ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 2/8 ojú ìwé 4-7
  • Àwọn Bàbá—Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń di Àwátì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Bàbá—Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń di Àwátì
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Tó Wà Nínú Káwọn Òbí Méjèèjì Tó Ti Kọra Sílẹ̀ Jùmọ̀ Máa Tọ́mọ
  • Àwọn Òbí Tí Kò Ṣègbéyàwó
  • Ìdí Tí Àwọn Ọ̀dọ́kùnrin Fi Ń Sá
  • Èso Àjàrà Tí Kò Pọ́n
  • Àwọn Ìsáǹsá Bàbá Ọmọ—Ṣé Lóòótọ́ Ni Wọ́n Lè Bọ́?
    Jí!—2000
  • Àwọn Ìdílé Tí Kò Ti Sí Bàbá—Fífòpin Sí Ìṣòro Náà
    Jí!—2000
  • Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ohun Mẹ́rin Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀
    Jí!—2010
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 2/8 ojú ìwé 4-7

Àwọn Bàbá—Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń di Àwátì

“Mi ò rí i kí Mọ́mì àti Dádì jà rí tàbí kí wọ́n máa jiyàn. Ohun tí mo mọ̀ ni pé Dádì ò wọ́n nílé, ṣùgbọ́n lójijì, ó di àwátì lọ́jọ́ kan! Mi ò mọ ibi tí dádì mi wà títí di òní yìí. Mo mọ̀ pé kò sí àjọṣe kankan láàárín wa.”—Bruce.

“Lára àwọn ọmọ tí a jọ wà nílé ìwé, èmi nìkan ni kò ní òbí méjèèjì, tí n kò ní ilé kan pàtó . . . Mo sábà máa ń ronú pé mi ò rẹ́ni fojú jọ. Mo sábà máa ń ronú pé mo dá yàtọ̀.”—Patricia.

OHUN tó fa ìṣòro kí ìdílé máa wà láìsí bàbá ni ọ̀làjú tó dé tó fa kí àwọn èèyàn máa ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ ẹ̀rọ. Bí ṣíṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ ẹ̀rọ ti bẹ̀rẹ̀ sí fa àwọn ọkùnrin kúrò nílé ni ipa tí àwọn bàbá ń kó nínú ìdílé bẹ̀rẹ̀ sí mẹ́hẹ; àwọn ìyá ló wá ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú títọ́ ọmọ.a Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn bàbá ni kì í já ìdílé wọn sílẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, láàárín nǹkan bí ọdún 1964 sí 1966, iye àwọn tó ń jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà pọ̀ sí i. Àwọn nǹkan tó ń dènà ìkọ̀sílẹ̀, bí ẹ̀sìn, ipò ìṣúnná owó, àwọn ẹbí àti ará, wá bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ kélekèle. Ìmọ̀ràn tí àwọn amọṣẹ́dunjú, tó jẹ́ ohun tí wọ́n máa jẹ ni wọ́n ń wá, ń fún àwọn tọkọtaya wá jẹ́ kí wọ́n máa kọra wọn sílẹ̀ gan-an, nítorí wọ́n ń sọ fún wọn pé ìkọ̀sílẹ̀ ò ní ṣe àwọn ọmọ wọn ní nǹkan kan ṣùgbọ́n pé ó tilẹ̀ lè ṣe wọ́n láǹfààní. Ìwé Divided Families—What Happens to Children When Parents Part, tí Frank F. Furstenberg, Kékeré, àti Andrew J. Cherlin ṣe, sọ pé: “Ní Belgium, ilẹ̀ Faransé, àti Switzerland bí àwọn èèyàn [ṣe ń kọra sílẹ̀] ti di ìlọ́po méjì [bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1960], ṣùgbọ́n ó ti tó ìlọ́po mẹ́ta ní Kánádà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti Netherlands.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ìyá làwọn ọmọ sábà máa ń wà lẹ́yìn tí ìkọ̀sílẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn bàbá tó kọ ìyàwó wọn sílẹ̀ ṣì máa ń fẹ́ rí àwọn ọmọ wọn. Ojútùú kan tó wọ́pọ̀ ni jíjùmọ̀ máa bójú tó wọn. Síbẹ̀, ó yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn bàbá tí wọ́n kọ ìyàwó wọn sílẹ̀ ni kì í fi bẹ́ẹ̀ yọjú sí àwọn ọmọ wọn. Ìwádìí kan fi hàn pé ọmọ kan péré lára àwọn mẹ́fà ló máa ń rí bàbá wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì lára gbogbo àwọn ọmọ náà ni kò rí bàbá wọn fódindi ọdún kan!

