Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Àwọn Ìsáǹsá Bàbá Ọmọ—Ṣé Lóòótọ́ Ni Wọ́n Lè Bọ́?
“Nígbà tó sọ pé, ‘mo ti lóyún fún ẹ,’ àyà mi já pà. Ta ló máa gbọ́ bùkátà ọmọ náà? Mi ò tíì tẹ́rù ìdílé í gbé nígbà yẹn. Ńṣe ló dà bí pé kí ń sá lọ.”—Jim.a
ÌRÒYÌN kan láti Ilé Ẹ̀kọ́ Alan Guttmacher sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan àwọn obìnrin ọ̀dọ́langba . . . tó ń lóyún lọ́dọọdún.” Iye tó sì tó “ìpín méjìdínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ tí àwọn ọ̀dọ́langba ń bí ni wọ́n ń bí láìṣègbéyàwó.”
Láyé ìgbà kan, àwọn ọkùnrin máa ń ka gbígbọ́ bùkátà ọmọ tí wọn bá bí sí àìgbọ́dọ̀máṣe. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé Teenage Fathers ti sọ, “kéèyàn lóyún láìṣègbéyàwó kì í tún ṣe nǹkan ìtìjú tàbí ẹ̀sín mọ́ bíi ti [ìgbà kan].” Ní àwọn àdúgbò kan, àwọn ọ̀dọ́ tiẹ̀ lè máa fojú pàtàkì wo ọmọkùnrin tó bá bímọ láàárín wọn pàápàá! Síbẹ̀, ìwọ̀nba àwọn ọ̀dọ́kùnrin ló máa ń gbé bùkátà àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí fún àkókò gígùn. Àmọ́ nígbà tó bá yá ọ̀pọ̀ ló máa ń wábi gbà tàbí kí wọ́n sá lọ.b
Ṣùgbọ́n ṣé ọ̀dọ́kùnrin kan lè bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ìṣòro tí híhùwà pálapàla ń fà? Kò ṣeé ṣe, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì wí. Ó kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Gẹ́gẹ́ bí a ó ti rí i, ràbọ̀ràbọ̀ ìpalára tí ìṣekúṣe máa ń fà fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin àti ọ̀dọ́kùnrin kì í tán lára wọn. Àwọn ọ̀dọ́ lè yẹra fún irú àwọn àbájáde wọ̀nyí nípa ṣíṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó ṣe kedere náà pé ká yàgò fún ìṣekúṣe.
Kì Í Fi Bẹ́ẹ̀ Rọrùn Láti Fẹsẹ̀ Fẹ
Títọ́ ọmọ ń béèrè fífi àkókò, owó, àti òmìnira ara ẹni rúbọ lọ́nà tó ga. Ìwé náà, Young Unwed Fathers sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ kan kì í fẹ́ láti ‘gbọ́ bùkátà ẹlòmíì,’ tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá máa ná wọn lówó.” Bó ti wù kó rí, ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń jìyà ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ṣe ni àwọn ilé ẹjọ́ àti àwọn aṣòfin ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ túbọ̀ ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn àwọn ọkùnrin tí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ bùkátà àwọn ọmọ wọn. Tí wọ́n bá ṣáà ti lè fìdí ẹni tó jẹ́ bàbá ọmọ múlẹ̀ lábẹ́ òfin, wọ́n lè ní kí ọ̀dọ́mọkùnrin tó lọ́mọ náà san owó tí wọ́n óò fi gbọ́ bùkátà ọmọ náà fún ọdún tó wà níwájú, ó sì yẹ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ lọ́ràn-anyàn tàbí kí wọ́n lọ máa ṣe iṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú láti bàa lè rówó gbọ́ bùkátà yìí. Ìwé náà, School-Age Pregnancy and Parenthood sọ pé: “Bí ọjọ́ orí ọmọkùnrin kan bá ṣe kéré tó nígbà tó di òbí ni ìwé tó kà ṣe máa kéré tó.” Tó bá sì ń kùnà láti san àwọn owó ìgbọ́bùkátà náà, ò lè mú kó jẹ gbèsè rẹpẹtẹ.
