Bí Àwọn Ọ̀dọ́langba Tó Di Ìyá Ọmọ Ṣe Lè Kojú Àwọn Ìṣòro Wọn
NÍGBÀ tí àwọn ọ̀dọ́langba bá lóyún, ńṣe ló máa ń mú kí wọ́n dojú kọ ìpinnu àwọn àgbàlagbà. Ọ̀dọ́langba kan to ti bímọ sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bí ẹni pé mo ti pé ọmọ ogójì ọdún. Mi ò gbádùn ìgbà kékeré mi.” Gbàrà tí ọmọbìnrin kan bá ti mọ̀ pé òun lóyún báyìí, ẹ̀rù lè máa bà á, kí àyà rẹ̀ má sì lélẹ̀ mọ́.
Bó o bá jẹ́ ọ̀dọ́langba, tó o sì ti lóyún, ó lè máa ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀. Àmọ́, jíjẹ́ kí ọkàn rẹ pami nítorí oríṣiríṣi èrò tí ń gbé ọ lọ́kàn sókè ò lè yanjú ìṣòro náà o. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.” (Oníwàásù 7:8; 11:4) Bí àgbẹ̀ kan bá dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí bí ojú ọjọ́ ṣe rí, ńṣe làwọn nǹkan tó yẹ kó ṣe á di ẹtì sí i lọ́rùn. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan di ẹtì mọ́ ọ lọ́wọ́ o. Bó pẹ́ bó yá, wàá pàpà jára mọ́ṣẹ́ tó já lé ẹ léjìká ni.—Gálátíà 6:5.
Kí láwọn nǹkan tó o lè ṣe? Àwọn kan lè sọ fún ọ pé kó o lọ ṣẹ́yún. Ṣùgbọ́n ẹni bá fẹ́ ṣe ohun tínú Ọlọ́run dùn sí ò gbọ́dọ̀ dán ìyẹn wò, nítorí Bíbélì sọ ọ́ ní kedere pé oyún ṣíṣẹ́ ò bá òfin Ọlọ́run mu. (Ẹ́kísódù 20:13; 21:22, 23; Sáàmù 139:14-16) Ẹ̀mí ọmọ inú ọlẹ̀, tó fi mọ́ èyí tí wọ́n lóyún ẹ̀ láìṣègbéyàwó, ṣeyebíye lójú Ọlọ́run.
Ti pé kó o kúkú fẹ́ ẹni tó o bímọ náà fún kẹ́ ẹ sì jùmọ̀ tọ́ ọmọ náà dàgbà ńkọ́? Ó ṣe kò ṣe, ìgbéyàwó ṣáà lè bàṣírí yín díẹ̀ kó sì gbà yín lọ́wọ́ ojútì. Àmọ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tó jẹ́ bàbá ọmọ náà bá tiẹ̀ gbà pé òun á jẹ́ kẹ́ ẹ jọ tọ́mọ náà dàgbà, fífẹ́ ara yín kì í sábà jẹ́ ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.a Pé ọ̀dọ́mọkùnrin kan lè fún obìnrin lóyún ò fi dandan sọ́ ọ di ẹni tó ní ọgbọ́n àti òye tó pọ̀ tó láti jẹ́ ọkọ rere kó sì tún ṣe ìṣe baba ọmọ . Bẹ́ẹ̀ sì ni kò túmọ̀ sí pé ó lè gbọ́ bùkátà aya àtọmọ. Ìyẹn nìkan tún wá kọ́ o, bí ẹ̀sìn tìẹ àti ti ọ̀dọ́mọkùnrin náà ò bá papọ̀, bíbá a ṣègbéyàwó á mú kó o ṣàìgbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Bíbélì tó sọ pé kó o ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Ìrírí ti jẹ́ ká lóye pé téèyàn bá kù gìrì wọnú ìgbéyàwó nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé, á wulẹ̀ dá kún ìrora àti ìjìyà ni nítorí pé ìgbéyàwó ọ̀hún lè máà pẹ́ kó tó tú ká.
