ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 8/8 ojú ìwé 9-10
  • O Lè Yan Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Yan Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kádàrá àti Òmìnira Láti Ṣe Ohun Tóo Bá Fẹ́
  • Àṣesílẹ̀ Làbọ̀wábá
  • Kí Ni Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Yóò Jẹ́?
  • Wíwádìí Kádàrá Ẹ̀dá
    Jí!—1999
  • A Ha Pinnu Ọjọ-Ọla Rẹ Nipasẹ Àyànmọ́ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìwọ Lo Máa Pinnu Bí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Ṣe Máa Rí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
  • Báwo Ni Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Yóò Ṣe Rí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 8/8 ojú ìwé 9-10

O Lè Yan Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ

AWALẸ̀PÌTÀN náà, Joan Oates, sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ka iṣẹ́ wíwò sí “àṣeyọrí pàtàkì tó gba làákàyè jákèjádò ayé ìgbàanì,” ṣe ni “àwọn wòlíì Hébérù bẹnu àtẹ́ lù ú.” Èé ṣe?

Bí àwọn orílẹ̀-èdè tó gbà pé àyànmọ́ ló ń pinnu ìgbésí ayé tilẹ̀ wà láyìíká wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì kò gbà rárá pé agbára kan lásánlàsàn ló ń darí ìgbésí ayé wọn. Nínú ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè náà, ó sọ fún wọn pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ . . . ẹnikẹ́ni tí ń woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí . . . olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀.”—Diutarónómì 18:10, 11.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò nígbàgbọ́ nínú àyànmọ́, tí wọn kò sì tọ awòràwọ̀ lọ, síbẹ̀ ọkàn wọn balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Kátólíìkì náà, Théo, táa kọ lédè Faransé ń ṣàlàyé ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀, ó sọ pé orílẹ̀-èdè yẹn gbà gbọ́ pé “agbára kan lásánlàsàn kọ́ ló ń darí èèyàn àti ayé. Ọlọ́run ní ète tí ó fi dá ènìyàn.” Kí ni ète yìí?

Kádàrá àti Òmìnira Láti Ṣe Ohun Tóo Bá Fẹ́

Ọlọ́run ṣèlérí àlàáfíà àti aásìkí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí wọ́n bá ṣègbọràn sáwọn òfin rẹ̀. (Léfítíkù 26:3-6) Ní àfikún, wọ́n ń wọ̀nà fún Mèsáyà tí yóò fi àwọn ipò òdodo lélẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà, orí 11) Àmọ́ o, a ò ní sọ pé tìtorí pé Ọlọ́run ṣèlérí nǹkan wọ̀nyí, kí olúkúlùkù wá jókòó gẹlẹtẹ máa wòréré ayé. Dípò ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a sọ fún wọn pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.”—Oníwàásù 9:10.

Òmìnira láti ṣe ohun tóo bá fẹ́ ni ọ̀ràn yìí dá lé. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lómìnira láti sin Ọlọ́run, kí wọ́n sì pinnu ohun tí ọjọ́ ọ̀la wọn yóò jẹ́. Ọlọ́run ṣèlérí fún wọn pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ẹ̀yin kì yóò bá kùnà láti ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ mi, èyí tí mo ń pa fún yín lónìí, láti lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín àti láti lè máa fi gbogbo ọkàn-àyà yín àti gbogbo ọkàn yín sìn ín, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò pèsè òjò fún ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀, òjò ìgbà ìkórè àti òjò ìgbà ìrúwé, ní tòótọ́, ìwọ yóò sì kó ọkà rẹ jọ àti wáìnì dídùn rẹ àti òróró rẹ.” (Diutarónómì 11:13, 14) Ọlọ́run bù kún Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ṣègbọràn.

Gẹ́rẹ́ kí wọ́n tó wọ ilẹ̀ tó ṣèlérí fún wọn, Ọlọ́run gbé yíyàn kan kalẹ̀ níwájú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì: “Wò ó, mo fi ìyè àti ire, àti ikú àti ibi, sí iwájú rẹ lónìí.” (Diutarónómì 30:15) Ọjọ́ ọ̀la kálukú sinmi lórí àwọn ìgbésẹ̀ tó bá gbé àti àwọn ìpinnu tó bá ṣe. Sísin Ọlọ́run túmọ̀ sí ìyè àti ìbùkún, ṣùgbọ́n kíkọ̀ láti sìn ín túmọ̀ sí ìnira. Ṣùgbọ́n lónìí ńkọ́?