Ìṣòro Tó Wà Nínú Káwọn Òbí Méjèèjì Tó Ti Kọra Sílẹ̀ Jùmọ̀ Máa Tọ́mọ

Kí tọkọtaya tí wọ́n ti kọra wọn sílẹ̀ tó lè ṣàṣeyọrí nínú jíjùmọ̀ máa tọ́mọ, wọ́n ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ gidigidi, kí wọ́n sì fọkàn tán ara wọn—ṣùgbọ́n àwọn ànímọ́ yìí sábà máa ń ṣọ̀wọ́n. Olùṣèwádìí Furstenberg àti èkejì rẹ̀ Cherlin sọ lọ́nà yìí pé: “Ìdí pàtàkì tí àwọn bàbá kì í ṣeé lọ wo àwọn ọmọ wọn mọ́ ni pé wọn ò fẹ́ kí nǹkan kan pa àwọn àti ìyàwó wọn àtijọ́ pọ̀ mọ́. Bákan náà ló jẹ́ pé ọ̀pọ̀ obìnrin kì í fẹ́ rí ọkọ wọn àtijọ́ sójú.”

Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ bàbá tí wọ́n ti kọ ìyàwó wọn sílẹ̀ ló sì máa ń lọ wo àwọn ọmọ wọn déédéé. Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn kì í sí pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn lójoojúmọ́, ó máa ń ṣòro fún àwọn kan láti hùwà bíi bàbá nígbà tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ọ̀pọ̀ ló ń yàn láti kúkú máa ṣe bí alájọṣeré, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbẹdẹmukẹ ni wọ́n máa ń fi gbogbo àkókò tí wọ́n bá jọ wà ṣe tàbí kí wọ́n máa ra nǹkan fáwọn ọmọ náà. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó ń jẹ́ Ari ṣàpèjúwe ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ tó bá lọ kí bàbá rẹ̀, ó sọ pé: “A kì í ní nǹkan pàtó kan táa fẹ́ ṣe, kò sófin ‘o gbọ́dọ̀ wọlé láago márùn-ún ààbọ̀.’ Fàlàlà ni mo máa ń yan kiri. Kò sọ́ràn má ṣe tibí, má ṣe tọ̀ún. Gbogbo ìgbà ni bàbá mi máa ń ra nǹkan fún mi.”—How It Feels When Parents Divorce, ìwé tí Jill Krementz ṣe.

Ó yẹ kí bàbá onífẹ̀ẹ́ mọ ‘bí a ṣe ń fi àwọn ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ rẹ̀.’ (Mátíù 7:11) Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ò ṣeé fi rọ́pò ìtọ́sọ́nà àti ẹ̀kọ́ tọ́mọ nílò. (Òwe 3:12; 13:1) Bí èèyàn bá wá sọ ara rẹ̀ di alájọṣeré tàbí àlejò dípò jíjẹ́ bàbá, ó dájú pé ìbátan bàbá sọ́mọ yóò forí sọgi. Ìwádìí kan sọ pé: “Ìkọ̀sílẹ̀ lè fọ́ ìbátan bàbá sọ́mọ yángá kó máà látùn-únṣe mọ́.”—Journal of Marriage and the Family, May 1994.

Ó máa ń dun àwọn ọkùnrin kan, tí inú sì máa ń bí wọn nítorí àìjẹ́ kí wọ́n dá sí ọ̀ràn àwọn ọmọ wọn—tàbí tí a ò kàn tilẹ̀ ṣú já wọn—ìdí nìyẹn tí wọ́n ṣe ń já ìdílé wọn sílẹ̀, tí wọn kì í náwó tó yẹ kí wọ́n ná lé wọn lórí.b (1 Tímótì 5:8) Ọ̀dọ́kùnrin kan tí inú bí sọ pé: “Mi ò rò pé nǹkan kan wà tí mo fẹ́ràn nípa bàbá mi. Kò tiẹ̀ ṣú já wa rárá, kò gbọ́ bùkátà kankan lórí wa, ìyẹn sì burú jáì.”