Bó o bá kúkú yọ̀ọ̀da ọmọ náà fún àwọn tó lè gbà á ṣọmọ ńkọ́? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn sàn ju oyún ṣíṣẹ́ lọ, ṣùgbọ́n ó yẹ kó o rántí pé bó ti wù kí ipò tó o bára ẹ burú tó, o láǹfààní láti ṣe ìyá ọmọ rẹ.
Kíkojú Àwọn Ìṣòro Náà
Kò sírọ́ ńbẹ̀, dídá ọmọ tọ́ ò rọrùn. Àmọ́ ṣá o, nípa títẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì débi tí agbára rẹ bá gbé e dé àti níní ìgbọ́kànlé pé Ọlọ́run lè fún ọ ní okun àti ìtọ́sọ́nà bó o ti ń kojú àwọn ìṣòro náà, o lè kẹ́sẹ járí. Àwọn ìgbésẹ̀ díẹ̀ tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ tó o lè gbé nìwọ̀nyí.
● Tún Ara Rẹ Ṣe Lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Rántí pé ẹni bá ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ti dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, ó ti ṣẹ̀ sí ìlànà gíga tó fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà. (Gálátíà 5:19-21; 1 Tẹsalóníkà 4:3, 4) Nítorí náà, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó ṣe kókó tí wàá gbé ni pé kó o ronú pìwà dà kó o sì tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 32:5; 1 Jòhánù 2:1, 2) Ó lè máa ṣe ọ́ bíi pé o kò yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run ń ràn lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ti ṣèlérí pé òun á dárí jì wá, ó sì máa ń ran gbogbo àwọn tó bá ronú pìwà dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn lọ́wọ́. (Aísáyà 55:6, 7) Nínú ìwé Aísáyà 1:18, Jèhófà sọ pé: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò [tí wọ́n wúwo, tí wọ́n lágbára gan-an], a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì [a óò mú wọn kúrò pátápátá].” Bíbélì tún gba àwọn tí wọ́n bá ṣẹ̀ sí òfin Ọlọ́run níyànjú pé kí wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí táwọn alàgbà tí a yàn sípò nínú ìjọ lè fún wọn.—Jákọ́bù 5:14, 15.
● Jáwọ́ nínú ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn túmọ̀ sí pé kí ìwọ àti bàbá ọmọ ẹ lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Bẹ́ ẹ bá ní kẹ́ ẹ jọ máa fẹ́ra nìṣó láìṣe ìgbéyàwó, ẹ ó wulẹ̀ kóra yín sínú ewu àtimáa hùwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí ni. Má ṣe gbàgbé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin Ọlọ́run ò fàyè gbàgbàkugbà, ààbò wa ló wà fún. Nicole, tá a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, níran ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì sọ pé: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé òtítọ́ ni ohun tí Ọlọ́run sọ. Fún àǹfààní ara wa náà sì ni.”—Aísáyà 48:17, 18.
● Sọ fún àwọn òbí rẹ. Ẹ̀rù lè máa bà ọ́ lóòótọ́ pé inú á bí àwọn òbí rẹ sí ọ. Dájúdájú, inú á bí wọn, wọ́n á sì máa ṣàníyàn nípa rẹ nígbà tí wọ́n bá gbọ́ pé o ti lóyún. Wọ́n tiẹ̀ lè máa ronú pé àwọn làwọn ò ṣiṣẹ́ àwọn bí iṣẹ́, kí wọ́n sì máa dá ara wọn lẹ́bi pé àwọn làwọn fà á tó o fi hùwà tí kò tọ́. Àmọ́, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ làwọn òbí rẹ ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ìrora ọkàn tí wọ́n ní nítorí àṣemáṣe rẹ máa tó kúrò, ọgbẹ́ tó dá sí wọn lọ́kàn sì máa tó jinná. Àwọn ló bí ọ lọ́mọ, wọn ò lè sọ pé o burú kí wọ́n lé ọ fẹ́kùn pa jẹ, torí náà wọ́n ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ. Bí wọ́n bá rí i pé o ronú pìwà dà, ó dájú pé wọ́n á fẹ́ láti fara wé bàbá ọmọ onínàákúnàá, ìfẹ́ á sì sún wọn láti dárí jì ọ́.—Lúùkù 15:11-32.
