ̀sìn kan náà ni wọ́n jọ ń ṣe níbẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ni wọ́n wá ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nígbà tí ẹnì kejì tẹ́wọ́ gba ọ̀nà ìjọsìn mí-ìn. Àwọn ipò mí-ìn lè wà tó ń fà á kí ìdílé máa ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́ ṣá o, ohun yòówù kó fà á, a kò gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó tàbí ká fojú tín-ín-rín rẹ̀, kìkì nítorí pé ohùn tọkọtaya ò ṣọ̀kan lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn. Ojú ribiribi ni Bíbélì fi ń wo ìjẹ́mímọ́ àti wíwà pẹ́ títí ìgbéyàwó, kódà nígbà tí tọkọtaya kì í báá jùmọ̀ ṣe ẹ̀sìn kan náà. (1 Pétérù 3:1, 2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi obìnrin náà sílẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:12) Bí tọkọtaya èyíkéyìí bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbádùn àlàáfíà nínú ìbátan onífẹ̀ẹ́ tó kún fún ọ̀wọ̀.—Éfésù 5:28-33; Kólósè 3:12-14; Títù 2:4, 5; 1 Pétérù 3:7-9.