Àwọn Òbí Tí Kò Ṣègbéyàwó

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ tíyàá wọ́n lọ gboyún níta ló ń mú kí iye àwọn ọmọ tí kò ní bàbá máa pọ̀ sí i. Ìwé Fatherless America sọ pé: “Nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú gbogbo ọmọ tí wọ́n ń bí ní [Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà] báyìí ló jẹ́ ọmọ àlè.” Lára nǹkan bí 500,000 ọmọ táwọn ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ọdún mọ́kàndínlógún ń bí lọ́dọọdún, àwọn ọ̀dọ́ tí kò ṣègbéyàwó ló ń bí ìpín méjìdínlọ́gọ́rin lára wọn. Àmọ́ ìṣòro kárí ayé nìyí o, torí níbi gbogbo làwọn ọ̀dọ́mọdé ti lọ ń gboyún wálé láti ìta. Àwọn ètò tó ń kọ́ wọn nípa ọ̀nà máà lóyún tàbí àwọn tó ń kìlọ̀ fún wọn láti má ṣèṣekúṣe kò ṣe nǹkan gúnmọ́ láti yí àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn padà kí wọ́n yé ṣèṣekúṣe.

Ìwé Teenage Fathers, tí Bryan E. Robinson ṣe, ṣàlàyé pé: “Ẹ̀tẹ́ àti ojú tó máa ń tini táa bá gboyún láìtíì relé ọkọ, láàárín ọdún 1960 sí 1969, kò sí níbẹ̀ mọ́ nítorí ìwà kòsẹ́ni-máa-mú-mi tí mo bá ṣèṣekúṣe tàbí tí mo bá gboyún láìtíì relé ọkọ tó túbọ̀ ń peléke sí i láwùjọ. . . . Bákan náà ni ìpolówó ọjà, orin, sinimá, àti tẹlifíṣọ̀n ò yé fi ìṣekúṣe bọ́ àwọn èwe ìwòyí. Àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ní Amẹ́ríkà máa ń sọ fún àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà pé ìbálòpọ̀ jẹ́ ara fífi ìfẹ́ hàn, ó gbádùn mọ́ni, ó sì mìrìngìndìn, àmọ́ wọn kì í sọ bí ayé oníṣekúṣe ṣe máa ń rí.”

Ó jọ pé inú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń dùn sí ṣíṣèṣekúṣe, ṣùgbọ́n wọn ò mọ ohun tó ń tìdí ẹ̀ yọ. Gbọ́ díẹ̀ lára ohun tí wọ́n sọ fún òǹṣèwé Robinson, wọ́n ní: “‘Ọmọbìnrin yẹn ò jọ [ẹni tó lè lóyún]’; ‘Ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ la máa ń ní ìbálòpọ̀’; òmíràn ní, ‘Mi ò ronú pé èèyàn lè lóyún nígbà àkọ́kọ́ tó bá ṣe é.’” Ó dájú pé àwọn ọ̀dọ́ kan mọ̀ dáadáa pé ìbálòpọ̀ lè yọrí sí oyún. Ìwé Young Unwed Fathers sọ pé: “Lójú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin [tó ń gbé àárín ìlú], àmì pàtàkì tó ń fi bí wọ́n ṣe gbajúmọ̀ tó láwùjọ wọn hàn ni ìbálòpọ̀ jẹ́; wọ́n sì máa ń fi iye obìnrin tí wọ́n ti bá lò pọ̀ yangàn. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin ló ń jura wọn sílẹ̀ fọ́kùnrin kí wọ́n lè fún wọn láfiyèsí.” Nínú ìṣọ̀wọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ń gbé àárín àwọn ìlú kan, wọ́n lè máa fi èyí tí kò bá tíì bímọ lára wọn ṣẹlẹ́yà pé “kò bóbìnrin sùn rí”!

Wàá rí i pé ipò náà túbọ̀ ń bògìrì ni tóo bá wo èsì ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní California lọ́dún 1993 nípa àwọn ọmọ tó yẹ kí wọ́n ṣì máa lọ síléèwé ṣùgbọ́n tí wọ́n ti bímọ. A sì rí i pé àwọn tí ìdá méjì nínú mẹ́ta lára àwọn ọmọbìnrin náà lóyún fún kì í ṣe àwọn ọ̀rẹ́kùnrin tí kò tíì pé ogún ọdún bí kò ṣe àwọn ọkùnrin tó ti lé lógún ọdún! Èsì àwọn ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ogún ọdún tó ti bímọ láìrelé ọkọ ló jẹ́ pé òfin kà á léèwọ̀ láti bá irú àwọn ọmọ kékeré bẹ́ẹ̀ lò pọ̀—tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ fífi ìbálòpọ̀ fìtínà ọmọdé. Irú àṣà ìfiniṣèjẹ tó gbilẹ̀ bẹ́ẹ̀ ń fi bí àwùjọ ẹ̀dá ṣe bàjẹ́, tó sì bàlùmọ̀ tó lóde òní hàn.—2 Tímótì 3:13.