Àṣesílẹ̀ Làbọ̀wábá

Àwọn òfin àbáláyé kan wà tó gbé wa dè, àmọ́ tí wọ́n jẹ́ fún ire wa. Ọ̀kan lára ìwọ̀nyí ni òfin àṣesílẹ̀ làbọ̀wábá, tàbí, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ ọ́, “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Táa bá ń tẹ̀ lé ìlànà yìí, a ó mọ àwọn nǹkan kan pàtó tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Táa bá ń wa ìwàkuwà, táa sì ń sá eré àsápajúdé, àfàìmọ̀ kí ọkọ̀ wa máà jáàmù, èyí tí kì bá rí bẹ́ẹ̀ ká ní jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ la ń wakọ̀. Táa bá ń mu sìgá, àfàìmọ̀ kí a máà ní àrùn jẹjẹrẹ, èyí tí kì bá rí bẹ́ẹ̀ ká ní a ò mu sìgá. A ò jiyàn o, irú ìṣẹ̀lẹ̀ bí rògbòdìyàn táwọn apániláyà dá sílẹ̀, táa mẹ́nu kàn nínú àkọ́kọ́ lára ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí, lè má ṣẹlẹ̀ sí wa, kò sì bọ́gbọ́n mu láti jókòó máa gbéṣirò lé ṣíṣeéṣe pé yóò ṣẹlẹ̀. Àmọ́ o, yíyíjú sí àyànmọ́ kò lè ṣe wá láǹfààní kankan. Kò lè là wá lóye nípa ọjọ́ òní tàbí ọjọ́ ọ̀la. Gbígba èké gbọ́ kò lè mú ọjọ́ ọ̀la dá wa lójú. Bẹ́ẹ̀ náà ni sísọ pé àmúwá Ọlọ́run ni gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ kò lè pèsè irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀.

Kí Ni Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Yóò Jẹ́?

Ọjọ́ ọ̀la wa kò sí lákọọ́lẹ̀ kankan, ṣùgbọ́n ohun táa bá ṣe nísìnyí ni yóò pinnu rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bùn ni ìwàláàyè jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, síbẹ̀ Bíbélì fi hàn ní kedere pé a ní ipa pàtàkì láti kó ní pípinnu ọjọ́ òní wa àti ọjọ́ ọ̀la wa. Òtítọ́ náà pé yíyàn náà wà lọ́wọ́ wa, yálà láti mú inú Ọlọ́run dùn, tàbí láti bà á nínú jẹ́, fi hàn pé Ọlọ́run fún wa lómìnira dé àyè kan láti ṣe ayé wa bó ṣe wù wá.—Jẹ́nẹ́sísì 6:6; Sáàmù 78:40; Òwe 27:11.

Ìyẹn nìkan kọ́, léraléra ni Ìwé Mímọ́ tẹnu mọ́ ọn pé ohun tí ọjọ́ ọ̀la wa yóò jẹ́ sinmi lórí ìfaradà wa àti báa bá ṣe lo ayé wa, nǹkan wọ̀nyí kì bá sì kan ọjọ́ ọ̀la wa rárá ká ní a ti kádàrá rẹ̀ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 24:13; Lúùkù 10:25-28) Nítorí náà, báa bá yàn láti ṣègbọràn kí a sì ṣolóòótọ́ sí Ọlọ́run, irú ọjọ́ ọ̀la wo la lè máa wọ̀nà fún?

Bíbélì fi hàn pé aráyé ní ọjọ́ ọ̀la tó gbámúṣé. A ó sọ ilẹ̀ ayé di párádísè níbi tí àlàáfíà àti ààbò yóò ti jọba. (Sáàmù 37:9-11; 46:8, 9) Ọjọ́ ọ̀la yẹn dájú nítorí pé Ẹlẹ́dàá tí í ṣe Olódùmarè yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Aísáyà 55:11) Ṣùgbọ́n àyànmọ́ kọ́ ló máa pinnu bóyá a ó fi ìwàláàyè nínú Párádísè jíǹkí wa; a óò gbádùn rẹ̀ táa bá ń ṣe ìgbọràn sí ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ nísinsìnyí. (2 Tẹsalóníkà 1:6-8; Ìṣípayá 7:14, 15) Ọlọ́run ti fún wa ní òmìnira láti ṣe ohun táa bá fẹ́, ó sì rọ̀ wá pé: “Yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó.” (Diutarónómì 30:19) Èwo nìwọ́ máa yàn? Ọwọ́ rẹ ni ọjọ́ ọ̀la rẹ wà o, kò sí lọ́wọ́ àyànmọ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ọlọ́run ti pète ọjọ́ ọ̀la tó gbámúṣé fún aráyé onígbọràn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́