Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ Ká sì Dáàbò Bò Wọ́n
Ó MÁA ń bani lọ́kàn jẹ́ gan-an bó bá di pé ọmọdébìnrin kan, tóun fúnra ẹ̀ ṣì wà lábẹ́ ìtọ́jú òbí, lóyún láìṣègbéyàwó. Síbẹ̀, nílé lóko làwọn ọ̀dọ́langba ti ń lóyún, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí ọ̀ràn náà ò kàn lọ́nà kan. Ńṣe ni wàhálà tó máa ń tìdí ẹ̀ wá wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀rí tó jẹ́ ká mọ bí òfin Ọlọ́run tó ní ká “sá fún àgbèrè” ṣe tọ̀nà tó.—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Síbẹ̀ náà, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan à ń rí ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n ti kọ́ ní ìlànà Ọlọ́run ṣùgbọ́n tó yàn láti má ṣe fi ohun tó ti mọ̀ sílò. Ó lè lọ́wọ́ sí ìwà pálapàla kó sì di pé ó lóyún. Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí ni Kristẹni tòótọ́ á ṣe? Nígbà tí irú ọ̀dọ́ tó ṣi ẹsẹ̀ gbé bẹ́ẹ̀ bá fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn, ńṣe ló yẹ kí àwọn òbí rẹ̀ àtàwọn míì nínú ìjọ Kristẹni ràn án lọ́wọ́ kí wọ́n sì tì í lẹ́yìn tìfẹ́tìfẹ́.
Ẹ jẹ́ ká tún gbé ọ̀rọ̀ Nicole yẹ̀ wò. Àwọn òbí rẹ̀ ń tọ́ ọ dàgbà kó bàa lè di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, ńṣe ló dà bíi pé ọ̀fọ̀ ṣẹ àwọn òbí ẹ̀ nígbà tó gboyún. Síbẹ̀, Nicole rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì sọ pé: “Àwọn Kristẹni bíi tèmi á wá mi wá sílé, wọ́n á sì máa rọ̀ mí pé kí n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí n má sì jìnnà sí ètò Jèhófà.”
Rárá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fara mọ́ ìwà pálapàla o. Ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé nípa fífi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò, àwọn tó ṣi ẹsẹ̀ gbé lè “para dà.” (Róòmù 12:2) Wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó dájú pé Ọlọ́run máa ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n bá ronú pìwà dà. (Éfésù 1:7) Wọ́n tún mọ̀ pé bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé wọ́n lóyún ọmọ kan láìṣègbéyàwó, kì í ṣe ẹ̀bi ọmọ náà. Nítorí náà, dípò tí àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni á fi ka irú ọmọ bẹ́ẹ̀ sí àṣìbí, wọ́n á fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, àánú àti inúure hàn sí i bí wọ́n á ṣe fi hàn sí ọmọ èyíkéyìí mìíràn nínú ìjọ.—Kólósè 3:12.
Ìyá kan tó ń dá ọmọ rẹ̀ tọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó tètè gba àwọn ohun tó ń kọ́ nínú Bíbélì gbọ́, ó sì ṣe ìyípadà pípabanbarì nínú ìgbésí ayé ẹ̀. Ó sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí pé: “Gbogbo wọn fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí èmi àtàwọn ọmọ mi. Bí mo bá nílò oúnjẹ, aṣọ àti owó, wọ́n máa ń fún mi. Nígbà tí mo tóótun láti máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n máa ń bá mi gbé ọmọ mi. Wọ́n ṣe gbogbo ohun tó wà ní agbára wọn láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà.”
Bá A Ṣe Lè Kòòré Ẹ̀
Síbẹ̀, ó sàn fíìfíì pé ká ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè kòòré irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ kó tiẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ rárá. Ìdí nìyẹn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń wá bí wọ́n á ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ gbilẹ̀ nínú ìdílé káwọn ọmọ sì máa gbé ní ìrọwọ́ rọsẹ̀. Dípò kí wọ́n wulẹ̀ máa dọ́gbọ́n fi àrùn éèdì tàbí oyún dẹ́rù ba àwọn ọ̀dọ́, ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí máa ń kọ́ wọn láti ní ìfẹ́ tòótọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run àti fún àwọn òfin rẹ̀. (Sáàmù 119:97) Wọ́n gbà gbọ́ pé kò yẹ kéèyàn fi ohun tó bá yẹ káwọn ọmọ mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ pa mọ́ fún wọn. Pàtàkì jù lọ ibẹ̀ ni pé wọ́n gbà gbọ́ pé láti ìgbà ọmọ ọwọ́ ló ti yẹ kí wọ́n kọ́ àwọn ọmọdé ní àwọn ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì. (2 Tímótì 3:15) Wọ́n máa ń rí ìtọ́ni gbà déédéé nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò. Àmọ́ ṣá o, a tún ń rọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ òbí láti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra wọn. A ti pèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ bí Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ tó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni nípa ìwà híhù.a
Títẹ̀ lé àwọn ìlànà tí kò gbọ̀jẹ̀gẹ́ tí Bíbélì fi lélẹ̀ nípa ìwà híhù fi gbogbo ara ta ko ìwà pálapàla táráyé ń gbọ́n mu bí omi. Ṣùgbọ́n ọ̀nà ìgbésí ayé tó lè gba àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin lọ́wọ́ wàhálà tó wà nídìí oyún ọ̀dọ́langba ni.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń fi inúure àti ìgbatẹnirò bá àwọn ìyá tí kò ṣègbéyàwó lò