Ìdí Tí Àwọn Ọ̀dọ́kùnrin Fi Ń Sá

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò tíì pé ogún ọdún tí wọ́n ń di bàbá àbúrò kì í sábà gbé ẹrù iṣẹ́ títọ́ ọmọ wọn títí lọ. Ọmọdékùnrin kan tí ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lóyún sọ pé: “Mo kàn sọ fún un pé, ‘Ó dìgbóṣe’ ni.” Ṣùgbọ́n bí àpilẹ̀kọ kan ti sọ nínú ìwé Family Life Educator, “èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀dọ́ tó ti di bàbá àbúrò ló sọ pé àwọn fẹ́ kí ìbátan tímọ́tímọ́ wà láàárín àwọn àti ọmọ àwọn.” Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn ọ̀dọ́ tó ti di bàbá àbúrò láìṣègbéyàwó ti fi hàn, ìpín àádọ́rin lára wọn ló máa ń lọ wo ọmọ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Àpilẹ̀kọ náà wá ṣàlàyé pé: “Ṣùgbọ́n bí àwọn ọmọ náà ṣe ń dàgbà sí i ni wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ lọ wò wọ́n mọ́.”

Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan tó ti di bàbá ṣàlàyé ohun tó ń fà á, ó ní: “Ká ní mo mọ̀ pé ó máa le tóyẹn ni, mi ò tiẹ̀ ní ṣe é rárá.” Àwọn ọ̀dọ́ tó lọ́kàn akin tàbí ìrírí tí wọ́n lè fi gbé ẹrù jíjẹ́ òbí kò tó nǹkan. Ọ̀pọ̀ lára wọn ni kò tíì kàwé tó, tí wọn kò sì tíì níṣẹ́ lọ́wọ́ tí wọ́n lè fi gbọ́ bùkátà. Nítorí náà, dípò táwọn èèyàn yóò fi máa fojú aláṣetì wò wọ́n, wọ́n á yáa gbàgbé ọmọ náà. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ti di bàbá sọ pé: “Gbogbo nǹkan kàn dojú rú fún mi ni.” Òmíràn dárò pé: “Agbára káká ni mo fi ń gbọ́ bùkátà ara mi; mi ò mọ nǹkan tí ǹ bá ṣe ká ní ọ̀ràn ti gbígbọ́ bùkátà [tọmọ mi] tún wọ̀ ọ́.”

Èso Àjàrà Tí Kò Pọ́n

Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, àwọn Júù máa ń pa òwe kan báyìí pé: “Àwọn òbí ni ó jẹ èso àjàrà tí kò pọ́n, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ni eyín kan.” (Ìsíkíẹ́lì 18:2, Today’s English Version) Ọlọ́run sọ fún àwọn Júù pé kò yẹ kí ọ̀ràn rí bẹ́ẹ̀, kò yẹ kí wọ́n tún ṣe àwọn àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. (Ìsíkíẹ́lì 18:3) Àmọ́, ó jọ pé ẹgbàágbèje ọmọdé ni eyín ń kan lónìí nítorí “èso àjàrà tí kò pọ́n” tí àwọn òbí wọ́n jẹ—àwọn ni wọ́n ń jìyà ìwà àìdàgbàdénú, àìgbọ́n, àti ìjákulẹ̀ táwọn òbí wọ́n ní nínú ìgbéyàwó. Ẹ̀rí pọ̀ jaburata tó ń fi hàn pé àwọn ọmọ tí a ń tọ́ láìsí bàbá wọn níbẹ̀ wà nínú ewu púpọ̀. (Wo àpótí tó wà lójú ewé 7.) Èyí tó tiẹ̀ ń bani lọ́kàn jẹ́ jù lọ ni pé ọ̀ràn kí ìdílé kàn wà láìní bàbá yìí sábà máa ń ti ìran dé ìran ni—ó máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ tí kì í tán bọ̀rọ̀.