● Má ṣe jẹ́ abaraámóorejẹ. Àwọn òbí, àwọn ẹbí àtàwọn ìbátan máa ń sábàá ṣe ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá lè ṣe láti gbárùkù tini. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí rẹ lè bá ọ wọ́nà bí wàá ṣe máa rí ìtọ́jú gbà. Bó o bá wá bímọ ọ̀hún tán, wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ béèyàn ṣeé tọ́jú ọmọ ọwọ́; wọ́n sì lè máa bá ọ gbé ọmọ náà. Nicole sọ nípa màmá ẹ̀ pé, “Èmi ni mo bímọ o, ṣùgbọ́n ó ṣe gudugudu méje láti bá mi tọ́jú ẹ̀.” Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ náà tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́, wọ́n lè bá ọ wá àwọn aṣọ ìtọ́jú ọmọdé àtàwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn tó lè wúlò fún ọ. (Òwe 17:17) Nígbà tí wọ́n bá ṣe ọ́ lóore, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì kó o sì “fi ara [rẹ] hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.” (Kólósè 3:15) Lílu àwọn èèyàn lọ́gọ ẹnu pé wọ́n ṣeun ò ní jẹ́ kí wọ́n ronú pé o ò mọrírì ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí ọ.
● Kọ́ béèyàn ṣeé ṣabiyamọ. Má ṣe dá gbogbo rẹ̀ dá àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ o. Ńṣe ni kó o bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ béèyàn ṣeé di ọ̀jáfáfá nídìí iṣẹ́ ọmọ títọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe máa tọ́jú ọmọ ẹ àti bí wàá ṣe máa tọ́jú ilé tí wàá sì máa wá òun tọ́mọ rẹ á jẹ. Iṣẹ́ abiyamọ ò rọrùn o. Ọ̀pọ̀ nǹkan lo ní láti kọ́ nípa irú oúnjẹ tó yẹ kọ́mọ jẹ, ìtọ́jú ọmọ tó bá ń ṣàìsàn àti àwọn nǹkan míì gbogbo tó jẹ mọ́ títọ́jú ọmọ. Ó sì dáa tó jẹ́ pé Bíbélì gba àwọn àgbà obìnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa gba àwọn ọ̀dọ́bìnrin níyànjú láti jẹ́ “òṣìṣẹ́ ní ilé.” (Títù 2:5) Láìṣe àníàní, màmá rẹ á kọ́ ọ ní àwọn ohun tó bá yẹ kó o mọ̀, àwọn míì tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà nínú ìjọ Kristẹni sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀.
● Máà náwó ní ìná àpà. Bíbélì sọ pé “owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.” (Oníwàásù 7:12) Ìtọ́jú ọmọ téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí máa ń náni lówó gan-an ni.
Bí ìjọba bá ṣètò ìrànwọ́ èyíkéyìí tó o lẹ́tọ̀ọ́ sí, kò burú bó o bá kọ́kọ́ jàǹfààní ẹ̀ ná. Àmọ́ ṣá, lọ́pọ̀ ìgbà ni ọmọbìnrin kan á ṣì máa wá ìrànlọ́wọ́ owó sọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ̀. Bọ́ràn tìẹ náà bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó tọ́ tó sì yẹ ni pé kó o máa ṣọ́wó ná. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tuntun ni wàá fẹ́ láti máa rà fọ́mọ ẹ, bóyá o kúkú lè dín iye owó tí wàá máa ná kù bó o bá ń lọ rajà lọ́dọ̀ àwọn tó ń ta bọ́-sí-kọ̀rọ̀.
● Kàwé díẹ̀. Òwe 10:14 sọ pé: “Àwọn ọlọ́gbọ́n ni ó ń fi ìmọ̀ ṣúra.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ Bíbélì ni ibí yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ohun tó ń sọ ò ṣaláì kan ẹ̀kọ́ ìwé nípa tara náà. Ó di dandan kó o kẹ́kọ̀ọ́ débi tó ò fi ní máa wojú kó o tó jẹun.
