Ojú Ìwòye Bíbélì
Bí A Ṣe Lè Yan Ẹni Tí A Óò Fẹ́
WỌ́N BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ OMIDAN KAN PÉ, “ǸJẸ́ O TIẸ̀ TI RONÚ RÍ NÍPA ÌGBÉYÀWÓ?” PÁRÁ TÓ MÁA DÁHÙN, Ó NÍ: “ṢÉ RÍRONÚ NÌKAN NI? ÀNÍ ỌKÀN MI Ò BALẸ̀.”
ÌDÁHÙN ṣàkó obìnrin yìí kò ṣàìsọ púpọ̀ fún wa nípa bí ọ̀ràn ìfẹ́ àti níní alábàárò ti ka àwọn kan láyà tó. Ọ̀pọ̀ ló ka rírí ọkọ tàbí aya fẹ́ sóhun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kárí ayé, ṣe ni onírúurú àjọ kàn ń dìde lọ́tùn-ún lósì tí iṣẹ́ wọ́n jẹ́ ríran àwọn tí ń wá àfẹ́sọ́nà lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n o, níbi púpọ̀ láyé, iye ìgbéyàwó tó ń forí ṣánpọ́n pọ̀ ju iye tó ń kẹ́sẹ járí lọ.
Ní àwọn ilẹ̀ tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé, àwọn èèyàn ló máa ń fúnra wọn wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Àmọ́, láwọn ibì kan ní Éṣíà àti Áfíríkà, àṣà bíbáni wá ẹni tí a óò fẹ́ ni wọ́n ṣì ń lò. Èyí ó wù kó jẹ́, a ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn yìí. Lára àwọn ìpinnu téèyàn ń ṣe láyé, tó lè mú ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́ wá, ṣàṣà ni eléyìí tó wúwo bíi ti ìgbéyàwó. Ìgbéyàwó onífẹ̀ẹ́ lè jẹ́ kí ayé èèyàn rójú, kó sì tòrò. Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, ìgbéyàwó òní-eré-ọ̀la-ìjà lè máa fa ẹ̀dùn ọkàn àti másùnmáwo ṣáá.—Òwe 21:19; 26:21.
Gẹ́gẹ́ bíi gbogbo èèyàn, àwọn Kristẹni tòótọ́ fẹ́ kí ìgbéyàwó wọn mú ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wá bá wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n tún fẹ́ láti máa mú inú Ọlọ́run dùn àti láti máa bọlá fún un. (Kólósè 3:23) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá àti Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbéyàwó, ó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun táa nílò gan-an àti ohun tó dára jù lọ fún wa. (Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24; Aísáyà 48:17-19) Pẹ̀lúpẹ̀lù, láti ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún téèyàn ti dáyé, iye ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ti rí pọ̀ jáǹrẹrẹ, àtèyí tó kẹ́sẹ járí àtèyí tó forí ṣánpọ́n. Ó mọ ohun tó gbéṣẹ́ àti ohun tí kò gbéṣẹ́. (Sáàmù 32:8) Nípasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó gbé àwọn ìlànà tó ṣe kedere, tó sì sọjú abẹ níkòó kalẹ̀, tó lè ran gbogbo Kristẹni lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Kí ni díẹ̀ lára ìlànà wọ̀nyí?
Má Wo Ìrísí Nìkan
Níbi táwọn èèyàn ti ń fúnra wọn yan ẹni tí wọn yóò fẹ́, ó lè jẹ́ pé wẹ́rẹ́ ni wọ́n bá àfẹ́sọ́nà wọn pàdé, tàbí kó jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ tàbí aráalé wọn ló mú wọn mọra. Ẹwà ara ló sábà máa ń ru ìfẹ́ sókè nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ ríra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tètè máa ń kó síni lórí gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, Bíbélì rọ̀ wá láti lajú sílẹ̀ dáadáa, ká má wo ìrísí nìkan nígbà táa bá ń ronú nípa ìgbéyàwó.
Ìwé Òwe 31:30 sọ pé: “Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.” Àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa “aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.” (1 Pétérù 3:4) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tí àfẹ́sọ́nà ní—àwọn ànímọ́ bí ìfọkànsìn Ọlọ́run àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run títí kan àkópọ̀ ìwà Kristẹni rẹ̀—ṣe pàtàkì gidigidi ju ẹwà ara lọ. Ó pọndandan láti ròólọ-ròóbọ̀ kí o tó dórí ìpinnu, kí o lè yan ẹni tó ní góńgó tẹ̀mí tí ìwọ náà ní, tó sì tún ń sapá láti fi èso tẹ̀mí Ọlọ́run hàn. Èyí yóò ṣe púpọ̀ láti mú kí ìgbéyàwó jẹ́ aláyọ̀.—Òwe 19:2; Gálátíà 5:22, 23.
‘Ṣègbéyàwó Kìkì Nínú Olúwa’
Níní góńgó àti ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú àfẹ́sọ́nà rẹ ṣe pàtàkì gan-an. Ìpèníjà ńlá ni ìgbéyàwó jẹ́, torí pé ó ń béèrè pé kí tọkọtaya ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nínú ìwà àti ìṣesí wọn. Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, bí góńgó ìwọ àti àfẹ́sọ́nà rẹ bá ti bára mu tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìyípadà wọ̀nyẹn yóò ṣe rọrùn tó.