Ṣé àwọn ìdílé tí kò ti sí bàbá ò lè ṣàṣeyọrí láyé wọn ni? Ó tì o. Kódà, ìròyìn ayọ̀ ló jẹ́ láti mọ̀ pé ìṣòro àìsí bàbá nínú ìdílé lè kásẹ̀ ńlẹ̀. Àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn èyí yóò jíròrò bó ṣe lè ṣeé ṣe.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bẹ́ẹ̀ káyé tó dayé ọ̀làjú, àwọn bàbá ni àwọn ìwé tó ń kọ́ni bí a ṣe ń tọ́mọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ń darí ọ̀rọ̀ sí, kì í ṣe àwọn ìyá.

b Olùwádìí Sara McLanahan àti èkejì rẹ̀, Gary Sandefur sọ pé, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, “nǹkan bí ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọdé tó yẹ kí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí gbígba ìtìlẹyìn ni [ilé ẹjọ́ kì í pàṣẹ] pé kí wọ́n máa fún ní ìtìlẹyìn, ìdá mẹ́rin àwọn tí wọ́n sì pàṣẹ pé kí wọ́n máa fún ní ìtìlẹyìn ni kì í rí nǹkan kan gbà. Àwọn tó sì ń rí gbogbo iye tó tọ́ sí wọn gbà lára àwọn ọmọ náà kò tó ìdá mẹ́ta.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

EWU TÍTỌ́MỌ LÁÌSÍ BÀBÁ

Ewu ńlá wà nínú kí ọmọ máa dàgbà láìsí bàbá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí a fẹ́ sọ yìí lè ba àwọn kan tó bá kà á lọ́kàn jẹ́, mímọ àwọn ewu tó ń bá a rìn ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti dènà ìpalára rẹ̀ tàbí kó kàn tiẹ̀ dín in kù. A tún fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ẹ̀rí tí a kó jọ yìí kan gbogbo àwùjọ èèyàn kì í ṣe àwọn èèyàn kan pàtó ló kàn. Ọ̀pọ̀ ọmọ ló sì jẹ́ pé wọ́n dàgbà nínú ìdílé tí kò ti sí bàbá, tí wọn ò sì ní irú ìṣòro wọ̀nyí. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ wa tó kẹ́yìn yóò ṣe fi hàn, ohun tó lè báni dín àwọn ìṣòro tó lè wá ṣẹlẹ̀ yìí kù ni kí òbí tètè wá nǹkan ṣe sí i, kí wọ́n sì fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Nítorí náà, gbé díẹ̀ lára àwọn ohun tó lè jẹ́ ewu fún ọmọ tí kò ní bàbá yẹ̀ wò.

◼ Bíbá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe Ń Peléke Sí I

Ìwádìí fi hàn kedere pé ìṣòro àìní bàbá ń mú kí ewu bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe pọ̀ sí i. Ìwádìí kan fi hàn pé lára ẹgbẹ̀rún méjìléláàádọ́ta [52,000] ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe, “ìpín méjìléláàádọ́rin nínú wọn ló jẹ́ àwọn ọmọ tó ti ilé tí kò ti sí ọ̀kan lára àwọn tó bí wọn níbẹ̀ tàbí kó má tilẹ̀ sí àwọn òbí méjèèjì.” Ìwé Fatherless America sọ pé: “Ní pàtàkì, ewu ìṣẹ̀lẹ̀ bíbọ́mọdé ṣèṣekúṣe tó ń pọ̀ sí i láwùjọ wa jẹ́ ìyọrísí pípọ̀ tí àwọn bàbá tí kò ṣègbéyàwó ń pọ̀ sí i àti pípọ̀ tí àwọn bàbá tó tún ìyá ẹni fẹ́ ń pọ̀ sí i, àti ti àwọn ọ̀rẹ́kùnrin tí ń pọ̀ sí i, àti pípọ̀ tí àwọn ọkùnrin tí kò bá wọn tan tàbí tí wọ́n kàn jọ ń gbé ń pọ̀ sí i.”

◼ Títètè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ní Ìbálòpọ̀ Ń Peléke Sí I

Nítorí pé àwọn ọmọ tó wà nínú ìdílé olóbìí kan lè máà rí àbójútó àti ìtọ́sọ́nà òbí tó pọ̀ tó, àyè sábà máa ń gbà wọ́n láti hùwà pálapàla. Ìṣòro àbíìkọ́ sì tún lè jẹ́ ìdí kan. Iléeṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìlera àti Ìpèsè fún Aráàlú sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí kò ní bàbá gboyún ju àwọn tó ní lọ.”