Ó dájú pé, kì í ṣe gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin ni kò láàánú àwọn ọmọ tí wọ́n bí. Ọ̀pọ̀ máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èrò rere. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fi hàn, ìpín márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn bàbá ọmọ tó jẹ́ ọ̀dọ́langba ló máa ń lọ wo ọmọ wọn ní ọsibítù. Síbẹ̀síbẹ̀, kì í pẹ́ rárá tí ẹrù iṣẹ́ gbígbọ́ bùkátà ọmọ fi máa ń wọ ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn bàbá tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ náà lọ́rùn.
Ọ̀pọ̀ máa ń rí i pé àwọn ò ní ìmọ̀ tàbí ìrírí tí àwọn fi lè rí iṣẹ́ tó bójú mu. Tó bá sì yá, nítorí ìtìjú àìrówó fi sílẹ̀ mọ́, wọ́n á kúkú yọwọ́ nínú gbígbé ẹrù iṣẹ́ náà. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀dọ́kùnrin kan lè máa jẹ̀ka àbámọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. Ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ bàbá jẹ́wọ́ pé: “Nígbà mìíràn, mo máa ń rò ó pé kí ló lè ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ mi. . . . Inú mi kò dùn rárá pé mo fi í sílẹ̀, àmọ́ mi ò tiẹ̀ wá rí i mọ́ báyìí. Bóyá á wá mi kàn lọ́jọ́ kan.”
Ìpalára Tó Ń Ṣe fún Ọmọ
Àwọn bàbá tó sá tún lè máa bá ìtìjú yí gan-an—ìtìjú pé olúwarẹ̀ ṣe àìdáa sí ọmọ ẹni. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé, ọmọ kan nílò ìyá kan àti bàbá kan. (Ẹ́kísódù 20:12; Òwe 1:8, 9) Nígbà tí ọkùnrin kan bá já ọmọ ẹ̀ jù sílẹ̀, ńṣe ló fi ọmọ náà sí ipò tí onírúurú ìṣòrò ti lè bá a. Ìròyìn kan tó wá láti Iléeṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìlera àti Ìpèsè fún Aráàlú sọ pé: “Máàkì tí àwọn ọmọ tí ìyá nìkan tọ́ máa ń gbà nínú ìdánwò ọlọ́rọ̀ ẹnu àti ti ìṣirò kì í pọ̀ rárá. Kí àwọn ọmọ tí òbí kan dá nìkan tọ́ sì tó pé ọdún mẹ́wàá, wọ́n á ti máa gbòdo, wọ́n á máa hùwà lódìlódì, èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló sì máa ń ní àìsàn tó ti di bára kú àti àrùn ọpọlọ. Ní ti àwọn ọ̀dọ́langba àti àwọn tó ti dàgbà díẹ̀, tó bá jẹ́ pé ìyá nìkan ló tọ́ àwọn náà, ewu wà pé wọ́n lè di ọlọ́mọ kí wọ́n tó pé ogún ọdún, tàbí kí wọ́n sá fi ilé ẹ̀kọ́ gíga sílẹ̀, tàbí kí wọ́n wẹ̀wọ̀n, tàbí kí wọ́n máà ríṣẹ́ ṣe, kí wọ́n má sì reléèwé.”
Ìwé ìròyìn Atlantic Monthly wá sọ pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí tó túbọ̀ ń ga sí i táà ń rí láwùjọ àti èyí tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbé jáde, àwọn ọmọ tó wá láti inú ìdílé tó ti dàrú nítorí ìkọ̀sílẹ̀ àti àwọn ọmọ tí wọ́n bí láìṣègbéyàwó kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàṣeyọrí nínú àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe bíi ti àwọn ọmọ tó wà nínú ìdílé tó ní bàbá àti ìyá. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ tó ń gbé nínú ìdílé olóbìí kan má ṣe dáadáa tó wọn ní ìlọ́po mẹ́fà. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n máà bọ́ nínú ìṣòro ọ̀hún.”
Àmọ́, ká má gbàgbé pé ewu tí a ń sọ yìí dá lórí àbájáde tí a rí kó jọ nínú ìwádìí tí a ṣe lọ́dọ̀ àwùjọ àwọn èèyàn, kò túmọ̀ sí pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn táa bá ní ká sọ nípa ti ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ ọmọ ló jẹ́ pé láìka bí ipò nǹkan ṣe burú nínú ìdílé tí wọ́n ti wá sí, wọ́n máa ń di àgbàlagbà tó wúlò tó sì mọ nǹkan tí wọ́n ń ṣe. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí ọkàn bàbá kan tó pa ọmọ ẹ̀ tì lè máa nà án ní pàṣán gidigidi. Bàbá tí kò tíì di ọkọláya kan sọ nínú ìwé Teenage Fathers pé: “Ẹ̀rù ń bà mí pé mo ti [ba] ìgbésí ayé ẹ̀ [jẹ́] títí ayé.”