Èyí jẹ́ ká rí ìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn Kristẹni níyànjú láti yẹra fún fífi “àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” (2 Kọ́ríńtì 6:14) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé fífẹ́ ẹni tí ẹ̀sìn rẹ̀ yàtọ̀, tí òye rẹ̀ nípa àwọn ìlànà Bíbélì sì yàtọ̀, lè dá wàhálà àti àìgbọ́ra-ẹni-yé sílẹ̀. Ìmọ̀ràn náà láti ‘ṣègbéyàwó kìkì nínú Olúwa’ mọ́gbọ́n dání. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Èrò Ọlọ́run ló gbé yọ. Àwọn tó bá hùwà ọlọgbọ́n nípa títẹ̀lé e yóò yẹra fún ọ̀pọ̀ ìdààmú àti ìṣòro tó ta kókó.—Òwe 2:1, 9.
Bíbáni Wá Ẹni Tí A Óò Fẹ́
Nípa àwọn ibi tí àṣà bíbáni wá ẹni tí a óò fẹ́ ṣì wà ńkọ́? Fún àpẹẹrẹ, ní gúúsù Íńdíà, àwọn kan díwọ̀n pé ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn ìgbéyàwó tó ń wáyé níbẹ̀, àwọn òbí ló ń ṣètò ẹni tí ọmọ wọ́n fẹ́. Yálà àwọn Kristẹni òbí tẹ̀ lé àṣà yìí tàbí wọn ò tẹ̀ lé e, jẹ́ ìpinnu kálukú. Bó ti wù kó rí, irú àṣà yẹn máa ń kẹ́sẹ járí bó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tẹ̀mí ló gbapò iwájú.
Àwọn tó fara mọ́ àṣà bíbániwá ẹni tí a óò fẹ́ sọ pé èyí jẹ́ kí ìpinnu tọwọ́ àwọn àgbàlagbà onírìírí wá. Kristẹni alàgbà kan ní Áfíríkà sọ pé: “Àwọn òbí kan gbà pé nítorí ọjọ́ orí àwọn ọmọ àwọn, àti nítorí pé wọn kò ní ìrírí, àwọn ò lè fi taratara gbára lé wọn pé wọ́n á ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa bí àfẹ́sọ́nà wọn ti dàgbà dénú tó nípa tẹ̀mí.” Òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò kan láti Íńdíà fi kún un pé: “Àwọn ọ̀dọ́ kò tíì ní ìrírí ayé, wọ́n sì lè fi ìwàǹwára ṣèpinnu.” Níwọ̀n bí àwọn òbí ti mọ ìwà ọmọ wọn ju ẹnikẹ́ni lọ, wọ́n gbà pé àwọn mọ nǹkan tẹ́lòmí-ìn ò mọ̀, tó lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn láti fọgbọ́n yan ohun tó dáa fọ́mọ àwọn. Síbẹ̀ á dáa kí wọ́n gba èrò ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin náà yẹ̀ wò.
Àmọ́ o, táwọn òbí bá gbójú fo àwọn ìlànà Bíbélì, ó lè jẹ́ orí wọn ni gbogbo rẹ̀ máa wá fàbọ̀ sí bí ìgbéyàwó náà bá kòṣòro lọ́jọ́ iwájú. Àwọn ìṣòro lè yọjú nítorí pé ó lè má ṣeé ṣe fáwọn àfẹ́sọ́nà náà láti mọ ara wọn dáadáa. Kristẹni kan tó jẹ́ bàbá ní Íńdíà sọ pé, nígbà tíṣòro bá sì dé, “ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ ni pé ẹjọ́ òbí àwọn ni.”
Ní ti àwọn Kristẹni òbí tí ń bá ọmọ wọn wá ẹni tí wọn yóò fẹ́, ó tún yẹ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà nísàlẹ̀ ikùn wọn. Ìṣòro máa ń dìde tó bá jẹ́ pé ohun ìní ti ara tàbí ìfẹ́ láti di olókìkí ló jẹ́ kí àwọn kan fẹ́ra. (1 Tímótì 6:9) Nítorí náà, ó dáa káwọn tí ń báni wá ẹni tí a óò fẹ́ béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé: ‘Ǹjẹ́ ètò tí mo ṣe yóò mú kí ayọ̀ àwọn méjèèjì kún, kí ipò tẹ̀mí wọn sì túbọ̀ dáa sí i? Àbí, ṣé kìkì nítorí kí ìdílé lè di ọlọ́lá àti ọlọ́là ni, tàbí torí àtiríjẹ nídìí ẹ̀ ni?’—Òwe 20:21.
Ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe kedere, ó sì ṣàǹfààní. Nígbà táa bá ń ronú nípa ẹni táa fẹ́ fẹ́, ìwà rere àti ipò tẹ̀mí àfẹ́sọ́nà náà ló gbọ́dọ̀ jẹ wá lọ́kàn gan-an, láìka àṣà táa tẹ̀ lé sí. Báa bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò mú ọlá wá fún Jèhófà Ọlọ́run, Olùdásílẹ̀ ètò ìgbéyàwó, tọkọtaya náà yóò sì gbé ìgbéyàwó wọn ka orí ìpìlẹ̀ tẹ̀mí tó dúró sán-ún. (Mátíù 7:24, 25) Èyí yóò fi kún ayọ̀ àti adùn ìgbéyàwó náà lọ́pọ̀lọpọ̀.