◼ Ipò Òṣì

Ìwádìí kan tó wáyé nípa àwọn ọ̀dọ́bìnrin adúláwọ̀ tí kò tíì pé ogún ọdún ní Gúúsù Áfíríkà sọ pé ipò òṣì ló máa ń pọ́n àwọn tó ń di òbí láìṣègbéyàwó lójú jù lọ. Àwọn tó ṣe ìwádìí náà sọ pé: “Nínú nǹkan bí ìdajì irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀, kò dájú pé irú ọ̀dọ́ tó ṣẹlẹ̀ sí lè padà sílé ìwé.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìyá tí kò relé ọkọ máa ń di aṣẹ́wó tàbí kí wọ́n máa ta oògùn líle. Ọ̀ràn náà lè má sàn ju ìyẹn lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, “ìpín mẹ́wàá lára àwọn ọmọ tó ní òbí méjèèjì ni wọ́n jẹ́ òtòṣì [ní ọdún 1995], tí a bá fi wé ìpín àádọ́ta lára àwọn ìdílé tó jẹ́ ìyá nìkan ni wọ́n ní.”—America’s Children: Key National Indicators of Well-Being 1997.

◼ Pípa Wọ́n Tì

Nítorí pé ó di ọ̀ranyàn fún àwọn òbí kan tí wọ́n ń dá ẹrù ìdílé gbé láti gbọ́ bùkátà ara wọn, ńṣe ni àwọn ẹrù iṣẹ́ wọ̀nyí máa ń bò wọ́n mọ́lẹ̀ débi tí wọn ò ní lè lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ẹnì kan tó gba ìkọ̀sílẹ̀ sọ pé: “Mo ń lọ síbi iṣẹ́ lójúmọmọ, mo sì ń lọ sílé ìwé lálẹ́—mo ń tipa bẹ́ẹ̀ lo ara mi nílò omi òjò. Mo sì ń pa àwọn ọmọ mi tì.”

◼ Ó Máa Ń Sọ Wọ́n Dìdàkudà

Àwọn olùwádìí bí Ọ̀mọ̀wé Judith Wallerstein ti wá rí i pé ìkọ̀sílẹ̀ máa ń dá ọgbẹ́ tí kì í san bọ̀rọ̀ síni lọ́kàn, èyí sì ta ko ohun tí àwọn ògbógi kan sọ pé àwọn ọmọ kì í pẹ́ gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn òbí wọ́n bá kọra sílẹ̀. “Ó lé ní ìdá mẹ́ta lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n wà láàárín ọdún mọ́kàndínlógún sí ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tó jẹ́ pé àtiṣe nǹkan gidi kan ò jẹ wọ́n lọ́kàn láàárín ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn táwọn òbí wọ́n kọra sílẹ̀. Wọ́n kàn wà láyé ṣá bí ẹni tí kò ní ète pàtó . . . tí kò sì lólùrànlọ́wọ́.” (Second Chances, láti ọwọ́ Ọ̀mọ̀wé Judith Wallerstein àti Sandra Blakeslee) A ṣàkíyèsí pé àwọn ọmọ táwọn òbí wọ́n ti kọra wọn sílẹ̀ máa ń ro ara wọn pin, wọ́n máa ń sorí kọ́, wọ́n máa ń ya pòkíì, wọ́n sì máa ń bínú nígbà gbogbo.

Ìwé The Single-Parent Family sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìwádìí ló fi hàn pé àwọn ọmọkùnrin tí a bá tọ́ láìsí ọkùnrin tó jẹ́ àwòkọ́ṣe fún wọn nítòsí kì í fi bẹ́ẹ̀ dá ara wọn lójú nípa irú ẹ̀yà wọn, wọn máa ń ro ara wọn pin, àti pé, lọ́jọ́ iwájú, ó máa ń ṣòro fún wọn láti wọnú àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìṣòro tó ṣeé ṣe káwọn ọmọbìnrin ní nítorí pé kò sí ọkùnrin tí wọ́n lè fi ṣàwòkọ́ṣe nítòsí kì í sábà fara hàn àfìgbà tí wọ́n bá bàlágà tàbí lẹ́yìn náà, àti pé nígbà tí wọ́n bá dàgbà, ó máa ń ṣòro fún wọn láti wọnú àjọṣe pẹ̀lú ọkùnrin tàbí obìnrin, kí wọ́n sì kẹ́sẹ járí.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́