Ìpèníjà Tí Ṣíṣètìlẹyìn Ń Mú Wá
Kì í kúkú ṣe gbogbo bàbá ló máa ń sá. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kan mọ̀ pé ẹ̀tọ́ àwọn ni láti ṣe ojúṣe àwọn fáwọn ọmọ àwọn, wọ́n á sì fẹ́ fi tinútinú ṣèrànwọ́ láti tọ́ wọn. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń jẹ́ pé ó dùn ún sọ ni, kò dùn ún ṣe. Ó sì lè jẹ́ pé, òfin ò fi bẹ́ẹ̀ fún bàbá kan tí kò tíì di ọkọláya lẹ́tọ̀ọ́, tó jẹ́ pé ọmọbìnrin yẹn àti àwọn òbí ẹ̀ nìkan ló ni àṣẹ lórí bí àkókò tó máa lò pẹ̀lú ọmọ ẹ̀ ṣe gbọ́dọ̀ pọ̀ tó tàbí kéré tó. Jim táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Ńṣe lèèyàn máa fi gbogbo ìgbà wá bóo ṣe máa ráyè sọ nǹkan kan lórí ọmọ náà.” Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n lè ṣe àwọn ìpinnu tí ọ̀dọ́ tó jẹ́ bàbá náà kò ní fara mọ́ rárá, irú bí i kí ẹnì kan gbà á ṣọmọ tàbí pé kí wọ́n tiẹ̀ ṣẹ́ oyún ọ̀hún.c Ọ̀dọ́ kan tóun náà jẹ́ bàbá dárò pé: “Kò rọrùn fún mi láti jẹ́ kí wọ́n kàn gbé e fún àjèjì kan, àmọ́ kò sí nǹkan tí mo lè ṣe.”
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kan máa ń gbà láti fẹ́ ẹni tó lóyún fún wọn.d Òótọ́ ni pé ìgbéyàwó yóò yọ ọmọdébìnrin kan nínú ìtìjú díẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ kí àwọn òbí méjèèjì lè jọ tọ́ ọmọ náà. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ méjèèjì nífẹ̀ẹ́ ara wọn ní ti gidi bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n hu ìwà pálapàla. Bí ó ti wù kó rí, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé bí ọmọkùnrin kan bá sáà ti lè bímọ, ó ti wá tó ọkọ tàbí bàbá ṣe nìyẹn. Ìyẹn ò sì túmọ̀ sí pé ó ní agbára láti gbọ́ bùkátà ìyàwó àti tọmọ. Ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ìgbéyàwó tí wọ́n ṣe nítorí oyún kì í sábàá tọ́jọ́. Nítorí náà gbogbo ìgbà kọ́ ni sísáré kó wọnú ìgbéyàwó máa ń jẹ́ ojútùú tó mọ́gbọ́n dání.
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́mọkùnrin ló máa ń náwó sórí àwọn ọmọ wọn. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ níṣàájú, ó ń béèrè ojúlówó ìpinnu fún bàbá kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ láti máa gbọ́ bùkátà náà lọ fún àkókò gígùn, bóyá fún ọdún méjìdínlógún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ! Àmọ́ tó bá ń bá ìrànlọ́wọ́ náà lọ, ìyẹn lè yọ ìyá àti ọmọ náà kúrò nínú gbígbé ìgbésí ayé òtòṣì.
Ti nínípìn-ín nínú títọ́ ọmọ náà dàgbà ńkọ́? Eléyìí náà tún lè jẹ́ ìpèníjà kan tó ṣòro. Nígbà mìíràn, òbí àwọn méjèèjì lè máa bẹ̀rù pé wọ́n tún lè lọ ní ìbálòpọ̀ papọ̀, nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n lè máà fẹ́ kí wọ́n máa ríra wọn, kódà, wọ́n tiẹ̀ lè má fàyè gba rírí ara wọn rárá. Ọmọbìnrin náà sì lè pinnu pé òun ò fẹ́ kí ọmọ òun mojú ọkùnrin kan tí kì í ṣe ọkọ òun. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, tí wọ́n bá fún bàbá náà láyè láti máa bẹ ọmọ ẹ̀ wò déédéé, á bọ́gbọ́n mu kí àwọn ìdílé rí i dájú pé àwọn wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn nígbà ìbẹ̀wò náà, kí ìwà pálapàla mìíràn má bàa tún ṣẹlẹ̀.