Ká sòótọ́, kì í ṣe ohun tó rọrùn ni pé kéèyàn máa relé ìwé nígbà tó ń tọ́mọ lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, béèyàn ò bá kàwé, òun àtọmọ tó bí lè wá máa gbọ́n ìyà mu bí omi, kí wọ́n máa dúró de ètò ìrànwọ́ ìjọba kí wọ́n tó rówó ná, kówó tó ń wọlé fún un máà tó nǹkan, kí wọ́n máa gbénú ilé hẹ́gẹhẹ̀gẹ kí ọmọ má sì róúnjẹ tó dáa jẹ. Nítorí náà, bó o bá rọ́gbọ́n ẹ̀ dá, máa kàwé ẹ lọ. Ìyá Nicole fi dandan lé e pé kí ọmọ òun parí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́, ìyẹn ló sì ran Nicole lọ́wọ́ láti rí ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbà tó fi di pé ó ń ṣiṣẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ lọ́yà láti fi pawọ́ dà.
Kí ní ṣe tó ò ṣèwádìí kó o bà a lè mọ irú àwọn ẹ̀kọ́ tó wà tó o lè kọ́? Bó bá nira jù fún ọ láti máa lọ sí yàrá ìkàwé, bóyá á lè ṣeé ṣe kó o máa kàwé nílé. Bí àpẹẹrẹ, o lè rí i pé àwọn ìwé téèyàn lè gbélé kà wúlò fún ọ gan-an.
O Lè Kẹ́sẹ Járí
Títọ́mọ láìṣègbéyàwó kì í rọrùn fún ọ̀dọ́bìnrin. Ṣùgbọ́n, o lè kẹ́sẹ járí! Bó o bá ní sùúrù, tó o sì múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá gbà, tó o sì gbẹ́kẹ̀ lé ìrànlọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run, o lè di òbí onífẹ̀ẹ́, tó tóótun, tó sì mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́. Ọmọ táwọn ìyá tí ò ṣègbéyàwó bá bí sì lè dàgbà di géńdé tó mọ̀wàáhù. Kódà, o tiẹ̀ tún lè rí bí ọmọ rẹ ṣe ń gbọ́ràn sí ọ lẹ́nu, tó ń fetí sí ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ ọ, tó sì dẹni tó ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Ìyẹn á sì mú kó o láyọ̀ gan-an.—Éfésù 6:4.
Bí Nicole ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà nìyí: “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, tó mú kí n lè borí gbogbo ìdíwọ́, inú mi dùn pé mo lè ran ọmọbìnrin mi kékeré lọ́wọ́ láti di onínúure, ẹni tó ń bọ̀wọ̀ fún àgbà àti ọ̀dọ́mọbìnrin tó ṣeé mú yangàn. Bí mo bá ń wò ó báyìí, màá sì máa rántí gbogbo àìsùn àti àìwo mi, ó sì tún máa ń mú kí ayọ̀ mi kún.”
Àmọ́ o, báwo ló ṣe yẹ káwọn àgbà máa hùwà sí àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n di ìyá àtàwọn ọmọ wọn? Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà tá a lè gbà ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè yẹra fún ìrora tó wà nínú lílóyún nígbà ọ̀dọ́langba?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó lè rí ìjíròrò nípa iṣẹ́ tó já lé àwọn ọ̀dọ́ tó di baba láìṣègbéyàwó lórí àtàwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ nínú “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” tá a tẹ̀ jáde nínú Jí! ti May 8, 2000, àti June 8, 2000.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Kékeré kọ́ ni ìṣòro táwọn ọ̀dọ́langba tó ti di ìyá ń dojú kọ bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kíkánjú ṣègbéyàwó nígbà téèyàn wà lọ́mọdé kọ́ ló máa yanjú ìṣòro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni lè ran àwọn ọ̀dọ́ tó bá ṣi ẹsẹ̀ gbé lọ́wọ́ láti padà jèrè ojú rere Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ó bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn òbí anìkàntọ́mọ parí ẹ̀kọ́ ìwé wọn