Nítorí ìfẹ́ wọn láti túbọ̀ fà mọ́ àwọn ọmọ wọn sí i, àwọn bàbá kan tí kì í ṣe ọkọláya ti kọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè ṣe ìtọ́jú ọmọ, bíi wíwẹ ọmọ, fífún ọmọ lóúnjẹ, tàbí kíkàwé sí ọmọ wọn létí. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ti ní ìmọrírì fún àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì tilẹ̀ lè gbìyànjú láti kọ́ ọmọ ẹ̀ ní díẹ̀ lára àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Éfésù 6:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sàn kí bàbá kan fún ọmọ ní àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ díẹ̀ ju pé kó má sí rárá, síbẹ̀, kò lè rí bákan náà bí i ti bàbá kan tó wà pẹ̀lú ọmọ ẹ̀ lójoojúmọ́. Bí ìyá ọmọ náà bá sì wá lọ fẹ́ ẹlòmíràn, ọ̀dọ́ tó jẹ́ bàbá náà lè máà lẹ́nu ọ̀rọ̀ mọ́, bí ọkùnrin mìíràn bá wá ń gba ojúṣe rẹ̀ ṣe lórí títọ́ ọmọ rẹ̀.
Ó ṣe kedere, nígbà náà pé, ìbànújẹ́ ńláǹlà ni bíbímọ láìṣègbéyàwó máa ń yọrí sí, fún àwọn òbí àti ọmọ náà. Yàtọ̀ sí àwọn ìṣòro tó ń bá a rìn, ewu pípàdánù ojú rere Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó dẹ́bi fún ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ tún wà níbẹ̀. (1 Tẹsalóníkà 4:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè fara da ipò àìláyọ̀ kan, bíi oyún ọ̀dọ́langba, ó yẹ kó yéni kedere pé ohun tó ti dára jù lọ ni láti má tiẹ̀ ṣe ìṣekúṣe rárá. Ọ̀dọ́ tó jẹ́ bàbá kan jẹ́wọ́ pé: “Tóo bá ti lè bímọ pẹ́nrẹ́n láìtíì ṣègbéyàwó, ayé ẹ ò tún ní rí bákan náà mọ́ láé.” Láìsí àní-àní, ọ̀dọ́ tó jẹ́ bàbá kan lè ní láti fara mọ́ àwọn àbájáde ìṣìnà rẹ̀ fún gbogbo ìyókù ìgbésí ayé ẹ̀. (Gálátíà 6:8) Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìmọ̀ràn Bíbélì bọ́gbọ́n mu nígbà tó sọ pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣé Kéèyàn Bímọ La Fi Ń Mọ̀ Pọ́kùnrin Ni?” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, May 8, 2000. Fún ìjíròrò lórí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́bìnrin tó ń bímọ láìṣègbéyàwó, wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Dídi Ìyá Láìṣègbéyàwó—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ sí Mi?” nínú ìtẹ̀jáde ti Jí!, July 22, 1985 (Gẹ̀ẹ́sì).
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ìṣẹ́yún—Òun Ha Ni Ìdáhùn náà Bí?” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, March 8, 1995.
d Òfin Mósè sọ pé ọkùnrin tó bá bá wúńdíá kan sùn ní láti fẹ́ ẹ. (Diutarónómì 22:28, 29) Bí ó ti wù kó rí, ìyẹn ò sọ ìgbéyàwó di dandan, nítorí bàbá ọmọdébìnrin náà lè má fara mọ́ ọn. (Ẹ́kísódù 22:16, 17) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni lónìí kò sí lábẹ́ Òfin yẹn mọ́, èyí tẹnu mọ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó ṣe wúwo tó.—Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́, November 15, 1989.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ohun tó ti dára jù lọ ni láti má tiẹ̀ ṣe ìṣekúṣe rárá